Olùdíje sípò Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó lábẹ́ áṣíà ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nínú ètò ìdìbò tó kọjá lọ yìí ti padà sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Àṣé lóòótọ́ ni pé àjò kò dàbí ilé.
Dọ́kítà Abdul-Azeez Adediran tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Jandor ti fi ẹnu ara rẹ̀ kéde pé òun ti di ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC tọkàntara.
Ilé iṣẹ́ rẹ̀ tó wà ní Ikeja ló kó àwọn oníròyìn jọ sí tó sì ti sọ èyí di mímọ̀.
Ẹnu lọ́ọ́lọ́ yìí ni Jandor kọ̀wé fi ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ ní èyí tó gbé e kọlu Bode George.
Jandor ṣe àlàyé pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kò torò rárá, ó wí pé wọn kò rí rògbòdìyàn abẹ́lé àti ọdún 2023 yanjú di ìsìn yìí, ṣé àwọn yẹn ni yóò to ìlú?
Jandor fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé lẹ́yìn tí òun fi ọ̀rọ̀ náà lọ àwọn àgbààgbà òṣèlú ni wọ́n jẹ́ kí òun mọ̀ pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kò le so èso rere kankan, èyí ló mú òun dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tó káràmásìkí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀, ẹgbẹ́ tó ń jáwé olúborí lọ́wọ́lọ́wọ́, ẹgbẹ́ tó ní àfojúsùn àti ìwòye ọ̀la rere, ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Nígbà tí wọ́n bi í léèrè pé kí ló mú un kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC tẹ́lẹ̀ lọ sí PDP? Èsì tó fọ̀ náà ni pé ọ̀rọ̀ òun dàbí obìnrin tí kò tíì tọ́ ilé ọkọ méjì wò ni, kò le mọ èyí tó gbe òun.
Á jẹ́ pé òun tí Jandor fẹ́ ṣe nìyìí tó fi kọlu Bode George nítorí pé ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn ni Bode George ki ìpọnrí rẹ̀ fún un, a mú ìròyìn náà wá fún yín pé ‘Ọ̀kan nínú àwọn Ògúná gbòǹgbò tíí dátọ́ lẹ́nu ìgbín inú ẹgbẹ́ PDP; Olóyè Bọ̀dé George ti gbéná wo ojú Jandor tí í ṣe ẹni tí ó díje dupò gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó lábẹ́ áṣíà egbẹ́ òṣèlú PDP ní àkókò ètò ìdìbò tó kọjá. Bọ̀dé ní àbùkù ńlá ni fún òun pé irú Adeniran Ọlajide tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Jandor lè máa fi ẹ̀sùn kan òun lórí ọ̀rọ̀ ẹgbẹ́ PDP ní Ìpínlẹ̀ Èkó.
A hú u gbọ́ pé Jandor tó kúrò nínú ẹgbẹ́ PDP ní àìpẹ́ yìí fẹ́sùn àgàbàgebè Kan Olóyè Bọ̀dé George pé ó ń ṣe lòdì sí ọmọ oyè PDP. Ó ní Bọ̀dé George ń fi àtìlẹ́yìn rẹ̀ hàn fún ọmọ oyè sí ipò gómìnà nínú Ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn, ó sì ń yí àwọn ọmẹẹgbẹ́ lọ́kàn padà pé kí wọ́n má dìbò fún PDP.
Nígbà tí olóyè Bọ̀dé George ń fi ẹ̀hónú rẹ̀ hàn, tóun bá rí ti Jandor gbọ́, yóò mú kí òkìkí tí Jandor rò pé òún ni di yẹpẹrẹ lásán ni nílùú Èkó. Ó sọ eléyìí lánàá nígbà tó ń kópa nínú ètò kan lórí ẹ̀rọ rẹdiò 102.5 Fm ” Ọ̀rọ̀ tó ń lọ” lédè Gẹ̀ẹ́sì. Bọ̀dé pe Jandor ní ọ̀lẹ olóṣèlú, tí kò fi tọkàn-tara ṣe iṣẹ́ ìfẹ́ ẹgbẹ́ kankan rí.
Bọ̀dé sọ ọ́ débi pé :
‘ Mo ti pé ọmọ ọgọ́rin ọdún, ọmọ ọwọ́ sì ni Jandor tí kò tí ì kọjá àgbékọ́rùn roko. Ọjọ́ la bí àkàrà rẹ̀ tó fẹ́ máa bímọ ẹnu? Kí ló mọ̀ nípa ẹgbẹ́ yìí ( PDP!)? Ọmọ ọwọ́ tí kò tíì já lẹ́nu ọmú ni Jandor tó bá kan ọ̀rọ̀ òṣèlú.
Kí n sọ ọ́ ní pàtó, mo kà á sí àrífín àti àfojúdi gbáà! Ọmọ tí mo bí kì í ṣe ẹgbẹ́ rẹ̀ dànù dànù. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dà bí ìpèdè Látìn kan tí a mọ̀ sí *Infradig * nígbà tí a wà ní ilé-ẹ̀kọ́ girama, ” Èyí tí a lè túmọ̀ sí èkúté ilé tó fi àkọ̀ sílẹ̀, tó ń jẹ ọ̀bẹ tẹnu ẹni ló fẹ́ẹ́ gbọ́” – ( èrò tiwa)
Nínú àlàyé Olóyè George, ó ní Jandor kò ní òye nípa bí ẹgbẹ́ ṣe rí, síbẹ̀ wọ́n gbà á láàyè láti jẹ́ ọmọ oyè fún ipò gómìnà, èyí tó mú kí ojúgbà rẹ̀ nínú ẹgbẹ́ LP, ìyẹn Gbádébọ̀ Vivour-Rhode gbà láti yẹ̀bá, tó sì dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ alátakò – PDP rẹ̀.
Olòyè Bode George ní onítìjú òun tóun ò leè kọ ọ̀rọ̀ sí lẹ́nu ló mú Jandor wá, tó sì díje pẹ̀lú ẹnìkan tó gbọ́n, tó kàwé, tó sì ti Ìwọ̀ oòrùn Èkó tó ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́wàá wá. Ó ní ẹni náà fíírì Jandor bí ìgbà tí ẹgbàá fíírì oókan’
Ní báyìí tó ti tẹ́ ìfẹ́ inú rẹ̀, ǹjẹ́ yóò tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ Bode George?
*** *** *** *** *** *** *** *** *** **
Èyí wù mí ò wù ọ́ ni kò jẹ́ kọ́mọ ìyá méjì ó le fẹ́ obìnrin kan náà.
Nígbà tí àwọn kan ń kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni awon kan tun ń padà sínú ẹgbẹ́ náà.
Yàtọ̀ sí El-Rufai tó kúrò nínú ẹgbẹ́ náà lẹ́nu lọ́lọ́ yìí, ńjẹ́ ẹ mọ̀ pé àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó náà ti ń digbá dagbọ̀n wọn kúrò nínú ẹgbẹ́ náà? Ẹ̀sùn tí wọ́n dẹ̀ fi ń kan àwọn adarí ẹgbẹ́ náà ni àìníyanjú àwọn ìbòrí ìbò, ìjàgùdù láàárín àwọn olórí, akitiyan àtiyanjú àsáwọ̀, àti ẹ̀sùn fífì kan ara wọn lórí ṣíṣe lòdì sí ẹgbẹ́. Lára àwọn aṣáájú tí wọ́n ti gbá sẹ́gbẹ̀ẹ́ níṣe tí ìjọba Tinubu ti gorí àlééfà yìí ni Yẹmí Ọ̀ṣínbàjò tó jẹ́ igbákejì Ààrẹ lábẹ́ ìjọba Buhari.
Àwọn mìíràn ni Ìbíkúnlé Amósùn; Káyọ̀dé Fáyẹmí; Rauf Arẹ́gbẹ́ṣọlá; Gbémisọ́lá Sàràkí ; Rochas Okorocha; Iyìọlá Omísore ati awọn mìíràn bẹ́ẹ̀.
Ǹjẹ́ ẹ̀yin rò pé torí aráàlú ni wọ́n fi ń yapa lọ́tùn-ún lósì àbí nítorí ti ara wọn? Àbí gbogbo àlùwàlá ológbò wọn, ọgbọ́n àti kó ẹran jẹ ní?
A kò kúkú le mọ inú wọn,ohun tí wọ́n bá sọ sí ìta náà la mọ. Àfi kí Elédùmarè ó yàn fún wa nílùú yìí nítorí kò gbọdọ̀ máa lọ báyìí.