ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ìròyìn Tó Gbòde

ÌDÁJỌ́ TI WÁYÉ LÓRÍ ÀWỌN TÓ Ń ṢE ÒWÒ ỌMỌ NÍ ONDO.

Àti àwọn ìròyìn mìíran tó gbòde.

by Adeola Olanrewaju
March 5, 2026
in Ìròyìn Tó Gbòde
0
ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.
0
SHARES
3
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ ọdún mọ́kànlá, ilé ẹjọ́ ti dá ẹjọ́ fún àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n ń ṣe òwò ọmọdé ní Okitipupa, ìpínlẹ̀ Ondo.
Tọkọtaya yìí ń lo ilé wọn tó wà ní òpópónà Sarajo, ìlú titun fún òwò ọmọ. Wọn yóò tan àwọn ọmọbìnrin tó bá gba oyún jọ sílé wọn pẹ̀lú ìlérí pé àwọn yóò ṣe ìtọ́jú rẹ̀. Bí wọ́n bá ti wọ inú ilé náà, wọn ò tún jáde mọ́, wọn yóò wà níbẹ̀ títí wọn yóò fi bímọ, lẹ́yìn náà ni wọn yóò gbé àwọn ọmọ náà tà fún àwọn oníbàárà wọn fún oríṣìí nǹkan.
Àwọn ọmọbìnrin náà yóò máa lóyún títí wọn yóò fi bí ọmọ inú wọn tán. Wọ́n ní ilé ìwòsàn tí wọ́n ń lò fún ìtọ́jú àwọn olóyún náà wọ́n sì tún ní ọkọ̀ tí wọ́n fi ń kó wọn lọ gba ìtọ́jú.
Òwò ẹranko ọ̀sìn ni wọ́n ní ń ṣe tí wọ́n sì kó àwọn ohun ọ̀sìn sínú ọgbà ilé náà bìbà àmọ́ òwò ọmọ ń lọ lábẹ́lẹ̀.
Ọdún 2014 ni ọwọ́ tẹ̀ wọ́n, ọkọ̀ mẹ́jọ, owó gọbọi, àwọn káàdì ilé ìwòsàn àti àwọn nǹkan mìíràn ni wọ́n bá nílé náà. Ìjọba ti gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo rẹ̀ báyìí.
Bákan náà ni adájọ́ pàṣẹ kí wọn ó san mílíọ́nù kan náírà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn obìnrin mẹ́ta tó jẹ́rìí nílé ẹjọ́. Ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá ni adájọ́ dá fún tọkótaya yìí ó sì tún fún wọn ní àǹfààní àtisan owó ìtanràn.

AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ ÌWÉ GÍGA ÌBÀDÀN MU ‘SNIPER’

Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Ìbàdàn kan tí a kò ní àǹfààní àtidárúkọ rẹ̀ ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn tó mu òògùn ìpakòkòrò ‘sniper’.
Ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìlera ni ó wà, àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ríi tí ó ń po ọṣẹ lẹ́nu tó sì ń yíra nílẹ̀, òun náà ló sọ fún wọn pé ‘sniper’ ni òun mu. Wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn Jaja níbi tí wọ́n ti ṣe ìtọ́jú rẹ̀ kí wọ́n tó gbé e lọ sí ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó UCH. Wọ́n ṣe ìtọ́jú rẹ̀ ní UCH, wọ́n gbé e sí orí ẹ̀rọ aso-ẹ̀mí-rọ̀ àmọ́ ó padà kú.
Funmi Adetuyibi; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé ìwòsàn UCH ṣe àlàyé pé ọmọ náà mu sniper’ ni àwọn sì ṣe ìtọ́jú rẹ̀ àmọ́ ó padà já sí ikú.
Wọ́n ránṣẹ́ sí àwọn òbí rẹ̀ láti Akure kí ó tó di pé ó kú, àwọn òbí rẹ̀ kò gbà pé òun ló mu ‘sniper’ náà fúnra rẹ̀, wọ́n ní wọ́n fún un mu ni àmọ́ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ nínú yàrá takú pé ọmọ náà jẹ́wọ́ fúnra rẹ̀ pé òun ló mu ún, wọ́n ní kò túra ká mọ́ ṣáájú ìgbà náà, kìí lọ kíláásì mọ́ kìí sì í gbé ìpè àwọn òbí rẹ̀ náà mọ́ kí ó tó di pé ó padà mu ‘sniper’ kú yìí.

ADVERTISEMENT

ADVERTISEMENT

ONIFOTO TI PÀDÁNÙ Ẹ̀MÍ RẸ̀ NÍ OJÚ Ọ̀NÀ ÈKÓ.

Orowole Kolapoz; gbajúgbajà olùyàwòrán àti ọlọ́kadà tí àwọn èèyàn mọ̀ sí Kọ́lá Onífọ́tò ti pàdánú ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàm̀bá tó wáyé ní Èkó.
Kola fẹ́ràn kí ó máa gun ọ̀kadà rẹ̀ káàkiri fún iṣẹ́ àwòrá tó ń ṣe, lọ́jọ́ tó ní ìjàm̀bá tó mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ yìí, ó kọ ọ́ sí ojú òpó rẹ̀ pé òun fẹ́ gun ọ̀kadà lọ sí Akure, ó ní èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí òun yóò gun ọ̀kadà kọjá Èkó lọ sí ìlú mìíràn, ó tún gbé oríyìn fún àwọn tó ti ṣe irú rẹ̀ ṣaájú pàápàá àwọn obìnrin, bákan náà ló ní ojú òun ti rí tó nídìí ọ̀kadà gígùn yìí.
Ìrìn àjò lọ sí Àkúrẹ́ yìí ni ó fẹ́ rìn tí ó fi pàdé ikú òjijì, Ọjọ́ta ni ó ti ní ìjàm̀bá náà tí wọ́n sì gbé e lọ sí ilé ìwòsàn FRSC tó wà ní Ọjọ́ta, ẹ̀yìn náà ni wọ́n darí rẹ̀ sí ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó ti ilé ìwé gíga Èkó tó wà ní Idi-Araba. Ọjọ́ kìíní oṣù Ẹrẹ́nà ni ó ní ìjàm̀bá tó mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ ní ọjọ́ kejì, ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni Kola lásìkò ikú rẹ̀ yìí.
Ìròyìn ikú rẹ̀ da omi tútù sí àwọn èèyàn lọ́kàn, wọ́n banújẹ́ lórí ikú rẹ̀, oríṣìí àwọn ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ni àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ kọ sí ojú òpó wọn láti kẹ́dùn ikú rẹ̀.
Inú oṣù Ṣẹẹrẹ ni Kola ra ọ̀kadà titun tó sì fi àwòrán rẹ̀ léde, ó ní ó wu òun láti jẹ́ ọlọ́kadà aládàáni àmọ́ ìrìn àjò àkọ́kọ́ rẹ̀ náà ló bá lọ yìí.

ÀWỌN ÈÈYÀN TẸ ARA WỌN PA NÍBI TÍ WỌ́N TI Ń PÍN OÚNJẸ ỌDÚN.

Àwọn èèyàn mẹ́rin ló ti kú báyìí nígbà tí wọ́n tẹ̀ wọ́n pa níbi tí wọ́n ti ń pín oúnjẹ ọdún.
Kofa Guga ní ìpínlẹ̀ Katina ni èyí ti ṣẹlẹ̀, wọn kò sì ṣẹ̀ máa pín oúnjẹ ọdún níbẹ̀, ti ọdún yìí yíwọ́ nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní tẹ ara wọn pa.
Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn tó ṣètò rẹ̀ ti ké sí àwọn ọlọ́pàá, wọ́n tú àwọn èrò náà ká wọ́n sì kó àwọn mẹ́rin náà ló sí ilé ìwòsàn àmọ́ wọ́n padà kú lọ́kọ̀ọ̀kan sílé ìwòsàn.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Kastina banújẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá náà korò ojú síi, wọ́n fi àìdùn inú wọn hàn nínú ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ránṣẹ́ sí àwọn ẹbí àwọn ẹni náà.

Èyí ni àkójọ àwọn ìròyìn tó ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ yìí tí a pè ní ÌRÒYÌN TÓ GBÒDE nítorí pé a kò fẹ́ kí etí yín di sí bí ó ṣe ń lọ nílùú. Ẹ má jìnnà sí ojú òpó wa fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìròyìn.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #iweiroyinyorubairoyintogbodenewsnewsinyorubanewsonlinenewsonlyreadnewstrendingnews
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
A Ó JÚWE ILÉ FÚN ÀWỌN ÒṢÌṢẸ́ ÌLERA TÓ BÁ ṢE ÌMẸ́LẸ́ – ÌJỌ́BA ÌPÍNLẸ̀ ONDO.

GÓMÌNÀ AIYEDATIWA PÀṢẸ KÍ ÀWỌN OLÓGUN Ó GBÓGUN TI ÀWỌN AJÍNIGBÉ.

Recommended

ÈMI KỌ́ OOO, MI Ò MỌ NNKANKAN NÍPA ÀÌSÀN RẸ̀, MO F’ỌLỌ́RUN ṢẸ̀RÍ

ÈMI KỌ́ OOO, MI Ò MỌ NNKANKAN NÍPA ÀÌSÀN RẸ̀, MO F’ỌLỌ́RUN ṢẸ̀RÍ

1 year ago
ỌLỌ́PÀÁ YÌNBỌN PA ARA RẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ NASARAWA.

ÀWỌN DARANDARAN TÚN GBÉ ÌṢE WỌN DÉ O, OKO Ẹ̀GẸ́ NI WỌ́N SUN NÍ ÌPÍNLẸ̀ OGUN.

1 year ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.