Ariwo àti ẹ̀bẹ̀ ló gbẹnu ògbólógbòó ajínigbéṣowó ìlú Èkó tí orúkọ rẹ̀ n jẹ́ Chukwudumeme Onmawadike tí ìnagijẹ rẹ̀ n jẹ́ EVANS kan. Ìgbà kejì rèé tó ti n rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó pé kí wọ́n ṣíjú àànú wo òun, kí òun sì máa lọ láyọ̀ àti àlááfíà nígbà tí ìjọba àpápọ̀ ti fún òun lómínira. Evans ni òun yóò fi ọkọ̀ akóyọyọ mẹ́rínlà ọ̀ṣàrà òun jìnkì àwọn tó ṣàgbákò ìgbèkùn òun lásìkò ìgbà àìmọ̀ rẹ.
Agbẹjọ́rò rẹ ni ó ti ronúpìwàdà báyìí lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́gboyè rẹ̀ lórí ìmọ̀ ẹ̀kọ̣́ ọrọ̀ ajé. O n ràwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó kí òun le è má ṣe olùkọ́ fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n ẹgbẹ́ rẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Chukwudumeme Onmawadike, Evans ni bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀wọ̀n gbére ni ìjọba àpapọ̀ dà fún òun pẹ̀lú ẹ̀sùn ìjínigbéṣowó àti ẹ̀wọ̀n ọdún mérìnlá fún dída omi àlááfíà ìlú rú, wọ́n ti dá òun sílẹ̀ nígbà tí òun ti ronúpìwàdà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.
Evans ní òun ti kẹ́kọ̀ọ́gboyè Olùkọ́ni , òun ti gba ìwé ẹ̀rí (NCE) ti ilé ẹ̀kọ́ gíga tàwọn olùkọ́ni ti ìlú Yewa. Ẹ̀kọ́ nípa ọrọ̀ ajé ni òun kọ́, òún sì yege lọ́dún mẹ́ta ẹ̀kọ́ náà. Evans tún ti n kàwèé síi ní ifáfitì NOUN tí Ààrẹ Olúṣẹgun Ọbásanjọ́ dá á lẹ̀ sí orílẹ̀ èdè Nàìjìríà.
Agbẹjọ́rò rẹ̀ ní kí ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó dá a sílẹ̀ nítorí kí ó le è lọ lo ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ tuntun rẹ̀ fún ànfàáni orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.Bí ẹ ò bá gbàgbé, nǹkan bí ọdún díẹ̀ sẹ́yìn ni ọwọ́ pálábá Chukwudumeme Onmawadike tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn mọ̀ si Evans ségi ni ilé rẹ̀ tó wà ni GRA. Ògbólògbó gbọ́mọgbọ́mọ ni ọkùnrin kúkúrú bìlísì yìí, yóò sì pa ẹni tí kò bá le è san iye òbítíbitì owó tí wọn bá bèèrè lọ́wọ́ onítọ̀hún. Iye owó ìtúsílẹ̀ tó le è gbà kéré tán jẹ́ ní mílíọ̀nù náírà.
Ẹgbẹlẹmùkún owó ilẹ̀ wa àti tòkèèrè, kọ́kọ́rọ́ ilé owó lóríṣiríṣi, ìbọn àti oríṣiríṣi nǹkan ni wọ́n bá lákàtà ọ̀daràn yìí. Láti ìgbà náà ló tí n jẹ́jọ́ ìwà láabi náà.
Ìjọba àpapọ̀ ti dáa sílẹ̀ nígbà to ti kẹ́kọ̀ọ́gboyè ṣùgbọ́n kò ṣeéṣe fún un bí ìjọba Ìpínlẹ̀ Èkó kò bá tú okùn lọ́rùn rẹ tán yánányánan. Evans ni kí wọ́n jẹ́ kí òun le è lọ ṣiṣẹ́ olùkọ́ tí orí rán òun.
Agbẹjọ́rò Etudo Emefo sọ gbangba gbàǹgbà níwájú Adájọ́ SHERIFAT SONAIKE pé olùjẹ́jọ́ ti kàwé yanjú, ó sì fi ìwé ẹ̀ri rẹ han nílé ẹjọ́. Ìgbẹ̀jọ́ ṣì
ń tẹ̀síwájú.