Ilé-iṣẹ́ Ààrẹ́ ti ta ko àhesọ ọ̀rọ̀ táwọn kan ń gbé káàkiri pé ijọba pàjáwìrì tóun gbé kalẹ̀ ní Ìpínlẹ̀ Rivers ní ọwọ́ kan òṣèlú nínú o. Wọ́n ní agbára òṣèlú ló ń gun ìjọba Tinubu tó fi yọ ọwọ́ kílàńkó Siminalayi Fubara kúrò nínú àwo iyán ìṣèjoba gẹ́gẹ́ bí Gómìnà ìpínlẹ̀ náà. Àmọ́ ilé-iṣẹ́ Ààrẹ́ ti fèsì pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ rárá.
Ilé-iṣẹ́ Ààrẹ ní ìgbésẹ́ náà wáyé láti má jẹ̀ẹ́ kí ètò ìṣèjoba ipinlẹ̀ Rivers di èyí tí a ń fi ipá àti rògbòdìyàn ṣe. Wọ́n ní àwọn kò leè la ojú wọn sílẹ̀, kí tàlùbọ̀ yí wọ̀ ọ́; pé bí nǹkan ṣe ń lọ nípìn-ínlẹ̀ náà ti ń bùáyà, ó ti ń kọjá ibi a fọ̀rọ̀ sí. Wọ́n ní àwọn ò sì lè fọwọ́ lẹ́rán kí gbogbo rẹ̀ yí wọn nípọn dè tán káwọn tóó gbé ìgbésẹ̀. Wọ́n ní Òjó ń rọ̀ ẹ ní kò tó tàná, ṣé ó ti dá ni? Wọ́n ní ìbẹ̀rẹ̀ ogun là á rí, ẹnìkan ò lè mọ òpin rẹ̀.
Nínú àlàyé tí Sunday Onanuga tí í ṣe olùdámọ̀ràn pàtàkì fún Ààrẹ́ fi léde ni ọjọ́ kẹtàlélogun, oṣù kẹta ọdún 2025, ó ní Ààrẹ ò leè bu ẹ̀ẹ̀kẹ́ diwọ́ títí tí gbogbo rẹ̀ yóò fi bú rẹ́kẹ́, tí yóò di iṣu atayán-anyàn-an kalẹ̀ kí ìjọba tóó ṣẹ̀ṣẹ̀ ta gìrì máa șá kíjokíjo kiri lórí àtipaná ọ̀tẹ̀. Wọ́n ní gbogbo rògbòdìyàn tó lalẹ̀ hù ní Rivers, wọ́n ní Fubara àti àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ Așòfin Ìpínlẹ̀ Rivers ni eku ẹdá ; tí wọ́n ń lọ́ ipò agbára mọ́ ara wọn lọ́wọ́. Wọ́n ní ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sì ti sọ ètò ìṣèjoba àdúgbò náà di akúrẹtẹ̀ kalẹ̀ gbáà.
Wọ́n ṣàlàyé síwájú sí i pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àlàkalẹ̀ ìdájọ́ ilé-ẹjọ́ tó ga jù nílẹ̀ yìí ti lako ìparí ọ̀rọ̀, síbẹ̀ àwọn tó ń bá ara wọn ta kàngbọ̀n lórí ọ̀rọ̀ yìí kò jẹ́ kógún ó mí o. Wọ́n sì ní àìfàgbà fẹ́nìkan ni kì í jẹ́ káyé ó gún. ‘ Èmi ò jù ọ́, ìwọ ò jù mí’ tí àwọn ikọ̀ méjèèjì ń bá ara wọn ṣe túbọ̀ ń jẹ́ kí wàhálà náà pọ̀ sí i lójoojumọ́ ni.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Ààrẹ́ sọ, wọ́n ní àwọn jàǹdùkú àti àwọn ajìjà-gbara ìpínlẹ̀ náà ti ń dún ìkookò pé àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í fọ́ gbogbo ọ̀pá epo káàkiri ẹsẹ̀ odò báyìí. Wọ́n ní èyí sì lè ní ipa burúkú lórí ètò ọrọ̀ ajé ilẹ̀ yìí lápapọ̀ báwọn ò bá tètè pinwọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Fún ìgbà díẹ̀ títí tí nǹkan yóò fi rọlẹ̀ ni ìgbésẹ̀ náà wà fún, kì í ṣe pé àwọn lé Gómìnà àti àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ lùgbẹ́ pátápátá o!
GÓMÌNÀ SIMINALAYI FUBARA FÈSÌ SÍ Ẹ̀SÙN TÍ A FI KÀN ÁN.
Fubara fèsì sí àwọn ẹ̀sùn oníkókó rẹpẹtẹ bíi iyán kókò tí a fi kàn án. Ó wí òun kò ní ìbáṣepọ̀ kankan pẹ̀lú àwọn jàǹdùkú tó ń fọ́ ọ̀pá epo káàkiri ìlú náà. Gómínà tí a dá dúró náà sọ láti inú àtẹ̀jáde tí akọ̀wé rẹ̀; Nelson Chukwudi gbé jáde pé òun kò lọ́wọ́ sí tàbí mọ ohunkóhun nípa bí àwọn jàǹdùkú ṣe ń fọ́ ọ̀pá epo. Ó wí pé ẹ̀sùn tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ ni kí àwọn ọlọ́pàá ó ṣe ìwádìí wọn dáadáa.
Nínú àtẹ̀jáde náà la ti rí i kà pé gbogbo àwọn fọ́nrán tí wọ́n gbé jáde náà níbi tí wọ́n ti fọ́ ọ̀pá epo ló jẹ́ ayédèrú. Fubara wí pé àwọn ará agbègbè náà fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ní agbègbè wọn.
Siminalayi Fubara sọ gbangba gbàǹgbà pé òun k̀ò lọ́wọ́ tàbí mọ ohunkóhun nípa ẹ̀sùn tí ìjọba àpapọ̀ fi kan òun nípa àwọn tí wọ́n ń fọ́ àgbá epo, ó wí pé kí ìjọba ó ṣe ìwádìí rẹ̀ fínní.
Ibi ọ̀rọ̀ ti gùn wá
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ló kéde ìpínlẹ̀ Rivers ní ìpínlẹ̀ pàjáwìrì lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun. Oṣù mẹ́fà ni ààrẹ wí pé kí Gómìnà Similayi Fubara ó lọ lò nílé pẹ̀lú igbákejì rẹ̀; Ngozi Odu àti gbogbo àwọn tí wọ́n dìbò yàn nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà.
Ààrẹ sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìgbésẹ̀ yìí pọn dandan láti mú kí gbogbo hílàhílo tó ń ṣẹlẹ̀ ní láàrin Gómìnà àti àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ náà ó rodò lọ mumi.
Ìlú kò le wa kò má ní olórí, nígbà tí Siminalayi Fubara ó máa fitan ewúrẹ́ jiyan jẹkà pẹ̀lú àwọn ebi rẹ̀ lágbàlá rẹ̀, Ibot-Ette Ibas ni ààrẹ yàn láti máa delé dè é. Ajagunfẹ̀yìntì ni Ibas, òun ni yóò máa ṣe àkóso ìpínlẹ̀ Rivers fún oṣù mẹ́fà náà.
Ní kété tí Ààrẹ Tinubú kéde ìjọba pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Rivers ni Gómìnà ìpínlẹ̀ náà gbé e bẹ́, tó sì di àwátì àfi ìgbà tí a ríi lọ́jọ́ Àìkù tó lọ yìí nílé ìjọsìn Salvation tó wà ní Portharcourt.
Ní gẹ́rẹ́ tí ìjọba Gómìnà Siminalayi Fubara bẹ̀rẹ̀ ní Rivers ni òun pẹ̀lú Nyesom Wike Ọ̀gá rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ìforí-gbárí, tí nǹkan ò sì fara rọ nítorí fànfà tó wà láàárín Fubara àti Wike tó jẹ́ Mínístà fún Olú ìlú ilẹ̀ yìí tó wà ní Àbújá. Fànfà náà tí ń lọ sí ibi tí àgbá tí fẹ́ẹ́ bú; tí kugú fẹ́ẹ́ bẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
Ìgbésẹ̀ ìjọba pàjáwìrì yìí ni Tinubú kéde, èyí tí ó ti fòpin sí ìṣèjọba Gómìnà Fubara; ìjókòó àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ Așòfin àti àwọn alákòóso ijoba rẹ̀ gbogbo. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ fi yé wa pé ìpàdé ni gomina Fubara ń ṣe lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn àlejò kan nígbà tí ìkéde náà dé bá a. Kíá náà ni Fubara ṣe páá-pàà-páá, tó fòpin sí ìpàdé náà, tó sì fi ilé ijoba sílẹ̀ láìsọ pàtó ibi tó forí lé. Òun àti àwọn abẹ́sinkáwọ́ rẹ̀ ló sì jọ kọ́wọ̀ọ́ rìn jáde.
Ní kété tí wọ́n kéde ètò ìṣèjọba pàjáwìrì náà ni a rí í tí wọ́n yára pààrọ̀ gbogbo àwọn Ẹ̀ṣọ́ aláàbò tó wà nílè ìjọba ; a ò sì tí ì mọ awọn tó pàṣẹ irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀. A sì tún gbọ́ ọ pé àwọn òṣìṣẹ́ EFCC tí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí lọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ijoba kọ̀ọ̀kan lórí gbogbo fànfà tó gba ètò ìjọba Fubara náà. Gbogbo nǹkan ló gbóná janjan báyìí ní Ìpínlẹ̀ Rivers kò fara rọ rárá.
Kàkà kó dẹ̀ lára ewé àgbọn, kankan ló ń le síi lọ̀rọ̀ ìpínlẹ̀ Rivers, ó wá jọ pé ìjọba ológun náà gan-an ni kò ní jẹ́ kó yanjú bọ̀rọ̀.
Discussion about this post