Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Kwara tó fìkàlẹ̀ sí Ilorin ti pàṣẹ kí wọn ó yọ̀ǹda ìyókù Hafsoh fún àwọn òbí rẹ̀ láti lọ sin.
Adájọ́ Hannah Ajayi ló pàṣẹ yìí nìgbà tí agbẹjọ́rò ẹbí Hafsoh bèèrè fún ìyọ̀ǹda ìyókù Hafsoh kí wọn ó sin ín kí ẹ̀mí rẹ̀ ó le sinmi.
Adájọ́ Hannah wí pé òun kò ní àtakò sí ìbéèrè yií, ó wí pé òun bá àwọn ẹbí Hafsoh kẹ́dùn ó sì pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó yọ̀ǹda ìyókù ọmọ náà fún àwọn òbí rẹ̀.
Ikú Hafsoh:
AbdulRahman ni orúkọ afurasí alápatà yìí, ìlú Ilorin ló tẹ̀dó sí, inú ilé rẹ̀ náà ló sọ di odò ẹran tó ti ń pa á kun ún. Èyí tó bu ú lọ́wọ́ yìí ni ti ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ tó pa, Hafsoh lọ kí AbdulRahman nílé ni kò dé mọ́. Ìtọpipin àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi mú AbdulRahman, ó ti pa ọmọ náà ó sì ti gé e níkèéníkèé sínú ike ọ̀dà ọlọ́mọrí.
Ó ti fojú ba ilé ẹjọ́ lẹ́ẹ̀kan níbi tó ti sọ pé òun kò jẹ̀bi, adájọ́ sì sún ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ síwájú.
Lónìí ni ìgbẹ́jọ́ mìíràn wáyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ni wọ́n péjú pésẹ̀ sílé ẹjọ́ náà níbi tí adájọ́ Hannah ti pàṣẹ kí wọn ó lọ sin àgékù ọmọ náà.
Ìṣẹ̀lẹ̀ méjì ló ṣẹlẹ̀ nínú oṣù Ẹrẹ́nà tí èyí ṣẹ̀, inú oṣù náà ni olórin ẹ̀mí kan náà gba ẹ̀mí lẹ́nu ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀.
A mú ìròyìn náà wá pé Akọrin ẹ̀mí ni Timilehin Ajayi, orí àfẹ́sọ́na rẹ̀; Salome Enejo ni wọ́n bá lọ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì bá àwọn ẹ̀ya ara yòókù tó ti gé lékìrìlékìrì sínú àpò nílé rẹ̀.
Ọjọ́ Àìkú ni ọjọ́ yìí, Timilehin gbé orí Salome sínú àpò, ìsìń ṣì ń lọ lọ́wọ́, olùjọ́sìn kan ló fura sí Timilehin pé ìrìn rẹ̀ mú ìfura dání bó ṣe ń lọ sí etídò kan tí kò jìnnà sílé ìjọsìn.
Ẹni yìí pe àwọn èèyàn mọ́ra, wọ́n sì tọ ipasẹ̀ rẹ̀, bí Timilehin ṣe rí wọn ló sọ àpò náà sódò. Wọ́n mú un pé kó yọ àpò náà kó sì tú u, ó feré gée àmọ́ wọ́n lé e mú, títú tí yóò tú àpo yìí, orí àfẹ́sọ́nà rẹ̀; Salome ni wọ́n bá nínú rẹ̀.
Ìdájọ́ ọwọ́ ni wọ́n fẹ́ ṣe fún un àmọ́ àwọn ọlọ́pàá gbà á kalẹ̀, lẹ́yìn náà ni wọ́n lọ tú ilé rẹ̀ tí wọ́n sì bá àwọn ẹ̀yà ara Salome nínú àpò méji.
Àwọn ẹbí Salome ṣe ìdámọ̀ ọmọ wọn, ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún ni Salome, àgùnbánirọ̀ sì ni pẹ̀lú.
Olùkọ́ni Bibeli ilé ìjọsìn náà; Caleb Umaru ṣe àlàyé fún àwọn ọlọ́pàá pé ọmọ ìjọ kan ló fura sí Timilehin nígbà tí ara rẹ̀ kò balẹ̀, ó ṣọ́ ọ títí tó fi dé etídò náà kí wọn ó tó wá mú un’
Lẹ́yìn ìgbà náà ni àwọn akọ̀ròyìn bá Timileyin Ajayi sọ̀rọ̀ pé báwo ni ó ṣe rí lára rẹ̀? Ẹ ka ohun tó wí ‘Timileyin Ajayi; akọrin ẹ̀mí tí ọwọ́ tẹ̀ nígbà tó pa Salome wí pé òun kò kábàámọ̀ pé òun pa ọmọbìnrin náà rárá, òun pa á òun pa á náà ni kò sí bàbàrà kankan níbẹ̀, Timilehin ní kí ẹ yé pọ́n jẹ̀bẹ̀ lákìísà.
Àwọn akọ̀ròyìn bá Timileyin sọ̀rọ̀ pé báwo ni ó ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tí wọ́n mú un fún ìpànìyàn àti pé báwo ni ó ṣe rí lára rẹ̀ pé ó pààyàn?
Timilehin kó àlàyé ṣe, ó kó ẹjọ́ rò pé kò sí nǹkan bàbàrà nínú pé òun pa Salome o, ó ti lé lọ́dún kan tí òun ti ń fẹ́ Salome, Timilehin ní òun fura síi pé ó ń fẹ́ àwọn ọkùnrin mìíràn ni òun ṣe pa á.
Ohun tí tí àwọn ẹbí Salome wí ni pé Timilehin jí Salome gbé ni pé àwọn kò ríi mọ́ ọmọ àwọn rí. Wọ́n ní ó pa á nípakúpa fún ìdí tí ó yé òun nìkan. Àbúrò bàbá Salome wí pé ìgé tó gé ẹran ọmọ náà lékìrìlékìrì fi hàn pé ó fẹ́ sè é jẹ tàbí tà á fún àwọn tí yóò jẹ ẹ́ ni. Wọ́n ní ìdájọ́ òdodo ni awon ń retí láti ọ̀dọ ìjọba.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé Timilehin yóò fojú ba ilé-ẹjọ́ láìpẹ́, bó bá sì fi le jẹ̀bi, yóò jìyà lábẹ́ òfin.
Ìgbẹ́jọ́ lórí ikú Salome ṣì ń lọ lọ́wọ́ àmọ́ ti afurasí tó ṣekú pa Bamishe ti gba ìdájọ́ ikú.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé:
Awakọ̀ BRT tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó ṣekú pa Oluwabamishe Ayanwola ni ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Èkó ti dá ẹjọ́ ikú fún lónìí, ọjọ́ kejì, oṣù Èbìbí.
Andrew Ominikoron ni orúkọ awakọ̀ BRT náà, ẹ̀sùn tí ìjọba fi kàn án ni pé ó bá Bamishe ní àjoṣepọ̀ tìpátìkúùkú ó sì tún gba ẹ̀mí rẹ̀.
Ẹni ọdún méjìlélógún ni Bamishe, ní ọjọ́ náà lọ́hùn-ún, Bamishe ń bọ̀ láti ibi iṣẹ́ rẹ̀ ó sì wọ ọkọ̀ BRT tí Andrew jẹ́ awakọ̀ rẹ̀. Ohùn tó fi ránṣẹ́ sí ọ̀rẹ́ rẹ̀ nípa bí Andrew ṣe gbé àwọn èèyàn kan lọ́nà àti bí ara ṣe fu ú ni ó jẹ́ ẹ̀rí nígbà tí wọ́n rí òkú rẹ̀.
Àti ìgbà náà ni ìgbẹ́jọ́ ti bẹ̀rẹ̀ tí àwọn obìnrin mìíràn tó ti fipá bá lò pọ̀ sì jáde sọ̀rọ̀.
Adájọ́ Sherifat Sonaike ti gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ lórí ẹ̀sùn náà pé Andrew jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn náà ó sì pàṣẹ kí wọn ó so ó rọ̀ títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lára rẹ̀.
Bí wọ́n tilẹ̀ pa Andrew, kò jí Bamishe padà sí ayé mọ́. A kò ní ṣàgbákò agbénipa.
Discussion about this post