Òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ kan tó wà ní ìpínlẹ̀ Ogun ti jẹ́ ìpè Elédùà lẹ́yìn tí ẹ̀rọ gbé e hánu tó sì lọ̀ ọ́ kúnná. Ogijo ní ìpínlẹ̀ Ogun ni ilé iṣẹ́ yìí wà. Abayomi ni orúkọ ọkùnrin yìí, ọjọ́ Ajé tó lọ yìí ni ó ṣe àgbákò ikú òjijì náà.
Àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ kò kọ́kọ́ fẹ́ ṣe àlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe ṣẹlẹ̀, wọ́n ní àwọn kò fẹ́ kí àwọn ọ̀gá ilé iṣẹ́ náà ó fi ìyà jẹ àwọn. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àrọwà, wọ́n ṣe àlàyé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́.
Àlàyé tí wọ́n ṣe náà ni pé amojú ẹ̀rọ náà tó jẹ́ òyìnbó ké sí Abayomi pé kí ó wá yọ nǹkan tó há sínú ẹ̀rọ náà tí kò fi yí mọ́. Abayomi kò mọ̀ pé amojú ẹ̀rọ yìí kò pa ẹ̀rọ náà tó fi kó sí inú rẹ̀ láti yọ ohun tó há sínú rẹ̀ náà, yíyọ tó yọ ọ́ tán ni ẹ̀rọ náà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà tó sì lọ Abayomi kúnná.
Wọ́n ní amojú ẹ̀rọ yìí kò dìde níbi tó jọkòó sí, ìgbà tí àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ ó fi yọ ọ́, ẹ̀rọ ti lọ̀ ọ́ ó sì ti kú.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Omolola Odutola pé lóòótọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.
Ní ìlú Ìwó:
Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti dájọ́ ikú fún Àlùfáà Kabiru Ibrahim lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn.
Ẹ̀sùn tí ìjọba fi kan Àlùfáà Kabiru ni pé ó ṣekú pa oníbàárà rẹ̀ tó wá ṣe aájò lọ́dọ̀ rẹ̀. Orúkọ oníbàárà náà ni Lukman Adeleke.
Adájọ́ Lateef Adegoke wí pé gbogbo ẹ̀rí ló fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Àlùfáà Kabiru ló ṣekú pa Lukman, fún ìdí èyí, adájọ́ pàṣẹ kí wọn ó so ó rọ̀ títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lẹ́nu rẹ̀.
Àlàyé tí a rí gbà lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni pé Lukman Adeleke sọ fún Àlùfáà Kabiru pé òun fẹ́ ra ilẹ̀ òun sì fẹ́ kó bá òun gba àdúrà síi.
Àlùfáà Kabiru sọ fún Lukman pé kí ó kó owó tí ó fẹ́ fi ra ilẹ̀ náà wá kí òun ó gba àdúrà síi lóru mọ́júmọ́. Lẹ́yìn tí Lukman sun ilé Àlùfáà Kabiru mọ́jú ni ó ti sọnù tí wọ́n sì ti ń wá a. Èèyàn kan ló ta wọ́n lólobó pé òun rí Lukman tó wọ inú ilé Àlùfáà Kabiru ní ó ku ọ̀la tó sọnù náà.
Àlùfáà Kabiru wí pé òun kò rí Lukman àmọ́ nígbà tí wọ́n mú un dáadáa, ó mú àwọn ọlọ́pàá lọ sí ibi tó ju òkú rẹ̀ jùnù sí nínú àpò.
Kò sí ọwọ́ òsì Lukman lára rẹ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹ̀yà ara mìíràn náà di àwátì. Ọ̀ọ́dúnrún ẹgbẹ̀rún náírà #300,000 ni owó tí Àlùfáà Kabiru torí ẹ̀ pa Lukman.
Lẹ́yìn gbogbo atótónu, adájọ́ Lateef Adegoke pàṣẹ kí wọn ó gba ẹ̀mí lẹ́nu Àlùfáà Kabiru pé ó jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn náà.
Ní ìpínlẹ̀ Anambra:
Ọmọ ọdún mẹ́ta kan ló ti gbẹ́mìí mìn lẹ́yìn tó tẹ àwọn wáyà iná mọ́lẹ̀ ní agbègbè Isiah Morah ní Awka tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Anambra. Àlàyé tí a rí gbà ni pé àwọn wáyà iná náà jábọ́ láti ori òpó ní ọjọ́ Ẹtì, àwọn ará àdúgbò ní àwọn kàn sí ilé iṣẹ́ iná láti wá kó o kúrò nílẹ̀ àmọ́ wọ́n bèèrè fún ọgbọ̀n naírà. Wọ́n ní lẹ́yìn tí àwọn san owó náà tán, ẹni tí wọ́n rán wá wí pé òun kò mó ibẹ̀ ó sì padà sí ọ́fíìsì.
Ọjọ́ Àìkú ni ìyá ọmọ ọdún mẹ́ta yìí rán an níṣẹ́ níwájú ilé, nígbà tí ó ń padà bọ̀, ó dá ẹsẹ̀ lé àwọn wáyà iná yìí iná sì gbé e. Wọ́n ṣe aájò rẹ̀ dé ilé ìwòsàn àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró mọ́, ọmọ náà ti dágbére fáyé.
Kò tó wákàtí méjì tí iná gbé ọmọ náà pa tí àwọn oníṣẹ́ iná ṣàdédé mọ ọ̀nà àdúgbò náà tí wọ́n sì kó àwọn wáyà náà kúrò.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra wí pé àwọn kò gba ìfisún lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Lágbo òṣèré:
Òṣèré tíátà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Godwin Nnadiekwe ti balẹ̀ sí ilé ìwòsàn lẹ́yìn tí Zubby Micheal gbá a nípàá láyà lórí ìtàgé.
Godwin ṣe àlàyé pé àwọn ń ya eré lọ́wọ́ ni Zubby gbá òun nípàá láyà ní èyí tí kò sí nínú àkọsílẹ̀ eré náà. Godwin wí pé lẹ́yìn tí ó gbá òun nípàá yìí, kò sí ẹni tó ṣe aájò òun tàbí gbìyànjú àti tọ́jú òun, ó ní fúnra òun lòun lọ sí ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú pẹ̀lú owó àpò òun.
Ohun tó wá burú nípa ọ̀rọ̀ náà ni pé ipò ìlera rẹ̀ ti burú síi, àwọn dọ́kítà wí pé àyà rẹ̀ ń ṣe ẹ̀jẹ̀ nínú yóò sì nílò ìtọ́jú gidi.
Godwin ní òun kò lérò àti ba Micheal lórúkọ jẹ́ àmọ́ ohun tí òun ń gbìyànjú àtisọ ni pé kò yẹ kí àwọn òṣèré ó má mú ìpalára bá ara wọn, ó ní iṣẹ́ náà kò ní ètò ìlera, oníkálukú ni yóò rán ohun tó bá ṣẹlẹ̀ sí i.
HAJJ 2025.
Ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n lọ ṣe iṣẹ́ hájì ọdún yìí tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Adizatu Dazumi ti dágbére fáyé lọ́hùn-ún. Ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin ni Adizatu lásìkò ikú rẹ̀ yìí. Ilé ìwòsàn King Fahad ló dákẹ́ sí láàárọ̀ àná; ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n lẹ́yìn àìsàn ránńpẹ́.
Ọmọ ìpínlẹ̀ Edo ni Adizatu, alága ètò hájì ìpínlẹ̀ Edo; Musah Uduimoh ló túfọ̀ ikú Adizatu lónìí ọjọ́ Ìṣẹ́gun.
Àlàyé tí Musah ṣe ni pé lẹ́yìn tí Adizatu parí tàwáàfù ni àárẹ̀ náà dé bá a tí wọ́n sì gbé e lọ sí ilé ìwòsàn ìyẹn lọ́jọ́ Àìkú tó sì padà dákẹ́ lọ́jọ́ Ajé.
Wọ́n ti sin Adizatu sí Mẹ́kà ní ìlànà ẹ̀sìn Mùsùlùmí wọ́n sì ti fi tó àwọn ẹbí rẹ̀ létí. Musah fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ránṣẹ́ sí àwọn ẹbí Adizatu ó sì kí wọn kú aráfẹ́rakù.
Discussion about this post