Ọ̀rọ̀ burúkú tòun tẹ̀rín ni ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti ìpínlẹ̀ Rivers láàárọ̀ yìí. Ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì ni Gift, olólùfẹ́ rẹ̀; Sunday tó má wá ń kí i ló tún dé pé òun fẹ́ ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, Gift kọ̀ jálẹ̀ pé òun kò ṣe nítorí pé Sunday ti mu àwọn èròjà agbára ní èyí tí kò ní jẹ́ kó tètè ṣe tán.
Ìròyìn wí pé Sunday kò gbà, ó fi agídí bo Gift mọ́lẹ̀ ni Gift bá gbé okó rẹ̀ sẹ́nu ó sì fi eyín já ìdajì rẹ̀ bọ́ sílẹ̀.
Ariwo Sunday ni àwọn ará ilé fi bò wọ́n, wọ́n tilẹ̀ fẹ́ lu Gift pa ni àwọn ọlọ́pàá ló gbà á sílẹ̀.
Àwọn ọlọ́pàá ti gbé Sunday lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú wọ́n sì ti mú Gift sí àhámọ́. Ó ku àlàyé tí Sunday yóò ṣe fún ìyàwó ilé rẹ̀ báyìí.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí obìnrin ó gé nǹkan ọmọkùnrin olólùfẹ́ rẹ̀ jábọ́. Ní ìpínlẹ̀ èkìtì lóṣù tó kọjá, Joy rí ẹ̀wọ̀n he nígbà tó fi abẹ fa ẹpọ̀n Ibrahim tó jẹ́ olólùfẹ́ rẹ̀ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Ilé ẹjọ́ tó fìkàlẹ̀ sí ìpínlẹ̀ Ekiti ti pàṣẹ kí Joy Ikoja ó lọ rọ́kún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn pé ó fa ẹpọ̀n ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
Ẹni ọgún ọdún ni Joy Ikoja, a kò tíì le sọ pàtó ohun tó ṣẹlẹ̀ láàrin òun àti ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀; Ibrahim Usman tó fi fi abẹ fa ẹpọ̀n rẹ̀ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ.
Ọjọ́ ìṣẹ́gun ni Joy fi ojú ba ilé ẹjọ́, ẹjọ́ náà kò le parí lọ́jọ́ náà fún àwọn ìdí tó pọ̀ ni adájọ́ bá pàṣẹ kí wọn ó fi Joy sí ọgbà ẹ̀wọ̀n kan ní Ado-Ekiti títí di ọjọ́ kejìlélógún, oṣùn Igbe tó lọ yìí.
Agbẹjọ́rò rẹ̀ gbìyànjú láti rọ ilé ẹjọ́ pé kí wọn ó gba onídùúró rẹ̀ kí ó le máa gba ilé wá jẹ́jọ́, ó wí pé afurasí náà kò mọ nǹkankan nípa ẹ̀sùn náà.
Adájọ́ Olatomiwa Daramola fagi lé ẹ̀bẹ̀ agbẹjọ́rò Joy ó sì pàṣẹ kí wọn ó mú un lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Ado-Ekiti títí di ọjọ́ ìgbẹ́jọ́ tó ń bọ̀.
Kò tán síbẹ̀ o, ní ìpínlẹ̀ Ekiti yìí kan náà ni ìyàwó ilé ti fi àdá gé okó ọkọ rẹ̀ féú tí ọkọ náà sì ṣáa ládàá pa. ìròyìn náà kà báyìí pé:
Tọkọtaya kan tí wọ́n ń gbé ní Ita-Eku ní igirigiri, Ado Ekiti tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ekiti ni wọ́n ṣá ara wọn ládàá pa ní òru mọ́jú.
Ọ̀rọ̀ náà ṣe àwọn ọmọ wọn gan-an ní kàyéfì, kò sí ẹni tó le sọ pàtó bí ó ṣe ṣẹ̀lẹ̀ nítorí wọ́n ti ìlẹ̀kùn mọ́rí.
Àkọ́bí wọn lọ́kùnrin, ọmọ ọdún mẹ́tàlá ṣe àlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ náà pé bàbá àwọn dé ní nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án alẹ́, ó ní òun kò le jẹun àyàfi bí ìyá àwọn bá dé.
Nígbà tí ìyá wọn dé, gbogbo wọn jọ jẹun, wọ́n gbàdúrà, bàbá wọn ka bíbélì sí wọn létí, gbogbo wọn sì wọ yàrá wọn lọ sùn.
Nígbà tó di òru ni àwọn ọmọ bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ́ ìró àdá láti inú yàrá bàbá wọn, títì láti inú ni ìlẹ̀kùn wọn wà, àwọn ọmọ bá lọ pe awon ará àdúgbò, nígbà tí wọn yóò fi dé, wẹ́lo ni yàrá náà kò sí ariwo kankan mọ́.
Àwọn ọ̀dọ́ àdúgbò já ìlẹ̀kùn yàrá náà, òkú tọkọtaya ni wọ́n bá nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ pẹ̀lú àwọn àpá àdá tó jinú lára wọn. Kódà, nǹkan ọmọkùnrin bàbá ti dá dúrò nílẹ̀; kò sí lábẹ́ rẹ̀ mọ́.
Ohun tí wọ́n le sọ nípa ipò tí wọ́n bá wọn náà ni pé bóyá ìyàwó gé okó ọkọ rẹ̀ ni ọkọ náà bá kó àdá bò ó ni wọ́n bá ṣá ara wọn pa. Èrò lásán ni èyí, kò ṣojú ẹnìkankan.
Àwọn akọ̀ròyìn bi ọmọ náà léèrè pé ṣé àwọn òbí wọn máa ń jà tẹ́lẹ̀.
Ọmọ yìí fèsì pé ìjà kìí ṣe ohun titun nílé àwọn nítorí pé gbogbo ìgbà ni ìyá àwọn máa ń bá bàbá àwọn jà lórí ẹ̀sùn pé bàbá àwọn ń yan àlè.
Ó wí pé bàbá àwọn máa ń bá àwọn ṣeré dáadáa àmọ́ tí ìyá awo bá ti dé ni àyà rẹ̀ ó máa já. Ọmọ yìí wí pé bàbá òun sọ fún òun lọ́jọ́ kan pé ẹ̀rù ìyá òun ń ba òun.
Àmọ́ ní alẹ́ ọjọ́ tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀, ìjà ni àwọn ń retí bí ìyá àwọn ṣe dé àmọ́ ẹ̀rín àti ọ̀yàyà ni ìyá wọn bá wọlé, inú gbogbo wọn dùn láìmọ̀ pé gbẹgẹdẹ ó padà gbiná lóru.
Ọmọ mẹ́rin ló wà láàárín tọkọtaya yìí, ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni àkọ́bí wọn, kò sí èyí tó tójú bọ́ nínú wọn.
Àwọn ará àdúgbò náà kín àlàyé tí ọmọ yìí ṣe lẹ́yìn. Wọ́n ní fádèyí olóró àdúgbò ni arábìnrin náà, gbogbo ìgbà ni ó máa ń bá ọkọ rẹ̀ jà, á wí pé ọkọ òun ń yan àlè.
Wọ́n ní ohun tó ṣẹlẹ̀ lóru ọjọ́ náà gan-an kò yé ẹnikẹ́ni tààrà nítorí pé wọ́n ti ilẹ̀kùn mọ́rí. Àwọn ará àdúgbò tilẹ̀ ṣe aájò wọn dé ilé ìwòsàn àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró mọ́.
Ọ̀rọ̀ yìí kan ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá gbọ̀ngbọ̀n nítorí pé ọlọ́pàá ni ọkùnrin náà kó tó kú.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Irú ìròyìn báyìí kìí ṣe ohun tó le dùn mọ́ ẹnikẹ́ni nínú, ìpalára tó ní ìjìyà lábẹ́ òfin ni kí èèyàn ó gé okó ọkùnrin tàbí fàá lẹ́pọ̀n ya, gbogbo àwọn wọ̀nyìí ni wọn yóò rí ẹ̀wọn he tí àwọn ọkùnrin náà sì ti di abo nítorí wọn kò ní le ṣe bíi ọkùnrin mọ́
Discussion about this post