Ilé ìwé gíga tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ́ ní Iyin Ekiti yóò gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọlé ní oṣù Ọ̀wàrà tó ń bọ̀ yìí.
Ilé ìwé náà tí a pe orúkọ rẹ̀ ní Federal University of Technology and Environmental Sciences yóò bẹ̀rẹ̀ ètò ẹ̀kọ́ pẹ̀lú ẹ̀ka mẹ́rin.
Giwa ilé ìwé yìí; Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbenga Aribisala sọ̀rọ̀ níbi ìkínikáàbọ̀ tó wáyé ní Ifaki-Ekiti, ó wí pé ètò ń lọ láti ṣe ilé ìwé náà ní èyí tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ó le máa gbé nínú rẹ̀.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbenga wí pé ilé ìwé náà yóò mú ìwà ọmọlúàbí lọ́kǔnkúndùn, ẹ̀kọ́ ìwà rere yóò máa tọ ẹ̀kọ́ ìwé kíkà lẹ́yìn, gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn ni yóò fakọyọ.
Ọ̀rọ̀ Ọ̀jọ̀gbọ́n tẹ̀ síwájú pé àfojúsùn ilé ìwé náà ni láti gbé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ga kìí ṣe láti pa owó sápò.
Bákan náà ni ó wí pé àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ láti gba iṣẹ́ olùkọ́ nílé ìwé náà yóò ní ànfààní láti fi orúkọ sílẹ̀ lójú òpó wọn lórí ìtàkùn ayélujára. Ìkìlọ̀ ni fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ gba iṣẹ́ nílé ìwé náà láti ṣọ́ra fún àwọn gbájúẹ̀ nítorí pé ilé ìwé náà kò gba alárinà kankan.
Ó ṣe pàtàkì láti fi kún un pé àjọ tó ń ṣe àkóso àwọn ilé ìwé ti ṣe àbẹ̀wò sílé ìwé náà wọ́n sì ti fi àṣẹ síi, kí wọn ó gba àṣẹ lọ́wọ́ àjọ JAMB ló kù.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Gbenga kò ṣàì má mẹ́nuba àwọn àdojúkọ tí ilé ìwé FUTES ní lásìkò yìí, èyí tó ṣe gbóògì ni àìtó owó láti ṣe gbogbo ohun tó yẹ, ó wí pé ìjọba kò le ṣe gbogbo rẹ̀ tán, èyí ló mú kí àwọn ó máa tọ àwọn èèyàn àti àjọ tó le ṣe ìrànwọ́ lọ.
Bí a bá rí ẹni tó le kọ́ ilé tàbí yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ sínú ilé ìwé yìí, a ó sọ ilé náà lórúkọ rẹ̀ yóò sì máa gba owó ìyálégbé.
Bí a bá sì rí àwọn tó fẹ́ ṣètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, ànfààní wà.
Lórí ilé ìwé gíga bákan náà, ìròyìn tí kò dùn mọ́ni nínú kan ló jáde láti ilé ìwé gíga Èkó UNILAG níbi tí akẹ́kọ̀ọ́ wọn kan ti kú sínú odò.
Báyìí ni ìròyìn nípa ikú Damilola Balogun ṣe lọ.
Damilola Balogun; akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Èkó ti kú sínú odò ní Lekki.
Àlàyé tí a rí gbà nípa ikú rẹ̀ ni pé òun àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ lọ sí ibi ìgbafẹ́ etídò kan tó wà ní Ibeju-lekki nígbà tí odò gbé e lọ níbi tó ti ń ṣeré létí omi.
Damilola ni ààrẹ àṣẹ̀ṣẹ̀yàn ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé náà, òun àti àwọn àṣẹ̀ṣẹ̀yàn bíi tiẹ̀ tẹ̀lé àwọn tó máa gbé ọ̀pá àṣẹ sílẹ̀ lọ ṣe ayẹyẹ ní ibi ìgbafẹ́ etídò náà lọ́jọ́rú, nígbà tó di ọjọ́ kejì, àwọn akẹgbẹ́ Damilola lọ àmọ́ òun àti àwọn méjì mìíràn nínú àwọn tó ń fipò sílẹ̀ dúró.
Ẹni tó ṣe àlàyé náà wí pé àwọn gbá bọ́ọ̀lù tán ni Damilola ní òun fẹ́ ṣeré létí omi kí òun ó sì máa ya àwòrán rẹ̀.
Ó ní òun kìlọ̀ títí pé òkun náà ń ru lárujù lásìkò náà àmọ́ Damilola kò dáhùn òun sì fi sílẹ̀ síbẹ̀.
Ẹ̀yìn ìgbà náà ni àwọn gbọ́ ariwo tí àwọn sì ríi pé Damilola ni odò ń wọ́ lọ pẹ̀lú ọwọ́ rẹ̀ lókè.
Àwọn adóòlá ẹ̀mí gbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí Damilola àmọ́ kò bá a mọ́.
Ìpele kẹrin ni Damilola wà ó sì yẹ kó bẹ̀rẹ̀ ìkọ́niwò ní ọjọ́ Ajé kó tó di pé ó bá odò lọ yìí.
Ọjọ́ kẹta ni wọ́n tó rí òkú rẹ̀ ní Museyo ní adojúkọ ibi tí omi náà ti gbé e wọ́n sì ti sin òkú rẹ̀ sí Museyo náà.
Olódùmarè nìkan ló le ṣọ́ àwọn ọmọ tí wọ́n wà nílé ìwé gíga gbogbo, ilé ìwé ni àwọn òbí rán wọn àmọ́ wọn yóò gba ibòmíràn lọ. Irú èyí fẹ́rẹ̀ kó bá ilé ìwé gíga Babcock nínú oṣù Igbe nígbà tí ọmọ arábìnrin Fijabi di àwátì fún ìdílé ọjọ́ mẹ́rin kó tó di pé wọ́n rí i, láàrin ìgbà tí wọ́n fi ń wá a náà, ìyá rẹ̀ fi ẹ̀sùn kan ilé ìwé giga Babcock pé
Arábìnrin Fijabi Oyindamola Omotayo ti ké gbàjarè síta lórí ọmọ rẹ̀ tó di àwátì lẹ́yìn tó gbé e lọ sí ilé ìwé.
Ilé ìwé gíga Babcock tó wà ní Ilishan-Remo, ìpínlẹ̀ Ogun ni ọmọ náà ń lọ, Oladipupo Sijuola sì ni orúkọ rẹ̀.
Ìyá rẹ̀ wí pé fúnra òun lòun gbé e lọ sí ilé ìwé náà ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Igbe. Ó ní ojú òun ló ṣe wọ inú ọgbà ilé ìwé náà lọ tí òun sì padà sílé.
Arábìnrin Fijabi ní òun pe ọmọ òun lẹ́yìn wákàtí mẹ́ta àmọ́ kò gbé aago, láti ìgbà náà ni òun kò ti ríi bá sọ̀rọ̀ tí òun kò sì gbúrǒ rẹ̀ títí di àsìkò yìí.
Ìyá Oladipupo ní òun wá a lọ sí ilé ìwé ní àná, ọjọ́ kejì, oṣù Èbìbí àmọ́ wọ́n sọ fún òun pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ a máa farasin sínú ọgbà ilé ìwé nígbà mìíràn pé kò sí ohun tó le ṣe ọmọ náà.
Ìyá Oladipupo kò fara mọ́ ohun tí Babcock sọ yìí, ó ní kí wọn ó wá ọmọ òun jáde ni. Bákan náà ló bèèrè pé kín ni ìdí tí wọ́n fi gbé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjì tó ríi gbẹ̀yìn; Lampard àti Tobi pamọ́?
Ní èsì sí ọ̀rọ̀ yìí, olùbádámọ̀ràn pàtàkì fún Gómìnà Dapo Abiodun lórí àtẹ̀jáde; Ọ̀gbẹ́ni Emmanuel Ojo wí pé òun ti kàn sí kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́, kọmíṣọ́nà sì ti kàn sí ọ̀gá ilé ìwé náà láti wá bí ọmọ náà ṣe rìn.
Ní báyìí, Oladipupo ti padà dé ilé ìwé Babcock sì ti fi ọwọ́ òsì júwe ilé fún un.



