Bí ìgbà tí èèyàn ń lọ kó adìyẹ lóko ni àwọn ajínigbé ṣe ń kó àwọn èèyàn ní ìpínlẹ̀ Delta pàápàá àwọn àgbẹ̀ tí wọ́n lọ sí oko. Kò sí ìrètí fún àwọn ẹbí àgbẹ̀ tó bá lọ oko láàárọ̀ pé yóò padà dé níbi tó le dé. Owó rọ̀ogúnlọ́gọ̀ ni wọ́n ń bèèrè fún bí owó ìtúsílẹ̀, ogúnlọ́gọ̀ àwọn èèyàn ló ṣì wà ní àkàtà wọn látàrí àìrówó san, bí ẹni pa ẹran ni wọn sì ń pa ẹni tí àwọn ẹbí rẹ̀ kò bá tètè sanwó ìtúsílẹ̀.
Inú oṣù Ẹrẹ́nà ni àwọn Fulani ajínigbé ikọ̀ ẹni márùn-ún kan lọ gbé ọ̀gbẹ́ni Chibueze ní abúlé Ogwashi-Uku, wọ́n mú un rìn lọ sí abúlé Ubulu-Uku níbi tí wọ́n ti gbé ọ̀gbẹ́ni Afam, Inú oko kan lọ́nà Powerline ní Ubulu-Uku ni wọ́n kó wọn sí fún ọjọ́ díẹ̀ kí wọ́ tó máa pe àwọn ẹbí wọn fún owó.
Oko tí wọ́n kó awọn ẹni yìí sí jẹ́ oko ọ̀gbẹ́ni Godwin, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Ẹrẹ́nà kan náà ni ọ̀gbẹ́ni Godwin, ìyàwó àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjì ló ṣiṣẹ́ lóko, wọn kò mọ̀ pé àwọn Fulani ajínigbé wà nínú oko, àwọn kàn ń ṣiṣẹ́ lọ ni tí wọ́n fi yọ sí wọn gúlẹ́.
Ẹ̀sẹkẹsẹ̀ ni wọ́n kó wọn mọ́ àwọn tí wọ́n jí gbé tẹ́lẹ̀, ìgbà tí àwọn ẹbí wọn kò tètè rówó san ni wọ́n pa ọ̀gbẹ́ni Godwin lójú aya àti àwọn ọmọ rẹ̀, owó rọ̀gùrọ́gún sì ni wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ẹbí àwọn méjì yòókù kí wọ́n tó fi wọ́n sílẹ̀.
Àwọn ará Ubulu-Uku wí pé àwọn Fulani ti sọ abúlé náà di ilé pàápàá àwọn ikọ̀ ẹlẹ́ni márùn-ún yìí, wọ́n wí pé ojoojúmọ́ ni àwọn ń sọnù ní abúlé náà tó sì jẹ́ pé àwọn márùn-ún yìí ló ń jí wọn gbé. Wọ́n ké sí ìjọba láti gbà wọ́n kalẹ̀.
Ìròyìn mìíràn tó fara pẹ́ èyí tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni ti àbọ̀dé ọ̀gá àgbà àjọ NYSC tẹ́lẹ̀rí; Ọ̀gágun Maharazu Tsiga tó dé láti àhámọ́ àwọn ajínigbé. Ìròyìn náà kà báyìí pé:
‘Ọ̀gá àgbà àjọ́ agùnbánirọ̀ NYSC tẹ́lẹ̀rí; Ọ̀gágun Maharazu Tsiga ṣe àlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí ní àkàtà àwọn ajínigbé, ó kọjá bẹ́ẹ̀.
Ọjọ́ mẹ́rìndínlọ́gọ́ta ni Tsiga lò ní àkàtà àwọn ajínigbé náà kí ó tó dé lỌ́jọ́bọ, ọ̀sẹ̀ yìí. Ó ṣe àlàyé pé àwọn tí wọ́n jí gbé tí àwọn jọ wà níbẹ̀ pọ̀ gan-an, wọ́n kó wọn jọ síbẹ̀ ni.
Ọjọ́ karùn-ún, oṣù kejì ọdún yìí ni wọ́n gbé Tsiga ní ilé rẹ̀ tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Bakori ní ìpínlẹ̀ Kastina. Ó wí pé ‘ẹ̀ẹ̀kan lọ́sẹ̀ la ń jẹun, Tuwo dawa náà sì ni wọ́n ń fún wa jẹ. Àkekèé àti èjò kò ṣàjòjì sí wa mọ́ nítorí pé ojoojúmọ́ la ń rí wọn. Àwọn ajínigbé yìí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, wọ́n á ní ká má wulè pe Ọlọ́run pé owó ni ká mú wá. Nǹkan tí wọ́n bẹ̀rù náà ni àwọn jagungagun ojú òfurufú, ẹ̀rù ikú máa ń bà wọ́n ó sì máa ń hàn lójú wọn bí àwọn jagunjagun ojú òfurufú náà bá dé. Bí àwọn ológun ojú òfurufú bá dé, àwa ni wọn yóò kó síta fi borí kó le jẹ́ pé àwa ni ọta yóò bà, Ọlọ́run ló fi ìṣọ́ rẹ̀ ṣọ́ mi láwọn àsìkò náà.
Òpọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ló wà ní ibẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba, àwọn lọ́gàálọ́gàá àti àwọn èèyàn jàkànjàkàn láàrin ìlú ló kún ibẹ̀. Lílù kò tó nínà, ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń nà wá nítorí àìrówó gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn wa, Èyí mú ìpalára bá ìlera mi nítorí pé mo ní àìsàn ìpayà lára tẹ́lẹ̀, yàtọ̀ sí lílù, oúnjẹ tí wọ́n ń fún wa jẹ́ kìkí iyọ̀ ní èyí tí kò dáa fún ìlera mi; bí ẹ ṣe ń wò mí yìí, mi ò le gun àtẹ̀gùn rárá’
Tsiga dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀gágun àgbà ilẹ̀ yìí fún akitiyan rẹ̀ láti gba òun sílẹ̀. Ó ní akọ iṣẹ́ ni iṣẹ́ ológun pàápàá dídojú ìjà kọ àwọn ajínigbé. Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ Zamfara, Sokoto, Kastina àti Niger fún ìlàkàkà wọn láti ìgbà tí wọ́n ti gbé òun.
Nígbà tí àwọn Fulani ajínigbé ń digun gbé àwọn èèyàn lọ́tùn-ún lósì, àwọn ẹ̀yà mìíràn náà ń ṣe tiwọn lálábọ́dé. Ìròyìn Memunat tí ọkùnrin kan tí kìí ṣe Fulani jí gbé ní Ejigbo, ìpínlẹ̀ Èkó tẹ̀ wá lọ́wọ́. A gbọ́ pé ‘Àwọn òbí Memunat AbdulRahman ti ké gbàjarè síta lórí bí afurasí gbọ́mọgbọ́mọ kan ṣe gbé Memunat nígbà tí ó ń bọ̀ láti ilé kéú.
Ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Ẹrẹ́nà ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ ní Ejigbo, ìpínlẹ̀ Èkó. Memunat; ọmọ ọdún márùn-ún ń ti ilé kéú bọ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀, arákùnrin náà pàdé wọn lọ́nà ó sì ní kí wọ́n má abọ̀ ní ilé ìtajà kan pé òun fẹ́ ra ìpápánu fún wọn. Ẹ̀gbọ́n Memunat ló kọ́kọ́ wọ inú ilé ìtajà náà, ẹ̀yìn tó máa wò báyìí, ọkùnrin náà ló rí tó ń gbé Memunat sá lọ rẹ rẹ rẹ.
Àwọn òbí ọmọ yìí bèèrè fún fọ́nrán ẹ̀rọ akáwòránsílẹ̀ ilé ìtajà yìí, inú rẹ̀ ni wọ́n ti rí ojú ọkùnrin náà kedere, ó wọ inú ilé ìtajà náà pẹ̀lú àwọn ọmọ méjéèjì níwájú rẹ̀, ẹ̀ẹ̀kan náà ló ki Memunat mọ́lẹ̀ tó sì bọ́ síta, ẹ̀rọ tó wà níta ilé ìtajà náà tún káa bí ó ṣe wọ kẹ̀kẹ́ maruwa tó sì lọ.
Àwọn òbí Memunat ti fi àwòrán ọmọ wọn àti ti afurasí náà léde pé ẹni tó bá kófìrí rẹ̀ kó kàn sí àwọn. Bákan náà ni àwọn ọlọ́pàá ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ lórí rẹ̀.
Ìlú kò fara rọ mọ́, ẹ jẹ́ kí a máa ṣọ́ra ká sì máa ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ wa. A kò ní bọ́ sọ́wọ́, àṣẹ.
Discussion about this post