Bí wọ́n bá léni níbìkan, ibikan náà ni èèyàn á kọrí sí. Mudashiru Obasa ń kojú àwọn àdojúkọ kan tó nípọn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó wà ní èyí tí igbó ti dá sí méjì lórí rẹ̀, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti Labour ké sí i kó wá dara pọ̀ mọ́ wọn.
Ọ̀rọ̀ ìyọnípò Obasa nípò agbẹnusọ àti àwọn ẹ̀sùn ìkówójẹ tí wọ́n fi kàn án, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti pín sí méjì, nígbà tí àwọn kan ṣègbè fún Obasa, àwọn mìíràn gbè lẹ́yìn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó.
Àwọn àgbà ọ̀jẹ̀ méjì; aṣòfin Anthony Adefuye àti olóyè Muraina Taiwo bu ẹnu àtẹ́ lu ìyọnípò Obasa pé kò tọ ọ̀nà òfin àti pé àwọn aṣòfin náà dìtẹ̀ mọ́ ọn ni. Olóyè Muraina Taiwo wí pé ìyọnípò Obasa yìí ti pín ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó sí méjì, ó bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ náà ó sì fẹnu kò lórí pé olórí àwọn ìyẹn ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ni yóò pa iná ọ̀rọ̀ náà.
Musiliu Obanikoro lòdì sí ọ̀rọ̀ àwọn aṣòfin méjèèjì yìí, ó wí pé àgbà ajá wọn ba awọ ẹranko jẹ́. Obanikoro bá àwọn àgbà méjì yìí wí pé kí wọn ó yàgò fún dídá kún ohun tó ti wà nílẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà.
Ohun tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó ń fẹ́ ni kí Obasa ó wá sí ilé ìgbìmọ̀ kó wá fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bí òun jẹ̀bi àbí kò jẹ̀bi, kàkà tí Obasa ó fi lọ iwájú ilé, ohùn ló ń fi ránṣẹ́ láti ilé rẹ̀.
Bí èyí ṣe ń lọ lábélẹ̀ ni ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sọ láti ẹnu igbákejì alága ìpínlẹ̀ Èkó; Benedict Tai pé bí ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò bá gbe Obasa mọ́, ààyè wà fún un nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Benedict wí pé bí Obasa bá dara pọ̀ mọ́ àwọn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, àwọn yóò ṣe gbogbo ètò tó bá yẹ àwọn yóò sì fi sí ipò tó bá tọ́ síi nínú ẹgbẹ́ náà.
Bákan náà ni Benedict wí pé àwọn yóò ṣe ọ̀fintótó láti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Obasa kò ní wá da ẹgbẹ́ náà rú bí àwọn kan ṣe ṣe sẹ́yìn.
Ẹgbẹ́ òṣèlú Labour náà kò ṣàì ganu sí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí, wọ́n ní kó máa bọ̀ pé ọmọ ọ̀lẹ nìkan lààyè ò gbà.
Alága ẹgbẹ́ òṣèlú Labour ìpínlẹ̀ Èkó; Pásítọ̀ Dayo Ekong ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ pé bí Obasa bá le dara pọ̀ mọ́ àwọn, ipò tó bá tọ́ síi ni yóò wà níwọ̀n ìgbà tó bá ti le pa òfin ẹgbẹ́ mọ́.
Àwọn akọ̀ròyìn bi pásítọ̀ Dayo pé ṣé bí Obasa bá dara pọ̀, yóò gba ìwé ìdíjedupò Gómìnà Èkó?
Pásítọ̀ Dayo fèsì pé òun kò ṣe ìlérí ìwé ìdíjedupò Gómìnà Èkó fún Obasa nítorí pé àwọn èèyàn kan ló wà nílẹ̀ kó tó dé àmọ́ bó bá dójú ṣúṣú, fùrọ̀ á là.
Gbogbo ọ̀rọ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ bí eré bí àwàdà nígbà tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó yọ agbẹnusọ wọn ìyẹn Mudashiru Obasa nípò fàì bí ẹni yọ jìgá. Oríṣìí itú ni wọ́n ti pa láti ìgbà náà.
Obasa wí pé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ń ṣàwàdà ni pé wọn kò le yọ òun nípò bíi báun, ó ní òun ṣì ni agbẹnusọ pé aṣọ tí ìpìn bá bọ́ sílẹ̀, kò sí ẹranko tó le gbé e wọ̀. Ṣé lóòótọ́ ni pé àtàrí àjànàkú ni ipò agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó kìí ṣe ẹrù ọmọdé?
Ilé aṣòfin Èkó fèsì sí ọ̀rọ̀ tí Obasa sọ yìí, wọ́n ṣe àlàyé ipò tí ìyọnípò Obasa wà báyìí àti àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.
Ọ̀rọ̀ yìí jáde láti ẹnu Olukayode Ogundipe pé àwọn tẹ̀lé àlàkalẹ̀ òfin nínú ìyọnípò rẹ̀ pé àwáwí lásán ni Obasa ń sọ pé wọn kò tẹ̀lé òfin.
Èkejì ni pé Obasa kò wá síbi ìpàde tó wáyé g lórí ìyọnípò rẹ̀. Ogundipe wí pé ó yẹ kí ó wá sí ìpàdé náà kó mójú ajé kònísọ̀ àmọ́ ó kọ̀ kò yọjú.
Yàtọ̀ sí pé Obasa tó lọ̀rọ̀ kò wá sí ìpàdé, ìdí tí ìpàdé lórí ìyọnípò rẹ̀ kò fi wáyé ni pé arábìnrin Meranda ṣẹ̀ṣẹ̀ wọṣẹ́ bíi agbẹnusọ náà ni nítorí náà, àwọn ohun mìíràn tó ṣe pàtàkì ló mójútó.
Kò tán síbẹ̀ o, ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin wí pé kékeré ni ẹ̀sùn owó géètì àti owó ọkọ̀ bọ̀gìnnì tí àwọn fi kan Obasa o, wọ́n ní àwọn ẹ̀sùn míìràn tó wà nílẹ̀ tó jẹ mọ́ owó rọ̀gùnrọ́gún wà nílẹ̀ tó sì jẹ́ pé òun ni ajé rẹ̀ ṣí mọ́ lórí. Ilé aṣòfin wí pé bí Obasa bá ti wá sí ìpàdé, àwọn yóò tẹ́ pẹpẹ àwọn ẹ̀sùn rẹ̀ fún un.
Àwọn akọ̀ròyìn bi Ogundipe léèrè bí wọn yóò bá pe àjọ EFCC sí ọ̀rọ̀ náà, Èsì tó fọ̀ náà ni pé lẹ́yìn tí àwọn àgbà aṣòfin bá gbé àwọn ẹ̀sùn náà wò, wọn yóò mọ̀ bí wọn yóò pe EFCC tàbí wọn kò ní pè é.
Ohun tí Obasa ń jẹ lẹ́nu ni pé òun kò sí nílé lásìkò tí wọ́n yọ òun ní èyí tó lòdì sí òfin.
Àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ péjú sí ilé rẹ̀ ìyẹn ilé agbẹnusọ Èkó ní Ikeja lọ́jọ́ Sátidé náà, òun tó wí ni pé òun ṣì ni agbẹnusọ ilé aṣòfin lábẹ́ òfin o, bí wọn ó bá tilẹ̀ yọ òun nípò, wọ́n gbọdọ̀ ti ẹsẹ̀ òfin bọ̀ ọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwàdà lásán ni wọ́n ń ṣe.
Obasa wí pé lábẹ́ òfin, dandan ni kí òun ó wà lórí ìjokòó bí wọ́n bá fẹ́ yọ òun nípò àbí ojú àwo ṣá ni àwo fi ń gba ọbẹ̀, ẹnìkan kìí sì fárí lẹ́yìn olórí, ó ṣe jẹ́ ìgbà tí òun lọ ìrìn àjò ni wọ́n yọ òun? Kò le ṣe é ṣe o.
Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé àwọn ẹ̀sùn tí ilé aṣòfin fi kan òun kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ rárá, òfûtùfẹ́tẹ̀ ásà tí ò ní káún nínú ni. Wọ́n ní òun fi bílíọ̀nù mérìndínlógún ṣe géètì, Obasa wí pé ṣé géètì Jẹ́ríkò ni géètì náà ni?
Wọ́n tún ní òun fi ogójì bílíọ̀nù ra ọkọ̀ bọ̀gìnnì, Obasa wí pé kí ẹ má dá wọn lóhùn o, àwáwí ni wọ́n ń wá kiri.
Ní báyìí rí ẹgbẹ́ òṣèlú méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ti ké sí Obasa, èwo lẹ rò pé yóò dara pọ̀ mọ́?