Ilé ìwé Aládàání kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Ogun ni àwọn òbí kan ti fẹ̀sùn kàn pé wọ́n sín gbẹ́rẹ́ fún àwọn ọmọ àwọn.
Abosede, ìyá ọmọ ọdún mẹ́rin kan ṣe àlàyé pé Alamis ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní yún odò ikùn rẹ̀, nígbà tí òun yẹ ibẹ̀ wò ni òun rí gbẹ́rẹ́ náà tí òun sì gbé e lọ sí ilé ìwòsàn. Àwọn dókítà ṣe àyẹwò wọn sì wí pé abẹ tí wọ́n fi sín gbẹ́rẹ́ náà ní àwọn kòkòrò àìfojúrí.
Ọmọbìnrin mìíràn tí òun náà ń lọ sí ilé ìwé yìí ni ìyá rẹ̀ ṣe àkíyèsí pé láti ọjọ́ tí òun ti lọ gbé e lọ́sàn-án ọjọ́ náà ni ọmọ òun ti máa ń sun oorun ju bó ṣe yẹ lọ.
Ilé ìwòsàn ni wọ́n ti sọ fún òun náà pé abe tó fi sin gbere náà ní àwọn kòkòrò aifojuri.
Àwọn òbí mejeeji yìí fi ẹsun kan obìnrin tó ni ilé ìwé yìí àmọ́ ó wí pé òun kò mọ nǹkan kan nípa rẹ̀.
Àwọn òbí yìí ní kó jé kí àwọn ó wo fọ́nrán ẹrọ akaworansile CCTV ilé ìwé náà, obìnrin yìí tún ní kò sí iná lójó náà pé àwọn ero náà kò sise.
Wọ́n tún ní ṣebi ilé ìwé rẹ ní ero afooorunsagbara INVERTER lóbìnrin yìí bá tún wí pé èrò náà kò ṣiṣe lojo náà. Èyí ló mú kí àwọn òbí yìí ó tọ àgọ́ ọlọ́pàá lọ.
Ìròyìn yìi ni yóò mú wa fẹsẹ̀ kan dé ìpínlẹ̀ Edo níbi tí Gómìnà ti kéde ètò ẹ̀kọ́ pàjáwìrí nítorín ipò ìdẹnukọlẹ̀ tí àwọn ilé ìwé ìjọba ìpínlẹ̀ náà wà. A ríi kà pé;
Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo, Ọ̀gbẹ́ni Monday Okpebholo ti kéde ètò pàjáwìrì lórí àwọn Ilé-ẹ̀kọ́ ìjọba jákèjádò ìpínlẹ̀ náà. Ó ní ẹdùn ọkàn ló jẹ́ fún òun nítorí ipò ìdíkẹ̀mù tí àwọn Ilé-ẹ̀kọ́ náà wà.
Nígbà tó ń ṣe àbẹ̀wò sí Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn Ilé-ẹ̀kọ́ náà tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Ikpoba-Okha àti Egor ní ẹkùn gúúsù ìpínlẹ̀ Edo, Gómìnà bá ọkàn jẹ́ púpọ̀ lórí ipò tí àwọn ohun èlò ẹ̀kọ́ wà ní agbègbè yìí.
Ó ní ohun tó yẹni ló yẹni o, okùn ọrùn kò yẹ adìẹ; bẹ́ẹ̀ ni ọmọ ẹranko ń lé mi í bọ̀ kò yẹ ọdẹ. Ó ní kì í ṣe irú ipò akúrẹtẹ̀ yìí ló yẹ kí Ilé-ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ ipinle Edo wà rárá; ó ní ó yẹ kí Ilé-ẹ̀kọ́ wọn tí ṣeé wò ju bí òún ṣe bá a yìí lọ. Ó ní nígbà tóun ń poloñgo ìbò lọ́jọ́ kìn-ínní àná, òún ṣèlérí àtibójú tó ètò ẹ̀kọ́; àti pé òun ṣèlérí àtikéde ètò pàjáwìrì lóri àwọn Ilé-ẹ̀kọ́ gbogbo jákèjádò ìpínlẹ̀ Edo; pàápàá àwọn àgbègbè tí ohun amáyé-dẹrùn wọ́n bá ti mẹ́ẹ́rí, tí kò sí nǹkan èlò ìgbàlódé tí yóò mú kí akẹ́kọ̀ọ́ kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà Ìrọ̀rùn.
Gómìnà tilẹ̀ dárúkọ Ilé-ẹ̀kọ́ kan ni pàtó fún àpẹẹrẹ. Ó ní nígbà tóun dé Ilé-ẹ̀kọ́ giramo àwọn ológun ní ìjọba ìbílẹ̀ Ikpoba-Okha àti Ilé-ẹ̀kọ́ gíga ní ìjọba ìbílẹ̀ Egor ohun tóun bá kò tilẹ̀ ṣeé kó rárá. Kò sí ṣíṣe, kò sí àìṣe; bí iṣẹ́ ò bá pẹ́ni, a kì í pẹ́ṣẹ́; bí ìrókò bá sì ti wó sílé agbẹ́dó, kí iṣẹ́ bẹ̀rẹ̀ ló kù. Èyí ló mú kóun bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ètò pàjáwìrì láti Ilé-ẹ̀kọ́ wọ̀nyí.
Ó ní iṣẹ́ yóò bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu nípa kíkọ́ gbàgede sí Ilé-ẹ̀kọ́ giramọ ti ológun; àti pé ojú ọ̀nà tó wọ ilé-ẹ̀kọ́ tí kò bójú rẹ́, yóò di títúnșe lẹ́yẹ-kò-sọkà.
Alákòóso ètò ẹ̀kọ́, Paddy Iyamu ní òún ti gbàṣẹ pé ọmọ kọ̀ọ̀kan ní ìpínlẹ̀ Edo ló gbọ́dọ̀ jẹ àǹfààní ètò ẹ̀kọ́ tó yè kooro.
Ìròyìn yìí fara pẹ́ ti ìpínlẹ̀ Èkìtì níbi tí àrá ti mú ilé ìwé kan balẹ̀. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé Ilé ìwé St Peter’s tó wà ní Igbemo, Èkìtì ti jóná kanlẹ̀ nígbà tí òjò kan rọ̀ tó sì sán àrá. Àrá yìí ṣáná pààràpà tí iná náà fi jábọ́ sí orí òrùlé ilé ìwé náà. Yàrá mẹ́rin ló mú balẹ̀ nílé ìwé náà.
Àwọn aláṣẹ ilé ilé ìwé náà kó àwọn akẹ́kòọ́ àti olùkọ́ lọ sí ilé ìwé AUD tó wà ní ìtòsí wọn kí wọ́n le tẹ̀síwájú nínú ètò ẹ̀kọ́ wọn.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkìtì; Banji Oyebamiji rán igbákejì rẹ̀; Monisade aya Afuye lọ ṣe àbẹ̀wò sí ilé ìwé náà. Arábìnrin Monisade banújẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó gbé oríyìn fún àwọn olùkọ́ ilé ìwé St Peter’s tí wọn kò jẹ́ kí èyí ó dí ìwé àwọn ọmọ náà lọ́wọ́.
Aya Afuye wí pé Gómìnà Oyebamiji yóò ṣe àtúnkọ́ ilé ìwé náà láìpẹ́ láì jìnnà
Bí a ṣe kọ èyí la ríi pé ó ṣe pàtàkì ká mú ìròyìn ilé ìgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti ilé ìwé gíga ìpínlẹ̀ sokoto wá sí etígbọ́ yìn. Ohun tí a gbọ́ ni pé nítorí àdojúkọ tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin ilé ìwé gíga ìpínlẹ̀ Sokoto ń kojú, ijọba kọ́ ilé ìgbé titun oníyàrá rẹpẹtẹ fún wọn àmọ́ ó ṣe ni láàánú pé ó ti jóná kanlẹ̀ báyìí.
Nǹkan bíi aago mẹ́ta ààbọ̀ ọjọ́ ìṣẹ́gun ni iná náà bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tó sì mú gbogbo ilé náà balẹ̀. Akẹ́kọ̀ọ́ kan bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ pé àwọn kò mọ ohun tó ṣe okùnfà iná náà.
Kò sí ẹni tó fara pa nínú ìṣẹlẹ̀ yìí, àwọn aláṣẹ ilé ìwé náà sì ti kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń gbé níbẹ̀ lọ sí ilé ìgbé mìíràn.
Olórí ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wí pé nǹkan bíi aago márùn-ún àwọn panápaná tó dé, ilé náà sì ti jó kanlẹ̀ lásìkò yìí.
Àwọn aláṣẹ ilé ìwé yìí kọ̀ láti sọ ohunkóhun lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Discussion about this post