Ìjọba ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ti fagi lé ẹjọ́ tí wọ́n ń bá Olorì Ọ̀ọ̀ni tẹ́lẹ̀; Naomi Silekunola àti Oriyomi Hamzat ṣe lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìtẹnipa tó wáyé ní Ìbàdàn nínú oṣù Ọ̀pẹ, ọdún tó kọjá.
Àpèjẹ fún àwọn ọmọdé ni àjọ Naomi gbé kalẹ̀ lọ́jọ́ náà ní ilé ìwé kan tó wà ní Bashorun, Ìbàdàn.
Aago tí wọ́n dá fún wọn kò tíì lù tí àwọn èèyàn fi bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe rọ̀tìrọ̀tì tí wọ́n sì tẹ àwọn ọmọdé márùndínlógójì pa.
Láti ìgbà náà ni ìgbẹ́jọ́ ti bẹ̀rẹ̀ tí ìjọba sì fi òfin mú Naomi Silekunola ; Olorì tẹ́lẹ̀, Oriyomi Hamzat; Olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ Agidigbo àti Abdullahi Fasasi; ẹni tó jẹ́ ọ̀gá ilé ìwé náà.
Ní báyìí, ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti fagi lé ẹjọ́ náà wọ́n sì ti dá àwọn mẹ́tẹ́ẹ̀ta sílẹ̀ láyọ̀ àti àlàáfíà.
Ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́; Abiodun Aikomo fi èyí múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni ìjọba Ọ̀yọ́ ti wọ́gi lé ẹjọ́ náà. Ó ṣe àlàyé pé àwọn ti a fẹ̀sùn kàn náà kò lérò àti pa àwọn ọmọ náà, ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn jẹ́ èyí tó jẹ́ èyí tó bani lọ́kàn jẹ́ ni.
Bí ó ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an
Àpèjẹ òpin ọdún tí Olorì Naomi Silekunola ṣe fún àwọn ọmọdé ní ìlú Ìbàdàn mú ẹ̀mí ọmọ márùndínlógójì lọ.
Èrò pọ̀ lápọ̀jù, wọn kò sì fi ètò wọlé ló fàá tí wọ́n fi tẹ àwọn ọmọ náà pa.
Ẹẹ́dẹ́gbaata (5000) ọmọdé ni ètò náà pèsè oúnjẹ fún àmọ́ àwọn èèyàn tó wà nibẹ̀ dín díẹ̀ ní ẹgbàárin (8000), kódà, inú ọgbà ilé ìwé náà ni ọ̀pọ̀ wọn sùn mọ́jú.
Aago mẹ́wàá ló yẹ kí ètò náà ó bẹ̀rẹ̀ àmọ́ nígbà tí yóò fi di nǹkan bí aago mẹ́jọ àárọ̀, àwọn èrò ti pọ̀ bíi baba èsùá wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí ní tẹ ara wọn pa.
Ilé iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ Agidigbo tó wà ní Ìbàdàn fèsì sí ẹ̀sùn tí àwọn èèyàn fi kàn wọ́n pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ikú àwọn ọmọ náà.
Alhaji Oriyomi Hamzat; Olùdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ náà sọ̀rọ̀ láti ẹnu Olùdarí ètò ilé iṣẹ́ náà; Olayinka Abdul-wahab pé àwọn kọ́ ni alákòóso ètò àpèjẹ náà. Àjọ ẹlẹ́yinjú àànú WINGS ti Olorì Naomi ló ṣètò àpèjẹ náà.
Ilé iṣẹ́ Agidigbo wí pé iṣẹ́ ìgbésáfẹ́fẹ́ ni àwọn gbà níbi ètò náà pé àwọn kìí ṣe alákòóso rẹ̀. Alhaji Oriyomi Hamzat bá àwọn òbí tí wọ́n pàdánù ọmọ wọn kẹ́dùn ó sì tọrọ àlàáfíà fún àwọn tó ṣì wà ní ilé ìwòsàn.
Àwọn òbí tó wà níbi àpèjẹ náà bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀. Ọ̀kan nínú wọn wí pé òun àti ọmọ òun sùn mọ́jú ni láìmọ̀ pé oorun ìkẹyìn tí àwọn yóò jọ sùn náà nìyẹn.
Òbí kan wí pé èrò pọ̀ lóòótọ́ àmọ́ bí àwọn alákòóso ètò náà bá ní ètò ni, ìṣẹ̀lẹ̀ náà ó bá má sẹlẹ̀.
Àwọn ikọ̀ akọ̀ròyìn kàn sí àwọn ilé ìwòsàn tí wọ́n gbé àwọn ọmọ náà lọ.
Ilé ìwòsàn Patnas tó wà ní Bashorun wí pé ọmọ mẹ́fà ni wọ́n kó wá sí ibẹ̀, márùn-ún ló kú nígbà tí àwọn ti yọ̀nda ọ̀kan tó yè fún àwọn òbí rẹ̀.
Ilé ìwòsàn Molly tó wà ní Idi-Ape àti ilé ìwòsàn Western tó wà ní Bashorun wí pé àwọn ọmọ tí wọ́n kó wá sí ibẹ̀ ti kú kí wọ́n tó gbé wọn dé (BID).
Ilé ìwòsàn UCH náà gba àlejò àwọn ọmọ márùn-ún, gbogbo wọn ló sì kú.
Ibi tó dé dúró báyìí.
Láti ìgbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀ ni àwọn afurasí náà ti ń pààrà ilé ẹjọ́. Ọjọ́ mọ́kànlélógún ni wọ́n kọ́kọ́ lò ní àtìmọ́lé kí wọn ó tó gba onídùúró wọn.
Ó níye ọjọ́ tí Oriyomi Hamzat lò nílé ìwòsàn nítorí ìjayà ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn olólùfẹ́ Naomi àti Oriyomi kò yé ké tantan lori ìtàkùn ayélujára láti bèèrè fún ìdásílẹ̀ àwọn tí a fẹ̀sùn kàn náà.
Adúrà wọn ti gbà báyìí tí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti fagi lé ẹjọ́ náà.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìtẹnipa mìíràn tó wáyé.
Ọdún tí àwọn òbí ò le gbàgbé bọ̀rọ̀ ni ọdún 2024. Yàtọ̀ sí èyí tó ṣẹlẹ̀ ní Ìbàdàn yìí, ìṣẹ̀lẹ̀ ìtẹnipa mìíràn wáyé ní Abuja nínú osù Ọ̀pẹ kan náà.
Ilé ìjọsìn Àgùdà Holy Trinity tó wà ní Maitama, Abuja ló pe àwọn èèyàn fún ẹ̀bùn ọdún lọ́jọ́ náà. Aago mẹ́fà ìdájì ni àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní tẹ ara wọn tí wọ́n sì àwọn èèyàn mẹ́wàá pa, nínú wọn ni ọmọdé mẹ́rin tí àwọn mẹ́jọ mìíràn sì tún fara pa. Josephine Adeh; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Abuja fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀.
Bákan náà ni ọmọ ṣorí ní ìpínlẹ̀ Anambra nígbà tí afúnnimáwobẹ̀ kan pe àwọn èèyàn láti wá gba ẹ̀bùn ọdún.
Agbègbè Okija ní ìpínlẹ̀ Anambra ni èyí ti ṣẹlẹ̀, àwọn èèyàn mẹ́ta ni wọ́n tẹ̀ pa bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ètò náà kò tíì bẹ̀rẹ̀ rárá.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra; Tochukwu Ikenga fi ìdí èyí múlẹ̀.
Ìhà tí ìjọba kọ sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Ìjọba ààrẹ Bola Ahmed Tinubu korò ojú sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìtẹnipa tó wáyé káàkiri náà, ààrẹ sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àìlétò àwọn tí wọ́n gbé ètò náà kálẹ̀ ló fa bí àwọn èèyàn ṣe tẹ ara wọn pa náà. Ó ṣe àkàwé pé òun náà máa ń ṣètò ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ fún àwọn èèyàn nílé rẹ̀ tó wà ní Èkó lọ́dọọdún pé irú èyí kò sì ṣẹlẹ̀ rí.
Ààrẹ bá àwọn òbí àwọn ọmọ náà kẹ́dùn ó sì ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn tí wọ́n bá fẹ́ ṣe irú rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú láti ṣe gbogbo ètò ààbò tó yẹ.
Discussion about this post