Àlùfáà àgbà nílẹ̀ yìí, oníwáàsí àgbáyé, ẹni tí ÁLÀ gbà fún , Ṣéù Farook Sulaiman Onikijipa bọ́ sí gbangba wálíà, Ó búra pẹ̀lú ìwé mímọ́ Kùrání láti sẹ́ ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé òun ló rán àsàsí sí Ṣéù HABEEB ADAM AL-ILORI, Ọ̀gá àgbà fún gbogbo ìjọ Mọ́ríkáàsì pátápátá L’ágége ọmọ bàbá wa àgbà ABDULLAI ADAM AL-ILORY pé àìsàn ọlọ́jọ́ pípẹ́ tó n yọ Mùdírù lẹ́nu, Ṣéù FAROOK SULAIMAN ONIKIJIPA ló fi ṣe é. Nínú wáàsí Ràmàdáànù tọdún yìí ni Ṣéù FAROOK ONIKIJIPA, Mufti Àgbà ní ìlú Ìlọrin n fi Ọlọ́run búra pé òun kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa àìsàn tó n ṣe Mùdírù rárá, òun kò rán àsàsí kankan sí i. Mufti wí pé : Àlùkùránì rèé, ìwé mímọ́, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ọba Àjọkẹ́ ayé, Àṣàkẹ́ ọ̀run, inú mọ́ṣáláṣí ilé Ọlọ́run ni mo wà yìí, láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ayé mi, mi ò ṣe ìbúra kankan rí pẹ̀lú ìwé mímọ́ Àlùkùránì àmọ́ lónìí, Mò n búra pé mi ò lọ́wọ́ sí àìsàn tàbí ọfà oró tó mú Mùdírù HABEEBLLAHI ADAM. Ṣéù FAROOK SULAIMON ní ‘Olúwa Álà, ilé rẹ ni mo wà yìí, Èmi FAROOK SULAIMON ONIKIJIPA, ọmọ bíbí AMINAT kò mọ nnkan kan nípa àìlẹra Mùdírù Mọ́ríkáàsì, Bí mo bá mọ ohunkóhun nípa àìsàn tó n ṣe Mùdírù Mọ́ríkáàsì tàbí lọ́wọ́ nínú rẹ̀, kí gbogbo ègún tó n bẹ nínú ìwé mímọ́ Àlùkùránì jẹ́ tèmi. Ẹmẹ̀ẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ṣéù FAROOK SULAIMON sọ èyí láti fi wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ẹ̀sùn ibi tí wọ́n fi kàn án, Ó ní bó bá jẹ́ pé àwọn kan ló n le èyí láti fi tàbùkù mi àti láti fi bàmí jẹ́, kí gbogbo ègún inú Àlùkùráànì yìí jẹ́ ti wọn, kó sì ṣẹ mọ́ wọn lára.
Ohun tó mú Ṣéù FAROOK SULAIMON ONIKIJIPA jáde láti gbé ìgbésẹ̀ yìí ni látàrí ẹ̀sùn ràbàndẹ̀ tí Mùdírù Mọ́ríkáàsì fi kàn án lásìkò tí wọn ṣe wáàsí inú àwẹ̀ ọdún 2025 yìí. Mùdírù Mọ́ríkáàsì, HABEEB ADAM AL-ILORY ni àìsàn òun kìí ṣe ojú lásán, àwọn olubi kan ló fi kaṣan ara òun de òun mọ́lẹ̀ bí ẹran láti ọdún púpọ̀ sẹ́yìn. Págà! kàyéèfì ni ọ̀rọ̀ bàntàbàntà tí Mùdírù Mọ́ríkáàsì L’Ágége yìí jẹ́, gbogbo ayé ló n kọ háà! háà! háà! A ò rí irú èyí rí ooo lásìkò tí Mùdírù b’ọ́hùn pé àìsàn tó n ṣe òun láti ọdún 2022 lọ́wọ́ kan ìkà Ṣéù FAROOK SULAIMON ONIKIJIPA nínú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Mùdírù Mọ́ríkáàsì kò nà tán, kò ṣe é ní ṣàn án là á rìn, ajé ní i múni pẹkọrọ lórí ẹni ti onítọ̀hún n ṣe ṣùgbọ́n gbogbo ọmọ ìjọ ló mọ̀ pé MUFTI ILORIN, FAROOK SULAIMON ONIKIJIPA ni ẹni náà, òun ni Mùdírù Mọ́ríkáàsì n báwí nítorí àwọn Àfàá àgbà méjéèjì ti ní ìkùnsínú ọjọ́ pípẹ́. Kìí ṣèní-kìí-ṣàná ni àwọn méjéèjì ti ní gbọ́mi-sómi-omi-ò-tó àti ìjà fàákája àjàkúakátá tí wọn kò rí i parí rẹ́ fún wọn.
Mùdírù Mọ́ríkáàsì ní MUFTI ILORIN ti ní òun sínú tipẹ́tipẹ́ kí bàbá òun, Ṣéù àgbà nílẹ̀ yìí, ADAM AL-ILORY tó dolóògbé, kí ló fàá? Bàbá Ṣéù ADAM kọ̀ láti fi orúkọ bàbá MUFTI ILORIN sínú àkójọpọ̀ tó kọ nígbà ayé rẹ̀ lásìkò tó n ṣàkójọ àwọn lóókọ-lóókọ, àwọn fọ́nyánmu kẹ́rù -ó-bẹ̀kọ nínú ìmọ̀ kéú nígbà náà. Mùdírù Mọ́ríkáàsì wí pé ‘ta ni mo n bá fàá? Èwo làbùrọ̀ sọ pé bàbá mi ṣẹ òun? Ó ní mi lórí-láyà láti ṣàkójọ àwọn Oníkéú nílẹ̀ yìí sínú tírà rẹ̀ tó kọ ṣùgbọ́n ó kọ̀ láti fi orúkọ bàbá MUFTI sínú rẹ̀. HABBEBLLAI ADAM tún tẹ́ pẹpẹ ọ̀rọ̀ pé MUFTI gan an kọ́ ni oyè Oníkíjìpá tọ́ sí, Ta tilẹ̀ ni bàbá rẹ̀ nílẹ̀ yìí? ta ló mọ òkòlò rẹ̀ l’Ọ́yọ̀? Bàbá rẹ̀ kìí kúkú ṣe ọmọ agboolé Oníkíjìpá tààràtà, ẹni tí oyè náà tọ́ sí ló n gbé inú agboolé, Àfáà ÀLÀBÍ ONÍKÍJÌPÁ làwa mọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹni tóyè náà tọ́ sí. Ṣéù HABEEBLLAI ADAM AL-ILORY ní ìpìlẹ̀ṣẹ̀ àìsàn òun bẹ́rẹ̀ ní gẹ́ẹ́rẹ́ tí òun ṣalábápàdé MUFTI ILORIN SULAIMON FAROOK lẹ́ẹ̀mejì ní òde ìgbéyàwó ní ìpínlẹ̀ Kúwárà tí ọmọ kéú FAROOK fi aṣọ ìnujú pélébé kan nù ún lójú, ó sì fún FAROOK SULAIMON. Ẹ̀kẹ̀ẹjì ni ìgbà tí wọ́n n retí Gómìnà, ọmọ kéú rẹ̀ tún fi aṣọ ìnujú nu ẹ̀yìn ọrùn rẹ̀, FAROOK tún gbàá lọ́wọ́ rẹ̀. Oṣù kejì lẹ́yìn náà ni mo bẹ̀rẹ̀ àìsàn. Bí a ti pàdé lóde aláàfáà, n kò le è fọhùn, bọ̀ọ̀ọ̀ ni mò n wò, èyí ọ̀rọ̀, n kò le è sọ mọ́, òjijì ni nnkan náà dé sími. MUFTI ti n bẹ lórí ìjókòó ki n tó dé, ó n dibọ́n pé ṣe ló n kími, lẹ́ẹ̀kan náà ló da nnkan sílẹ̀ ni mo bá fẹ́ yọ̀ ṣubú, ọpẹ́lọpẹ́ tó sáré dù mí, ibẹ̀ ni mo gbà dé ilé ìwòsàn jẹ́nẹ́rà ìlọ̀rin. Lẹ́yẹ ò sọkà, MUFTI jù àdó méjì sínú àpò mi, ó ní ìdira ló wà fún, MUFTI ní kí àwọn ọmọ kéú rẹ̀ tètè lọ yọ ọ́, ó ní òun gbọ́dọ̀ tètè ṣe sààárà ẹran fún àdó náà.
Ìjà àjàkúakátá náà gbilẹ̀ láàrín àwọn ẹni Ọlọ́run méjéèjì yìí, ojoojúmọ́ ló n lé kenkà sí i pàápàá bí ọba SULU GAMBARI tún fi Ṣéù FAROOK jẹ oyè tuntun, MUFTI ILORIN; oyè tó lààmì-laka nínú ẹ̀sìn ìsìláàmù bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ìlú Ìlọrin ni Mùdírù àti MUfti, àfi kí Álà dáwọ́ ibi dúró nílẹ̀ yìí, Kó báwa pa iná adébọ rẹ́, Kó gbé súnà Ànọ́bì ga, Kó jọ̀ọ́ tún àwọn Adarí ẹ̀sìn wa ṣé.
Ṣéù àgbà fún ìjọ FATHIU QUAREEB, SULAIMON ADANGBA náà jẹ́ ọ̀kan lára Àfàá tí Álà gbà fún nílẹ̀ yìí, gbogbo ìgbà ni ó máa n fààyè sílẹ̀ láti bá àwọn Akọ̀ròyìn wa sọ̀rọ̀ lórí oun tó n ṣẹlẹ̀ nínú ẹ̀sìn Ìsìláàmù pàápàá lásìkò oṣù Ràmàdáànù yìí. Àgbà Lèmọ́mù ni Ṣéù ADANGBA ní ìpínlẹ̀ Èkó, ọmọ ìlú Ìlọrin ní i ṣe, àgbà ọ̀jẹ̀ nínú kéú, ilé kéú Mọ́ríkáàsì ló ti jáde lọ́dún 1985, ó ṣiṣẹ́ olùkọ́ níbẹ̀ títí di ọdún 1999, ADANGBA tún kàwé gboyè ni Massachuset, Harvard University láti ọdún 2016, Amúgbálẹ́gbàá Ṣéù ABDULLAI ADAM AL-ILORY ní i ṣe títí di ìgbà tí bàbá fi wọ káà ilẹ̀ lọ. Ṣéù IBRAHIM ADNGBA n gba gbogbo Mùsùlùmí òdodo nímọ̀ràn láti lo ọjọ́ mẹ́wàá tó gbẹ̀yìn oṣù àwẹ̀ Rámàdáànù yìí dáradára láti fi jírẹ̀bà fún Álà, Oṣù ọ̀wọ̀ àti oṣù àpọ́nlé tó n fún ara ní ìlera rèé, àwẹ̀ n ṣàdínkù ọ̀rá ara, o n túbọ̀ jẹ́ kí a súnmọ́ Álà, àlàáfíà yóò sì jọba ní orílẹ̀ èdè wa nígbà tí àwa gan an bá wà ní àlàáfíà. Ṣéù ADANGBA wí pé ‘Ànọ́bì ní kí a wá ọjọ́ mẹ́wàá ìgbẹ̀yìn oṣù Ràmàdáànù sí òòru ọjọ́ kọkànlélógún, karùndínlọ́gbọ̀n, kẹtàdínlọ́gbọ́n, kọkàndínlọ́gbọ̀n kí a lè ṣalábàpàdé òòru kádàrá, kí a bẹ ÁLÀ lóṣù yìí nípa kíka ìwé mímọ́ àlùkùránì, Álà yóò sì tẹ́wọ́ gba gbogbo iṣẹ́ olóore wa, Yóò sì san wá ní ẹ̀san ayé àti ọ̀run.
Discussion about this post