Àjọ ẹ̀ṣọ́ aáàbò Onelga Security tó wà ní ìpínlẹ̀ Rivers ti ṣe ìkìlọ̀ fún gbogbo àwọn adáhunṣe pé kí wọn ó kúrò ní ìlú títí ọjọ́ méje òní.
Àwọn agbègbè tọ́rọ̀ kàn ni Ogba Egbema àti Ndoni. Wọ́n ní àwọn fún gbogbo àwọn adáhunṣe olóògùn tó wà ní agbègbè náà ní ọjọ́ méje kí wọn ó fi kúrò láàárín ìlú pàápàá àwọn tí wọn kìí ṣe ọmọ bíbí agbègbè náà.
Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò náà lwí pé adáhunṣe tó bá tàpá sí àṣẹ yìí yóò jẹ ìjìyà tó yẹ. Ó ṣe àlàyé pé àwon kò dá àṣẹ yìí pa, ọba ìlú náà fi ọwọ́ síi. Wọ́n ní tó fi dé orí àwọn ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba ló faramọ́ ìpinu yìí.
Àlàyé náà tẹ̀síwájú pé lẹ́yìn ọjọ́ méje òní, adáhunṣe tí àwọn bá mú yóò mọ̀ pé àwọn kò fi ọ̀rọ̀ náà seré, bákan náà ni bàbá onílé rẹ̀ náà yóò jẹ nínú ìyà náà.
Ibi tí ó gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ náà sí ni pé láìpẹ́, àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní máa mú gbogbo àwọn ọmọbìnrin tó bá wọ asọ tó fara sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn yóò máa kó ẹgba jáde báyìí, gbogbo ọkùnrin tó bá gbé sokoto sí bẹ̀bẹ̀rẹ́ ìdí ni àwọn yóò máa lù láìpẹ́ yìí.
Wọ́n ní kò sí ààyè fún ọmọbìnrin láti rìn ní títì pẹ̀lú aṣọ mọnbé, aṣọ tó faya sílẹ̀, èyí tó fìdí sílẹ̀ àti gbogbo aṣọ tí kò bá bá ti ọmọlúàbí mu.
Bákan náà ni kò sí ààyè fún àwọn ọkùnrin láti gbé irun kíkún tàbí gbé sokoto sí bẹ̀bẹ̀rẹ́ ìdí.
Èyí jẹyọ ní ìhà sí bí ọwọ́ àwọn agbófinró ṣe tẹ olórí ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ kan ní Ogba pẹ̀lú àwọn orí èèyàn. Àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tí àwọn náà jẹ́ ẹ̀ṣọ́ aláàbò náà kò gbẹ́yìn nínú ìṣe yìí.
Inú ọ̀sẹ̀ tó lọ yìí ni àwọn ọlọ́pàá mú wọn tí wọ́n sì wà ní àhámọ́ báyìí.
A kò le fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé lílé tí wọ́n fẹ́ le àwọn adáhunṣe agbègbè náà ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó ń lọ lọ́wọ́.
Ìròyìn mìíràn tó ń jà ràìnràìn lórí afẹ́fẹ́ ni ti ọ̀dọ́mọkùnrin kan alóyinlẹ́pọ̀n tó fún obìnrin mẹ́wàá lóyún láàrin oṣù mẹta.
Kódà, kọ́míṣọ́nà fún ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin bèèrè fún àmọ̀ràn lórí rẹ̀ nítorí ó kọjá bẹ́ẹ̀.
A gbọ́ pé Kọmíṣọ́nà fún ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin àti ètò àwùjọ ti ìpínlẹ̀ Anambra; Arábìnrin Ify Obinabo ti ké gbàjarè lórí ọ̀dọ́mọkùnrin kan ẹni ọdún méjìdínlógún tó fún àwọn ọmọdébìnrin mẹ́wàá lóyún láàrín oṣù mẹ́ta. Kọmíṣọ́nà wí pé ọ̀rọ̀ yìí ṣo òun lọ́wọ́ òun sì ń fẹ́ àmọ̀ràn.
Ọ̀dọ́mọkùnrin kan ẹni ọdún méjìdínlógún ní ìpínlẹ̀ Anambra ni ọ̀gá rẹ̀ lé e padà sí ọ̀dọ àwọn òbí rẹ̀ lẹ́yìn tó fún ọmọ rẹ̀ àti ọmọ iṣẹ́ rẹ̀ lóyún.
Iṣẹ́ ló lọ kọ́ lọ́dọ̀ ọ̀gá yìí àmọ́ kò lò ju oṣù Méji lọ tó fi fún ọmọ ọ̀gá àti ọmọṣẹ́ ọ̀gá lóyún.
Dídé tó dé padà sí abúlé rẹ̀, ọmọbìnrin mẹ́jọ mìíràn ló fún lóyún láàrín oṣù kan. Ìyá rẹ̀ wí pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti sú òun, òun bèèrè pé ṣé òògùn ni ó fi ń bá wọn lò ni àmọ́ ọmọ yìí wí pé òògùn kọ́, ó ní òun ṣe ìlérí fún wọn pé òun yóò fẹ́ wọn níyàwó lọ́jọ́ ìwájú ni.
Kọmíṣọ́nà ní ọ̀rọ̀ yìí ṣo òun lọ́wọ́ òun sì ń fẹ́ àmọ̀ràn àwọn aráàlú.
Bákan náà ni ọwọ́ wa tẹ ìròyìn kan tó sọ nípa ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ gbé kalẹ̀ fún afurasí tó ṣekú pa Comfort.
A gbọ́ pé Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Èkìtì ti dájọ́ ikú fún David Isaiah fún ẹ̀sùn ìpànìyàn. Ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni David, ẹ̀sùn tí ìjọba fi kàn án ni pé ó jí Comfort James gbé ó sì tún gba ẹ̀mí rẹ̀.
Saviour Daniel tí wọ́n jọ ṣekú pa Comfort ti kú sí àgọ́ ọlọ́pàá kí ìgbẹ́jọ́ tó parí. Adájọ́ pàṣẹ pé kí wọn ó sọ David sí ẹ̀wọn ọdún mọ́kànlélógún fún ẹ̀sùn ìjínigbé kí wọn ó sì so ó rọ̀ títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lára rẹ̀ fún ẹ̀sùn ìpànìyàn lẹ́yìn gbogbo atótónu.
Ọ̀kan nínú àwọn gbélépawó ilé ìtura Afrika ni Comfort, lọ́jọ́ náà, Comfort pe àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ní ilé ìtura náà pé wọ́n ti jí òun gbé o wọ́n sì ń bèèrè fún ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀run náírà owó ìtúsílẹ̀.
Irona; ẹni tó ni ilé ìtura náà ní àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ sọ fún òun pé Comfort kò padà dé láti ìgbà tí oníbàárà kan ti gbé e lọ. Irona ní òun fi tó àwọn agbófinró létí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.
Ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ Comfort ni àwọn ọlọ́pàá fi tọpinpin àwọn tó gbé e lọ, wọ́n mú àwọn ọlọ́pàá dé ibi tí wọ́n sọ òkú rẹ̀ sí, ìgbẹ́jọ́ sì bẹ̀rẹ̀.
Àwọn akẹgbẹ́ Comfort mẹ́fà ló jẹ́rìí síi nílé ẹjọ́ pé David ni ẹni tó wá gbé Comfort lọ lọ́jọ́ náà.
Àlàyé tí David fúnra rẹ̀ ṣe kò tako ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án yìí, ó ní lẹ́yìn tí òun àti èkejì òun; Daniel bá Comfort lò pọ̀ tán, àwọn so ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ méjéèjì àwọn sì fi ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ pe àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ pé kó bèèrè owó ìtúsílẹ̀. David ní nígbà tí owó kò jáde ti ó sì ti rí ojú àwọn ni àwọn ṣe da ásíìdì lée lórí tó sì kú, lẹ́yìn náà ni àwọn lọ ju òkú rẹ̀ nù.
Adájọ́ Olalekan Olatawura wí pé kò sí àriyànjiyàn mọ́ lórí ẹjọ́ náà, ẹni tó gbé panla ti jẹ́wọ́, ó gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ ó sì gbàá ládùúrà fún un pé kí Ọlọ́run ó ṣe ìdáríjì fún ẹ̀mí rẹ̀.
Discussion about this post