Ẹgbẹ́ òṣèlú APC rọ àwọn ọmọ Nàìjíría láti má dìbò yan olùdíje lábẹ́ áṣíà ẹgbẹ́ òṣèlú PDP mọ́ rárá, wọ́n ní ẹ kò gbọdọ̀ fún wọn ní anfààní láti di ipò agbára kankan mú nítorí pé wọn kò le so èso rere kankan fún yin.
Olùdarí ìfitónilétí ẹgbẹ́ òṣèlú APC; Bala Ibrahim ló tú pẹrẹpẹ́ẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ lórí ìfọrọ̀wánilẹ́nuwò tó ṣe pẹ̀lú àwọn oníròyìn.
Bala wí pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kò le to ara rẹ̀ débi tí yóò to ìlú, ó ní ṣebí ẹ̀yin náà ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ náà.
Àlàyé náà tẹ̀síwájú pé Nàìjíría kò tíì bọ́ nínú mọ̀dàrú tí PDP ṣe láàárin ọdún mẹ́rìndínlógún tí wọ́n fi darí wa, àtúntò yìí ni ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ń ṣe tó sì ń fọ ìdọ̀tí tí wọ́n ṣe kalẹ̀ mọ́.
Bala ní ẹni bá lójú tó sì fi mọ ìran án wò yóò ríi pé gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP jẹ́ ọ̀nà tí Ọlọ́run fẹ́ fi hàn wá pé wọn kò yẹ ní ẹni tó ń darí ìlú.
Ó rọ àwọn adarí ẹgbẹ́ náà àti àwọn ọmọlẹ́yìn kí wọ́n wá kọ́ ìṣèlú lọ́dọ̀ olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìyẹn Abdullahi Ganduje. Bala wí pé Ganduje yóò kọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń ṣe ìṣèlú tí kò ní ìkorò nínú.
Àwọn akọ̀ròyìn bi Bala léèrè ohun tó rí sọ sí ọ̀rọ̀ tí àwọn kan ń sọ pé ààrẹ Bola Ahmed Tinubu àti ẹgbẹ́ òṣèlú APC lọ́wọ́ sí rògbòdìyàn tó ń lọ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Bala kọ́kọ́ rẹ́rìn-ín músẹ́, lẹ́yìn náà ló fèsì pé àhesọ lásán ni ọ̀rọ̀ náà pé kò sí ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ ràrá.
Ó wí pé báwo ni yóò ṣe ṣe é ṣe láti da ẹgbẹ́ òṣèlú PDP rú fún àwọn? Àkọ́kọ́, ilé ẹgbẹ́ àwọn jìnnà síra wọn, ẹ̀kejì, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú APC.
Bala wí pé kí àwọn èèyàn ó yẹra fún àhesọ ọ̀rọ̀ nítorí pé kò sí òótọ́ kan nínú rẹ̀.
Bala kò ṣàì fẹnuko síbi pé kí àwọn ọmọ Nàìjíría ó má dìbò yan olùdíje lábẹ́ áṣíà ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kankan pàápàá ìdìbò ààrẹ tó ń bọ̀ lọ́nà yìí, ó ní kí ẹ dúró ṣinṣin pẹ̀lú ìgbàgbọ́ yín nínú ìṣèjọba Bola Ahmed Tinubu.
Ibi okùn ti gùn wá –
Ohun tó mú kí Bala ó gbé ẹnu sí máìkì náà ni ìpàdé àtúntò tí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP pè tó forí ṣọ́pọ́n.
Ọjọ́bọ ni ìpàdé náà wáyé ní ìpínlẹ̀ Bauchi, ẹsẹ̀ wọn kò sì pé bóyá òun náà ni kò jẹ́ kí ẹnu wọn ó kò.
Igbákejì ààrẹ ìjarùn-ún; Atiku Abubakar kò yọjú síbi ìpàde náà, èyí kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé òun ni adarí ẹ̀kun àríwá nínú ẹgbẹ́ náà.
Àwọn Gómìnà tó wá síbi ìpàde náà ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Bauchi; Bala Mohammed, Gómìnà ìpínlẹ̀ Taraba; Agbu Kefas àti Gómìnà ìpínlẹ̀ Adamawa; Ahmadu Fintiri.
Àwọn aṣojú ikọ̀ májẹ́óbàjẹ́ náà kò gbẹ́yìn, akọ̀wé gbogbogbò tẹ́lẹ̀rí; Olagunsoye Oyinlola ló ṣáájú wọn wá síbi ìpàde náà.
Ọ̀rọ̀ bí wọn yóò ṣe pa àwọn iná aáwọ̀ tó wà nílẹ̀ káàkiri tí wọn yóò sì bẹ̀rẹ̀ ètò ìdìbò ọdún 2027 ni wọ́n bá lọ sí ìpàdé àmọ́ gbogbo rẹ̀ ló lú pọ̀ bí àdàlú, kò padà forí sọ ibìkankan.
Ọ̀rọ̀ tí a ń sọ bọ̀ —
Gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP yìí ló fa ọ̀rọ̀ tí Bala Ibrahim; ẹni tó jẹ́ adarí Ìfitónilétí ẹgbẹ́ òṣèlú APC sọ tó sì fi gba àwọn ọmọ Nàìjíría lámọ̀ràn pé kí wọn ó má tilẹ̀ dábàá àtidìbò fún olùdíje lábẹ́ áṣíà ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Ẹni tí yóò bá dáṣọ fúnni, tọrùn rẹ̀ ló ṣáà yẹ ká wò, àwọn rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni Bala fi gbe ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́sẹ̀ pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP kò le to ara rẹ̀ débi tí yóò to ìlú, ó ní ṣebí ẹ̀yin náà ń rí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ náà pàápàá láàrin àwọn alága àbí kín ni wọ́n ń pè wọ́n?
Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé Nàìjíría kò tíì bọ́ nínú ipá tí ìṣèjọba tí PDP ní lórí wa láàárin ọdún mẹ́rìndínlógún tí wọ́n fi wà nípò ààrẹ. Iṣẹ́ ribiribi ni ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ń ṣe láti ríi pé gbogbo nǹkan padà bọ́ sípò fún Nàìjíría.
Bala Ibrahim rọ àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti àwọn ọmọlẹ́yìn kí wọ́n wá kọ́ ìṣèlú lọ́dọ̀ olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ìyẹn Abdullahi Ganduje. Ẹni tó bá mọ̀nà ni ó yẹ kí a tẹ̀lé, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní láti wá kọ́ ìṣèlú tó bágbà mu lọ́dọ̀ Ganduje yóò kọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń ṣe ìṣèlú tí kò ní ìkorò nínú.