Aláàfin Ọ̀yọ́; Ọba Abimbola Akeem Owoade ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé kò dìgbà tí ilé ọba bá jó ká tó bu ẹwà síi nípa ṣíṣe àlàyé àwọn ètò àtúnṣe tó ní fún ààfin.
Ọba Owoade sọ èyí nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ó wí pé àtúnṣe tí yóò wáyé ní ààfin kò ní pa àwọn ohun ìṣẹ̀m̀báyé inú rẹ̀ lára. Kábíèsí, ikú bàbá-yèyé, aláṣẹ èkejì òrìṣà wí pé ààfin àkọ́kọ́ tí Aláàfin Atiba Latunbosun kọ́ ní nǹkan bíi igba ọdún sẹ́yìn kò tíì rí àtúnṣe kan gbòógì láti ìgbà náà.
Aláàfin Akeem Owoade tẹ̀síwájú pé ẹni bá ti wọ inú ààfin yóò mọ̀ pé lóòótọ́ ló nílò àtúnṣe, àwọn ilé kan ń fẹ́ àtúnṣe nígbà tí wọn yóò tún kọ́ àwọn ilé titun mìíràn.
Ọba Owoade kò ṣàì má gbé oríyìn fún Aláàfin àná; Ọba Lamidi Adeyemi, ó wí pé ‘Mo kí ọba Adeyemi fún akitiyan rẹ̀ láti pa àṣà àti ìṣe Yorùbá mọ́, ibi tí Ọba Adeyemi fi àdàgbá rọ̀ sí ni n ó ti bẹ̀rẹ̀, n ó ríí dájú pé mo gbé àṣà àti ìṣe Yorùbá lọ sí ìpele gíga’
Ìrìn àjò mi dé ipò Aláàfin.
Aláàfin Abimbola Owoade ṣe ìmúwásíràn-ántí bí ìyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Aláàfin Ọ̀yọ́ titun ṣe lọ. Ó wí pé ‘Ìlú Òyìnbó ni mow à tí àwọn ẹbí mi ní ìdílé Mọ̀gájì fi kàn sí mi pé kí n díje du ipò Aláàfin, mo kọ́kọ́ ní mi ò ṣe àmọ́ nígbà tí wọ́n rọ̀ mí, mo gbà láti díje. Aago márùn-ún ìdájí tí mo jí ní Canada ni mo rí àtẹ̀jíṣẹ́ láti ọ̀dọ́ àbúrò mi pé kí n yẹ ojú òpó kan wò, ohun tí mo bá níbẹ̀ náà ni pé Gómìnà Seyi Makinde ti fi ọwọ́ sí ìyànsípò Akeem Abimbola Owoade gẹ́gẹ́ bíi Aláàfin Ọ̀yọ́ titun. Bí mo ṣe jọba rèé o’
Àfojúsùn Aláàfin fún àwọn ọ̀dọ́ Ọ̀yọ́.
Aláàfin titun ṣe àlàyé àwọn àlàkalẹ̀ tó ní fún àwọn ọ̀dọ́ pé ‘Ohun tí àwọn ọ̀dọ nílò jùlọ náà ni iṣẹ́ tí wọn yóò máa fi gbọ́ bùkátà wọn tí wọn ò fi ní máa fi ẹsẹ̀ gbálẹ̀ kiri. Yàtọ̀ sí iṣẹ́, àwọn ọ̀dọ́ nílò ààbò àti ìfọ̀kànbalẹ̀. Ètò ń lọ lábẹ́lẹ̀ lórí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún àwọn ọ̀dọ́, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí yóò dá lé iṣẹ́ ọwọ́, òwò ṣíṣe àti ìmọ̀ ayélujára fún àwọn tó ti kàwé àti àwọn tí wọn ò ní àǹfààní àti kàwé’
Ètò ìlera Ọ̀yọ́
Aláàfin Abimbola Owoade ṣe àlàyé ètò tí ó ní fún ìlera àwọn ará Ọ̀yọ́, ó wí pé ‘A ó kọ́ ilé ìwòsàn ìlú tí àwọn èèyàn ó ti máa gba ìtọ́jú ọ̀fẹ́ pàápàá àwọn tó kù díẹ̀ káàtó fún. Mo ti kó àwọn irinṣẹ́ ìgbàlódé kan wọlé láti òkè òkun, gbogbo Ọ̀yọ́ ló sì mọ̀ síi.’
Àwọn èèyàn mánigbàgbé
Aláàfin titun wí pé ‘Àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n ti ṣe iṣẹ́ takuntakun fún ìdàgbàsọ́kè àti ìlọsíwájú ìlú Ọ̀yọ́, a ó sọ àwọn agbègbè kan lórúkọ wọn kí a fi le máa ṣe ìrántí wọn’.
Báyìí ni ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò náà ṣe lọ pẹ̀lú Oba Akeem Abimbola Owoade. Ọjọ́ àbámẹ́ta tí ó ṣe ìwúyè náà ni ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò yìí wáyé. A mú ìròyìn ìwúyè Ọba Akeem Abimbola Owoade wá fún yín pé: ‘Gbogbo ayé ló péjúpésẹ̀ síbi ìwúyè Ọba Akeem Abimbola Owoade lọ́jọ́ àbámẹ́ta níbi tó ti gba adé Aláàfin Ọ̀yọ́ titun.
Àwọn lọ́balọ́ba, àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn tó fi dé orí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ló wà níbi ìwúyè náà. Lára wọn la ti rí mínísítà fún ohun àmúṣagbára; Olóyè Adebayo Adelabu tó wá ṣojú ààrẹ Bola Ahmed Tinubu (ṣé ẹ ò gbàgbé pé ààrẹ wà ní Faransé) a rí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́; Seyi Makinde, a rí agbẹnusọ fún ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Ọ̀yọ́; Debo Ogundoyin bákan náà la rí Ààrẹ ọ̀nà kakaǹfò ilẹ̀ Yorùbá; Iba Gani Adams.
Àwọn orí adé tí a rí tọ́ka sí níbẹ̀ ni Ọ̀ọ̀ni Ifẹ̀; Ọba Adeyeye Eniitan Ogunwusi Ojaja ii, Sultan Sokoto; Sa’ad Abubakar, Ṣọ̀ún Ògbómọ̀ṣọ́; Ọba Ghandi Olaoye, Olúwòó ti Ìwó; Ọba AbdulRosheed Akanbi, Asẹ́yìn ti ìlú Ìṣẹ́yìn; Ọba Sefiu Oyebola, Olú ti Igbóọrà; Ọba Jimoh Titiloye àti Asigangan ti ìlú Ìgàngán; Ọba Rafiu Ariowoola.
Ọgbà ilé ìwé girama Oliveth tó wà ní Ọ̀yọ́ ni ìwúyè náà ti wáyé, ó kọjá bẹ́ẹ̀. Ọba Akeem Owoade ni Aláàfin kẹrìndínláàdọ́ta lẹ́yìn tí Aláàfin Adeyemi iii wàjà lọ́dún mẹ́ta sẹ́yìn.
Ṣaájú ìwúyè yìí ni Aláàfin Owoade ti gba ọ̀pá àṣẹ lọ́wọ́ Gómìnà Seyi Makinde ní ọ́fíìsì rẹ̀ nínú oṣù Ṣẹẹrẹ. Lẹ́yìn náà ni ó wọ ìpèbí fún ọjọ́ mọ́kànlélọ́gún gbáko.
Níbi ìwúyè náà tó wáyé lọ́jọ́ àbámẹ́ta ni ààrẹ ilẹ̀ wa; Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu ti ṣe àpèjúwe àpèrè Aláàfin gẹ́gẹ́ bíi ìwúrí àṣà, ìṣe àti ọ̀kan nínú àwọn àpèrè tó lágbára jùlọ nílẹ̀ Adúláwọ̀. Ó wí pé ojúṣe Aláàfin ni láti pa àṣà àti ìṣe ìran Yorùbá mọ́ àti láti gbé àṣà lárúgẹ kó sì máa ṣe àtilẹ́yìn fún ìjọba.
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu bèèrè fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn ará Ọ̀yọ́ kí Aláàfin titun ó le kógo já’
Ó ṣe pàtàkì láti mẹ́nuba ẹ̀gbà ọrùn Aláàfin Owoade tó dá awuyewuye sílẹ̀ lórí ìtàkùn ayélujára. Nígbà tí àwọn kan wí pé àgbélèbú tíí ṣe àmì ẹ̀sìn ọmọlẹ́yìn Jesu ni ẹ̀gbà náà, wọ́n ní Ọba Owoade gbàgbọ́ nínú Jesu gẹ́gẹ́ bíi Ọlọ́run àti Olùgbàlà, àwọn tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀ṣe dá wọn lọ́hùn pé òṣẹ́ Ṣànǹgó tí a fi wúrà rọ ni ẹ̀gbà náà pé ó jìnnà pátá sí àgbélèbú Jesu.
Bí a kò bá gbàgbé ìtàn, àrọ́mọdọ́mọ Ṣànǹgó ni Aláàfin, Ṣànǹgó ló sì ni oṣẹ́. Bákan náà ni Aláàfin Owoade dé adé Ṣànǹgó ní Kòso gẹ́gẹ́ bíi ọ̀kan nínú àwọn ìgbésẹ̀ àtijọba.
Discussion about this post