Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers tí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu júwe ilé fún; Siminalayi Fubara ti sọ̀rọ̀ nípa ìhà tó kọ sí ìpadàsípò náà báyìí. Ó wí pé bí wọ́n bá fi dá tòun nìkan, òun kò tilẹ̀ fẹ́ padà sí ipò náà mọ́ nítorí pé ẹ̀mí òun ti ṣí kúrò nínú ìṣèjọba náà àmọ́ àwọn tí wọ́n dúró ti òun lásìkò yìí tí wọ́n sì ń sa ipá wọn láti ríi pé òun padà sípò ni yóò mú kí òun ó padà bí àsìkò bá tó.
Níbi ayẹyẹ ìrántí Alàgbà Edwin Kiagbodo Clark tó wáyé ní àná; ọjọ́ Àìkú ni Fubara ti sọ èyí. Ilé ìjọsìn Royal house of grace ni ayẹyẹ náà ti waye.
Ó wí pé ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí òun máa sọ̀rọ̀ ní gbangba láti ìgbà tí wọ́n ti dá òun dúró nínú oṣù Ẹrẹ́nà. Fubara ṣe àlàyé pé kí àwọn èèyàn ó má ṣe sọ ayẹyẹ náà di àpéjọ olóṣèlú, kí wọn ó jẹ́ kó mọ ní ìrántí Alàgbà Edwin Kiagbodo Clark.
Fubara gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ síbi pé òun ní ìfọ̀kànbalẹ̀ lásìkò yìí ju ìgbà tí òun wà nípò Gómìnà lọ.
Ọ̀rọ̀ yìí jáde lẹ́yìn tí Nyesom Wike; ẹni tí òun àti Fubara jọ ní èdè àìyedè lásìkò gbogbo wàhálà náà wí pé inú òun dùn láti jẹ́ ọ̀kan nínù ìgbìmọ̀ ìṣèjọba ààrẹ Bola Ahmed Tinubu. Ìròyìn náà kà báyìí pé Mínísítà fún olú ìlú wa Àbújá, ẹni tó ti fìgbà kan jẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers; Nyesom Wike ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ kan pé inú òun máa ń dùn ni ní gbogbo ìgbà tí òun bá rántí pé àwọn èèyàn mọ̀ pé òun jẹ́ ọ̀kan gbòógì nínú ìṣejọba Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.
Bí éégún ẹni bá jóo re, orí a yá atọ́kùn ni ọ̀rọ̀ náà jẹ́ fún Nyesom Wike, gbogbo bí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ṣe ń dábírà lọ́tùn-ún, tó ń ṣe bẹbẹ lósì tí ìlú ń dùn yùngbà, tí eku ń ké bí eku, tì ẹyẹ ń ké bíi ẹyẹ, tí ọmọnìyàn náà sì ń fọhùn bíi ọmọnìyàn ló wú Wike lórí tó fi sọ pé inú òun dùn láti jẹ́ ọ̀kan nínú ìṣejọba yìí.
Nyesom Wike sọ ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn àbẹ̀wò tó ṣe sí àwọn ojú ọ̀nà tí ìjọba ń ṣe lọ́wọ́ ní Abuja lónìí, ọjọ́ Àbámẹta, ọjọ́ kẹwàá, oṣù Èbìbí. Ó wi pé ìgbé ayé onípele gíga ni ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti pèsè fún àwọn ará Abuja, ètò àti àlàkalẹ̀ Renewed hope; ìrètí ìsọdọtun tí ààrẹ̀ gbé kalẹ̀ ń ṣiṣẹ́ tí a rán an.
Ọ̀rọ̀ Wike tẹ̀síwájú pé òun ti sọ tẹ́lẹ̀ ṣáájú àsìkò yìí pé àìní aṣáájú rere ni ìṣòro wa ní ìlú yìí, ṣé ẹ̀yin náà wá ríi báyìí pé ibi tí aṣáájú rere bá ti wà, gbogbo mùtúmùwà ni yóò jẹ adùn ibẹ̀. Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti fi àpẹrẹ olórí rere lélẹ̀ ó sì ń wá ìdùnú fún gbogbo àwọn èèyàn.
Wike wí pé òun kò rí ìdí tí èèyan kan ó fi sọ pé ààrẹ Tinubu ò ṣe tó àfi bí ẹni náà bá fọ́ lójú inú tì kò tún fi tòde rína tàbí ki irú ẹni bẹ́ẹ̀ o jẹ́ alábòsí tí kò fẹ́ràn nǹkan ire. Wike wí pé inú òun dùn pé ìlérí ìgbé ayé ìrọ̀rùn tí àwọn ṣe, àwọn ti mú un ṣẹ.
Kò tán síbẹ̀ o, Nyesom Wike wí pé nígbà ti ààrẹ bá ń ṣe àjọyọ̀ ọdún kejì nípò, àwọn yóò sí aṣọ lójú éégún àwọn àkànṣe iṣẹ́ ribiribi tó ti gbé ṣe, lára rẹ̀ ni gbọ̀ngán ìgbàlódé Abuja àti ilé iṣẹ́ omi tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀.
Wike parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ síbi pé ní ọjọ́ àjọ̀dún ọdún kejì ààrẹ ni a ó rí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn àkànṣe iṣẹ́ tí ààrẹ ti gbé ṣe.
Ipò tí ìpínlẹ̀ Rivers wà báyìí:
Nǹkan kò fara rọ ní ìpínlẹ̀ Rivers lásìkò yìí, ìròyìn tó jáde ní àná tún lé kenkà, ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni wọ́n bá àwọn ẹ̀yà ara èèyàn lọ́wọ́ olórí ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ àti àwọn ẹmẹ̀wàá rẹ̀, ní èsì sí èyí, àwọn ẹ̀ṣọ́ aáàbò Onelga Security ti ṣe ìkìlọ̀ fún gbogbo àwọn adáhunṣe pé kí wọn ó kúrò ní ìlú títí ọjọ́ méje òní.
Àwọn agbègbè tọ́rọ̀ kàn ni Ogba Egbema àti Ndoni. Wọ́n ní àwọn fún gbogbo àwọn adáhunṣe olóògùn tó wà ní agbègbè náà ní ọjọ́ méje kí wọn ó fi kúrò láàárín ìlú pàápàá àwọn tí wọn kìí ṣe ọmọ bíbí agbègbè náà.
Olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò náà lwí pé adáhunṣe tó bá tàpá sí àṣẹ yìí yóò jẹ ìjìyà tó yẹ. Ó ṣe àlàyé pé àwon kò dá àṣẹ yìí pa, ọba ìlú náà fi ọwọ́ síi. Wọ́n ní tó fi dé orí àwọn ìgbìmọ̀ lọ́balọ́ba ló faramọ́ ìpinu yìí.
Àlàyé náà tẹ̀síwájú pé lẹ́yìn ọjọ́ méje òní, adáhunṣe tí àwọn bá mú yóò mọ̀ pé àwọn kò fi ọ̀rọ̀ náà seré, bákan náà ni bàbá onílé rẹ̀ náà yóò jẹ nínú ìyà náà.
Ibi tí ó gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ náà sí ni pé láìpẹ́, àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní máa mú gbogbo àwọn ọmọbìnrin tó bá wọ asọ tó fara sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn yóò máa kó ẹgba jáde báyìí, gbogbo ọkùnrin tó bá gbé sokoto sí bẹ̀bẹ̀rẹ́ ìdí ni àwọn yóò máa lù láìpẹ́ yìí.
Wọ́n ní kò sí ààyè fún ọmọbìnrin láti rìn ní títì pẹ̀lú aṣọ mọnbé, aṣọ tó faya sílẹ̀, èyí tó fìdí sílẹ̀ àti gbogbo aṣọ tí kò bá bá ti ọmọlúàbí mu.
Bákan náà ni kò sí ààyè fún àwọn ọkùnrin láti gbé irun kíkún tàbí gbé sokoto sí bẹ̀bẹ̀rẹ́ ìdí.
Ibo ni ọ̀rọ̀ yóò já sí?
Discussion about this post