Adelé Gómìnà Ìpínlẹ̀ RIVERS tí Ààrẹ BOLA AHMED TINUBU yàn sí ipò, Ọ̀gágun àná tẹ́lẹ̀, IBAS IBOK-ETE sọ wí pé kí owó gọbọi tí ìjọba SIMINALAI FUBARA jẹ àwọn òṣíṣẹ̀ Kánsù ní ìpínlẹ̀ RIVERS bẹ̀rẹ̀ sí ní í di sísan ní báyìí-báyìí. Ọjọ́ Ẹtì tó kọjá ni IBAS OBOT-ETE ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn lórí òbítíbitì owó tí ìpínlẹ̀ RIVERS jẹ́ gbogbo òṣìṣẹ́ Alága Kànsù. Lásìkò ìpàdé pẹ̀lú àwọn Alága Kànsù àti Adarí NIGERIA UNION OF LOCAL GOVERNMENT EMPLOYERS ( NULGE) ẹ̀ka ti ìpínlẹ̀ RIVERS pa á láṣẹ ní kíá, mọna -wáà kí owó oṣù tí wọ́n jẹ́ sẹ́yìn di sísan lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. IBAS OBOT-ETE ní gbogbo bí ìlú ti kan bóbó bí ìbó, tí àtijẹ-àtimu sì le fún àwọn Ará ìlú ni òun mọ̀, gbogbo ìdojúkọ àwọn òṣìṣẹ́ tó n ṣiṣẹ́ sin ìlú láì gba owó ọ̀yà iṣẹ́ ọjọ́ pípẹ́ láti oṣù kejì títí di oṣù kẹta tó n tán lọ yìí mú òun lọ́kàn gidigidi. IBAS ṣàlàyé pé èyí wàyé látàrí ìdáwọ́kọ́ owó tó yẹ kó bọ́ sí àpò ìṣúná owó ìpínlẹ̀ RIVERS nítorí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ SUPREME tọjọ́ kejìdínlọ́gbọ́n oṣù kejì ọdún yìí wó wọ́gilé ìdìbò Alága Kánsù ti oṣù ọ̀wàrà ọdún 2024.
IBAS ní : ‘Mo mọ̀ dàjú pé ọ̀rọ̀ náà le púpọ̀ fún àwọn òṣìṣẹ́ àgàgà lásìkò yìí tí wọ́n ṣiṣẹ́ láì rí owó gbà, Ẹ kú àmúmọ́ra, Ẹ tún kú ìrọ́jú, Mò n fi àsìkò yìí kéde pé gbogbo ìgbésẹ̀ bí owó náà yóò ṣe jẹ́ sísan ni mo ti dágbálé báyìí, Màá gbìyànjú láti san gbogbo gbèsè pátápátá tán láì ṣẹ́ku ọ̀kan.
Gẹ́gẹ́ bí Aṣíwájú rere, Olùfọkànsìn, ọ̀rọ̀ ọmọ ìpínlẹ̀ yìí ló jẹ wá lógún, A ó sì bu òróró ìtutù sí ojú ọgbẹ́ ọlọ́jọ́ pípẹ́. Mo ti gba iṣẹ́ yìí, ó sì ti di ṣíṣe. Fún ìdí èyí, Mo tún n pa á láṣẹ kí àwọn lọ́gàá-lọ́gàá Alága Kànsù ṣe ojúṣe wọn bó ti tọ́ àti bó ti yẹ kí wọ́n sì fi tómi létí, èyí yóò fún mi ní ànfàání láti túbọ̀ le è ṣe si. IBAS OBOT-ETE ní òun yóò gbájúmọ́ ìfòtítọ́-inú-ṣiṣẹ́ kárakára kí a sì jìnà sí ìnákúnàá àti ìṣowó ìlú kúmọkùmọ. Ó ni ‘ìjọba tó súnmọ́ Ará ìlú jùlọ àwọn ni wọ́n n rẹrù Ará ìlú sórí mọ́n-ọ́n-mọ́n-ọ́n, ìṣèjọba wọn sí gbọdọ̀ kún fún ojú àánú, ìkẹ́, ìtẹríba àti iṣẹ́ takuntakun fún ìlọsíwájú àwùjọ.
IBAS ní : ‘ Ìṣèjọba mi kò ní ṣowó ìlú kúmọ-kùmọ, láti àsìkò yìí lọ, ìṣirò ni a ó máa fi ọkọ dído ṣe, gbogbo tọ́rọ́-kọ́bọ̀ ni yóò lákọsílẹ̀. Oṣù mẹ́fà péré ni wọ́n fún mi lórí Àlèéfà, Mo gbọ́dọ̀ rí i dájú gbangba -gbàngbà pé gbogbo owó àwọn èèyan ìpínlẹ̀ RIVERS ló ní àkọsílẹ̀ nítorí ìtàn kò ní gbàgbé ẹnikẹ́ni yálà sí rere tàbí láburú, ká fi òtítọ́ inú ṣiṣẹ́, kí a yé é du àpò tara ẹni nìkan.Gómìnà tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ RIVERS, NYESOM WIKE ní kí àlàáfíà tó le è jọba ní ìpínlẹ̀ RIVERS, ó pọndandan kí SIMINALAYI FUBARA ṣe nnkan méjì yìí:
NYESOM WIKE ní kí SIMINALAYI FUBARA tẹ́ pẹpẹ owó ìṣúná tọdún 2025 yìí sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tí MARTINS AMAEWHULE jẹ́ adarí wọn. NYESOM WIKE tún ní dandan gbọ̀n ọ̀n kí Gómìnà FUBARA fi orúkọ àwọn kọmíṣánnà ìpínlẹ̀ RIVERS ránṣẹ́ fún ìfọwọ́sí. NYESOME WIKE tó jẹ́ Mínísítà fún olú ìlú wa Àbújá ní tí FUBARA bá kọ̀ láti ṣe èyí, ọ̀rọ̀ yìí kò ní le è wọ̀ ní ìpínlẹ̀ RIVERS. Ohun tó ṣe kókó tó sì ṣe pàtàkì ni kí ìgbé Àlàáfíà wà ní ìlú nígbà tí a bá ti ṣe ohun tó tọ́ àti ohun tó yẹ, Àlàáfíà yóò jọba , ara á rọ tẹrú-tọmọ láì jẹ́ bẹ́ẹ̀, kò le è rọgbọ. WIKE ní taraṣàṣà báyìí kó lọ tètè tẹ́ pẹpẹ ìwé ìṣúná owó ọdún yìí sí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ RIVERS, tún tẹ́ pẹpẹ orúkọ àwọn kọ́míṣánnà tó pójú òṣùwọn bákan náà.
NYESOM WIKE ló ṣíṣọ lórí eégún ọ̀rọ̀ yìí lásìkò tó n bá àwọn Akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ pé òun ló fa SIMINALAYI FUBARA kalẹ̀ sí ipò Gómínà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò dùn mọ̀ àwọn olóṣèlú tí kìí ṣe ẹ̀yà IJAW lọ́rùn. WIKE ní ‘ẹ̀ta hóró ni ẹ̀yà IJAW, wọn ò lẹ́tọ̀ọ́ sí ipò Gómìnà ìpínlẹ̀ RIVERS, àwọn pẹ̀lú NIGER DELTA, àfi ẹ̀yà BAYELSA.
IBAS OBOT-ETE tún ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn lọ́ba-lọ́ba ní ìpínlẹ̀ RIVERS pé òun nílò ọgbọ́n inú àti òye wọn láti ṣiṣẹ́ kí ìṣọ̀kan le è padà jọba ní ìpínlẹ̀ RIVERS nítorí pé kò sí ohun tí wàhálà fẹ́ fà kalẹ̀ bí kòṣe ìtàpá sí òfin ìpínlẹ̀ náà. IBAS ní kí àwọn ládéládé- lóyèloyè káràmásìkí bí ìṣọ̀kan yóò ṣe wà ní ìlú. Ó ní èyin ọba ni Alárinà láàrín ìjọba àti Ará ìlú, ọba ni Aláṣẹ èkejì òrìṣà, ọba sì ni Làgàta láàrín onjà méjì kí Ẹ máa ṣègbèlẹ́yìn ẹgbẹ́ kan. ‘Ẹ ló ọgbọ́n inú yín, òye àti ipò pẹ̀lú agbára fún ìṣọ̀kan ilẹ̀ yìí. Ààyè wà fún un yín kí a jọ tukọ̀ náà ní gbèdéke tá a ní kí Àlàáfíà le è jọba. Mo rọ̀ ọ yín kí Ẹ jìnà sí kèéta, Ẹ tara ṣàfilọ̀ bẹ́ ẹ bá kẹ́ẹ́fín nnkan. Lẹ́yìn gbogbo atótónu, IBAS OBOT-ETE, alága ìgbìmọ̀ àwọn lọ́ba-lọ́ba ìpínlẹ̀ RIVERS, CHIKE AMADI WORLU-WODO ní ìyànsípò IBAS láti máa delé de FUBARA SIMINALAYI jẹ́ nnkan tó dùn mọ́ gbogbo wa nínú, Òun ni Làgàta tí yóò fi òpin sí yánpọnyánrin tó n da omi àlàáfíà ìpínlẹ̀ RIVERS rú.
Discussion about this post