Òṣèré tíátà ilẹ̀ wa Bukky Raji tí orúkọ ìtàgé rẹ̀ ń jẹ́ Aminatu papapa ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí gbogbo ọmọ orílẹ̀-ède Nàìjíríà pé kí wọn ó dákun dábọ̀ fiyè dénú fiyè dékùn fiyè de gbogbo ara, kí wọn ó ṣe àforíjìn fún òun lórí bí òun ṣe ṣe ìpolongo ìbò fún Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu lọ́dún 2023.
Nínú fọ́nrán kan tó fi sí ojú òpó Oyinmomo lórí ìkànnì Youtube ni Bukky Raji ti ṣe àlàyé pé ọrọ̀ ajé ni ìpolongo ìbò tí òun ṣe fún Tinubu nígbà náà, òun kò rò ó jinlẹ̀ rárá. Ó wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí gbogbo ọmọ Nàìjíríà pàápàá àwọn tí ọ̀nà ìjẹ wọn ti dàrú kí wọn ó ṣe àforíjìn fún òun.
Aminatu papapa wí pé òun gé ìka àbámọ̀ jẹ lórí ìpolongo tí òun ṣe náà nítorí pé òun kò mọ̀ pé ìnira ni ìṣejọba Tinubu yóò mú bá aráàlú.
Ó wí pé òun gan-an fara gbá nínú ìnira náà nítorí pé ìrẹsì ni òun ń tà, nígbà tí ààrẹ àná; Muhammadu Buhari ti ẹnu ìloro ni òun ṣe wò ó pé Tinubu ni yóò ṣí ẹnu ìloro náà nítorí pé ọmọ Yorùbá ni.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé gbogbo ìrètí òun ló já sófo nítorí pé kò ṣí ẹnu ìloro ní èyí tó mú ìpalára bá òwò ìrẹ̀sì òun.
Yàtọ̀ sí èyí, gbogbo ìlérí tí wọn ṣe fún òun àti àwọn òṣèré ẹgbẹ́ òun, wọn kò mú ọ̀kankan ṣẹ nínú wọn, òfo lórí òfo ni gbogbo rẹ̀ já sí.
Kìí ṣe pé Tinubu kò fún wọn lówó rárá, Aminatu papapa wí pé ìwọnba owó tó jáde láti ọ̀dọ Tinubu, àwọn àgbààgbà òṣèré ni wọ́n há a mọ́wọ́ tí wọ́n sì kọ̀ láti fún àwọn ìsín nínú rẹ̀. Àwíjàre wọn ni pé àwọn ti wà nínú iṣẹ́ náà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.
Ṣáájú àkókò yìí ní ọdún 2023 ni Aminatu papapa ti fèsì sí fọ́nrán tí Adunni Ade ṣe níbi tó ti bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn òṣèré ẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n fi ogójì ọjọ́ ṣe ìpolongo ìbò fún Tinubu lórí ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàdọ́rùn-ún náírà péré.
Èsì tí Aminatu papapa fún Adunni Ade lọ́dún náà ni pé òun kò ṣe ìpolongo ìbò náà nítorí owó bíkòṣe nítorí ìfẹ́ àti ìrèti àmọ́ ní báyìí, ó ní òun kábàámọ̀ pé òun ṣe ìpolongo ìbò náà ó sì bèèrè fún ìdáríjìn ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo ọmọ Nàìjíríà.
Kìí ṣe Bukky Raji ni ẹni àkọ́kọ́ tí yóò sọ irú èyí, Alapinni òòṣà náà ti sọ nǹkan tó jọ mọ́ èyí ní ọ̀sẹ̀ bíi mélòó sẹ́yìn. Ohun tí òun náà sọ ni wí pé òun kábàámọ̀ lórí ìpolongo ìbò tí òun ṣe fún Tinubu.
Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Gbajúgbajà ìlúmọ̀ọ́nká òṣèré ilẹ̀ wa; Ganiu Nafiu tí orúkọ ìtàgé rẹ̀ ń jẹ́ Alápìnni Òòṣà ti tú pẹrẹpẹ́ẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ lórí bí ó ṣe kábàámọ̀ ṣíṣe ègbè lẹ́yìn Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ní ọdún 2015.
Alápìnni wí pé gbogbo àwọn tí àwọn ṣe àtìlẹ́yìn náà àti ìpolongo fún Tinunu lọ́dún náà lérò pé olùgbalà ni ó dé fún wọn tí yóò mú ayé rọrùn àmọ́ idakejì rẹ̀ ló já sí. Ó wí pé àwọn kò tíì rí kọ́bọ̀ owó ìpolongo náà gbà di àsìkò yìí.
Ó wí pé àti Tinubu àti ọmọ rẹ̀ Seyi, kò sí èyí tó rántí àwọn nínú àwọn méjéèjì, odidi oṣù méjì ni àwọn fi kóra jọ ṣe ìpolongo ìbò fún Tinubu, wọ́n wọ inú ọjà, wọ́n dé ojúlé sí ojúlé, Olaiya Igwe tún wẹ̀ lódò níhòòhò, síbẹ̀, Tinubu kò sanjọ́ fún àwọn.
Bákan náà ni ó bu ẹni àtẹ́ lu ohun tí Seyi Tinubu ṣe nípa sísan owó ilé ìwòsàn àwọn aláàárẹ̀ ní Àríwá. Alápìnni wí pé Seyi fi àwọn aláàárẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá sílẹ̀ lọ san owó ilé ìwòsàn wọn ní ilẹ̀ Hausa, èyi fi hàn pé Yorùbá ò já mọ́ nǹkan kan níwájú rẹ̀.
Tinubu yìí náà sì ni àwọn kan ń ṣe àtìlẹ́yìn fún lórí bí yóò ṣe wọlé ìbò ọdún 2027. Ọ̀rọ̀ yìí wà dá bíi gángan tó kọjú sí àwọn kan tó sì kọ̀yìn sí àwọn ẹlòmíràn.
Lára àwọn tó ń ṣègbè fún Tinubu lásìkò yìí ni Tompolo, ó wí pé:
Alága ilé iṣẹ́ ètò ààbò kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tantita ní ìpínlẹ̀ Delta; Ekpemupolo tí ìnagijẹ rẹ̀ ń jẹ́ Tompolo ti sọ̀rọ̀ lórí ìgbàgbọ́ àti ìrètí rẹ̀ nínú ìṣèjọba Bola Ahmed Tinubu.
Tompolo wí pé ẹni tó bạ mọ̀nà náà ló yẹ ká tẹ̀lé, kò sì sí ẹni méjì tó mojú Ògún Nàìjíríà lásìkò yìí ju Ààrẹ Bola Tinubu lọ. Ó wí pé digbí ni òun wà lẹ́yìn Tinubu tí òun sì ní ìgbẹ́kèlé nínú rẹ̀ pé òun ni yóò mú orílẹ̀-ede Nàìjíríà dé ilẹ̀ ìlérí.
Bí a bá pa obì, a ó yọ abidun ni, èyí ló mú kí Tompolo ó ṣe àlàyé àwọn àṣeyọrí tí ikọ̀ Tantita ti ṣe lábẹ́ ìjọba Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu. Ó wí pé ikọ̀ Tantita náà ti ṣẹ́gun àwọn tí wọ́n máa ń bẹ́ ọ̀pá epo rọ̀bì dé ààyè tó lápẹẹrẹ.
Lọ́gán tí àwọn bá sì ṣẹ́gun èyí láṣẹ̀ẹ́wọlẹ̀ ni ọrọ̀ ajé Nàìjíríà yóò tún gbèrú síi látàrí pé èyí tí àwọn tó ń bẹ́ ọ̀pá epo ń jí náà yóò kúrò níbẹ̀.
Tompolo ṣe ìlérí wí pé ìbò mílíọ́nù mẹ́wàá ni òun yóò fi jíṣẹ́ nínú ètò ìdìbò ààrẹ ọdún 2027.
Tọ̀, ọ̀rọ̀ rèé o, àwọn tí wọ́n ṣe ìpolongo ní ọdún 2023 ní àwọn gé ìka àbámọ̀ jẹ, àwọn kan ní ìgbà ọ̀tun ló dé fún àwọn, àwọn sì ṣetán àti ṣe àtìlẹ́yìn fún un ní ọdún 2027.
Dájúdájú, ohun tó kọjú sẹ́nìkan, ẹ̀yìn ló kọ sí ẹlòmíràn.




