Nọ́mbà mẹ́rin péré ni pín-ìn-nì ìdánimọ̀ ilé ìfowópamọ́ yálà tí a bá fẹ́ fi káàdì ìgbowó gba owó tàbí tí a fẹ́ lo ẹ̀rọ ayára-bí-àṣá afẹ́fẹ́ bánkì ṣọwọ́ sí ẹlòmìíràn, Ẹ kíyèsí ara, Ẹ máà bọ́ sọ́wọ́ àwọn oníjìbìtì gbájúẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ti kó sọ́wọ́ àwọn ọmọ olè, tí wọn gbọ́n gbogbo owó wọn lọ, àwọn ọmọ olè yìí tún ti fi àkàṣù ẹlòmìíràn yá òbítíbitì owó tí wọn kò mọwọ́-mẹsẹ̀ tí wọ́n sì n rọ́ owó san padà fún ilé ìfowópamọ̀.
Ẹ yẹra fún lílo èyíkèyí nínú àwọn Nọ́mbà ìdánimọ̀ yìí gẹ́gẹ́ bíi pín-ìn-nì ìdánimọ̀ yín:
a. 1234 – ookan,éèjì,ẹẹ́ta, ẹẹ́rin
5678 – Aárùn ún, ẹéfà, eéje, Ẹẹ́jọ
Ìdí ni pé nọ́mbà yìí rọrùn fún àwọn ọmọ olè láti tètè ronú kàn, kí wọ́n lòó láti fi gbọ́n gbogbo owó lọ nínú àkàṣù owó yín
b. Ẹ yẹra fún nọ́mbà àtẹ̀lé bí i :
1111 – oókan lẹ́ẹ̀mẹrin léraléra
2222 – eéjì mẹ́rin léraléra
3333 – ẹẹ́ta lẹ́ẹ̀mẹrin léraléra
4444 – ẹẹ́rín lẹ́ẹ̀mẹrin léraléra
d. Ẹ yẹra fún lílo déètì ọjọ́ ìbí, àyájọ́ ìgbéyàwó tàbí ọjọ́ ìrántí mìíràn tó rí ó léwu gidigidi, ó rọrùn fún àwọn oníjìbìtì láti rí i lórí ẹ̀rọ ayélujára àgàgà ìtàkùn ìbánidọ́rẹ̀ẹ́.
e. Ẹ tún yẹra fún lílo nọ́mbà àdúgbò tí ẹ̀ n gbé.
ẹ. Ẹ yéé lo nọ́mbà mẹ́rin tó gbẹ̀yìn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ yín, àwọn ọmọ olè le è tètè kó fìrí rẹ kí wọ́n sì fi ṣeyín ni ìjàmbá
Ẹ máa fura ooo, A ò ni ṣiṣẹ́ fún ọmọ ẹlòmíìràn jẹ́.
Ǹjẹ́ ẹ ti gbọ́ nípa ọ̀fin titun fún àwọn oníbàárà ilé ìfowópamọ́?
Ọ̀gá àgbà fún ilé ìfowópamọ́ àgbà ní ilẹ̀ Nàìjíríá, ìyẹn CBN; Alàgbà Cardoso ní ó pọn dandan kí àwọn oníbàárà bẹ̀rẹ̀ sí i fara gbá ọgọ́rùn ún kan náírà lórí Ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún náírá ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá fi káádì gbowó lẹ́nu ẹ̀rọ tí kìí ṣe èyí tó jẹ́ bánkì tiwọn.
Ọ̀gá àgbà ní òfin ni kí gbogbo ilé ìfowópamọ́ máa san ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún sókè fún oníbàárà lẹ́ẹ̀kannáà láìsí gbígbowó kélekèle. Bí owó bá jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì náírà, ọgọ́wàá náírà ni oníbàárà yóò san lórí owó, bí owó ṣe n pọ̀ si ní ìfaragbá yóò ma gòkè sí i.
A tún ún rọ àwọn oníbàárà ilé ìfowópamọ́ kí wọn máa lo afẹ́fẹ́ ìfowóránṣẹ́ àti èyíkèyí nínú ọ̀nà tí a lè fi owó ṣẹwọ́ sí ìbòmííràn láì faragbá ìjìyà ọgọ́rùn ún náírà sókè. Oníbàárà tún le è máa lọ sọ́dọ̀ àwọn osìṣẹ́ bánkì ẹsẹ̀ títì, POS láti yẹra fún owó ìyọkúyọ yìí.
Òfin yìí yóò bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kínní, oṣù Erénà tó n bọ̀ yìí láti le è máa fi tọ́jú ẹ̀rọ ìgbowó àti ike ìgbowó náà. Bí oníbàárà bá lo ẹ̀rọ ìgbowó àwọn ilé ìtajà nlá nlá tábí ilé oúnjẹ ìgbàlódé. Bánkì yóò kọ́kọ́ fa ọgọ́rùn-ún náìrà yọ pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà ṣángílítí.
Ì bá dára bí àwọn oníbàárà kọ̀ọ̀kan kò bá ṣàyọjúràn sí ti ẹlòmíìràn, kí ilé oge wọn tóge e jẹ, kí wọn ma bá a fi ìgbákúùgbá gbára látàrí lílo ẹ̀rọ ìgbowó tí kìí ṣe ti wọn tàbí èyí tó jẹ́ ti ilé ìtajà àti ilé oúnjẹ ìgbàlódé.