Ìjọba Èkó ṣe àpérò kan lánàá níbi tí wọ́n ti ṣí aṣọ lójú éégún àwọn ìjìyà titun nípa ti owó ìtanràn fún àwọn awakọ̀ tó bá rú òfin ojú pópó.
Kọmíṣọ́nà fún ìgbòkègbodò ọkọ̀ ojú pópó; Ọ̀gbẹ́ni Oluwaseun Osiyemi ṣe àlàyé pé ìgbésẹ̀ titun yìí yóò kún èyí tó ti wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀ lórí ìdènà eré àsápajúdé lójú pópó.
Àwọn ẹ̀rọ kan ti wà lójú pópó tẹ́lẹ̀ tó ń ṣọ́ bí àwọn awakọ̀ ṣe ń pa òfin ìwakọ̀ mọ́ sí tó sì ń jábọ̀ fún àwọn ọlọ́pàá níbùdó wọn, wọ́n ní àwọn ẹ̀rọ titun yìí yóò ṣe àfikún iṣẹ́ tí àwọn ẹ̀ro ti tẹ́lẹ̀ yìí ń ṣe.
Ilé iṣẹ́ Huawei ni ìjọba Èkó jọ gbé àwọn ẹ̀rọ titun yìí kalẹ̀.
Ohun tí àwọn ẹ̀ro náà yóò ṣe ni pé yóò máa ka iye kìlómítà tí ọkọ̀ kọ̀ọ̀kan tó bá gba ojú pópó tí a bá fi ṣọ́ ń sá yóò sì tún máa ṣọ́ bí àwọn ọkọ̀ ṣe tẹ̀lé iná mọ̀nàmọ́ná adarí ọkọ̀ sí.
Ọkọ̀ tí kò bá tẹ̀lé iná mọ̀nàmọ́ná adarí ọkọ̀ yóò san ogún ẹgbẹ̀rún náìrà owó ìtanràn nígbà tí èyí tó bá sáré kọjá òdiwọ̀n yóò san àádọta ẹgbẹ̀rún náìrà.
Kò sí pé a ń lé ọkọ̀ mú pẹ̀lú àwọn ẹ̀rọ titun yìí, awakọ̀ tó bá ti rúfin yóò kàn gbọ́ tun-tun lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, àtẹ̀jíṣẹ́ lórí òfin tó rú àti iye tí yóò san ni yóò bá níbẹ̀.
Méjì ẹ̀rọ wọ́n ti gbé sí àwọn ojú pópó báyìí, ọ̀kan wà ní Alápẹ̀rẹ̀ nígbà tí èkejì wà ní òpópónà Mobolaji Bank Anthony.
Ọ̀gbẹ́ni Osiyemi wí pé àwọn owó ìtanràn yìí kìí ṣe láti fi ara ni ẹnikẹ́ni bíkòṣe láti jẹ́ kí àwọn awakọ̀ ó máa ṣe jẹ́jẹ́ kí wọn ó sì pa òfin ọkọ̀ wíwà mọ́.
Àwọn tí wọ́n wà níbi àpérò náà ni aṣojú lati ilé iṣẹ́ mínísítà fún ìgbòkègbodò ọkọ̀; Olawale Musa, kọmísọ́nà fún ìmọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé; Olatunbosun Alake àti àwọn mìíràn tọ́rọ̀ kàn.
Wọ́n fìdìí rẹ̀ múlẹ̀ níbi ìpàdé náà pé àìtẹ̀lé àwọn òfin ọkọ̀ wíwà ló ń ṣe òkùnfà ọ̀pọ̀ àwọn ìjàmbá ọkọ̀ tó ń wáyé tó sì ń mú ẹ̀mí lọ.
Wọ́n ní ìgbésẹ̀ titun yìí yóò mú kí àwọn awakọ̀ ó ti ọwọ́ ọmọ wọn bọ aṣọ.
A kò le sọ pé wọ́n jẹ ayó pa nítorí pé lóòótọ́ ni pé àwọn ìjàmbá ọkọ̀ mìíràn jẹ́ àfọwọ́fà awakọ̀.
Àná la mú ìròyìn kan wá fún yín nípa awakọ̀ ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan tó sáré àsápajúdé tó sì rún òṣìṣẹ́ àbò ojú pópó ìpínlẹ̀ Èkó Lastma lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀ wómúwómú.
Ọkọ̀ yìí jáde láti Agidingbi ya wọ oríta Omole, eré àsápajúdé gidi ni wọ́n sọ pé ọkọ̀ yìí bá jáde, ó pàdánù ìjánu rẹ̀ lójijì ó sì mú òṣìṣẹ́ lastma yìí gùn mọ́lẹ̀.
Awakọ̀ yìí ṣíyán kò dúró gbọbẹ̀, ó fẹsẹ̀ fẹ́ẹ nígbà tó rí ohun tó ṣẹlẹ̀ àmọ́ àwọn ọlọ́pàá dọdẹ rẹ̀ wọ́n sì ríi mú.
Nígbà tí wọn yóò fi gbé òṣìṣẹ́ LASTMA yìí dé ilé ìwòsàn ìjọba ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó ti ìpínlẹ̀ Èkó; LASUTH, ẹ̀ka ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ni wọ́n gbé e lọ, àwọn dọ́kítà sì wí pé wọn le tọ́jú apá náà àmọ́ wọ́n gbọdọ̀ gé ẹsẹ̀ náà ní kíákíá.
Wọ́n gé ẹsẹ̀ ọ̀tún arákùnrin yìí o, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ náà kò gbé ṣéṣé mọ́.
Ọ̀gá àgbà àjọ LASTMA ṣe àbẹ̀wò sí arákùnrin yìí nílé ìwòsàn, kò le royìn gbogbo ohun tí ojú rẹ̀ rí tán.
Olalekan Bakare-Oki wí pé ọ̀rọ̀ náà burú fún arákùnrin yìí. Ó ṣe àpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà bíi àgbákò burúkú.
Ó ṣe àfikún pé bí awakọ̀ náà bá ṣe jẹ́jẹ́ ni, ó ṣeéṣe kí ìṣẹ̀lẹ̀ asọnidaláàbọ̀ ara yìí ó má ṣẹlẹ̀.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ LASTMA; Adebayo Taofiq pé òṣìṣẹ́ Lastma kan tó ń lọ síbi iṣẹ́ rẹ̀ ṣe alábàápàdé ìjàmbá tó mú ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀ lọ tó sì tún mú ìpalára bá ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
Wọ́n ní ọwọ́ tẹ awakọ̀ náà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó kọ́kọ́ sá lọ àmọ́ àwọn ọlọ́pàá ṣe àwárí rẹ̀.
Awakọ̀ yìí ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí fún ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.