Gbajúgbajà òṣèrébìnrin, ẹni Àádọ́rin ọdún dín díẹ̀, Arábìnrin YÉTÚNDÉ ÒGÚNṢỌLÁ tú pẹẹrẹpẹ́rẹ̀ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ lórí ìgbéyàwó òun àti ọ̀gá àgbà òṣèré tó jẹ́ ọkọ rẹ̀, Olóògbé ÌṢỌ́LÁ ÒGÚNṢỌLÁ TIMOTHY tí gbogbo ayé mọ̀ sí ‘I SHOW PEPPER’ lásìkò tí àkẹ́gbẹ́ rẹ̀ KÚNLÉ AFOD n ṣé ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú rẹ̀ lórí ẹ̀rọ alátagbà YÚTUUBÙ láìpẹ́ yìí. Màmá Àyọ̀ní gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ti mọ̀ wọ́n sí nínú eré àgbéléwò ọdún gbọgbọrọ sẹ́yìn lórí ìkànnì ṣana ṣẹ́fùn nígbà kan rí sọ pé òun ni ìyàwó ẹlẹ́ẹ̀keje tí olóògbé TIMOTHY ÒGÚNṢỌLÁ ÌṢỌ̀LÁ fẹ́ tí òun tún gba ìyàwó méjì mìíràn lẹ́yìn. Màmá YÉTÚNDÉ ÒGÚNṢỌLÁ wí pé:
‘Nígbà tí mo fẹ́ ọkọ mi, èmi ni ìyàwó ẹlẹ́ẹ̀keje rẹ̀, bàbá tún fẹ́ obìnrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ méjì mìíràn lé mi. Oníyàwó púpọ̀ ni TIMOTHY ÌṢỌ̀LÁ ÒGÚNṢỌLÁ, Ó kàn jẹ́ pé àwọn ìyàwó rẹ̀ kìí pẹ́ kọ̀ọ́ sílẹ̀ nítorí iṣẹ́ tíátà tó n ṣe,wọ́n sì gbé ọmọ jù sílẹ̀ fún un fẹsẹ̀ fẹ. Bí èyí tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, èmi ṣì ni ààyò rẹ̀. Ìdí tí mo fi jẹ́ ààyò rẹ ní pé iṣẹ́ kan náà ni a jọ n ṣe , òṣèré orí ìtàgé ni àwa méjéèjì jọ n ṣe, òun ló fàá tí ìfẹ́ mi fi gbilẹ̀ púpọ̀ lọ́kàn rẹ̀. Ó fẹ́ràn mi ju àwọn aya rẹ̀ tókù lọ, èyí kò sì dá owú gbígbóná sílẹ̀ láàrín wa títí tó fi wọ káà ilẹ̀ lọ. Ìfẹ́ òtítọ́ ni a fi bá ara wa lò , mí ò rí wọn bí orogún bẹ́ẹ̀ ni àwọn pàápàá kò fi ọwọ́ orogún mú mi àgàgà tó jẹ́ pé èmi àti ọkọ mi ni a jọ n pawó wọlé sínú àpò ẹbí. Iṣẹ́ wa ni a fi n gbọ́ bùkátà inú ilé pátápátá láì ṣẹ́kú nnkankan rárá.
Nnkan yìí gan an ni kò jẹ́ kí ìkùnsínú wà láàrín èmi àti àwọn orogún mi nítorí wọ́n n jẹ ànfaàní mi púpọ̀.
Òṣèrè mìíràn tún tú kẹ̀kẹ̀ ọ̀rọ̀ sílẹ̀ lórí bí ìgbéyàwó rẹ̀ ti lọ, àwọn ni gbogbo olólùfẹ́ wọn mọ̀ sí MÀMÁ ERÉKỌ̀. Màmá Eréko ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbàmọ́ra àti ìforítì pẹ̀lú ìfaradà ní àwọn dojúkọ nínú ìgbèyáwo wọn.
‘Mo ní ìfòrítì àti ìgbàmọ́ra púpọ̀, ojú mi rí tóóó, ẹ̀mí mi fẹ́ẹ̀ pin, ìbẹ̀rù bojo lójoojúmọ́ àgàgà tí ọkọ mi tún wá jẹ́ oníṣìná paraku. Tẹ̀dùn-okàn-tẹ̀dùn-okàn ni MÀMÁ ERÉKO fi n sọ ìwà láabi tí ọkọ rẹ̀ wù fún un. Màmá ni ọkọ yóò gbé àlè wa wá sí ilé yóò ni kí n fi ilé sílẹ́ kí òun le è ráàyè ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àlè rẹ̀.,kò sì ṣe é ṣe fún màmá láti dojú ìjà kọ ọ́ nítorí pé wọ́n gbà pé ọkọ ni adé orí aya, àti pé ọkọ ẹni ni adé orí ẹni tí kò gbọdọ̀ ṣíbọ́. Orí ìbùsùn mi náà ni ọkọ mi àti àlè rẹ̀ yóò ti bá ara wọn ní ìbálòpọ̀, ìbẹ̀rù bojo kò ní jẹ́ kí n nlè da lẹ́kun ìwà nàbì yìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ṣe ni inú máa n bí i ní àsìkò yìí.
Àwuyewuye tún lọ lórí ẹ̀rọ ayélujára pé òṣèrébìnrin KATE HENSHAW ṣetán láti fẹ́ Òjíṣẹ́ Ọlọ́run IGHODOLO, wọ́n ní ìwé ìpè síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó wọn ti wà níta báyìí àti pé ọdún yìí gan an ni yóò jẹ́.
Nígbà tí àwọn àkọ̀ròyìn fi ọ̀rọ̀ wá òjíṣẹ́ Ọlọ́run IGHODOLO lẹ́nu wò, ó ní:
Àwọn tó n gbélé pawó lórí ẹ̀rọ ayélujára fesibúùkù ló n gbọ́yìí-sọ̀yí,àhesọ ọ̀rọ̀ lásán ni, mò ṣì ní ìfẹ́ aya mi IBIDUN IGHODOLO àti àwọn ọmọ méjì tí a gbà tọ́, mi ò ṣetán láti fẹ́ ẹnikẹ́ni lọ́wọ́ yìí. Bí àwọn gbélépawó bá ti tà dáradára tán, kí wọ́n wá san owó ìdámẹ́wàá wọ́n nílé Ọlọ́run. Bí ẹ kò bá gbàgbé, àtànkálẹ̀ àrùn COVID 19 ló ṣekú pa Aràbìnrin IBIDUN IGHODOLO ní oṣù kẹfà ọdún 2020. Kò tí ì bímọ lásìkò ìgbà náà, ọmọkùnrin kan àti obìnrin ni òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ gbà tọ́ tó fi jẹ́ Ọlọ́run nípè.
Bí ẹ kò bá gbàgbé, àtànkálẹ̀ àrùn COVID 19 ló ṣekú pa Aràbìnrin IBIDUN IGHODOLO ní oṣù kẹfà ọdún 2020. Kò tí ì bímọ lásìkò ìgbà náà, ọmọkùnrin kan àti obìnrin ni òun pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ gbà tọ́ tó fi jẹ́ Ọlọ́run nípè. Òjíṣẹ́ Ọlọ́run IGHODOLO ní òun kò tíì ṣetán láti fẹ́ obìnrin mìíràn rárá àgàgà KATE HENSHAW tí wọ́n n sọ pé òun ni aya tuntun tí òun fẹ́ gbé níyàwó.
Ọ̀rọ̀ lórí ìgbèyáwò àwọn òṣèré tó tún n jà rainrain lórí ẹ̀rọ ayélujára báyìí ni tí òṣèrékùnrin GANIU KẸ́YÌNDÉ MOROOF tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí ìjọba LANDE. Fọ́nrán kan jáde bí ìyáwó ilé rẹ̀ tí n fín iná bí ìgbà tí Alágbẹ̀dẹ n fín ewìrì, igbó ló n fà bí ẹ̀mọ́. Ìjọba LANDE ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ akẹgbẹ́ òun ló n bá ìyàwó ṣe òwo nàbì, ó dárúkọ BABA TEE gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára wọn, ó tún ní ọ̀kan tilẹ̀ wà tó jẹ́ pé bí òun bá dárúkọ rẹ̀, ó ṣeéṣe kí ẹ̀mí òun lọ síi. Ìjọba LANDE ni òun rí ìyàwó òun lẹ́ ni tó ti bímọ rí ṣùgbọ́n ìfẹ́ òtítọ́ tí òún ní sí i ló ṣe kókó jùlọ. Ìjọba LANDE ní òun fi owó bá a lò gẹ́gẹ́ bí ọkọ rere tí n ṣe sí aya rẹ̀ ṣùgbọ́n ìyàwó sì n fi ọ̀bẹ ẹ̀yìn jẹ òun níṣu.
Ó jọ́ pé ọ̀rọ̀ yìí tí n dá ọgbẹ́ ọkàn sí i lọ́kàn nítorì bí ẹ ò bá gbàgbẹ́, Ìjọba LANDE ló fẹ́ lọ pokùnsó lọ́dún díẹ̀ sẹ́yìn kí àwọn èèyàn tó dìde sí í, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ bí wọn kò tilẹ̀ mọ ìdí tó fi fẹ́ pokùnso. Hùn ùn! ọ̀rọ̀ pọ̀ nínú ìwé kọ́bọ̀ nípa ìgbéyàwó àwọn òṣèré ilẹ̀ Nàìjíríà àfi káfi sẹ́nu báyìí, ká dákẹ́.