Mínísítà fún ètò ààbò ilẹ̀ yìí, Bello Matawalle ti ṣe àlàyé bí ìjọba Tinubu kò ṣe fi ààyè gba àwọn agbésùnmọ̀mí lásìkò tirẹ̀ tó ṣe pé ó dojú ìjà gidi kọ wọ́n ni, Matawalle wí pé igba mẹ́rin ni àwọn agbésùnmọ̀mí tí àwọn ti pa lásìkò ìṣejọba Tinubu yìí.
Ó ṣe àlàyé pé àwọn agbékalẹ̀ titun tí ìṣejọba Tinubu gbé kalẹ̀ ni àwọn fi ń kojú àwọn agbésùnmọ̀mí tí àwọn sì ń mú wọn balẹ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé ìṣọwọ́ gbógun ti àwọn agbésùnmọ̀mí yìí tó ìdí tí a fi gbọdọ̀ dìbò yan ààrẹ Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027 kí ó le bá àwọn agbésùnmọ̀mí náà kanlẹ̀ pátápátá.
Mínísítà fún ètò ààbò wa wí pé àwọn ti ṣe àgbékalẹ̀ ikọ̀ tí ó ń gbógun ti àwọn ajínigbé tí wọ́n ń fi imú wọn danrin ní èyí tó mú kí ìjínigbé ó di ohun ìgbàgbé báyìí. Bákan náà ni ó wí pé àwọn àlàkalẹ̀ ààrẹ Tinubu lórí ètò ààbò yẹ ní ohun tí ó yẹ kó gba oríyìn fún nítorí pé yàtọ̀ sí àwọn agbésùnmọ̀mí ẹgbẹ̀rin tí àwọn ti pa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ìjà olóró ni àwọn ti rí gbà padà lọ́wọ́ wọn.
Matawalle gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé kí ẹ̀yin ọmọ Nàìjíríà ó dìbò yan Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027 kí ó le tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ rere.
Ní ìpínlẹ̀ Bayelsa.
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Bobos ti ṣekú pa olórí wọn; Olotu Omubo nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ipò náà.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bayelsa pé àwọn ọmọlẹ́yìn Olotu Omubo náà ni wọ́n pa á nítorí pé wọ́n fẹ́ fi èèyàn tiwọn sí ipò náà ní ẹni tí wọ́n lérò pé àsìkò rẹ̀ yóò san àwọn.
Ìdílé Nembe ni Omubo ti jáde wá, òpópónà Goodnews ní Azikoro, Yenagoa ni wọ́n pa á sí lọ́jọ́bọ, ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Igbe tó lọ yìí. Ìṣọ́wọ́paá nípakúpa tí wọ́n pa á kalẹ̀ ló tọ́ka sí pé iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni.
Bákan náà ni àwọn èèyàn rò o pé o ṣeéṣe kó jẹ́ àwọn ikọ̀ mìíràn ló pa á ní ìránró àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn tó ti pa.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé ìjà abẹ́nú wà nínú ẹgbẹ́ Bobos tí Omubo jẹ́ olórí wọn, wọ́n ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ ló pa á lọ́nà tí yóò fi dàbí pé àwọn ikọ̀ mìíràn ni ó ṣekú pa á. Wọ́n ní ìdí ni pé wọ́n kò fẹ́ Omubo ní olórí wọn mọ́.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe àfikún pé oríṣìí ẹ̀sùn ni Omubo ní nílẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀
Èyí tó tún bani lọ́kàn jẹ́ bí èyí ni ìròyìn nípa àwọn tí wọ́n sin ọmọ relé ọkọ tí wọn kò sì padà délé, kìí kúkú ṣe pé wọ́n jókòó tìí lọ́hùn-ún, ìjàmbá ọkọ̀ ni kò jẹ́ kí wọn ó padà wọ inú ilé wọn. Èèyàn márùn-ún ló gbẹ́mìí mìn nínú ìjàmbá náà.
Ìròyìn náà kà báyìí pé Ìyàwó ọ̀sìngín ni àwọn èèyàn náà gbé lọ sí ilé ọkọ rẹ̀ ní Bauchi kí ó tó di pé ọkọ̀ wọn dànù nígbà tó kù díẹ̀ kí wọn ó dé ilé. Èèyàn márùn-ún ló pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí àwọn yòókù farapa.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kano, Abba Yusuf fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ṣọwọ́ sí àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn pé òun kí wọn kú arafẹ́rakù.
Ohun tó burú jù nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni pé ẹbí kan náà ni àwọn márùn-ún tí wọ́n kú náà; Alhaji Soraju àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjì pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹ́ta tí gbogbo wọn sì jẹ́ ẹbí ìyàwó titun náà.
Gómìnà Yusuf kí ẹbí Soraju kú àtẹ̀mọ́ra, ó ní òun yóò máa fi àdúrà ràn wọ́n lọ́wọ́ lásìkò àfẹ́kù yìí
Ní ìpínlẹ̀ Nasarawa
Ọkọ̀ kan tí ọ̀gbẹ́ni Abu Agyeme ti patì sínú ọgbà rẹ̀ ni àwọn ọmọdé márùn-ún kan kú sínú rẹ̀, ohun tí àwọn ọlọ́pàá rí dìmú ni pé bóyá wọ́n ń ṣeré nínú ọkọ̀ náà ni ó tì pa mọ́ wọn nítorí pé àyẹ̀wò dọ́kítà fi hàn pé ooru ló pa wọ́n.
Agbègbè Agyaragu ní ìjọba ìbílẹ̀ Obi ní ìpínlẹ̀ Nasarawa ni èyí ti ṣẹlẹ̀. Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Nasarawa; Rahman Nansel ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ láàárọ̀ yìí pé àwọn gba ìpé nípa ikú àwọn ọmọdé márùn-ún tí ọjọ́ orí wọn kò ju ọdún márùn-ún sí mẹ́wàá lọ.
Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n ṣe aájò wọn dé ilé ìwòsàn Aro níbi tí dọ́kítà ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ooru ló ṣekú pa àwọn ọmọ náà.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Nasarawa; Shetima Jauro-Mohammed ti pàṣẹ kí ìwádìí ìjìnlẹ̀ ó wáyé lórí ikú àwọn ọmọ náà.
Kọmíṣọ́nà bá àwọn òbí àwọn ọmọ náà kẹ́dùn, ó kí wọn kú àmúmọ́ra.
Ní kété tí dọ́kítà parí àyẹ̀wò ni wọ́n yọ̀ǹda òkú wọn fún àwọn òbí wọn nítorí pé ara wọn ti sè.
Àwọn ọlọ́pàá tún gbé ìṣe wọn dé o.
Nínú fọ́nrán kan tó gba orí ìtàkùn ayélujára kan ni a ti rí àwọn ọlọ́pàá ilẹ̀ wa tí wọ́n ki ọ̀dọ́mọkùnrin kan mọ́lẹ̀ tí wọ́n sì ṣe é bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú.
Ẹnìkan tí ojú òpó rẹ̀ ń jẹ́ General_Somto ló fi fọ́nrán yìí sí orí ìtàkùn ayélujára, nínú rẹ̀ ni a ti rí àwọn ọlọ́pàá méjì kan pẹ̀lú aṣọ lọ́rùn tí wọ́n ń lu ọ̀dọ́mọkùnrin náà tí wọ́n sì ń gbá ìdí ìbọn mọ́ ọn lórí.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti fèsì sí fọ́nrán yìí pé kí General_Somto ó fi ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tis ̣ẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn kí ó le ran ìwádìí àwọn lọ́wọ́.
A kò tíì le ṣe ìdámọ̀ àwọn ọlọ́pàá inú fọ́nrán náà lásìkò yìí
Discussion about this post