Ẹ̀rọ amúnawá kan tó wà ní ìtòsí ọgbà àtúnṣe ìwà Akwa Ibom ló bú gbàmù lójijì, àwọn méjì tí wọ́n ń retí ìdájọ́ ló kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí àwọn méjì mìíràn farapa.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé àwọn wáyà kan ló kanra wọn tí ọ̀kan sì já lé orí yàrá àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà.
Adarí ọ̀gbà ẹ̀wọn ìpínlẹ̀ Anambra; Frank Okonkwo ṣe àpèjúwe ìṣẹ̀lẹ̀ náà bí èyí tó bani lọ́kàn jẹ́.
Ó wí pé jíjà tí áyà náà já lé wọn lórí, ó ju àwọn méjéèjì sókè ni láti orí ìjókòó tí wọ́n wà, ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣe.́ òògùn òyìnbó Uyo ni wọ́n gbé wọn lọ àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró mọ́.
Ẹ̀sùn ìdigunjalè àti ìjínigbé ni àwọn méjì náà ń jẹ́jọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ kí ọlọ́jọ́ tó dé. Wọ́n ti kàn sí àwọn ẹbí wọn lórí ikú wọn àmọ́ ó dìgbà tí ìwádìí bá parí kí wọ́n tó le yọ̀ǹda òkú wọn.
WỌ́N KÓ GBOGBO Ẹ̀RỌ ÌRÁNṢỌ LỌ NÍ ÌSỌ̀ ARÁNṢỌ.
Àwọn alọkólóhunkígbe ti já ìsọ̀ aránṣọ́ kan ní agbègbè Sagamu, ìpinlẹ̀ Ogun, àwọ irinṣẹ́ àti ẹ̀rọ tí iye wọn dín díẹ̀ ní mílíọ́nù ni wọ́n kó lọ.
Ọ̀gbẹ́ni Saheed Oyewole gba ìpè láti ọ̀dọ ẹnìkan tó jẹ́ ará àdúgbò ibi tí ìsọ̀ wà pé ìsọ̀ rẹ̀ wà ní ṣíṣí, nígbà tí yóò fi dé ibẹ̀, gbogbo àwọn ẹ̀rọ ìránṣọ́ rẹ̀ mẹ́rẹ́ẹ̀rin àti àwọn aṣọ oníbàárà rẹ̀ ni wọ́n ti kó lọ.
Omolola Odutola; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé Oyewole fi ẹjọ́ sùn lágọ̀ọ́ wọn nípa bí wọ́n ṣe já ìsọ̀ rẹ̀.
WỌ́N TI YÌNBỌN PA TIMOTHY LÉKÒÓ.
Àwọn kan tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ adigunjalè ti yìnbọn pa akọ́ṣẹ́mọsẹ́ onígbàjámọ̀ kan ní agbègbè Satelite, ìpínlẹ̀ Èkó.
Sebastine Timothy ni orúkọ onígbàjámọ̀ yìí, alẹ́ ọjọ́ náà nígbà tó dé láti ibi iṣẹ́ rẹ̀ sílé rẹ̀ ni àwọn adigunjalè náà ṣe ìkọlù síi, wọ́n kó àwọn ohun ìní rẹ̀ wọ́n sì tún wọ́ owọ́ nínú àpò owọ́ ilé ìfowópamọ́ rẹ̀, lẹ́yìn náà ni wọ́n yìnbọn fún un lórí.
Ìró ìbọn tí àwọn aráalé rẹ̀ gbọ́ ni wọ́n fi lọ sí ẹnu ọ̀nà rẹ̀, inú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ ni wọ́n bá a.
ILÉ ÌWÉ GÍGA UNIZIK YAN Ọ̀GÁ ÀGBÀ TITUN.
Ilé ìwé gíga Nnamdi Azikiwe tó wà ní Awka tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Anambra ti yan ọ̀gá àgbà titun báyìí. Ọ̀gá àgbà titun náà ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Bond Anyaechie.
Ìyànsípò yìí wáyé lẹ́yìn ọdún kan tí wọ́n yọ ẹni tí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu yàn sípò náà. Ọ̀jọ̀gbọ́n Bernard Odoh ni ààrẹ yàn lọ́gàá UNIZIK àmọ́ kò bá àwọn adarí ilé ìwé náà lára mu.
Àjọ àwọn olùkọ́ yarí kanlẹ̀, wọ́n ní Ọ̀jọ̀gbọ́ Bernard Odoh kò ní ìwé ẹ̀rí tó kúnjú fún ipò náà àti wí pé ìyànsípò rẹ̀ ní ọwọ́ kan ejò nínú nítorí kò ṣe àwọn ìdánwò àti àwọn ohun mìíràn tó yẹ kó ṣe.
Lẹ́yìn gbogbo fàǹfà, wọ́n yọ Ọ̀jọ̀gbọ́n Bernerd nípò náà wọ́n sì ti yan Ọ̀jọ̀gbọ́n Bond báyìí.
Alága àwọn adarí ilé ìwé náà; Olugbenga Kukoyi sọ nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ pé àwọn tọ gbogbo ọ̀nà tó yẹ kí àwọn tó yan Ọ̀jọ̀gbọ́n Bond ni, ó ní ìyànsípò rẹ̀ kò ní kọ́lọ́fín nínú
INÁ JÓ ILÉ OÚNJẸ KAYAT NÍ BORNO.
Ṣàdédé ni iná sẹ́yọ ní ilé oúnjẹ Kayat tó wà ní òpópónà Polo ní Maiduguri tíí ṣe olú ìlú ìpúnlẹ̀ Borno.
Nǹkan bíi aago mọ́kànlá òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú ni iná náà sẹ́yọ, àwọn panápaná ìpínlẹ̀ náà ló tètè kojú rẹ̀ kò bá jóná kan éérú.
Nínú àtẹ̀jáde tí alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Borno; Nahum Daso bu ọwọ́ lù la ti ríì kà pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò la ẹ̀mí lọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe àlàyé pé àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà lọ́jọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Bélú pé ilé oúnjẹ Kayat ti ranná ní Maiduguri. Lọ́gán ni kọmíṣọ́nà ọloọ́pàá; Naziru Abdulmajid ti pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó máa lọ sí ibẹ̀ tó sì tún ké sí ilé iṣẹ́ panápaná.
Yàtò sí pípa iná náà, àwọn ọlọ́pàá ríi dájú pé àwọn dóòlà ẹ̀mí àwọn èèyàn àti dúkíà tí kò tíì múná, àwọn aráàlú kan sáárá fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe náà.
Alukoro fún ilé iṣ̣́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Borno; Nahum Daso rọ àwọn èèyàn láti máa ṣe jẹ́jẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀rọ tó ń lo iná ọba.
Ọ̀RẸ́ MÉJÌ GÚN ARA WỌN PA NÍTORÍ OBÌNRIN.
Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni Gafar àti Hammed kó tó di pé abo dá ìjà sílẹ̀ láàrin wọ́n. A gbọ́ pé àwọn méjéèjì nífẹ̀ẹ́ obìnrin kan náà wọn kò sì ṣetán àti yọ̀ǹda rẹ̀.
Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni Hammed Usman Tunde nígbà tí Gafar jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún. Ọmọ ìlú Ilorin ni àwọn méjéèjì.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, àwọn méjéèjì pàdé ní ìsọ̀ onírèké lọ́jà Gboro, Ilorin. Èdè àìyedè ni wọ́n kọ́ fi bẹ̀rẹ̀ àgi bó ṣe di ìjàkadì, ẹ̀ẹ̀kan náà ni Gafar fa ọ̀bẹ yó tó sì fi gún Hammed láyà, lẹ́yìn náà ló sá lọ.
Àwọn èèyàn ṣe aájò Hammed dé ilé ìwòsàn aládàáni kan ní Gboro àmọ́ ó ti kú kí wọ́n tó dé ibẹ̀.
Títí di àsìkò yìí, kò sí ẹni tó mọ ibi tí Gafar wà bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ti sá kúrò nílé.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara; Adetoun Ejire-Aderemi. Ó wí pé àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà ní aago méjì ọ̀sán lọ́jọ́rú, nígbà tí wọn dé ibẹ̀, ẹ̀jẹ Hammed ni wọ́n bá nílẹ̀ tí àwọn èèyàn sì ti gbé e lọ sí ilé ìwòsàn. Àwọn ọlọ́pàá ta mọ́ra lọ sílé Gafar àmọ́ wọn kò bá ẹyẹ, tọdé tàgbà ilé náà tin a pápá bora kódà wọn kò dúró kó ẹrù.
Kọmiṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà; Adekimi Ojo bá àwọn ẹbí Hammed kẹ́dùn ó sì kí àwọn ará ọjà Gboro kú ìbọ̀wọ̀ fún òfin tí wọn kò dáná sun Gafar náà.




