• About
  • Advertise
  • Careers
  • Contact
Saturday, May 31, 2025
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
NEWSLETTER
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • All
    • ijamba oko
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ọrọ̀-Ajé
    • Òṣèlú
    A Ń ṢE ÌFILỌ́LẸ̀ ÌPÌLẸ̀ RERE FÚN ỌJỌ́ IWÁJÚ TÓ GÚN RÉGÉ – ÀÀRẸ̀́ BOLA AHMED TINUBU.

    GBỌ̀GÁN ÌDÁNWÓ WÓ PA ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ TARABA.

    ÌYÁ ÀTI ÌYÁ ÌYÁ TA ỌMỌ ỌJỌ́ MÉJÌ.

    Ẹ̀RỌ LỌ ÒṢÌṢẸ́ ILÉ IṢẸ́ KÚNNÁ NÍ ÌPÍNLẸ̀ OGUN.

    SAUDI TI KÉDE ỌJỌ́ KẸFÀ, OṢÙ IGBE NÍ ỌJỌ́ ỌDÚN ILÉYÁ.

    ÀBẸ̀WÒ MI SÍ ILÉ MUHAMMADU BUHARI KÒ LỌ́WỌ́ ÒṢÈLÚ NÍNÚ – EL RUFAI

    ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ EL-RUFAI Ó SAN Ẹ̀Ẹ́DẸ́GBẸ̀RÚN MÍLÍỌ́NÙ NÁÍRÀ OWÓ ÌTANRÀN.

    Ẹ TẸ̀LÉ MI KÁLỌ INÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC TÀBÍ KÍ Ẹ KỌ̀WÉ FIPÒ YÍN SÍLẸ̀ – GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ AKWA IBOM SÍ ÀWỌN KỌMÍṢỌ́NÀ RẸ̀.

    ỌMỌ ỌDÚN MẸ́RÌNLÁ SÁ KÚRÒ NÍLÉ ỌKỌ RẸ̀, ỌKỌ RẸ̀ FI SHARIA GBÉ E.

    ÀWỌN OLỌṢÈLÚ LÓ Ń FÚN ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ LỌ́WỌ́ – GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ BORNO.

    WỌ́N TI RÍ HAMDIYYAH O!

    HAMDIYYAH SHARIF TI DI ÀWÁTÌ.

    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ọrọ̀-Ajé
    • Òṣèlú
  • Ìròyìn Tó Gbòde
  • Eré ìdárayá
  • Ìdánilárayá
    • All
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin

    ÌGBÉYÀWÓ PRISCILLA MÌLÚ TÌTÌ.

    ÌGBÉYÀWÓ PRISCILLA MÌLÚ TÌTÌ.

    LÁÀRIN TINUBU, EEDRIS ABDULKAREEM ÀTI WOLE SOYINKA.

    Ìròyìn Jákèjádò.

    Ìròyìn Jákèjádò.

    MO TA ILÉ ÀTI Ọ̀NÀ MI LÓRÍ ÀÌSÀN ÌTỌ̀ ṢÚGÀ – AGBÓHÙNSÁFẸ́FẸ́.

    TUFACE RA ÀWỌN AṢỌ TITUN FÚN ÌFẸ́ RẸ̀ TITUN; NATASHA

    ỌKÙNRIN MỌ́KÀNLÉLÓGÚN LÓ BÁ ÌYÀWÓ MI LÒ PỌ̀- ÌJỌBA LANDE

    MI Ò NÍ LE BÁ BABA TEE ṢIṢẸ́ PỌ̀ – ÌJỌBA LANDE.

    ÈMI NI ÌYÀWÓ ẸLẸ́Ẹ̀KEJE ỌKỌ MI :

    ÈMI NI ÌYÀWÓ ẸLẸ́Ẹ̀KEJE ỌKỌ MI :

    Ramadan Kareem!

    Ramadan Kareem!

    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ìgbé-Ayé
    • All
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Oge Ṣiṣe

    Trending Tags

    • Golden Globes
    • Mr. Robot
    • MotoGP 2017
    • Climate Change
    • Flat Earth
    • Oge Sise
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
    • All
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
    ÌYÀWÓ NI OLAMIDE FẸ́ FỌ́ IRIN MỌ́ LÓRÍ TÓ FI BA ỌMỌ RẸ̀, ỌMỌ ỌDÚN KAN.

    ILÉ ẸJỌ́ DÁJỌ́ IKÚ FÚN ỌKÙNRIN TÓ ṢEKÚ PA COMFORT JAMES.

    Àwọn agbébọn

    ÀWỌN AGBÉBỌN ṢE ÌKỌLÙ SÍ ÌPÍNLẸ̀ KWARA.

    ÌGBÉYÀWÓ PRISCILLA MÌLÚ TÌTÌ.

    ÌGBÉYÀWÓ PRISCILLA MÌLÚ TÌTÌ.

    ILÉ ỌBA Ọ̀YỌ́ KÒ JÓ ÀMỌ́ A Ó BU ẸWÀ SÍI – ỌBA OWOADE.

    ALÁÀFIN YAN OSUNTOLA NÍ OLÙBÁDÁMỌ̀RÀN PÀTÀKÌ.

    Àkàgbádùn

    Àkàgbádùn

    Ewì

    Ewì.

    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ààyè Olóòtú

Home Ààyè Olóòtú

ÌJÀMBÁ INÁ GBA Ẹ̀MÍ ÈÈYÀN MẸ́RIN NÍ ÌPÍNLẸ̀ JIGAWA.

Àwọn mẹ́wàá mìíràn fara pa.

by Adeola Olanrewaju
February 23, 2025
in Ààyè Olóòtú, Ìgbé-Ayé, Ìròyìn, Ìròyìn Agbègbè, Ìròyìn Tó Gbòde, Ọ̀rọ̀ Ààbò, Ọ̀rọ̀ ìdílé, Ọrọ̀-Ajé
0
ÌJÀMBÁ INÁ GBA Ẹ̀MÍ ÈÈYÀN MẸ́RIN NÍ ÌPÍNLẸ̀ JIGAWA.
0
SHARES
20
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky

A kò ní rìn lọ́jọ́ tèbi ń pa ọ̀nà, ẹ ṣe àmín ẹ gbétọ́ àdúrà mìn gbogbo jànmọ́n-ọn.
Iná tó jó ní Jigawa lọ́tẹ̀ yìí kọjá afẹnuròyìn, ó burú jáì.
Ọkọ̀ akérò kan tó kó èrò mẹ́rìnlélógójì ló gbaná lójú ọ̀nà, àwọn èèyàn mẹ́rin ló jóná kọjá mímọ̀ nígbà tí àwọn mẹ́wàá mìíràn fara pa yánnayànna.
Ohun tó ṣe òkùnfà iná náà gẹ́gẹ́ bíi àyẹ̀wò tí àwọn ọlọ́pàá ṣe ni pé ibùsùn kan tí awakọ̀ náà so mọ́ ẹ̀yìn ọkọ̀ rẹ̀ ló ràn mọ́ èéfín tó ń tú jáde lẹ́yìn ọkọ̀ náà, ibùsùn yìí ran iná ó sì ràn mọ́ ọkọ̀ náà kíá tí gbogbo ọkọ̀ sì sọ iná dorin.
Àwọn ọmọdé mọ́kàndínlógún ló wà nínú ọkọ̀ yìí nígbà tí àwọn àgbà jẹ́ márùndínlọ́gbọ̀n. Àwọn àgbà mẹ́rin ló jóná gúrúgúrú kọjá mímọ̀ tí àwọn mẹ́wàá mìíràn sì fara pa.
Àwọn ọlọ́pàá ti gbé àwọn tó fara pa lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú wọ́n sì yọ̀ǹda òkú àwọn tó kú fún àwọn mọ̀lẹ́bí wọn.

Ọdún tó kọjá la mú ìròyìn iná tó gba ẹ̀mí àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ Niger wá fún yín.
Ìjọba ìbílẹ̀ Agaie ní ìpínlẹ̀ ni ó ti ṣẹlẹ̀.
Ọkọ̀ agbépo bẹntiróòlù kan ló forí sọ ọkọ̀ tó kó màálù tí iná náà sì sẹ́yọ tó sì ba nǹkan jẹ́ gan-an.
Àádọta màálù àti ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà nínú ọkọ̀ yìí , ó jóná kọjá mímọ̀. Agbègbè Wudil ní ìpínlẹ̀ Kano ni àwọn onímàálù náà ti gbéra kí ikú tó ká wọn mọ́ ìpínlẹ̀ Niger.
Aláṣẹ ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Niger; ọ̀gbẹ́ni Abdullahi Baba-Arab ṣe àlàyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà pé òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú ni ìjàmbá iná náà wáyé, ó wí pé àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà tí àwọn sì ta mọ́ra dé ibẹ̀ àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró, elérú ti sun igi, nǹkan bàjẹ́ kọjá àtúnṣe. Ọgbọ̀n èèyàn ni wọ́n kọ́kọ́ rí ṣà, ìgbà tí wọ́n tú inú àwọn ọkọ̀ náà fíní, wọ́n tún rí méjìdínlógún síi, gbogbo àádọta màálù náà jóná gúrúgúrú.
Abdullahi wí pé àwọn ti sin gbogbo àwọn èèyàn náà papọ̀ sínú oórì kan.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Niger bá àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn tó kú náà kẹ́dùn.

Ìjàmbá iná mìíràn tún wáyé ní ìpínlẹ̀ Zamfara ní ọ̀sẹ̀ yìí.
Ọjà Talata-Mafara tó wà ní ìpínlẹ̀ Zamfara ni èyí ti ṣẹ̀. Àwọn èèyàn ń dúnàá dúrà lọ́wọ́, arákùnrin kan wá ra ẹ̀tù sí ìbọn rẹ̀ lọ́jà náà, ibi tó ti ń ki ìbọn náà ni ó ti bú gbàmù mọ́ ọn lọ́wọ́, kìí wá ṣe pé ó bú nìkan, ó bú mọ́ àwọn ẹ̀tù ìbọn yòókù tó wà nílẹ̀, ni àrá bá ran bọ́ḿbù lọ́wọ́, àfi gbòlà tí iná dé, iná náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tó bá nǹkan jẹ́ gan-an.
Àádọta àwọn èèyàn ni wọ́n jóná nínú ìjàmbá yìí, wọ́n farapa gan-an ni tó ṣe pé ilé ìwòsàn tí wọ́n kọ́kọ́ gbé wọn lọ kò le tọ́jú wọn.
Ikọ̀ akọ̀ròyìn kàn sí ilé ìwòsàn ìjọba Talata-Mafara tí wọ́n gbé wọn lọ, àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ wí pé àwọn ti ní kí wọn ó gbé wọn lọ sí ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó Usman Danfodiyo ní Sokoto nítorí pé ó ju ohun tí àwọn le tọ́jú lọ.
Àlàyé náà tẹ̀síwájú pé bí àwọn ó ba tiẹ̀ gbìyànjú láti tọ́jú wọn gan-an, àwọn kò ní àwọn irinṣẹ́ tó kúnjú òṣùwọ̀n tí àwọn le lò. Wọ́n wí pé àwọn èèyàn náà farapa gidi gan-an ni kìí ṣe kèremí.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣe àlàyé pé iná náà kò ní òun kò run gbogbo ọjà, ọpẹ́lọpẹ́ àwọn panápaná tí wọ́n wá kojú rẹ̀.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Talata-Mafara; Yahaya Yari wí pé òun wà ní Sokoto pẹ̀lú àwọn èèyàn náà àmọ́ ó kọ̀ láti sọ ipò tí wọ́n wà báyìí.
Gbogbo akitiyan láti kàn sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò yọrí sí rere lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí.
Kò tíì tán o, àwọn ilé ìkọ́jàsí kan jóná ní ìpínlẹ̀ Anambra lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.
Àwọn ọlọ́jà ilé ìkọ́jàsí kan tó wà ní Tambasi, òpópónà Limca ní Idemili ìpínlẹ̀ Anambra pàdánù ọjà tó lé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù náírà nínú ìjàmbá iná tó sẹ́yọ lóru.
Ohun tó ṣe òkùnfà iná náà kò tíì jẹ́ mímọ̀ lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí.
Okey, ọ̀kan nínú àwọn tí ó ń gbé ní itòsí ilé ìkọ́jàsí náà wí pé iná náà bẹ̀rẹ̀ láti igun kan lára ilé náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí jó wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ tó sì ràn mọ́ gbogbo ilé náà láàrin ìṣẹ́jú àáyá.
Àwọn tí ilé wọn fara ti ilé ìkọ́jàsí yìí sáré kó ẹrù wọn jáde nítorí ìbẹ̀rù pé bí ó bá jó ilé ìkọ́jàsí náà tán ó le náwọ́ gán ilé wọn.
Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná gbìyànjú láti pa iná náà, lẹ́yìn bíi wákàtí kan tí wọ́n ti kojú rẹ̀ ni wọ́n tó ríi pa.
Ẹni tó ń mójútó àtẹ̀jáde fún ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Anambra; Chukudi Chiketa wí pé àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ta mọ́ra dé ibẹ̀, lẹ́yìn bíi wákàtí kan, wọ́n rí iná náà pa àmọ́ ṣe ni iná náà tún sẹ́yọ lẹ́yìn ìṣẹ́jú díẹ̀. Wọ́n kó àwọn òṣìṣẹ́ panápaná ránṣẹ́ síi wọ́n sì jọ pa iná náà lápawọlẹ̀.
Ìjàmbá iná mélòó la fẹ́ sọ nípa rẹ̀? Ṣé ẹ rántí àwọn iná tó jó ní Ìbàdàn léraléra ní òpin ọdún tó kọjá?
Ọ̀kan wáyé ní Ori-Eru, Idikan ní Ìbàdàn. Aago mẹ́ta òru kọjá ni iná náà bẹ̀rẹ̀ ní ilé alájà méjì náà. Ìyá àgbà, bàbá àgbà àti ọmọọmọ wọn ọkùnrin kan tó wá lo ìsinmi ilé ìwé lọ́dọ̀ wọn ti jóná nínú ìjàmbá iná náà o.
Àwọn òṣìṣẹ́ panápaná gbìyànjú lóòótọ́ àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró mọ́, eléérú ti sun igi.

Ìjàmbá iná mìíràn wáyé ní ọjà Araromi, Agodi ní ìlú Ìbàdàn kan náà. Aago méjì òru kọjá ni iná náà sẹ́yọ tó sì gorí ilé fẹjú kankan.
Ọjà tó lé ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ mílíọ̀nù náírà ló jóná nínú ìjàmbá náà.
Ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ sa ipá wọn, iná náà pọ̀ lápọ̀jù , wọ́n béèrè fún ìrànlọ́wọ́ àwọn ilé iṣẹ́ panápaná kéékèèkèé pé kí wọn ó gbé omi wá nítorí afẹ́fẹ́ panápaná kò ká iná náà.
Nígbà tí àwọn panápaná ń gbìyànjú láti pa iná, àwọn jàǹdùkú ti ya wọ inú ọjà náà tí wọ́n sì ti ń jí àwọn ọjà ọlọ́jà gbé lọ.
Olùdarí ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́; Akinyemi Akinyinka ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde pé àwọn jàǹdùkú, eṣinṣin ò kọ ikú ti ya wọ inú ọjà o, wọ́n sì ti ń jí àwọn ọjà gbé sá lọ.
Akinyemi béèrè fún ìrànlọ́wọ́ àwọn panápaná àdúgbò pé kí wọn ó gbé omi wá sí ọjà Araromi náà nítorí iná náà pọ̀ ju agbára afẹ́fẹ́ ìpaná lọ.

Ìjà iná burú, a ò ní ríi láṣẹ Èdùmàrè. Àṣẹ

Facebook Comments Box
Tags: auto 🔥fire incidentfirefightersIbadan fireÌròyìnIwe Iroyin YorubajigawafirenewsNiger fireNigeriapolitics
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
ÌJÀMBÁ INÁ GBA Ẹ̀MÍ ÈÈYÀN MẸ́RIN NÍ ÌPÍNLẸ̀ JIGAWA.

ÌRÒYÌN JÁKÈJÁDÒ -ÈÈYÀN MẸ́RÌNLÉLÓGÓJÌ NI ỌKỌ̀ NÁÀ KÓ ---

Recommended

ỌKÙNRIN MỌ́KÀNLÉLÓGÚN LÓ BÁ ÌYÀWÓ MI LÒ PỌ̀- ÌJỌBA LANDE

ỌKÙNRIN MỌ́KÀNLÉLÓGÚN LÓ BÁ ÌYÀWÓ MI LÒ PỌ̀- ÌJỌBA LANDE

3 months ago

Kunle ré ọmọ kékeré nípàá.

3 months ago

Popular News

  • A Ń ṢE ÌFILỌ́LẸ̀ ÌPÌLẸ̀ RERE FÚN ỌJỌ́ IWÁJÚ TÓ GÚN RÉGÉ – ÀÀRẸ̀́ BOLA AHMED TINUBU.

    GBỌ̀GÁN ÌDÁNWÓ WÓ PA ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ TARABA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • A Ń ṢE ÌFILỌ́LẸ̀ ÌPÌLẸ̀ RERE FÚN ỌJỌ́ IWÁJÚ TÓ GÚN RÉGÉ – ÀÀRẸ̀́ BOLA AHMED TINUBU.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • Ẹ̀RỌ LỌ ÒṢÌṢẸ́ ILÉ IṢẸ́ KÚNNÁ NÍ ÌPÍNLẸ̀ OGUN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • SAUDI TI KÉDE ỌJỌ́ KẸFÀ, OṢÙ IGBE NÍ ỌJỌ́ ỌDÚN ILÉYÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ EL-RUFAI Ó SAN Ẹ̀Ẹ́DẸ́GBẸ̀RÚN MÍLÍỌ́NÙ NÁÍRÀ OWÓ ÌTANRÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • About
  • Advertise
  • Careers
  • Contact

© 2024 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Sign In with Facebook
Sign In with Google
Sign In with Linked In
OR

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Sign Up with Facebook
Sign Up with Google
Sign Up with Linked In
OR

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In