Gómìnà ìpínlẹ̀ Akwa Ibom; Umo Eno ti pàṣẹ fún gbogbo àwọn kọmíṣọ́nà rẹ̀ pé kí wọn ó tẹ̀lé òun kálọ inú ẹgbẹ́ òṣèlú APC tàbí kí wọn ó kọ̀wé fipò wọn sílẹ̀.
Níbi ìpàdé tó bá àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ ṣe ní Ọjọ́bọ, ọ̀sẹ̀ yìí ló ti sọ fún gbogbo wọn pé gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti mọ̀ pé òun ti kọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ tí òun sì ń lọ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, dandan ni kí gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ ìgbìmọ̀ òun ó tẹ̀lé òun kí àwọn ó jọ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Gómìnà Eno wí pé kọmíṣọ́nà tí èyí kò bá tẹ́ lọ́rùn kó kọ̀wé fipò rẹ̀ sílẹ̀ kíá. Ó ní òun kò ṣetán àti bẹ ẹnikẹ́ni láti gbọ́ kí wọ́n sì má retí kí òun ó parọ̀wà fún wọn, ẹni tí kò bá ti tẹ́ lọ́rùn kó gba ilé rẹ̀ lọ ni.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé òun kò ní fi ààyè gba kí àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ òun ó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò tí yóò máa wá ṣiṣẹ́ tako òun, ó wí pé gbogbo wọn ló gbọdọ̀ ṣe òdodo sí òun nípa títẹ̀lé òun lọ inú ẹgbẹ́ APC.
Ó ṣe àlàyé pé ìdí tí òun fi kọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sílẹ̀ ni pé ẹgbẹ́ náà kò kúnjú òṣùnwọn, ó ní òun kò le fi inú tán wọn nínú ètò ìdìbò tó ń bọ̀ kí wọ́n má lọ fi ọṣẹ yí òun.
Eno wí pé bí òun kò tilẹ̀ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn gan-an tí òun dá dúró, òun yóò jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò náà nítorí pé àwọn èèyàn òun nífẹ̀ẹ́ òun.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Akwa Ibom yìí kọ́ ni yóò kọ́kọ́ ṣe irú èyí, gómìnà ìpínlẹ̀ Delta náà ti ṣe irú rẹ̀ sẹ́yìn, àtilé àtọ̀nà rẹ̀ ló kó lọ inú ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Gọ́mìnà ìpínlẹ̀ Delta; Sheriff Oborevwori ti kéde ìṣípòpadà rẹ̀ láti jíjẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Kìí ṣe Sheriff nìkan ló yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, bí ìgbín bá fà ni ó fi ọ̀rọ̀ náà ṣe, Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta tẹ́lẹ̀rí; Ifeanyi Okowa àti gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Delta tó fi dé orí alága ìjọba ìbílẹ̀ ni wọ́n ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC báyìí.
Ìkéde yìí wáyé ní Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹtalélógún, oṣù Igbe ní Asaba tíí ṣe olú ìlú Delta. Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà nnì; James Manager ló fi ìkéde yìí síta lẹ́yìn ìpàdé oníwákàtí mẹ́fà tó wáyé ní ilé ìjọba tó wà ní Asaba.
Aṣòfin James wí pé gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Delta pátá ló ti gbà láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Tó fi dé orí agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ pátá tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, gbogbo wọn ló ti digbá dagbọ̀n wọn báyìí láti ré kété sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Kọmiṣọ́nà fún ìfitónilétí ní ìpínlẹ̀ Delta; Ọ̀gbẹ́ni Aniagwu Charles náà sọ̀rọ̀ lórí ìṣípòpadà yìí, ó wí pé àwọn kò le wà nínú ọkọ̀ tó ti rì, ó di dandan kí àwọn ó ṣe àtúnṣe sí ètò ìṣejọba àwọn ní èyí tó gba kí àwọn ó ṣe ìpinnu tó nípọn bẹ́ẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Charles wí pé ìpinnu yìí yóò jẹ́ kí iṣẹ́ rere ó le tẹ̀síwájú ní ìpínlẹ̀ Delta. Dídarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC yóò mú kí ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ó dé bá ìpínlẹ̀ Delta, ìgbé ayé àwọn ará Delta yóò di ọ̀tun, ìpínlẹ̀ Delta ó wá di ìpínlẹ̀ tí yóò ṣe máa mú yangàn láàrin àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ọ̀gbẹ́ni Charles tẹ̀síwájú pé àwọn aṣáájú ló ṣe ìpinnu náà, ó sì di dandan kí gbogbo àwọn ìsọmọgbè ó tẹ̀lé e nítorí pé ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Delta ló jẹ gbogbo àwọn lógún.
Abdullahi Ganduje; ẹni tó jẹ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC náà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé gbogbo àwọn gómìnà yòókù ni yóò darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Ó wí pé ààrẹ̀ Bola Ahmed Tinubu ń ṣe dáadáa sí àwọn olóṣèlú àti aráàlú lápapọ̀ ni gbogbo wọn ṣe ń rọ́ wọ inú ẹgbẹ́ òṣèlú APC láti fi ìfẹ́ wọn hàn síi padà. Ṣebí àgbà tí kò bínú ni ọmọ rẹ̀ ń pọ̀, Ganduje wí pé èyí fi hàn bí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ṣe jẹ́ bàbá dáadáa sí gbogbo wọn.
Ní báyìí tí gbogbo ìpínlẹ̀ Akwa Ibom náà yóò darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ìpínlẹ̀ wo ló tún kàn?
Ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Akẹ́kọ̀ọ́ kan tó ń ṣe ìdánwò àṣekágbá oníwèé mẹ́wàá WAEC lọ́wọ́ ni ọkọ̀ àjàgbé kan ti tẹ̀ pa báyìí ní ìpínlẹ̀ Ogun. Ohun tí a gbọ́ ni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé girama Seico tó wà ní Ikangba ní Ijebu-Ode ń bọ̀ láti ilé ìwé lẹ́yìn ìdánwò ọjọ́ Ẹtì, inú wọn ń dùn wọ́n sì mú ìwé ìbéèrè ìdánwò náà lọ́wọ́ nígbà tí ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré tó sì wọ àárín wọn.
Akẹ́kọ̀ọ́bìnrin kan ló tẹ̀ pa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí ó ṣe àwọn mìíràn léṣe. Ọ̀gbẹ́ni Eko Nicholas, ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣe àlàyé péo ọkọ̀ àjàgbé náà pàdánù ìjánu rẹ̀ ní òpópónà Molipa tó sì já wọ àárín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà kó tó wá lọ fi orí sọ ọgbà ilé ìjọsìn ìràpadà tó wà ní ibẹ̀.
Nicholas wí pé òun kò le sọ pàtó òun tó mú kí ọkọ̀ náà ó pàdánú ìjánu rẹ̀, ó wí pé láti ìgbà tí ìjọba ti tún ọ̀nà náà ṣe tó sì ti já geere ni ìjàm̀bá ti ń wáyé lójú ọ̀nà náà látàrí eré àsápajúdé àwọn awakọ̀. Ó ní òun dá ìjọba lẹ́bi àwọn ìjàm̀bá náà nítorí pé wọn kò ṣe kankéré ìdánà tí yóò mú àdínkù bá eré àsápajúdé sí ọ̀nà náá.
Àlàyé Nicholas tẹ̀síwájú síi pé ó di èèyàn mẹ́fà tí ó ti bá ìjàm̀bá lọ lójú ọ̀nà náà láàrín oṣù Èrèlé tí wọ́n ṣe ọ̀nà náà sí àsìkò yìí. Ó wí pé ilé ìwé pọ̀ ní agbègbè náà ní èyí tó mú kí àwọn ọmọ ó pọ̀ ní ọ̀nà náà. Àwọn onílé agbègbè náà ti kọ ìwé sí ìjọba pé kí wọn ó wá ṣe kankéré ìdánà sí ojú ọ̀nà náà àmọ́ wọn kò tíì rí èsì kankan gbà títí di àsìkò yìí.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá náà sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n ní àwọn gba ìfisùn nípa ìjàm̀bá náà àti akẹ́kọ̀ọ́ tó gbẹ́mìí mì ìwádìí sì ti bẹ̀rẹ̀ lórí rẹ̀.
Discussion about this post