Iná tún dún gbùlà ní ìpínlẹ̀ RIVERS ní Soku ìjọba ìbílẹ̀ Akuku Toru lọ́sẹ̀ kan gééré lẹ́yìn tí iná ṣe ọṣẹ́ ní TRANS NIGER PIPELINE ní ìjọba ìbílẹ̀ Bodo, Gokana àti oga/ Egbema/Ndoni. Ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ YEAC-NIG, YOUTH AND ENVIRONMENTAL ADVOCACY CENTRE ló fi ìdí ọ̀rọ̀ iná náà múlẹ̀ pé òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú 23rd, Oṣù kẹta ọdún 2025 ni iná ṣẹ́yọ gbùlà níbi ọ̀pá ìfọpo SOKU OIL FACILITY tí àwọn adarí rẹ̀ jẹ́ NIGERIA LIQUEFIED NATIONAL GAS ( NLNG).
Nínú àtẹ̀jíṣẹ́ tí ọ̀gá àgbà ẹgbẹ́ ọdọ́, FYNEFACE DUMNAMENE FYNEFACE fi ránṣẹ́ ló fi tú àkàrà sépo pé ṣàdéédé ni ojú òfurufú dúdú báyìí fún èéfín, lá bá gbọ́ pé ilé ìfọpo Soku ló n gbiná. Ó ní iye wákàtí tí iná náà fi jà ranyinranyin, títí di àsìkò tí a fi n kó ìròyìn yìí jọ, a kò le è sọ ohun tó ṣokunfà iná náà. Olórí ẹgbẹ́ YEAC ní kí àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn tètè ṣe ìwádìí ohun tó ṣokùnfà iná ní Soku. Wọ́n tún rọ àjọ NATIONAL OIL SPILL DETECTION AND RESPONSE AGENCY (NOSDRA) kí àwọn náà fọwọ́sowọ́pọ̀ láti fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ iná hàn sí gbàgede kí wọ́n sì fi àwọn ọ̀bàyéjẹ́ jófin lábẹ́ òfin ti abala PIA 2021. YEAC tún ṣàlàyé pé ní kíákíá báyìí ni kí ìjọba tètè dẹ́kun iná òjijì yìí kí àlàbọrùn tó ó di ẹrù. Ẹ̀kẹẹta rèé tí iná yóò gbiná láàrín ọ̀sẹ̀ kan ní ìpínlẹ̀ RIVERS, alákọ́kọ́ ni èyí tó dún gbàmù ní Ògoni, ẹ̀keejì ṣẹlẹ̀ ní Oga / EGBEMA/ NDONI ní kété tí Ààrẹ BOLA AHMED TINUBU kéde kónílé-ó-gbélé ní ìpínlẹ̀ RIVERS lọjọ́ kejìdnlógún oṣù yìí, oṣù mẹ́fà gbáko ni Ààrẹ fi kéde kónílé-ó-gbélé. Ìdí ni pé Ààrẹ BOLA AHMED ní kí SIMINALAYI FUBARA àti ìgbákejì rẹ̀ NGOZI ODU gbélé wọn látàrí àìkájú òṣùwọ̀n àti ká fi ni joyè àwòdì ká má le è gbé adìẹ, wọn kò le è dáàbò bo ọpá epo ní ìpínlẹ̀ náà. Ìṣẹ̀lẹ̀ iná ọmọ ọ̀rara yìí ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ọ̀dọ́ ìlú kan n fi ẹ̀họ́nnú hàn lórí fọ́nrán tó gbòde bí inú àwọn kò ti dùn sí yíyọ bí i jìgá tí Ààrẹ BOLA AHMED TINUBU yọ SIMINALAYI FUBARA àti ẹmẹẹ̀wá rẹ̀. Ojúṣe ìjọba ni láti dáàbò bo ẹ̀mí àti dúkìá ìlú rẹ̀, kí wọ́n sì dásí ọ̀rọ̀ iná ojoojúmọ́ kí tó di ẹ́ka ìrókò tí apá kò ní ká mọ́. Lóòtọ́, oṣù mẹ́fà kónílé-ó-gbélé ti ìpínlẹ̀ RIVERS jẹ́ fún ànfàaní ìjọba àwa-ara-wa ilẹ̀ Nàìjíríà. Èyí yóò jẹ́ ohun ìdùnnù àti ìwúrí bí àwọn ọmọ ìlú bá yéé sunkún èké kiri. FYNEFACE DUMNEMENE rọ àwọn ọmọ ilẹ̀ Nàìjíríà láti máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ sọ, kí wọ́n yéé tútukútu, kí wọ́n dẹ́kun fífi ẹnu tú Àlàáfíà orílẹ̀ èdè yìí. Èrò rere wa gbọdọ̀ jẹ́ fún ìṣẹ́ takuntakun, òtítọ́ inú, ìmọ̀ ẹ̀rọ àti sáyẹ́nsì, iṣẹ́ ọ̀gbìn, ẹ̀kọ́, ofin èmi ò j-ọ́-ìwọ-ò-jùmí orílẹ̀ èdè yìí. Ẹ jẹ́ kí a gbájúmọ́ ìpinnu rere fún ìlẹ̀ Nàìjíríà.
Awuyewuye kan tilẹ̀ gbìlẹ̀ báyìí pé Nyesom WIKE ni bàbá ìsàlẹ́ ìpínlẹ̀ RIVERS òun sì ni ìròmì tó n dún ní ìsàlẹ̀ odò bí bẹ́ẹ̀kọ́ Ààrẹ BOLA AHMED TINUBU kò ní máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Ó ní Mínísítà lásánlàsàn ni WIKE,kìí ṣe olórí olóógun ilẹ̀ wa, kìí sì ṣe olórí àjọ EFCC tàbí Adájọ̀ àgbà nílẹ̀ yìí, Ẹ jàmi lórí rẹ̀, Ẹ sìmẹ̀dọ̀, Ẹ yéé da omi Àlàáfíà ìlú rú.Awuyewuye kan tilẹ̀ gbìlẹ̀ báyìí pé Nyesom WIKE ni bàbá ìsàlẹ́ ìpínlẹ̀ RIVERS òun sì ni ìròmì tó n dún ní ìsàlẹ̀ odò bí bẹ́ẹ̀kọ́ Ààrẹ BOLA AHMED TINUBU kò ní máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Ó ní Mínísítà lásánlàsàn ni WIKE,kìí ṣe olórí olóógun ilẹ̀ wa, kìí sì ṣe olórí àjọ EFCC tàbí Adájọ̀ àgbà nílẹ̀ yìí, Ẹ jàmi lórí rẹ̀, Ẹ sìmẹ̀dọ̀, Ẹ yéé da omi Àlàáfíà ìlú rú.
Bákan náà ni ogúnlọ́gọ̀ àwọn obìnrin ìjọba ìbílẹ̀ OKRIKA wọ aṣọ dúdú, aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n fọ́nká sí ìlú PORT HARCOURT, wọ́n n wọ́de láti fi ẹ̀họ́nnú hàn lórí rírọkúnlé ti Ààrẹ BOLA AHMED TINUBU ní kí FUBARA lọ rọọ́kúnlé fún oṣù mẹ́fà gbáko nítorí àìkájú òṣùwọ̀n tó ní ìpínlẹ̀ wọn.
Bákan náà ni ogúnlọ́gọ̀ àwọn obìnrin ìjọba ìbílẹ̀ OKRIKA wọ aṣọ dúdú, aṣọ ọ̀fọ̀, wọ́n fọ́nká sí ìlú PORT HARCOURT, wọ́n n wọ́de láti fi ẹ̀họ́nnú hàn lórí rírọkúnlé ti Ààrẹ BOLA AHMED TINUBU ní kí FUBARA lọ rọọ́kúnlé fún oṣù mẹ́fà gbáko nítorí àìkájú òṣùwọ̀n tó ní ìpínlẹ̀ wọn.
Ìpayà ni ìwọ́de yìí jẹ́ fún gbogbo èèyàn nítorí a kò le è sọ ohun tí yóò tìdí rẹ̀ yọ kí ọ̀sẹ̀ mẹ́fà tó ó pé. Wọ́n ní kí Ààrẹ BOLA AHMED TINUBU tètè gbé ìgbésẹ̀ tó nípọn sí ọ̀rọ̀ yìí kí àlàbọrùn má bá a di ẹ̀wù.
Akọ́wé àgbà fún Gómìnà FUBARA ní kí àwọn aráàlú má mikàn, má fòyà, àlàáfíà ni FUBARA àti ẹbí rẹ̀ wà, kò sí ewu lóko lóngẹ́ àfi gìrìrì àparò, Ẹ yéé tẹ̀lé ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ inú ẹ̀rọ̀ ayélujára pé bóyá àwọn ológun tó gbòde ti kó FUBARA ní papámọ́ra, kò jọọ́, àlàáfíà ni gbogbo ilé wà, ara kò ṣe nnkan.
Àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ti n wá bí ọ̀rọ̀ yóò ṣe yanjú láàrín àwọn àgbà awo tó n ṣe fàákája ní ìpínlẹ̀ RIVERS, wọ́n ti jókòó ṣùgbọ́n Adarí agbẹnusọ fún ẹ̀yà NIGER DELTA, ANABS SARA-IGBE ní àwọn k tí ì gbọ́ nnkan lẹ́nu Gómínà FUBARA. MAHMUD JEGA tó jẹ́ gbajúgbajà olóòtú ìwé ìròyìn ilẹ̀ yìí ní Ààrẹ nìkan ló le è làjà yìí àti pé ṣe ní Ààrẹ n ṣègbèlẹ́yin NYESOM WIKE tó sì n nà ìka àbùkù bá FUBARA. JEGA ní ẹnìkan kò le è fi Àbújá ṣe ilé kò sí máa ti ọwọ́ bòkú lójú ní RIVERS, kò bójúmu rárá àfi kí Ààrẹ tètè dáa lọ́wọ́ kọ́ bí ọ̀rọ̀ kò bá fẹ́ bẹ́yìn yọ bó bá di ọdún 2027. Kí SUPREME COURT pàápàá dá ẹjọ́ bí ó ti tọ́ àti bí ó ti yẹ.
Discussion about this post