Ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ wa ti yan Ọ̀gágun Onyinyechi Anele gẹ́gẹ́ bíi adélé alukoro fún ilé iṣẹ́ ológun. Olú ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ wa ni ìròyìn yìí ti jáde láàárọ̀ yìí.
Ìyànsípò yìí wáyé lẹ́yìn tí iṣẹ́ gbé alukoro tó wà nípò náà tẹ́lẹ̀; ìyẹn Ọ̀gágun Onyema Nwachukwu lọ sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ ológun mìíràn níbi tí yóò ti máa sin ìlú báyìí.
Ọ̀gágun Anele ni obìnrin àkọ́kọ́ tí yóò di ipò alukoro ilé iṣẹ́ ológun mú nílẹ̀ yìí, ọjọ́ kejìlélógún, oṣù Igbe tí a wà yìí náà ni Anele yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi adélé alukoro.
Lórí ìròyìn ilé iṣẹ́ ológun yìí kan náà, Ọ̀gágun tó ń ṣe àkóso ìgbanisíṣẹ́-ológun ní ìpínlẹ̀ Anambra; Chima Ekeator ti sọ wí pé igba péré ni àwọn ọ̀dọ́ tó fi orúkọ sílẹ̀ nínú ètò ìgbaniwọlé sínú iṣẹ́ ológun tó ń lọ lọ́wọ́ yìí.
Ọ̀gágun Chima sọ èyí níbi ìlanilọ́yẹ nípa iṣẹ́ ológun tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Anambra, ó wí pé ó ṣe pàtàkì láti la àwọn ọ̀dọ́ lọ́yẹ nípa iṣẹ́ ogun kí wọ́n le darapọ̀ mọ́ àwọn ológun ilẹ̀ yìí.
Ọ̀gágun Chima rọ àwọn olórí ọ̀dọ́ káàkiri ilẹ̀ Anambra láti gba àwọn ọ̀dọ́ agbègbè wọn níyànjú àti darapọ̀ mọ́ iṣẹ́ ológun. Nípa báyìí, àwọn ará Gúúsù-ìlà òòrùn náà ó le lẹ́nu ní ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ yìí, kò ní jẹ́ pé àwọn ẹ̀ka mìíràn nìkan ni yóò dipo mú nílé iṣẹ́ ológun.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra; Chukwuma Soludo kín ọ̀rọ̀ Ọ̀gágun Chima lẹ́yìn, ó wí pé ó ṣe pàtàkì láti bẹ̀rẹ̀ sí ní la àwọn ọ̀dọ́ lóye nípa iṣẹ́ ológun kí wọn ó le darapọ̀.
Gómìnà Soludo rọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwon baálẹ̀ láti mú ọ̀dọ́ mẹ́wàá wá fún ìforúkọsílẹ̀ náà lágbègbè wọn. Ó wí pé àwọn ọ̀dọ́ tí ọjọ́ orí wọn kò ju ọdún mẹ́ẹ̀dógún sí méjìlélógún ni àwọn ń fẹ́ kí wọ́n wa fi orúkọ sílẹ̀.
Ìjọba ológun.
Àwọn obìnrin Rivers tú yáyá tú yàyà jáde láàárọ̀ àná Ọjọ́rú láti ṣe ìwọ́de tako ìjọba ológun tó wà lórí àpèrè ní ìpínlẹ̀ Rivers. Wọ́n láwọn ò fẹ́ Ọ̀gágun Ete Ibas lórí ipò adárí mọ́ kí ààrẹ Tinubu ó dá Gómìnà àdìbòyàn; Siminalayi Fubara padà sí ipò rẹ̀. Ṣebí ẹni tó mọ àtiwáyé olúnǹgó náà níí mọ àtipadà rẹ̀.
Ìwọ́de yìí wáyé lẹ́yìn ìwọ́de àtakò tó wáyé lọ́jọ́ Ajé ní èyí tí ikọ̀ àwọn obìnrin kan fi ṣègbè fún Ibas.
Láti ìgbà tí Ọ̀gágun Ibas ti górí àpèrè ní ìpínlẹ̀ Rivers ni ọ̀rọ̀ náà ti dàbí ti adìyẹ tó bà lé okùn, ara ò rọ àwọn ará Rivers bẹ́ẹ̀ sì ni ara ò rọ ìjọba pàápàá. Bí àwọn kan ṣe ń ṣe ìwọ́de tako ìjọba ológun náà ni àwọn kan ń ṣe ìwọ́de ṣègbè fun un pé òun gan-an làwọn ń fẹ́.
Láàrín àwọn tó ń ṣe ìjọba náà gan-an, nǹkan kò fara rọ. Ní kété tí Ọ̀gágun Ibas gun orí apèrè ni olórí àwọn òṣìṣẹ́ ti gbé bọ́dì tó kọ̀wé fi ipò sílẹ̀. A gbọ pé Dọ́kítà George Nwaeke kọ̀wé ìfipòsílẹ̀ ránṣẹ́ sí olórí ìlú titun; Admiral Ibos-Ete Ibas pé òun kò ṣe iṣẹ́ mọ́.
Nínú èsì tí Ibas fi ránṣẹ́ síi ni ó ti dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún àsìkò péréte tó lò pẹ̀lú òun, Ibas kọ ọ́ pé kò dùn mọ́ òun nínú pé ó ń lọ àmọ́ kò sí ohun tí òun le fi dáa dúró. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ó sì ro rere síi fún ọjọ́ iwájú.
Àfi bí ìgbà tí Ibas ń retí kí George ó fipò rẹ̀ sílẹ̀ kó tó yan akọ̀wé ìjọba ni, Lọ́gán ló yan akọ̀wé àgbà ìjọba titun sípò. Ẹni tó yàn náà ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Ibibi Worika.
Ibas wí pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyẹ̀wò àwọn ìwé ẹ̀rí àti àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, kò sí ẹlòmíràn tó tó ipò náà dì mú ju Ibibi Lucky Worika lọ.
Èyí wáyé lẹ́yìn tí ààrẹ àti Gómìnà Fubara fi ohùn ránṣẹ́ síra wọn, ààrẹ fi ẹsùn kan Fubara pé òun ló ń fa rúgúdù ìpínlẹ̀ náà, Fubara náà fèsì pé òun kò mọ nǹkan kan nípa àwọn ẹ̀sùn náà.
Àwọn ẹsùn tí ìjọba Tinubu fi kan Fubara ni lílẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn adàlúrú láti bẹ́ ọ̀pá epo, àìkúnjú òṣùwọ̀n àti ìfẹ́ ara ẹni.
Èsì tí Fubara fọ̀ náà ni pé òun kò ní ìbáṣepọ̀ kankan pẹ̀lú àwọn jàǹdùkú tó ń fọ́ ọ̀pá epo káàkiri ìlú náà. Gómínà tí a dá dúró náà sọ láti inú àtẹ̀jáde tí akọ̀wé rẹ̀; Nelson Chukwudi gbé jáde pé òun kò lọ́wọ́ sí tàbí mọ ohunkóhun nípa bí àwọn jàǹdùkú ṣe ń fọ́ ọ̀pá epo. Ó wí pé ẹ̀sùn tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ ni kí àwọn ọlọ́pàá ó ṣe ìwádìí wọn dáadáa.
Nínú àtẹ̀jáde náà la ti rí i kà pé gbogbo àwọn fọ́nrán tí wọ́n gbé jáde náà níbi tí wọ́n ti fọ́ ọ̀pá epo ló jẹ́ ayédèrú. Fubara wí pé àwọn ará agbègbè náà fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ní agbègbè wọn.
Siminalayi Fubara sọ gbangba gbàǹgbà pé òun k̀ò lọ́wọ́ tàbí mọ ohunkóhun nípa ẹ̀sùn tí ìjọba àpapọ̀ fi kan òun nípa àwọn tí wọ́n ń fọ́ àgbá epo, ó wí pé kí ìjọba ó ṣe ìwádìí rẹ̀ fínní.
Nígbà tí èyí ṣì ń lọ lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Rivers, kò dájú pé ìpínlẹ̀ náà tòrò ní kíákíá báyìí látàrí pé Ọ̀gágun Ibas gan-an kò ráàyè to ìlú, òní ẹjọ́, ọ̀la ìpàdé lo ń bá kiri láti ìgbà tó ti górí àpèrè náà. Kódà, lónìí yìí kan náà ni ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ránṣẹ́ pèé kí wọ́n tún le ṣe àṣàrò lórí àwọn ìwọ́de tó ń lọ lọ́tùn-ún lósì.
Discussion about this post