Olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìpínlẹ̀ Rivers tó kọ̀wé fipò sílẹ̀; George Nwaeke ti sọ̀rọ̀ tako ohun tí ìyàwó rẹ̀ sọ pé wọ́n jí i gbé.
George wí pé ní kété tí òun fipò sílẹ̀ ni òun lọ sí Abuja lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò. Ìdí ni pé àwọn ọ̀rọ̀ kan ń jà ràìnràìn nílẹ̀ léyì tí ó kún ìdí tí òun fi kọ̀wé fipò sílẹ̀ tí òun sì gbọdọ̀ yanjú kí wọ́n má ma wá òun kiri.
Nwaeke ní nígbà tí òun rí fọ́nrán ìyàwó òun tó ń sunkún pé wọ́n jí òun gbé àti gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tó ń sọ, ó ya òun lẹ́nu nítorí pé ìyàwó òun mọ̀ pé Abuja ni òun wà. George wí pé àwọn kan ni wọ́n fọn ohùn tí ìyàwó òun fọn síta síi nínú o.
Nwaeke gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé kí a má dá ìyàwó òun lóhùn o, eré orí ìtàgé ló ń ṣe.
Nínú fọ́nrán tó gborí afẹ́fẹ́ kan ni a ti rí ìyàwó ẹni tó ti fìgbà kan rí jẹ́ olórí òṣìṣẹ́, àmọ́ tó ti kọ̀wé fipò sílẹ̀ báyìí ní ìpínlẹ̀ Rivers, ìyẹn Arábìnrin aya Nwaeke ti fi ariwo bọnu pé òun ò mọ ibi tí ọkọ òun wà mọ́ báyìí o! Ó ti pòórá lọ́nà abàadì láìmọ ibi tó gbà àlọ.
Aya Nwaeke sọ pé àwọn kan tí wọ́n kó ara wọn jọ, tóun ò sì mọ orúkọ wọn àti ẹyẹ tó su wọ́n, ni wọ́n pàșẹ fọ́kọ òun pé kí wọ́n parọ́ mọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers tí wọ́n șẹ̀șẹ̀ rọ̀ lóyè; Siminalayi Fubara pé ó lẹ́bọ lẹ́rù lórí ìpasípayọ owó kan tó tó bílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún owó dọ́là ( 15 bn dollars). Èyí tó jẹ́ owó ìjọba ipinlẹ̀ Rivers.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí Aya Nwaeke ṣe, ó ní ọ̀rẹ́ ọkọ òún pe ọkọ òun wá sí Abuja, àti pé ọkọ òun ní wọ́n ní kóun kọ àkọsílẹ̀ tí yóò ṣe àkóbá fún gómìnà Fubara. Nínú àìbàlẹ̀ ọkàn ni ìyàwó Nweke ti ń ṣàlàyé pé lẹ́hìn tí ọkọ òun ti ní Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ lórí ẹ̀rọ tẹlifisan, ni òun ò ti gbúròó ọkọ òun mọ́.
Arábìnrin aya Nwaeke ní òun ń béèrè lọ́wọ́ ọkọ òun bóyá wọ́n fún un lókùn lọ́rùn láti máa kà bòròbòrò lòdì sí ipa Fubara. Ó ní ọkọ òun sọ fóun tẹ́lẹ̀ pé ìdí tóun (Nwaeke) ṣe kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ ní pé wọ́n kó àwọn abààmì ìwé kan wá sọ́dọ̀ òun, tí wọ́n sì ni kóun kéde fáráyé pé gómìnà tí wọ́n rọ̀ lóyè ti ṣe pàámọ́-pàábò owó ìjọba; aya Nwaeke ni ọkọ òun lóun sọ fáwọn tọ̀hún pé kàkà tóun fi máa jẹ́rìí èké ti Fubara, òun yóò kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀ ni.
Ní báyìí, ọkọ ní ká má dá ìyàwó òun lóhùn pé àwọn kan ló fi ọ̀rọ̀ náà síi lẹ́nu, ṣé kìí ṣe pé ejò ti lọ́wọ́ nínú báyìí?
Bí a kò bá gbàgbé, ẹnu lọ́ọ́lọ́ yìí ni Nwaeke kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ fún àwọn ìdí tí kò hànde. A mú ìròyìn náà wá fún yín pé ‘Dọ́kítà George Nwaeke kọ̀wé ìfipòsílẹ̀ ránṣẹ́ sí olórí ìlú titun; Admiral Ibos-Ete Ibas pé òun kò ṣe iṣẹ́ mọ́ o.
Nínú èsì tí Ibas fi ránṣẹ́ síi ni ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún àsìkò péréte tó lò pẹ̀lú òun, Ibas kọ ọ́ pé kò dùn mọ́ òun nínú pé ó ń lọ àmọ́ kò sí ohun tí òun le fi dáa dúró. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ó sì ro rere síi fún ọjọ́ iwájú.
Àfi bí ìgbà tí Ibas ń retí kí George ó fipò rẹ̀ sílẹ̀ kó tó yan akọ̀wé ìjọba ni, Lọ́gán ló yan akọ̀wé àgbà ìjọba titun sípò. Ẹni tó yàn náà ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Ibibi Worika.
Ibas wí pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyẹ̀wò àwọn ìwé ẹ̀rí àti àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, kò sí ẹlòmíràn tó tó ipò náà dì mú ju Ibibi Lucky Worika lọ’
Ẹ̀yin ará, ṣé ó ní nǹkan mìíràn tó ń ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Rivers tí kò hàn sí àwa oníròyìn ni? abi? Láti ìgbà tí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti rọ Fubara nípò ni onírúurú àwọn ọ̀rọ̀ mìíràn ti ń jẹyọ. A kò gbọ́ nǹkan kan nípa ọ̀gbẹ́ni George tẹ́lẹ̀ títí tó fi kọ̀wé fipò sílẹ̀ tí ọ̀rọ̀ òun àti ìyàwó rẹ̀ tún tako ara wọn yìí.
A kọ ọ́ lókè pé ìyàwó Nwaeke ní àwọn kan ní kí ọkọ òun ó fi ọwọ́ sí ìwé òfegèé tí yóò jẹ́rìí pé Fubara kó owó lápò ìjọba tí ọkọ òun sì yarí kanlẹ̀. Ó ní ìdí rèé tó fi fipò náà sílẹ̀ pé òun kò le jẹ́rìí èké. Ọkọ náà ní àwọn ọ̀rọ̀ kan ló mú òun fipò sílẹ, ó sì kọ̀ láti ṣíṣọ́ lójú éégún àwọn ọ̀rọ̀ náà, ohun tí ó kàn sọ náà ni pé òun lọ sí Abuja lọ yanjú rẹ̀, ó jọhun pé òótọ́ díẹ̀ wà nínú ohun tí ìyàwó rẹ̀ sọ yìí, àwọn wo ni wọ́n ń gbénú igbo dúnkokò mọ́ Nwaeke? Àwọn wo ni wọ́n fẹ́ lọ́ ọ̀rọ̀ mọ́ Fubara lẹ́sẹ̀? Àwọn wo nigi wọ́rọ́kọ́ tó fẹ́ da iná ìpínlẹ̀ Rivers rú? Ṣé ẹni tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ náà ni àbí àwọn mìíràn?
Bí ẹ kò bá gbàgbé, wàhalà tó wà láàrin Nyesom Wike; ẹni tó ti fìgbà kan jẹ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Rivers yìí kan náà àti Siminalayi Fubara; Gómìnà tí a rọ̀ lóyè yìí ni ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ gbogbo wàhálà yìí. Fubara kò wọn ọ́n kún fún Wike, Wike náà kọ̀ láti gbàá láàbọ̀.
Ọ̀rọ̀ rèé o, ibo ni gbogbo rògbòdìyàn yìí máa já sí?
Discussion about this post