Adájọ́ àgbà ti fèsì sí ọ̀rọ̀ tó ń jà ràìnràìn lórí ìtàkùn ayélujára pé Ogbonna ṣe ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélógún nítorí pé ó ra ẹ̀rọ amúnáwá tí wọ́n jí gbé.
Adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ Ogun; Oluwasina Ogungbade ló fèsì sí ọ̀rọ̀ náà pé ẹ̀sùn ìdigunjalè ni Ogonna torí ẹ̀ ṣe ẹ̀wọ̀n kìí ṣe nítorí pé ó ra ẹ̀rọ amúnáwá tí àwọn kan jí gbé.
Adájọ́ Oluwasina wí pé ní ọjọ́ kẹta, oṣù kẹwàá ọdún 2003 ni Ogonna àti àwọn ikọ̀ rẹ̀ lọ digun ja ilé epo kan tí wọ́n sì pa ẹ̀ṣọ́ aláàbò kan.
Àlàyé náà kà báyìí pé:
‘ní ọjọ́ kẹta, oṣù Ọ̀wàrà, ọdún 2000, Ogonna àti àwọn ikọ̀ rẹ̀ lọ digun kó ilé epo ELF kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Ogun wọ́n sì gbé ẹ̀rọ amúnáwá ńlá ibẹ̀ lọ. Wọ́n fọ́ irin mọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ilé epo náà méjì lórí; Moses Bankole àti Yusuf Akanni.
Moses Bankole kú lẹ́sẹ̀késẹ̀ nígbà tí Yusuf tó yè jẹ́ ẹlẹ́rìí ìjọba. Ogonna jẹ́ amojú-ẹ̀rọ tó ń tún ẹ̀rọ amúnáwá ṣe, òun ló tú ẹ̀rọ náà níbi tí wọ́n dè é mọ́.
Ní aago méjì ààbò orù ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, àwọn ọlọ́pàá dá ọkọ̀ kan dúró ní Toll gate, omi inú ọ̀rá àti igi ni wọ́n fi bo ẹ̀rọ náà mọ́lẹ̀, nígbà tí Ogonna àti àwọn ẹmẹ̀wàá rẹ̀ kò le sọ bí ẹ̀rọ náà ṣe jẹ́ ni wọ́n fi mú wọn tó fi wá padà já sí pé ẹ̀rọ tí wọ́n gba ìfisùn rẹ̀ ní ilé epo ELF ni ẹ̀rọ náà.
Awakọ̀ ọkọ̀ náà; Kolawole Oladeji wa ọkọ̀ sá lọ tó sì já Ogonna sílẹ̀ lọ́jọ́ náà. Àwọn ọlọ́pàá mú Ogonna lọ sínú àtìmọ́lé àmọ́ ó bá inú òrùlé jáde.
Nọ́ḿbà ara ọkọ̀ náà tí àwọn ọlọ́pàá ti kọ sílẹ̀ ni wọ́n fi tọpinpin ẹni tó ni ọkọ̀ náà, òun ló júwe àwọn awakọ̀ rẹ̀ mẹ́rin tí wọ́n sì mú Sunday Oloyede, Sunday ló júwe ibi tí wọn ti mú Kolawole tó wa ọkọ̀ náà lóru ní Toll gate.
Ọwọ́ tẹ àwọn mẹ́wàá mìíràn, gbogbo wọn ni wọ́n jẹ́jọ́ ní ilé ẹjọ́. Ẹni tí Ogonna ta ẹ̀rọ náà fún; Ali Rihan kò gbẹ́yìn’
Adájọ́ Oluwasina Ogungbade wí pé Ogonna kò ra ẹ̀rọ amúnáwá náà, òun gan-an ló jí ẹ̀rọ náà gbé. Ó wí pé bí ó bá rà á ni, ó yẹ kó mú ìwé ẹ̀rí pélébé jáde han ìjọba àmọ́ òun gan-an ló kọ ìwé ẹ̀rí pélébe fún Ali Rihan tó ta ẹ̀rọ náà fún.
Lórí ẹ̀sùn ìdigunjalè àti ìpànìyàn náà ni adájọ ìgbà náà ṣe dá ẹjọ́ ikú fún Ogonna àti ikọ̀ rẹ̀ àmọ́ lẹ́yìn ọdún mẹ́rìndínlógún, àwọn kan nínú wọn rí ìdárìjì gb à láti ọ̀dọ Gómìnà.
Ọ̀rọ̀ adájọ́ Oluwasina gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé kí àwọn èèyàn ó yàgò fún ọ̀rọ̀ tó ń lọ pé nítorí pé Ogonna ra ọjà olè ni ó ṣe ṣe ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélógún, ó wí pé àwọn tí Ogonna pa lára àti ẹni tó pa kò ní gbàgbé oró náà láyé.
Ọ̀rọ̀ yìí jáde ní ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn n ígbà tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Abia; Alex Otti gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò tó sì dáríjìn Ogonna. Ó ti wá ń lọ káàkiri pé wọ́n fi ìyà àìtọ́ jẹ Ogonna.
Ní báyìí, Adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ Ogun ti ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí bí iṣu ṣe kú àti bí ọ̀bẹ ṣe bẹ ẹ́.
Bí a ṣe ń kọ èyí lọ́wọ́ ni ìròyìn kan náà tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti ìpínlẹ̀ Akwa Ibom nípa àwọn ọmọ ìyá méjì tí wọ́n sẹkú pa ẹ̀gbọ́n wọn.
A gbọ́ pé:
Akaninyene Thomas Okpon àti Ime Thomas Okpon tí àwọn méjéèjì jẹ́ ọmọ ìyá àti ọmọ bàbá ti bẹ́ orí ẹ̀gbọ́n wọn sógán bí ajá Ògún lórí ẹ̀sùn pé òun ló ń ṣe àwọn tí kò jẹ́ kí ayé àwọn ó ní ìtumọ̀.
Agbègbè Abasi Asutan ní ìjọba ibílẹ̀ Ibesikpo Asutan ní ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀ lọ́dún 2018.
Akaninyene àti Ime lọ dá ẹ̀gbọ́n wọn; Friday lọ́nà nígbà tó ń bọ̀ láti oko ọdẹ, wọ́n fi ẹ̀sùn kàn án pé oṣó ni, òun ni kò jẹ́ kí àwọn ó ṣe rere láyé, wọ́n bẹ́ orí rẹ̀ wọ́n sì sin orí náà lọ́tọ̀ àti ara rẹ̀ lọ́tọ̀ sínú igbó.
Ẹni ọdún mẹ́tàdínlógójì ni Ibe nígbà tí Akaninyene jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n àti bàbá àwọn ọmọ mẹ́ta. Láti ọdún 2018 náà ni ìgbẹ́jọ́ ti bẹ̀rẹ̀ àmọ́ Ime ti kú sí àgọ́ ọlọ́pàá kí ìgbẹ́jọ́ tó parí.
Níbi ìgbẹ́jọ́ tó wáyé ní ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Akwa-Ibom lónìí, Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹwàá, oṣù Agẹmọ ni Adájọ́ Okon ti pàṣẹ pé kí wọn ó so Akaninyene rọ̀ títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lára rẹ̀.
Adájọ́ wí pé lẹ́yìn gbogbo atótónu àti àwíjàre, kò sí àníàní pé Akaninyene àti Ime jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn. Ó wá páṣẹ pé kí wọn ó so Akaninyene rọ̀ títí ẹ̀mí rẹ̀ ó fi bọ́.
Ká fi ẹsẹ̀ kan dé ìpínlẹ̀ Gombe níbi tí àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ wa ti ṣe àwọn agbésùnmọ̀mí bí ọṣẹ ṣe ń ṣe ojú.
Ìròyìn náà kà báyìí pé:
ÀWỌN ỌMỌ OGUN ILẸ̀ YÌÍ ṢE SIA FÚN ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ NÍ ÌPÍNLẸ̀ KEBBI.
Ikọ̀ ológun ilẹ̀ yìí tí wọ́n pe orúkọ wọn ní 223 Light Battalion ti kojú àwọn agbésùnmọ̀mí ní ibùdó wọn tó wà ní Danko Wasagu ní ìpínlẹ̀ Kebbi.
Ó lé ní irinwó àwọn agbésùnmọ̀mí tí wọ́n wà ní bùbá náà, wọ́n dìde sí àwọn ológun àmọ́ àwọn ológun ló ṣẹ́gun wọn. Àwọn tí wọn kò kú kò fi ara ire lọ, gbogbo wọn ló fara gbọta.
Bákan náà la gbọ́ pé àwọn ológun ojú òfurufú náà kún àwọn torí ilẹ̀ lọ́wọ́ ni ọwọ́ ṣe dun àwọn agbésùnmọ̀mí yìí.
Ile iṣẹ́ ológun dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ka tó ṣe ìrànwọ́ fún wọn wọ́n sì fi àwọn ará ìlú lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ ń mẹ́yẹ bọ̀ lápò ni.





