Bí wọ́n bá sọ fún ẹ̀gbọ́n Joy pé omi ni yóò se ẹja jinná, yóò jiyàn rẹ̀. Àbúrò rẹ̀ tó finú tán jí ọmọ rẹ̀ gbé láti tà fún àwọn tí yóò lò ó.
Agbègbè Kwamba, Suleja ní ìpínlẹ̀ Niger ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀. Ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Ọ̀pẹ ọdún tó kọjá ni ìyá ọmọ oṣù mẹ́fà yìí fi ọmọ rẹ̀ ti Joy; ẹni tó jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ pé òun fẹ́ jáde.
Dídé tí yóò dé lálẹ́, kò bá ọmọ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni kò bá Joy tó fi ti ọmọ náà. Kò kọ́kọ́ bìkítà pé bóyá ó sáré jáde ni àmọ́ nígbà tí Joy kò gbé aago tí ilẹ̀ fi ṣú ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé ewu ń bẹ lóko lóńgẹ́.
Obìnrin yìí kàn sí àwọn ọlọ́pàá Suleja wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.
Ohun tó mú kí ìwádìí náà ó rọrùn ni àwọn ara ilé rẹ̀ méjì tí wọn kò sí nílé láti ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà, bí ọ̀kan nínú wọn ṣe dé ni àwọn ọlọ́pàá he é bíi ìgbín, òun ló júwe ibi tí Joy àti àwọn méjì yòókù wà.
Agbègbè Kubwa ní Abuja ni wọ́n gbé ọmọ oṣù mẹ́fà náà lọ láti tàá, Emmanuel Ezekiel jẹ́wọ́ pé àwọn ti ń gbìmọ̀pọ̀ tipẹ́ láti jí ọmọ náà gbé pẹ̀lú Joy, nígbà tí àwọn sì rí anfààní láti gbé e ni àwọn ṣe jọ jí ọmọ náà gbé lọ tà.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ Joy àti Favour, wọ́n mú àwọn ọlọ́pàá lọ sí ilé Patience Obana tí yóò bá wọn ta ọmọ náà, kò tíì rí ọmọ náà tà tí àwọn ọlọ́pàá fi mú un. Àlàáfíà sì ni ọmọ yìí wà.
Wasiu Abiodun; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Niger bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ pé àwọn mú Joy Nuwa; ẹni ogún ọdún tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Nasarawa, Emmanuel Ezekiel; ẹni ọgbọ̀n ọdún tó sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Niger, Favour James; ẹni ọdún márùndínlọ́gbọ̀n tó sì jẹ́ ọmọ ìlú Niger bákan náà àti Patience Obana; ẹni ọdún mẹ́tàlélógún tí òun sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Abuja lórí ẹ̀sùn ìjọ́mọgbé.
Kìí wá ṣe pé ẹ̀sùn ìjọ́mọgbé nìkan o, ọmọ títà ni iṣẹ́ Patience, Kubwa ní Abuja ló tẹ̀dó sí.
Àwọn ọlọ́pàá ti gba ọmọ náà padà lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì ti gbé e fún ìyá rẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Abiodun wí pé àwọn ti kó àwọn afurasí mẹ́rin yìí sí àtìmọ́lé, wọn yóò fi ojú ba ilé-ẹjọ́ láìpẹ́.
Ọ̀rọ̀ àwọn ajínigbé àti ajọ́mọgbé yìí ti gba àpérò nílǔ yìí, lónìí lọ́la bí ẹkún apọkọjẹ. Àwọn èèyàn kò le sùn fi orí lé òṣùká, bí ilẹ̀ ṣúni síta, inú fu àyà fu ni.
Ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tó fara pẹ́ èyí ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Kaduna ní oṣù Ògún ọdún tó kọjá yìí kan náà nígbà tí àwọn ajinigbe palẹ̀ àwọn èèyàn mẹ́sàn-án mọ́ ní ìpínlẹ̀ Kaduna.
Orin ‘káàbọ̀, ṣé dáadáa ló dé’ ni àwọn ajínigbé kọ pàdé ìyá àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjì tí wọ́n gbéra kúrò ní Èkó lọ sí Kaduna láàárọ̀ ọjọ́ náà tí wọ́n sì jí wọn gbé ní ìrọ̀lẹ̀ ọjọ́ kan náà.
Èèyàn mẹ́sàn-án ni wọ́n gbé lọ lápapọ̀, nínú wọn ni aya akọ̀ròyìn Muhammed Bashir àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjì wà.
Bashir fún ra rẹ̀ ló kéde lójú òpó ìbánisọ̀rọ̀ àjọ akẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọn ó gba òun ra òun kalẹ̀ o, ìsinmi ni ìyàwó àti àwọn ọmọ òun fẹ́ lọ lò lọ́dọ̀ ìyá àgbà ní Kaduna, wọ́n dé sí Kaduna láàárọ̀, àwọn ajínigbé sì gbé wọn lọ ní àsálẹ́.
Àwọn ọlọ́pàá àtí àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ti ta mọ́ra láti wá àwọn èèyàn náà.
Mélòó la ó kà nínú eyín adìpèlé? Tinú ọrún, tòde ẹ̀jọ.
Bí ojumọ́ ṣe ń mọ́ tí ọ̀yẹ̀ ń là ni àwọn èèyàn ń ké gbàjarè àwọn èèyàn wọn tí wọ́n jí gbé. Àbí ẹ̀yin ò gbọ́ nípa èyí tó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun nígbà tí wọ́n gbé odidi ìyàwó ọlọ́pàá?
Ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kìn-ínní ọdún yìí ( 2025) ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé yìí wáyé, tí arábìnrin náà sì gba ìtúsílẹ̀ lẹ́hìn tó ti lo ọjọ́ mẹ́jọ gbáko ní kàtà wọn.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ACP ìpínlẹ̀ Ogun; Múyiiwá Adejọbí sọ , àwọn kan lára àwọn ajínigbé náà fara gbọgbẹ́. Wọ́n sì rí onírúurú irin-iṣẹ́ gbà lọ́wọ́ wọn. Yàtọ̀ sí èyí, wọ́n gba owó tó tó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ lọ́wọ́ wọn, bí irú èyí tí wọ́n fi tọ́dẹ pàkúté fún wọn tí ọwọ́ fi tẹ̀ wọ́n.
Wọ́n ní yinniyinni, kẹ́ni ó ṣèmíì, èyí ló mú kí Ọ̀gá Ọlọ́pàá yán-ányán-án ní orílẹ̀ èdè yìí, IGP Káyọ̀dé Ẹgbẹ́tókun gbé òṣùbà ràbàǹdẹ̀ fún ikọ̀ àwọn Ọlọ́pàá tó ṣe iṣẹ́ ribiribi náà.
Ní báyìí, arábìnrin aya Odumosu ti wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.
Òmíràn mà tún ṣẹlẹ̀ o, àbí ẹ̀yin ò ríi gbọ́ pé àwọn agbanipa ya wọ inú ilé ìjọsìn ìjọ mímọ́ Christ Hebrew tó wà ní òdo ẹran, ìdíròkó, ìpínlẹ̀ Ogun tí wọ́n sì ṣekú pa Yomi Adetula, ẹni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́ta ni pásítọ̀ ìjọ náà.
Pásítọ̀ Yomi Adetula ni àwọn agbanipa yìí bá lọ́rọ̀, orí pẹpẹ ìwàásù ni pásítọ̀ Yomi wà tí àwọn aráabí fi wọlé sínú ilé ìjọsìn náà, wọ́n rọ̀jò ìbọn fún Pásítọ̀ Yomi, gbogbo ara rẹ̀ ni ọta ìbọn dálu. Lẹ́yìn tí wọ́n yìnbọn mọ́ ọn tán ni wọ́n tún fi ààké fọ́ orí rẹ̀ kí wọ́n le ní ìdánilójú pé ó ti kú.
Omolola Odutola; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ṣe àlàyé pé àwọn ọlọ́pàá tara ṣàṣà dé ilé ìjọsìn náà nígbà tí wọ́n gba ìpè pàjáwìrì. Inú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ ni wọ́n bá pásítọ̀ Yomi, gbogbo ara rẹ̀ ló lu fún ọta ìbọn tí wọ́n sì tún fi ààké fọ́ orí rẹ̀ kalẹ̀.
Àwọn ọlọ́pàá lé àwọn afurasí yìí àmọ́ ẹnu ìloro ni wọ́n gbà sá lọ.
Wọn kò ṣe àwọn ọmọ ìjọ tàbí ẹlòmíràn léṣe, pásítọ̀ Yomi nìkan náà ni wọ́n wá pa. Èyí ló kọ àwọn èèyàn lóminú pé kín ni pásítọ̀ le ṣe fún àwọn ẹni ibi yìí?
Ìwádìí ìjìnlẹ̀ fi hàn pé ọ̀gá ni pásítọ̀ Yomi nínú iṣẹ́ ìwádìí àti ìdáàbòbò. Wọ́n ní ó ń ṣe ìwádìí ẹ̀sùn kan tó níí ṣe pẹ̀lú olóṣèlú kan pàtàkì.
Kò sí ẹni tó le sọ pàtó bóyá ìwádìí tó ń ṣe yìí ló fa ikú rẹ̀ tàbí nǹkan mìíràn.
Àwọn ọlọ́pàá ti gbé òkú Yomi lọ sí ilé ìgbókùúsí Ilaro.
Ìjínigbé lọ́tùn-ún, ìpànìyàn lósì, orílẹ̀-èdè wa ń ṣàn fún ẹ̀jẹ̀. Kí Olódùmarè bojú àánú wo Nàìjíría.