Ọ̀kan nínú àwọn àgbà àti așaájú ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re, ìyẹn ẹgbẹ́ tó ń jà fún ẹ̀tọ́, àṣà àti òṣèlú ilẹ̀ Yorùbá àti Nàìjíríà lápapọ̀ Bàbá Ayọ̀délé Adébánjọ ti tẹ́rí gbaṣọ, ó ti papò dà, bẹ́ẹ̀ ni ẹja ńlá lọ lómi o. Ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún ni bàbá lò lókè eèpẹ̀ kó tó dágbére fáyé ni àná, ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù kejì ọdún yìí 2025. Ilé rẹ̀ ní Lẹ́kí ní Ìpínlẹ̀ Èkó ló sì ṣe ‘ hìn-ìn’ sí.
Nínú Ìròyìn tó ti ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí bàbá Adébánjọ wá, wọ́n fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé bàbá àwọ́n ti fàdàgbá ayé tì síbì kan o. ” Ó sùn wọ́ọ́rọ́wọ́ láàárọ̀ yìí ọjọ́ Ẹtì, February 14, 2025 ní ilé rẹ̀ ni Lẹ́kí lÉkòó, ó sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún.
Bàbá Adébánjọ jẹ́ ògbóǹtarìgí agbẹjọ́rò, ó sì jẹ́ akọ̀wé fún ẹgbẹ́ Ọlọ́pẹ- Action group ( A. G) ọjọ́un. Òun sì ni aṣíwájú ẹgbẹ́ tó ń jà fún àṣà, ìṣe àti ètò òṣèlú tó mọ́yán lórí fún ìran Yorùbá, ìyẹn Ẹgbẹ́ Afẹ́nifẹ́re.
Àwọn tó gbẹ̀yìn bàbá ni ìyàwó rẹ̀ ẹni ẹ̀rìnléláàádọ́rùn-ún ọdún, Olóyè Christy Ayọ̀-Adébánjọ ; ọmọ ; ọmọọmọ àti àwọn ọmọọmọọmọ.
” Títí láé ni a ó máa rántí ìfàyàrán rẹ̀ láti jà fún Òótọ́, ìdájọ́ òdodo àti ẹ̀tọ́ ọmọniyan. Ìgbàgbọ́ àti ìjàgùdù rẹ̀ fún Nàìjíríà lómìnira àti onítẹ̀síwajú kò lẹ́gbẹ́ rárá. Eléyìí ló sì ń jà fún títí Ọlọ́jọ́ fi dé bá a”
Àwọn ẹbí fi léde pé ìjíròrò ń lọ lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn ọrẹ́ àti ojúlùmọ̀ bàbá jákèjádò ilẹ̀ Nàìjíríà àti ní Òkè òkun láti fẹnu kò lórí bí ètò ìsìnkú tó jíire yóò ṣe di gbígbé kalẹ̀. ‘A ó máa fi èyí tó aráàlú létí tó bá yá.
Ìwé ìbánikẹ́dùn táwọn èèyàn yóò máa fọwọ́ sí tí wà ní ṣíṣí sílẹ̀ ní ilé rẹ̀, 8, Ayọ̀ Adébánjọ close, Lekki phase 1,Lagos; ati ní ìlú abínibí rẹ̀ ní Isanya Ogbo lẹ́bàá Ìjẹ̀bú-òdẹ, Ìpínlẹ̀ Ògùn.