Orin tí Eedris AbdulKareem kọ ti dá awuyewuye sílẹ̀ láárin àjọ NBC, Eedris Abdulkareem fúnra rẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka àti ìjọba àpapọ̀.
‘Tell your papa´ ni akọlé orin náà, àkóónú orin náà dá lé ìṣejọba Ààrẹ àdìbòyàn Bola Ahmed Tinubu.
Eedris Abdulkareem bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣejọba tó wà lóde pé ìwà jẹgụ́dú jẹrá ló gbé wọn wọ̀ bí ẹ̀wù, wọn kò bìkítà nípa àwọn tí wọ́n ń ṣe ìjọba lé lórí tí ebi ti fẹ́rẹ̀ lù pa.
Bákan náà ló sọ nípa ètò ààbò tó ti dẹnu kọlẹ̀, ọ̀wọ́ngógó epo àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.
Àjọ tó ń mójútó àgbéjáde àti ìkéde; NBC fi òfin de orin náà lórí gbogbo àwọn ìkànnì lọ́jọ́ kẹwàá, oṣù Igbe yìí, wọ́n ní orin Tell your papa náà lòdì sí òfin àgbéjáde.
Eedris Abdulkareem fi èrò rẹ̀ nípa Ìfòfindè náà hàn lójú òpó ìbánidọ́rẹ̀ẹ́ Instagram rẹ̀ pé ìjọba tó wà lóde ní ọdún 2004 tí òun bá wí pẹ̀lú orin tó pe àkọlé rẹ̀ ní Nigeria Jagajaga sàn ju èyí tó wà lóde lásìkò yìí lọ. Ó wí pé ìjọba àsìkò yìí kò ní àròjinlẹ̀, wọn kò mọ̀ ju kí wọ́n máa fi ọlá jiyọ̀ lọ.
Eedris Abdulkareem tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìjọba ìsìn yìí kóríra òótọ́ ọ̀rọ̀ wọn kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni ó yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò, ọ̀ràn ńlá ni kí èèyàn ó ṣe àtakò ìṣejọba ìsìn yìí.
Ẹgbẹ́ àwọn kọrinkọrin; PMA náà lòdì sí ìfofidè yìí, wọ́n ní èyí gan-an ni yóò mú kí àwọn èèyàn ó gbọ́ orin náà láti mọ ohun tó wà nínú rẹ̀ gan-an tí wọ́n ti fòfin dèé.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka náà bu ẹnu àtẹ́ lu Ìfòfindè yìí, ó wí pé èyí lòdì sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó fi ààyè gba fìfi èrò ẹni hàn. Bákan náà ló wí pé ìwà àṣìlò agbára gbáà ni èyí jẹ́.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka jẹ́ ìjọba lẹ́gọ̀ọ́ pé orin tí wọ́n fi òfin dè nìkan kò tó, ó yẹ kí wọn ó fi òfin de Eedris Abdulkareem fúnra rẹ̀ pé kò gbọdọ̀ kọrin mọ́, kí wọn ó tún gbé ilé iṣẹ́ tó gbé orin náà jáde lọ ilé ẹjọ́ kí wọ́n sì má gbàgbé láti kó gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ Eedris tí wọ́n jọ kọ orin náà kí ó le pé dáadáa.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka tẹ̀síwájú pé ìjọba alábòsí ni ìjọba tó bá ń gbọ́ ti àwọn tó ń yìn ín nìkan. Ó wí pé òun kò tíì gbọ́ orin náà gan-an àmọ́ ìfofindè náà jẹ́ ìwà àìláròjinlẹ̀ láti ọ̀dọ ìjọba àpapọ̀.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ síbi pé ìjọba kàn bá Eedros Abdulkareem ṣe ìpolongo orin náà ni nítorí pé Ìfòfindè náà ló mú kí àwọn èèyàn ó gbọ́ orin náà káàkiri ní èyí tí yóò mú owó tabua wọlé fún Eedris tó kọ ọ́.
Yàtọ̀ sí Ọ̀jọ̀gbọ́n Wole Soyinka, àwọn èèyàn náà bu ẹnu àtẹ́ lu ìfofindè yìí, ẹnìkan ẃ pé kò sí irọ́ nínú àkóónú orin náà.
Ẹlòmíràn náà wí pé nítorí pé orin náà fẹ ìdí ìjọba síta ni wọ́n ṣe fi òfin dè é nígbà tí ẹnìkan nạ́à wí pé ara ìjọba kọ òótọ́ ọ̀rọ̀.
Ohun tí Eedris Abdulkareem sọ pé ọ̀ràn ńlá ni kí èèyàn ó sọ̀rọ̀ tako ìjoba tó wà lóde nísìn yìí fara pẹ́ òótọ́ bí a bá wo ọ̀rọ̀ Hamdiyya Sidi Shariff.
Ta ni Hamdiyya Sidi Shariff?
Hamdiyya jẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin ẹni ọdún méjìdínlógún, ó jẹ́ ajìjàǹgbara lórí ìkànnì ayélujára. Ìpínlẹ̀ Sokoto ni ó ń gbé pẹ̀lú àwọn òbí rẹ̀. Àwọn ohun tó máa ń kọ nípa rẹ̀ náà ni ipò ààbò tó mẹ́hẹ ní ìpínlẹ̀ Sokoto àti àwọn àdojúkọ wọn, pàápàá àwọn obìnrin.
Ní ọjọ́ kan, Hamdiyya ń bọ̀ láti ibi tó ti lọ gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tí àwọn olè dá a lọ́nà, wọ́n lù ú lálùbami kí wọ́n tó tì í bọ́lẹ̀ láti inú kẹ̀kẹ́ maruwa lórí eré lẹ́yìn tí wọ́n ti gba gbogbo ohun tó wà lára rẹ̀.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló mú kí Hamdiyya ó tún tẹpẹlẹ mọ́ àwọn ohun tó máa ń kọ sí ojú òpó ayélujára rẹ̀. Èyí tó kó o sí wàhálà yìí ni fọ́nrán tó ṣe ní èyí tó ti ké sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto; Ahmed Aliyu láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ ààbò tó mẹ́hẹ ní ìpínlẹ̀ náà.
Ohun tó sọ nínú fọ́nrán náà ni wí pé Àwọn agbésùnmọ̀mí ń wọlé jáde láìsí ìdíwọ́ kankan, àrà tó wù wọ́n ni wọ́n ń dá tọ́sàn tòru sì ni wọ́n fi ń wọ ìlú wá ṣe ọṣẹ́ ọwọ́ wọn. Hamdiyya wí pé àwọn obìnrin tí wọ́n ti sọ di aláìlọ́kọ mọ́ ń jìyà kiri abúlé ni, bí wọ́n bá tún wá wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí olú ìlú ní àwọn ibùdó aláìnílé, níṣe ni wọ́n ń bá wọn sùn ní tìpátìkúùkú níbẹ̀’
Hamdiyya dárúkọ Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto; Ahmed Aliyu nínú fọ́nrán náà pé kó wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí.
Ẹ̀sùn tí ìjọba fi kan Hamdiyya ní ilé ẹjọ́ ìjọba ni pé ó bu ẹnu àtẹ́ lu ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní Sokoto ní èyí tó tàbùkù ìjọba ìpínlẹ̀ Sokoto. Láti inú oṣù Bélú ọdún tó kọjá ni ìgbẹ́jọ́ náà ti bẹ̀rẹ̀ tí kò sì ní àǹfààní àtilọ ilé.
Títí di àsìkò yìí, Hamdiyyah ṣì wà ní àtìmọ́lé lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tó ṣì ń retí ìyanu tí yóò ṣẹlẹ̀.
Ó jọ gáté kò jọ gáté, ṣé kò ti fi ẹsẹ̀ májéèjì lélẹ̀ gátegàte báyìí?
Ṣé ìjọba alágbádá la ń lò àbí ìjọba ológun? Ìdí ni pé kò sí ìyàtọ̀ láàrín ìṣejọba alágbádá yìí àti ti ológun.
Discussion about this post