Ọjà tó wà ní òpópónà Iweka ní Onitsha ti jóná gúrúgúrú lóru àná mọ́jú.
Nńkan bíi aago mẹ́jọ àbọ̀ alẹ́ àná ni ina náà sẹ́yọ tó sì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsọ̀ balẹ̀.
A kò tíì le sọ ohun tó ṣe òkùnfà iná náà lásìkò tí a kọ ìròyìn.
Ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Anambra fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé àwọn gba ìpè pàjáwìrí náà ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án kọjá nípa iná náà.
Àwọn panápaná ṣe iṣẹ́ wọn lóòótọ́ àmọ́ iná náà kò ṣàì má jó àwọn ìsọ̀ mẹ́rin kanlẹ̀ tí ọjà olówó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ sì ṣòfò dànù. Àwọn ọjà bíi àga ilé, ìbùsùn àti àwọn ohun èlò inú ilé mìíràn ló bá iná náà rìn.
Ilé iṣẹ́ panápaná ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ohun tó ṣe okùnfà iná náà
Èyí wáyé lẹ́yìn tí a mú ìròyìn ọjà ìrẹsì Wurukum tó jóná wá fún yín pé ‘ọjà ìrẹsì Wurukum tó wà ní ìpínlẹ̀ Benue náà sọ iná dorin, lásìkò tí kò sí oúnjẹ nílùú tí ìrẹsì di góòlù lọ́jà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpò ìrẹsì tún jọná, èyí ò ha pọ̀jù bí? A rí ìròyìn náà gbà pé iná sẹ́yọ ní ọjà ìrẹsì tó wà ní Wurukum ní ìtòsí afárá odò Benue ní Makurdi tíí ṣe olú ìlú Ìpínlẹ̀ Benue.
Ìrẹsì tó jóná kọjá ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù náírà. Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná tilẹ̀ ṣaájò àmọ́ ṣe ni iná náà gori ilé fẹjú toto ni, kò ní òun ò run gbogbo àwọn ìsọ̀ ìrẹsì náà.
Ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́jà náà tó pe orúkọ rẹ̀ ní Mercy wí pé ìrẹsì tí iye rẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́wàá náírà ni ó jóná nísọ̀ oun pẹ̀lú àwọn irin iṣẹ́ tí wọ́n fi ń pàkúta inú ìrẹsì.
Jeremiah náà wí pé òun kò tilẹ̀ mọ ibi tí òun yóò ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kó àwọn ọjà òun jáde lòun ṣe ń wòó títí tó fi jóná tán.
Alága ọja Wurukum; Yerva Igyar wí pé àwọn irin iṣẹ́ bíi mẹ́fà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àpò ìrẹsì ló jóná keérú.
Bákan náà ni wọ́n wí pé kìí ṣe wáyà iná ló fa iná náà nítorí pé àwọn kò lo iná ọba rárá ní ọjà náà. Wọ́n rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Gómìnà Hyacinth Alia fún ìrànlọ́wọ́.
Ṣé ẹ gbọ́ ti ilé alájà méjì tó jóná ní ìpínlẹ̀ Èkó?
Ilé alájà méjì kan tó wà ní ojúlé kẹrìndínlógún kejì, òpópónà Agidi ní ibùdókọ̀ Osogun, Alapere ti jóná kan éérú báyìí.
Èyí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ fún ìlé iṣẹ́ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì; Olufemi Oke-Osanyintolu pé àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án àárọ̀ nípa ilé náà tó ń jó.
Àwọn òṣìṣẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ẹ̀ka Alausa ati àwọn panápaná ló ta mọ́ra dé ibẹ̀, wọ́n bá ilé náà ti gbogbo òkè rẹ̀ ti jóná. Yàrá mẹ́rin ló wà ní òkè ilé yìí, gbogbo rẹ̀ ló jóná àmọ́ kò dé àwọn yàrá ìsàlẹ̀.
Àyẹ̀wó fi hàn pé iná náà sẹ́yọ láti inú yàrá ìdáná tó wà lókẹ làtàrí àwọn wáyà iná tó gún ara wọn.
Kò sí ẹni tó fara pa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bíi ohun tí a rí gbà.
Ọjọ́ wo ni ti orí afárá Otedola ṣì ṣẹlẹ̀ ná? Ní èyí tó ẹ̀mí tọkọtaya titun lọ. A ṣì ń jẹ ti ìlú Abuja lẹ́nu níbi tí ogúnlọ́gọ̀ àwọn èèyàn ti jóná.
A mú ìròyìn náà wá fún yín pé ‘Ọkọ̀ àjàgbé kan tó gbé afẹ́fẹ́ tí ọkọ̀ le mú sàgbára CNG ló pàdánù ìjánu rẹ̀ ní ìtòsí afárá Karu ní Abuja.
Ìrọ̀lẹ́ òní Ọjọ́rú ni ìjàmbá yìí wáyé, ọkọ̀ náà pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré ó sì lọ kọlu ọkọ̀ mìíràn, kíá ni iná sẹ́yò tí ó sì ràn kárí láàárín ìṣẹ́jú àáyá.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn tí iná yìí ká mọ́ inú ọkọ̀ ni iná yìí ti mú balẹ̀, a kò tíì le sọ ní pàtó iye ènìyàn tí ó ti bá ìsẹ̀lẹ̀ yii rìn.
Nínú fọ́nrán tí ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán kan gbé jáde ni àwọn èèyàn ti ń kígbe tí wọ́n sì ń jó nínú iná náà.
Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná àti ẹ̀ka mìíràn tọ́rọ̀ kàn sa ipá wọn àmọ́ ẹni tó kàn ló mọ, ẹ̀mí ṣòfò lọ́jọ́ náà.
Ohun tó bani lókàn jẹ́ jùlọ ni ti tọkọtaya kan tí ìgbéyàwó wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ pé oṣù kan tí wọ́n bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ. Àwọn ẹbí wọn ti wà nínú ọ̀fọ̀ ńlá láti ìgbà tí iná náà ti mú ẹ̀mí àwọn ìrètí ọ̀la wọn lọ.
Ǹjẹ́ ẹ tilẹ̀ gbọ́ pé ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Èkó ṣe ìdènà fún iná nlá méjì tí kò bá ba nǹkan jẹ́ gan-an?
Ọkọ̀ àjàgbé kan tó gbé afẹ́fẹ́ ìdáná mà ló dànù sí ojú ònà Epe nígbà tí ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan tó gbé epo bẹntiróòlù náà dànù sí òpópónà Apapa sí Oshodi.
Bí kìí bá ṣe pé àwọn panápaná yìí kojú àwọn ọkọ̀ yìí, nǹkan ò bá yan bí wọ́n bá fi le bú gbàmù.
Ilé iṣẹ́ panápaná ló fi ọ̀rọ̀ yìí sí ojú òpó X wọn pé ọkọ àjàgbé tó gbé afẹ́fẹ́ ìdáná náà pàdánù ìjánu rẹ̀ ó sì kó sínú kòtò kan ní òpópónà Ketu sí Epe.
Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ta mọ́ra dé ibẹ̀ wọ́n sì ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́. Wọ́n dóòlà ẹ̀mí awakọ̀ náà; ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n àti ọmọ iṣẹ́ rẹ̀; ọmọ ọgbọ̀n ọdún.
Bákan náà wọ́n dẹ́kun ìjàmbá iná mìíràn tí kò bá tún súyọ ní òpópónà Apapa sí Oshodi nígbà tí ọkọ̀ àjàgbé kan tó gbé epo bẹntiróòlù pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì da epo sí gbogbo ojú pópó. Awakọ náà fẹsẹ̀ fẹ́ẹ kí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò tó dé, wọ́n dẹ́kun ìjàmbá náà wọ́n sì wọ́ ọkọ̀ náà kúrò lójú pópó.
Ìjàm̀bá iná ń gbilẹ̀ síi lójúmọ́, a kò ní ṣàgbákò rẹ̀ lọ́la Elédùmarè, Àṣẹ.
Discussion about this post