Hamdiyyah Sharif; ọmọbìnrin tó ké sí gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto pé kí ó wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí ti di àwátì báyìí.
Agbẹjọ́rò rẹ̀; Abba Hikima ló fi ìròyìn yìí léde lórí ìtàkùn ayélujára pé Hamdiyyah lọ ra oúnjẹ ní agbègbè rẹ̀ ní àárọ̀ ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní nǹkan bíi aago mẹ́wàá kò sì tíì padà dé di àsìkò yìí.
Hikima wí pé àwọn ti fi tó àwọn agbófinró létí wọn yóò sì bùn wá gbọ́ bó bá ṣe jẹ́.
Ta ni Hamdiyyah Sharif?
Hamdiyyah jẹ́ ọ̀dọ́mọbìnrin kan tó ní ìgboyà púpọ̀. Ìpínlẹ̀ Sokoto ni wọ́n bíi sí ibẹ̀ náà lò sì dàgbà sí.
Àwọn ohun tó máa ń kọ sí ojú òpó rẹ̀ náà ni ipò ààbò tó mẹ́hẹ ní ìpínlẹ̀ Sokoto àti àwọn àdojúkọ wọn, pàápàá àwọn obìnrin.
Gbogbo bí àwọn agbésùnmọ̀mí ṣe máa ń wọ àárín ìlú wá ṣe ọṣẹ́ láìsí ìdíwọ́ kankan fún wọn àti bí wọ́n ṣe máa ń bá àwọn obìnrin lò pọ̀ ni Hamdiyyah máa ń kọ nígbà mìíràn, a tún fi àwòrán kín ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́yìn.
Ní ọjọ́ kan, Hamdiyya ń bọ̀ láti ibi tó ti lọ gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà tí àwọn olè dá a lọ́nà, wọ́n lù ú lálùbami kí wọ́n tó tì í bọ́lẹ̀ láti inú kẹ̀kẹ́ maruwa lórí eré lẹ́yìn tí wọ́n ti gba gbogbo ohun tó wà lára rẹ̀.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló mú kí Hamdiyya ó tún tẹpẹlẹ mọ́ àwọn ohun tó máa ń kọ sí ojú òpó ayélujára rẹ̀. Èyí tó kó o sí wàhálà yìí ni fọ́nrán tó ṣe gbẹ̀yìn ní èyí tó ti ké sí Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto; Ahmed Aliyu láti wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ ààbò tó mẹ́hẹ ní ìpínlẹ̀ náà.
Ohun tó sọ nínú fọ́nrán náà ni wí pé àwọn agbésùnmọ̀mí ń wọlé jáde láìsí ìdíwọ́ kankan, àrà tó wù wọ́n ni wọ́n ń dá, tọ́sàn tòru sì ni wọ́n fi ń wọ ìlú wá ṣe ọṣẹ́ ọwọ́ wọn.
Hamdiyya wí pé àwọn obìnrin tí wọ́n ti sọ di aláìlọ́kọ mọ́ ń jìyà kiri abúlé ni, bí wọ́n bá tún wá wá ìrànlọ́wọ́ lọ sí olú ìlú ní àwọn ibùdó aláìnílé, níṣe ni wọ́n ń bá wọn sùn ní tìpátìkúùkú níbẹ̀’
Hamdiyya dárúkọ Gómìnà ìpínlẹ̀ Sokoto; Ahmed Aliyu nínú fọ́nrán náà pé kó wá nǹkan ṣe sí ọ̀rọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí.
Láti ìgbà tó ti ṣe fọ́nrán náà ni ìdààmú ti dé báa. Ilé ẹjọ́ Sharia ni wọ́n kọ́kọ́ gbé e lọ níbi tí ìjìyà rẹ̀ ó ti jẹ́ pípa àmọ́ àwọn lájọlájọ tó dá sí ọ̀rọ̀ náà ni wọ́n fi gbé ẹjọ́ náà lọ sí ilé ẹjọ́ ìjọba.
Ẹ̀sùn tí ìjọba fi kan Hamdiyya ní ilé ẹjọ́ ìjọba ni pé ó bu ẹnu àtẹ́ lu ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní Sokoto ní èyí tó tàbùkù ìjọba ìpínlẹ̀ Sokoto. Wọ́n ní ó pe Gómìnà Ahmed Aliyu ní agbésùnmọ̀mí ó sì bà á lórúkọ jẹ́.
Láti inú oṣù Bélú ọdún tó kọjá ni ìgbẹ́jọ́ náà ti bẹ̀rẹ̀ tí kò sì ní àǹfààní àtilọ ilé. Òní ilé ẹjọ́, ọ̀la ọgbà ẹ̀wọ̀n ni Hamdiyyah ń kojú láti ọdún tó kọjá.
Àwọn àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn àti agbẹjọ́rò rẹ̀ ṣe àlàyé oríṣìí àdojúkọ tí wọ́n ń kojú lórí ọ̀rọ̀ Hamdiyyah yìí. Agbẹjọ́rò rẹ̀ wí pé oríṣìí ìpè ni òun máa ń gbà tí wọ́n fi ń halẹ̀ mọ́ òun pé kí òun ó jáwọ́ nínú ẹjọ́ náà, ó wí pé àìmọye ìgbà ni wọ́n ti dá òun lọ́nà tí wọ́n sì ṣe òun báṣubàṣu pé kí òun o jáwọ́ nínú ẹjọ́ náà.
Pabambarì rẹ̀ ni pé ìjọba ìpínlẹ̀ Sokoto gbé ẹjọ́ náà kúrò ní ìpínlẹ̀ Sokoto lọ sí ìpínlẹ̀ mìíràn ní èyí tó mú kí ó nira fún Hikima tó jẹ́ agbẹjọ́rò rẹ̀ àti àwọn èèyàn rẹ̀ láti kàn sí i.
Àwọn àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn láti òkè òkun ló dá sí ọ̀rọ̀ náà kí wọ́n tó gba onídùúró rẹ̀ láìpẹ́ yìí.
Kò tíì ju bíi ọ̀sẹ̀ mélòó lọ tí wọ́n gba onídùúró Hamdiyyah tí ó tún ti di àwátì yìí, ta ni afurasí báyìí?
Ṣé ìjọba ìpínlẹ̀ Sokoto ni ká fura sí ni àbí àwọn ajínigbé àbí àwọn agbésùnmọ̀mí?
Ta ló pa Osemudiamen; òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ tó sọnù?
Osemudiamen Idemudia; òṣìṣẹ́ ilé ìfowópamọ́ tí wọ́n ń wá láti ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù yìí ni wọ́n ti rí òkú rẹ̀ ní ilé ìgbókùúsí kan ní Yaba báyìí.
Agbègbè CMS ní Èkó ni ilé ìfowópamọ́ tí Osemudiamen ti ń ṣiṣẹ́ wà, lọ́jọ́ náà tó di àwátì, ó jáde níbi iṣẹ́ pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ oníkalúkú sì wọ ọkọ̀ ilé rẹ̀. Àti ìgbà náà ni wọn kò ti ríi mọ́.
Àwọn ẹbí rẹ̀ kéde pé àwọn ń wá Osemudiamen lórí gbogbo ìkànnì ayélujára, wọ́n wá a dé gbogbo ilé ìwòsàn àti ilé ìgbókùúsí káàkiri kí wọ́n tó wá rí òkú rẹ̀ ní ilé ìgbókùúsì kan tó wà ní Yaba.
Àpá àdá wà ní orí, ojú àti ẹsẹ̀ rẹ̀ méjéèjì tó tọ́ka sí pé àwọn kan ló ṣá a ládàá pa.
Ilé ìgbókùúsí náà wí pé àwọn ọlọ́pàá ló gbé òkú rẹ̀ wá sí ibẹ̀ àwọn kò sì mọ orúkọ tàbí àgọ́ tí wọ́n ti wá.
Kò sí bí ìwádìí yóò ṣe wáyé lórí ikú tó pa Osemudiamen mọ́ nítorí kò sí àyẹ̀wò wọn kò sì mọ ibi tí àwọn ọlọ́pàá náà ti rí òkú rẹ̀, paríparí ẹ̀, wọn kò mọ àwọn ọlọ́pàá tó gbé e lọ pamọ́ sí ilé ìgbókùúsì náà.
Àwọn ẹbí rẹ̀ ti gbé òkú rẹ̀ kúrò lọ sin wọ́n sì fi ohun gbogbo lé Adẹ́dàá lọ́wọ́. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kò tíì wí nǹkan kan sí iṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Discussion about this post