Ọ̀gá ọlọ́pàá ti ìpínlẹ̀ AKWA IBOM ní ọwọ́ ti tẹ pásítọ̀ ìjọ REDEEMED CHRISTAIN CHURCH OF GOD (RCCG), ọmọ ọdún méjìlélógójì tí orúkọ rẹ̀ n jẹ́ VICTOR OKOH látàrí bí ó ti ṣá ìyàwó rẹ̀ VICTORIA ẹni ọdún méjìdínlógójì pa pẹ̀lú ẹ̀sùn pé ò n ṣàgbèrè.
Ọjọ́ kẹwàá oṣù yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ tó gbomijé lójú ẹni yìí ṣẹlẹ̀ ní agbègbè EFFIONG ESSANG ní ìjọba ìbílẹ̀ ORON ní ìpínlẹ̀ AKWA IBOM. Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ pasitọ VICTOR OKOH, ó ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá níbi tí wọ́n ti n fi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò láti mọ ohun tó rí lọ́bẹ̀, tó fi waro ọwọ́. Ikú VICTORIA ti dá ọ̀fọ̀ nlá sílẹ̀ ní agbègbè rẹ̀ nítorí ṣe ni tọmọdé tàgbà n kárí bọnú, tí wọ́n dáró, tí wọ́n n kọ hàà!hàà! irú kí lèyí ọmọ Anífowóṣe?
DSP TIMFON JOHN ní báyìí, ẹjọ́ ti dé ọ̀dọ̀ àwọn, ọwọ́ sì ti tẹ ọ̀daràn, ó wà lákàtà wa ṣùgbọ́n òkú VICTORIA wà ní ilé ìgbókù sí ní jẹ́nẹ́ra ọsibítù ìpínlẹ̀ náà. Ní kété tí pasitọ VICTOR OKOH ti ṣiṣẹ́ láabi rẹ̀ tán ló bá lọ fara pamọ́ sábẹ́ òrùlé, ibẹ̀ ni ọwọ́ ti bàá. Àwọn ará àdúgbò ní kìí ṣèní kìí ṣàná ni gbọ́nmi-si-ò-tó ti n wáyé lààrín tọkọ tayà yìí, bí wọ́n ti máa n ṣe ní gbogbo ìgbà nìyí, kò jọwá lójú àmọ́ tọjọ́ yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ nítorí ọ̀rọ̀ ọjọ́ yìí di fàá-kája débi pé pasitọ VICTOR OKOH ti pilẹ̀ ní kí ìyàwó máa lọ ilé àwọn òbí rẹ̀, ó ní òun kò ṣe mọ́. Ṣàdéédé ló tún pèé wọlé padà, a ò mọ bí ọ̀rọ̀ ti padà bẹ́yìn yọ tó fi di pé pasitọ VICTOR fi ṣá VICTORIA pa mọ́ ilé. Ní àkókò yìí, pasitọ VICTOR OKOH tilẹ̀kùn gbọingbọin pa, kò fún àwọn olùlàjà kankan láàyè láti làwọ́n. Gbogbo bí ìyàwó ṣe n kígbe , ‘Ẹ gbà mí oooo, Ó ti fẹ́ pamí oooo, Yééè! a kò le è gbàá sílẹ̀ nítorí kò ṣeéṣe fún wa ni á bá pe aago àwọn ọlọ́pàá kí wọ́n tètè wá dá sí ọ̀rọ̀ náà kó tó bẹ́yìn yọ. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn ọlọ́pàá ti dé, wọ́n sì fi tipàtipá fa ilẹ̀kùn já ní wọ́n bá bá VICTORIA nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ àti àdá tó n kán tóó,tóó,tóó fún ẹ̀jẹ̀ ara rẹ̀.
PPRO,DSP TIMFON JOHN ní kíá! àwọn ọlọ́pàá ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi yìí, abẹ́ òrùlé ni wọ́n ti fa ọkọ ìyàwó yọ níbi tó kájọ sí bí ejò sèbé ni ọwọ́ bá ba aláṣejù rẹ̀. Kọmíṣánnà ọlọ́pàá ti ìpínlẹ̀ AKWA IBOM, CP BABA AZARE ní ìwà láabi gbáà lèyí, PASITO VICTOR OKOH gbọ́dọ̀ fojú ba ilé ẹjọ́. Kọmíṣánnà gba tọkọ tayà níyànjú pé kí wọ́n máa fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ yanjú aáwọ̀ tó bá jẹyọ láàrín wọn ní kíákíá, ìwà ta-n-kú-ta-n-kù kò yẹ ọmọ ènìyàn. Ó ní ọ̀dàran yóò fojú bá ilé ẹjọ́ fún ẹ̀sùn ìpànìyàn tó lódìí sí òfin orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Nàìjíríà lẹ́yìn ìgbà tí àwọn ọlọ́pàá bá parí ìwádìí ti wọn tó n lọ lọ́wọ́-lọ́wọ́.
Bákan náà ní ìjọba ìbílẹ̀ Bende ní ìpínlẹ̀ ABIA, ọ̀gbẹ́ni MADUKA ISAAC ti fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn bí ọmọ rẹ̀ NDUKWE ISAAC, ọmọ ogún ọdún ti ṣàgbákò ikú òjijì lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ àdúgbò wọn níbi tí wọ́n ti fi ìyà jẹ ẹ́ fún olè jíjà àti ìwà alọ́nilọ́wọ́gbà. Ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu ni ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n oṣù kínní ọdún yìí nígbà tí ìbànújẹ́ wọlẹ́ tọ ẹbí ISAAC; Ọ̀gbẹ́ni MADUKA ISAAC tó jẹ́ bàbá ọmọ yìí ní ikú ọmọ yìí ti sọ gbogbo ìdílé rẹ̀ sínú ìbànújẹ́ ayérayé. Bàbá ní bí ọ̀rọ̀ ti lọ rèé :
NDUKWE ISAAC àti ìyá rẹ̀ UWAEZWO ISAAC jọ n gbé papọ̀ ní OKAI BENDE, iṣẹ́ àgbẹ̀ alárojẹ ni wọ́n jọ n ṣe, iṣu àti ìrẹsì ni ìyá àti ọmọ n dáko rẹ̀, kódà, wọ́n rí tajé ṣe nídìí iṣẹ́ yìí tẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀! Kó tó di ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ láabiy yìí, NDUKWE ISAAC bèrè owó lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ láti fi ra aṣọ àti àwọn nnkan pẹ́ẹ́-pẹ̀-pẹ́ tó nílò fúnrarẹ̀ nítorí owó náà fẹ́ máa dán bí àwọn ọ̀dọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀, ìyá ní kò jọọ́, òun kò lówó ni ọmọ bá kúkú lọ yọ owó lẹ́yìn, ó fi ra àṣọ tuntun , rédíò àti àwọn nnkan tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọrin náírà nínú ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ̀fà tó jí lọ́wọ́ ìyá rẹ̀, lọ̀rọ̀ bá di iṣu ata-yán-an-yàn-an làárín àwọn méjéèjì ni àwọn àgbọ̀rọ̀dùn bá bẹ̀rẹ̀ sí da ọmọ ní ìgbájú olóyì, ìnà náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí NDUKWE ISAAC fi gbé ẹ̀mí mì láì fún un láàyè láti ro àwíjàre tirẹ̀, wọ́n nàá bí ẹni máa pa á kó tó dágbére fáyé. MADUKA n rọ àwọn ọlọ́pàá kí ìyá náà má jẹ ọmọ rẹ̀ gbé nítorí kò lẹ́tọ̀ọ́ láti fi ìdájọ́ sọ́wọ́ ẹni àgàgà lábẹ̀ òfin ilẹ̀ wa.
Ìròyìn mìíràn tún ni ti ọkọ tó lu ìyáwó rẹ̀ pa nítorí oúnjẹ ìṣínu àwẹ̀ RAMADAN tó n lọ lọ́wọ́. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ní agbègbè FADAMAM MADA nítòsí GOVT GIRLS COLLEGE ní ìpínlẹ̀ BAUCHI, ALHAJI NURU ISAH , ọmọ àádọ́ta ọdún na ìyàwó rẹ̀ WASILA ABDULLAHI, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún pa lẹ́yìn ìjà àti asọ̀ lórí oúnjẹ àti èso tí wọn yóò fi ṣínu àwẹ̀ RAMADAN tó n lọ lọ́wọ́-lọ́wọ́ yìí. Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú wọn sọ pé ẹgba ni ALHAJI NURU ISAH kó bo ìyàwó rẹ̀ WASILA títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lára rẹ̀. Gbogbo akitiyan láti dóòlà ẹ̀mí rẹ̀ ló jásí pàbo. Kọ́miṣánnà ìpínlẹ̀ BAUCHI, CP AUWAL MUSA MUHAMMED fi da àwọn ẹbí olóògbé pé ‘ẹlẹ́ṣẹ̀ kan kò ní lọ láì jìyà àti pé kò sí ààyè fún ìfìyàjẹni lọ́nà àìtọ́, kí tọkọ tayà máa tètè yanjú aáwọ̀ ní pẹ̀lẹ́ kùtù kó tó búrẹ́kẹ́. Ó ní ALHAJI NURU ISAH wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá báyìí.
Bẹ́ẹ̀ lọmọ sorí ní ìpínlẹ̀ Èkó ní MEIRAN níbi tí Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga ifáfitì LASU, ADIJA ṣe kú sínú iyàrá àfẹ́sọ́nà rẹ lọ́jọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù kejì ọdún yìí lásìkò tí ìjà ṣẹlẹ̀ láàrín àwọn méjéèjì, àfẹ́sọ́nà náà ti na pápá bora , a kò gbúròó rẹ títí di bí a ti n kó ìròyìn yìí jọ, ọ̀rọ̀ rí bákan náà ní ìpínlẹ̀ Ògùn ní agbègbè OGUN WATERSIDE tí Ojú gún ìyàwó rẹ̀, JOSEPHINE ISAAC pa ní aago kan òru ọjọ́ Ẹtì tó kọjá lẹ́yìn ìjà àjàkúakátá. Òwúrọ̀ ọjọ́ kejì ni àbúrò olóògbé tó wá fi ọ̀rọ̀ náà tó ọlọ́pàá létì ṣùgbọ́n ọkọ ti sálọ. Ọ̀gá ọlọ́pàá OMOLOLA ODUNTOLA ní láìpẹ́ ọwọ́ pálábá rẹ̀ yóò sẹ́gi.