Àwọn àgbà olóṣèlú ti kóra jọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC pẹ̀lú èròǹgbà àti gba ipò ààrẹ orílẹ̀-ède yìí kúrò lọ́wọ́ Asíwájú Bola Ahmed Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027.
Ọjọ́rú, ọjọ́ kejì, oṣù Agẹmọ ni ìpàdé náà wáyé níbi tí àwọn àgbààgbà òṣèlú ilẹ̀ yìí ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC. Yar’Adua Centre tó wà ní Abuja ni ìpàdé náà ti wáyé.
Lára àwọn tí wọ́n darapọ̀ náà ni igbákejì ààrẹ̀ ilẹ̀ yìí nígbà kan rí, ẹni tó ti díje du ipò ààrẹ lọ́pọ̀ ìgbà àmọ́ tó ń fìdí rẹmi; Atiku Abubakar, a rí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ìjẹta; Rauf Aregbesola, bákan náà ni Peter Obi; ẹni tó jẹ́ olùdíje sipò ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Labour náà kò gbẹ́yìn.
Ọ̀pọ̀ àwọn olóṣèlú mìíràn náà ni wọ́n darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ADC lánàá yìí.
David Mark ni wọ́n fi ṣe alága gbogbogbò nígbà tí wọ́n fi Rauf Aregbesola jẹ akọ̀wé àgbà.
Níbi ìpàdé náà ni wọ́n ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn yóò díje du ipò ààrẹ àti gbogbo ipò yòókù ní o.dún 2027 tí àwọn yóò fi gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ Tinubu.
Ìgbésẹ̀ yìí kò dùn mọ́ àwọn kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ oṣèlú ADC láti ìpìlẹ̀ nínú, wọ́n ní àwọn tó wá darapọ̀ náà tí wọ́n sì gba ìṣàkóso ẹgbẹ́ náà kò lérò rere sí Nàìjíríà, wọ́n ní nígbà tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú tí wọ́n ti yapa, alátakò ni wọ́n jẹ́ sí ADC, nítorí ipò tí wọ́n ń wá ni wọ́n ṣe di ọmọ ẹgbe.́ òṣèlù ADC ọ̀sán gangan.
Dumebi Kachikwu; ẹni tó jẹ́ olùdíje sípò ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú ADC lọ́dún 2023 ló sọ ọ̀rọ̀ yìí. Dumebi wí pé wọn kò ní àfojúsùn àti ìwòye adarí ìlú, àpò wọn ló jẹ wọ́n lógún.
Bákan náà ni ẹgbẹ́ òṣèlú PDP fèsì sí ìṣípòpadà yìí, adélé alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP; Umar Damagum ló sọ wí pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP wà ní digbí, mìmì kan kò mì ín, kí àwọn èèyàn ó yé bu ẹnu àtẹ́ lu ẹgbẹ́ náà pàápàpá àwọn tó lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlù ADC.
Ìdarapọ̀ yìí kọjá pé wọ́n darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú lásán, wọ́n ní àwọn yóò yó Tinubu nípò nípa jíjáwé olúborí nínú ìdìbò ọdún 2027.
Ní èsì sí èyí, ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń lògbà lọ́wọ́ APC sọ̀rọ̀, wọ́n ní àwọn tí wọ́n ti pẹ́ nínú òṣèlú láìṣe àṣeyọrí kankan ni wọ́n ń kóra wọn jọ pètepèrò àti wọlé ìdìbò ọdun 2027. APC wí pé àwọn olóṣèlú yìí kò ṣetán àti fẹ̀yìntì ló fa gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe yìí.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC wí pé àwàdà lásán ni wọ́n ń ṣe nítorí pé wọn kò le wọ ibi kankan ju yàrá wọn lọ lọ́dún 2027. Kódà, wọ́n wí pé ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀ lásán lọ̀rọ̀ wọn.
Olùdíje dupò ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú Labour lọ́dún 2023; Peter Obi ti sọ̀rọ̀ lórí dídarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC. Ó wí pé àwọn ará ìlú ló jẹ ẹgbẹ́ òṣaèlú náà lógún kìí ṣe ti ìmọtara-ẹni-nìkan.
Peter Obi wí pé bí ẹgbẹ́ náa nbá wọlé lọ́dún 2027, Nàìjíríà yóò bọ́ sípò padà.
Ó kọ ọ́ sí ojú òpó rẹ̀ pé ìṣípòpadà náà pọn dandan nígbà tí àwọn jókòó wo ipò tí orílẹ̀-ède Nàìjíríà wà lónìí, bí àwọn kò bá gbé irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àwọn kò nífẹ̀ẹ́ Nàìjíríà ni.
Ṣáájú ìṣípòpadà yìí ni àwọn tí wọ́n ṣe ìpolongo ìbò fún Tinubu ti géka àbámọ̀ jẹ lórí ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán. Lára wọn ni Aminatu Papapa, Alapinni àti Lalude.
Aminatu papapa wí pé:
òun gé ìka àbámọ̀ jẹ lórí ìpolongo tí òun ṣe náà nítorí pé òun kò mọ̀ pé ìnira ni ìṣejọba Tinubu yóò mú bá aráàlú.
Ó wí pé òun gan-an fara gbá nínú ìnira náà nítorí pé ìrẹsì ni òun ń tà, nígbà tí ààrẹ àná; Muhammadu Buhari ti ẹnu ìloro ni òun ṣe wò ó pé Tinubu ni yóò ṣí ẹnu ìloro náà nítorí pé ọmọ Yorùbá ni.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé gbogbo ìrètí òun ló já sófo nítorí pé kò ṣí ẹnu ìloro ní èyí tó mú ìpalára bá òwò ìrẹ̀sì òun.
Yàtọ̀ sí èyí, gbogbo ìlérí tí wọn ṣe fún òun àti àwọn òṣèré ẹgbẹ́ òun, wọn kò mú ọ̀kankan ṣẹ nínú wọn, òfo lórí òfo ni gbogbo rẹ̀ já sí.
Kìí ṣe pé Tinubu kò fún wọn lówó rárá, Aminatu papapa wí pé ìwọnba owó tó jáde láti ọ̀dọ Tinubu, àwọn àgbààgbà òṣèré ni wọ́n há a mọ́wọ́ tí wọ́n sì kọ̀ láti fún àwọn ìsín nínú rẹ̀. Àwíjàre wọn ni pé àwọn ti wà nínú iṣẹ́ náà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún.
Ṣáájú àkókò yìí ní ọdún 2023 ni Aminatu papapa ti fèsì sí fọ́nrán tí Adunni Ade ṣe níbi tó ti bu ẹnu àtẹ́ lu àwọn òṣèré ẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n fi ogójì ọjọ́ ṣe ìpolongo ìbò fún Tinubu lórí ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàdọ́rùn-ún náírà péré.
Èsì tí Aminatu papapa fún Adunni Ade lọ́dún náà ni pé òun kò ṣe ìpolongo ìbò náà nítorí owó bíkòṣe nítorí ìfẹ́ àti ìrèti àmọ́ ní báyìí, ó ní òun kábàámọ̀ pé òun ṣe ìpolongo ìbò náà ó sì bèèrè fún ìdáríjìn ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́ gbogbo ọmọ Nàìjíríà.
Kìí ṣe Bukky Raji ni ẹni àkọ́kọ́ tí yóò sọ irú èyí, Alapinni òòṣà náà ti sọ nǹkan tó jọ mọ́ èyí ní ọ̀sẹ̀ bíi mélòó sẹ́yìn. Ohun tí òun náà sọ ni wí pé òun kábàámọ̀ lórí ìpolongo ìbò tí òun ṣe fún Tinubu.
Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Gbajúgbajà ìlúmọ̀ọ́nká òṣèré ilẹ̀ wa; Ganiu Nafiu tí orúkọ ìtàgé rẹ̀ ń jẹ́ Alápìnni Òòṣà ti tú pẹrẹpẹ́ẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ lórí bí ó ṣe kábàámọ̀ ṣíṣe ègbè lẹ́yìn Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ní ọdún 2015.
Alápìnni wí pé gbogbo àwọn tí àwọn ṣe àtìlẹ́yìn náà àti ìpolongo fún Tinunu lọ́dún náà lérò pé olùgbalà ni ó dé fún wọn tí yóò mú ayé rọrùn àmọ́ idakejì rẹ̀ ló já sí. Ó wí pé àwọn kò tíì rí kọ́bọ̀ owó ìpolongo náà gbà di àsìkò yìí.
Ó wí pé àti Tinubu àti ọmọ rẹ̀ Seyi, kò sí èyí tó rántí àwọn nínú àwọn méjéèjì, odidi oṣù méjì ni àwọn fi kóra jọ ṣe ìpolongo ìbò fún Tinubu, wọ́n wọ inú ọjà, wọ́n dé ojúlé sí ojúlé, Olaiya Igwe tún wẹ̀ lódò níhòòhò, síbẹ̀, Tinubu kò sanjọ́ fún àwọn.
Bákan náà ni ó bu ẹni àtẹ́ lu ohun tí Seyi Tinubu ṣe nípa sísan owó ilé ìwòsàn àwọn aláàárẹ̀ ní Àríwá. Alápìnni wí pé Seyi fi àwọn aláàárẹ̀ ilẹ̀ Yorùbá sílẹ̀ lọ san owó ilé ìwòsàn wọn ní ilẹ̀ Hausa, èyi fi hàn pé Yorùbá ò já mọ́ nǹkan kan níwájú rẹ̀.
Bákan náà lọmọ ṣorí lọ́dọ̀ Lalude, ó ní òn dá ara òun lẹ́bi pé òun ṣe ìpolongo ìbò fún Tinubu lọ́dún 2023.




