Ìjàm̀bá ọkọ̀ mẹ́ta ló ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ Àìkú,ọjọ́ ọdún ìtunu ààwẹ̀. Ọ̀kan ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kastina, òmírà wáyé ní Ogijo, ìpínlẹ Ogun nígbà tí ẹ̀kẹta ṣẹlẹ̀ ní Maryland, ìpínlẹ̀ Èkó.
Ìjàm̀bá ọkọ̀ ní Kastina:
Ogún èèyàn ni ọkọ̀ akérò Hummer náà kó lọ́jọ́ ìtunu ààwẹ̀, òpópónà Malumfashi-Kafur ní ìjọba ìbílẹ̀ Malumfashi ní ìpínlẹ̀ Kastina ni ọkọ̀ yìí dànù sí.
Èèyàn mẹ́sàn-án ló kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí àwọn mọ́kànlá yòókù farapa yánnayànna.
Àjọ tó ń mójútó ìgbòkegbodò ọkọ̀, ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Kastina sọ̀rọ̀ láti ẹnu adarí wọn; Aliyu Ma’aji pé Èkó ni ọkọ̀ náà ti gbéra, Kastina náà ni ó ń lọ, ibẹ̀ náà ló sì dànù sí. Ó wí pé àwọn èèyàn mọ́kànlá tó yè náà ni àwọn kó lọ sílé ìwòsàn.
Ma’aji ṣe àlàyé pé ọkọ̀ yìí nìkan ló ní ìjàm̀bá náà o, ohun tí ìwádìí sì fi hàn ni pé awakọ̀ náà sáré àsápajúdé ní èyí tó mú kí ó pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì gbókìtì.
Mẹ́ta nínú àwọn mọ́kànlá náà ni wọ́n tún padà gbé lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Rimi nítorí pé wọ́n dá lẹ́sẹ̀, wọ́n dá àwọn méje sílẹ̀ nígbà tí ọ̀kan yòókù ṣì ń gba ìtọ́jú.
Ìjàm̀bá ọkọ̀ ní Ogun àti Èkó:
Ìdájí ọjọ́ Àìkú ní nǹkan bíi aago mẹ́fà kọjá ni ọ̀kan ṣẹlẹ̀ níbi tí ọkọ̀ àjàgé eléjò kan ló pàdánù ìjánu rẹ̀ kọlu ọkọ̀ akérò kan tó kó èèyàn méjìlá ní Ogijo.
Àwọn èèyàn ṣe aájò wọn dé ilé ìwòsàn àmọ́ ẹnìkan gbé ẹ̀mi mì nígbà tí àwọn mọ́kànlá yòókù ń gba ìtọ́jú.
Ìjàm̀bá yìí fa súnkẹrẹ-fà-kẹrẹ lójú pópó àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ TRACE ti yanjú rẹ̀.
Èkejì ló ṣẹlẹ̀ ní Maryland, Èkó níbi tí àwọn ọkọ̀ kórópe méjì kan kọlu ara wọn. Ọ̀kan ló pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré tó sì lọ kọlu èkejì, àwọn méjéèjì wọ́ ara wọn lórí eré náà lọ kọlu èèyàn kan tó dúró tirẹ̀ sí ẹgbẹ́ títì ní tirẹ̀. Wọ́n ti gbé òkú ẹni náà lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Ikeja.
Olùbádámọ̀ràn Gómìnà Babajide Sanwoolu; Sola Giwa fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ránṣẹ́ sí ìdílé olóògbé náà. Ó gba àwọn awakọ̀ níyànjú láti máa ṣe àyẹ̀wò ọkọ̀ wọn lóòrèkóòrè.
Bákan náà la tún gbọ́ pẹ ìjàm̀bá ọkọ̀ mìíràn wáyé ní ìpínlẹ̀ Abia. Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Ọkọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò kan ló dànù sí Isieke ní òjú ọ̀nà Umuahia sí Bende. Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ojú pópó, àwọn ọlọ́pàá, àwọn ológun àti àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò abẹ́lé tí gbogbo wọn jẹ́ mẹ́sàn-án ló wà nínú ọkọ̀ náà.
Ohun tó ṣe òkùnfà ìjàm̀bá náà ni ìjánu ọkọ̀ náà tó já pàtì lórí eré ní èyí tó mú kí ọkọ̀ náà ó gbókìtì. Ẹni tó kú jẹ́ ẹ̀ṣọ́ aláàbò ojú pópó ti ìjọba àpapọ̀ FRSC nígbà tí àwọn yòókù ti wà ní ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Abia; Alex Otti bá ẹbí olóògbé náà kẹ́dùn ó sì tún wí pé ìjọba yóò san owó ìtọ́jú àwọn tó farapa.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu adarí àjọ ẹ̀ṣọ́ aláàbò ojú pópó, ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Abia; Ngozi Ezeoma. Ó ṣe àlàyé wí pé ọkọ̀ náà pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré ló jẹ́ kí ó gbókìtì. Alẹ́ ọjọ́ Àìkú ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní oríta Isieke. Ilé ìwòsàn ìjọba Umuahia ni wọ́n gbé àwọn mẹ́jọ náà lọ nígbà tí wọ́n gbé òkú ẹni tó kú náà lọ sí ilé ìgbókùúsí.
Bí a ṣe ń kọ ìròyìn yìí lọ́wó ni ìròyìn kan tẹ̀ wá lọ́wọ́ nípa Dare àti ọmọ baba onílé kan tí àwọn ajínigbé gbé lọ ní ọjọ́ Ẹtì tó lọ yìí. Ohun tí a gbọ́ náà ni pé:
Àwọn ajínígbé palẹ̀ bàbá kan àti ọmọ kan mọ́ ní ijede, ìpínlẹ̀ èkó.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ti ṣe àlàyé bí wọ́n ṣe gba bàbá kan àti ọmọ bàbá onílé kan kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé.
Ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n, oṣù Igbe ni àwọn ajínigbé náà ya wọ agbégbè Ijede ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án alẹ́. Wọ́n gbé arákùnrin kan tó ń jẹ́ Dare àti ọmọ bàbá onílé tó ti ilé Dare lọ.
A gbọ́ pé àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí yìí mú àwọn èèyàn yìí ní tìpàátikúùkú wọ́n sì tún pa ajá ọdẹ kan. Benjamin Hundeyin; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó wí pé àwọn ta mọ́ra ní gẹ́lẹ́ tí àwọn gba ìpè náà. Wọ́n fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọdẹ ìbílẹ̀ láti wá àwọn èèyàn náà rí.
Ọjọ́ àbámẹ́ta ni wọ́n rí àwọn ẹni náà gbà kalẹ̀ láì farapa tí wọ́n sì fà wọ́n lé àwọn mọ̀lẹ́bí wọn lọ́wọ́.
Ó ṣe pàtàkì láti mú ìròyín ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Àìkú yìí kan náà ní ìpínlẹ̀ Kwara. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ náà ni pé àrá ba nǹkan jẹ́ gan-an ní ìpínlẹ̀ kwara.
Ó lé ní igba ilé àti ilé ìwé ìjọba ni òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá ti dà wó ní ìpínlẹ̀ Kwara. Àwọn agbègbè Ilorin tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara, Ogele àti Eyenkorin ní ìjọba ìbílẹ̀ Asa ni èyí ti ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ Àìkú ọjọ́ ọdún ìtunu ààwẹ̀.
Ohun tí a gbọ́ ni pé ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àìkú ni òjò náà bẹ̀rẹ̀ tó sì mú àrá ńlá dání. Àrá yìí pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tó fi wó ogún ilé palẹ̀ ráúráú, òrùlé bíi igba ló ká dànù, àwọn ilé ìwé àti ilé iṣẹ́ náà kò gbẹ́yìn.
Igbákejì alága ìlú Ifeodun ní Eyenkorin; Ọ̀gbẹ́ni Zubairu Abiola banújẹ́ lórí iṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó wí pé ìjàm̀bá náà pọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ti di aláìnílé lórí látàrí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Abiola ké sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara láti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn tọ́rọ̀ kàn. Ó wí pé èyí Gómìnà kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ṣe ìrànwọ́ fún àwọn tó nílò rẹ̀, nítorí náà ni àwọn ṣe ké sí i lórí ọ̀rọ̀ yìí.
Discussion about this post