Àjọ CSO kan ti orúkọ wọn ń jẹ́ The Network for Actualisation of Social Growth and Viable Development ṣetán láti gba ẹjọ́ Comfort Emmanson rò níwájú adájọ́. Kódà, wọ́n ní àwọn kò ní gba owó lọ́wọ́ rẹ̀.
Àjọ yìí dá ilé iṣẹ́ Ibom Air lẹ́bi, wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn òṣìṣẹ́ IbomAir pé wọ́n tẹ ẹ̀tọ́ arábìnrin Emmanson mọ́lẹ̀.
Bákan náà ni wọ́n wí pé ìfìyàjẹni lásán ni bí wọ́n ṣe ti Comfort mọ́ kirikiri.
Àjọ yìí wí pé àwọn ti ṣetán láti gba agbẹjọ́rò fún Comfort lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí àwọn ni yóò sì ná gbogbo owó ìdí rẹ̀.
Omoniyi Akingunola; ẹni tó jẹ́ adarí àjọ yìí ṣe àlàyé pé fífi òfin ìrìnnà de Comfort láìgbọ́ ti ẹnu rẹ̀ náà jẹ́ ìtẹ̀tọ́mọnìyàn-lójú-mọ́lẹ̀.
Bákan náà ló dá àwọn ọlọ́pàá lẹ́bi pé wọ́n gbè Comfort lọ sí ilé ẹjọ́ láìṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà.
Akingunola wí pé fọ́nrán tí wọ́n fi léde nìkan ni àwọn ọlọ́pàá mú dání, wọn kò bèèrè ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú bàlúù náà.
Àwọn ọlọ́pàá kò bèèrè ìdí tí obìnrin tó jẹ́ òṣìṣẹ́ náà ṣe dínà mọ́ Comfort pé kò ní sọ̀ kalẹ̀.
Àjọ yìí ti ṣètán báyìí láti bá Comfort pe ilé iṣẹ́ Ibom Air lẹ́jọ́.
Ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Akingunola sọ yìí farapẹ́ àlàyé tí Timi Agbaje ṣe lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Amòfin ni Timi Agbaje, ó ṣe fọ́nrán kan nínú èyí tó ti ṣe àlàyé àwọn ẹ̀bi Comfort àti ti ilé iṣẹ́ Ibom Air.
Ẹ̀bi Ibom Air ló pọ̀jù nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ náà.
Láti ìgbà ìṣẹ̀lẹ̀ Comfort yìí ni a ti bẹ̀rẹ̀ sí ní rí oríṣìí fọ́nrán nínú èyí tí àwọn òṣìṣẹ́ IbomAir ti ń ṣe àwọn arìnrìnàjò wọn níṣekúṣe.
Àwọn èèyàn wí pé àwọn òṣìṣẹ́ IbomAir ṣáájú àsìkò yìí kìí ṣe àwọn arìnrìnàjò wọn dáadáa.
Bí ọ̀rọ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀:
Nínú fọ́nrán tó gbòde kan ni a ti rí àwọn òṣìṣẹ́ IbomAir tí wọ́n ń wọ́ arábìnrin Emmanson bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ bàlúù ní pápákọ̀ òfurufú Muritala Muhammed.
Àlàyé tí ilé iṣẹ́ Ibom Air ṣe ni pé Emmanson gbá etí òṣìṣẹ́ wọn, ó sì tún gbìyànjú àtifọ́ nǹkan mọ́ ọn lórí.
Ṣáájú kí bàlúù náà tó gbéra ní Uyo, wọ́n ní kí Emmanson ó pa ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ àmọ́ ó kọ̀, awakọ̀ bàlúù náà kéde pé kí gbogbo ènìyàn ó pa ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ wọn, síbẹ̀ Emmanson kọ̀, ẹni tó jókòó sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ gba ẹ̀rọ náà lọ́wọ́ rẹ̀ ó sì pa á.
Ọ̀rọ̀ náà dìjà láàrin wọn àmọ́ wọ́n parí ẹ̀.
Nígbà tí wọ́n dé Ikeja ní pápákọ̀ òfurufú Muritala Muhammed, Comfort ṣe ìkọlù sí òṣìṣẹ́ obìnrin tó ní kó pa ẹ̀rọ rẹ̀ ní Uyo, ó mú un láti ẹ̀yìn, ó yọ irun orí rẹ̀, ó gbá etí rẹ̀ ó sì gbìyànjú àtifọ́ panápaná mọ́ ọn lórí.
Awakọ̀ òfurufú ló ké sí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò, wọ́k gbìyànjú àti jẹ́ kó sọ̀ kalẹ̀ àmọ́ níṣe ni Emmanson ṣe ìkọlù sí àwọn náà, mi ni wọ́n bá fi agídí tìpǎtìkûkú wọ́ ọ bọ́ sílẹ̀.
Níbi tí wọ́n ti ń wọ́ ọ ni aṣọ rẹ̀ ti ya tí gbogbo ọmú rẹ̀ sì wà ní ìta gedegbe.
Nígbà tí wọ́n tún wọ́ ọ bọ́ sílẹ̀ tán, Emmanson tún mú gbogbo wọn bú ó sì tún gbá ọ̀kan létí.
Ilé iṣẹ́ Ibom Air wí pé àwọn ti fa Comfort Emmanson lé àwọn agbófinró lọ́wọ́ àwọn sì ti kọ ìwé sí àjọ tó ń mójútó ìrìn àjò ojú òfurufú.
Èyí ni àlàyé tí ilé iṣẹ́ Ibom Air ṣe nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà wọ́n sì fi òfin de arábìnrin Emmanson títí ayé, kò tún le lo bàlúù ilé iṣẹ́ wọn mọ́.
Oríṣìí àwọn èèyàn ló ti dá sí ọ̀rọ̀ Comfort Emmanson yìí, ọ̀pọ̀ ló sì di ẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà ru àwọn òṣìṣẹ́ IbomAir.
Wọ́n ní àwọn òṣìṣẹ́ náà ló tọ́ Comfort níjà kó tó di pé ó ya mọ́ wọn lọ́wọ́.
Fọ́nrán rẹ̀ tí wọ́n tún wá fi léde pẹ̀lú gbogbo ọmú rẹ̀ níta tún jẹ́ ohun tí àwọn èèyàn kan fajú ro sí, wọ́n ní wọ́n mọ̀ọ́nmọ̀ fi Comfort ṣe ẹ̀sín ni.
Timi Agbaje náà sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ẹni tó fi fọ́nrán náà lédè le ṣe ẹ̀wọ̀n ọdún méjì lábẹ́ òfin tàbí san owó ìtanràn mílíọ̀nù méje náírà.
Bákan náà ló sọ wí pé ẹni tó fa aṣọ Comfort ya náà le ṣe ẹ̀wọ̀n lábẹ́ òfin.
Arábìnrin Aisha Yesufu; ẹni tó jẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn náà sọ sí ọ̀rọ̀ yìí.
Ó wí pé àwọn ọlọ́pàá yára gbé Comfort lọ sí ilé ẹjọ́ àmọ́ wọn kò tíì fi òfin gbé Kwam1 láti ìgbà tó ti ṣe tirẹ̀.
Àṣà Kwam tó gbòde yìí ni àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ká ní Kwam1, Kwam2, Kwam3 tí ó sì ti dé orí Kwam4 báyìí.
Kwam 3 ni ti obìnrin kan pẹ̀lú IbomAir yìí kan náà, a rí obìnrin náà tó ní òun kò ní lọ bí àwọn ẹrù òun kò bá pé. Ó fi ẹ̀sùn kan Ibom Air pé ẹrù òun dín ọ̀kan, wọ́n jọ pò ó, nígbà tó sọ̀ kalẹ̀, ó ní òun yóò gba owó òun padà ní pípé.
Kwam4 ni fọ́nrán ọkùnrin kan tó gbòde pẹ̀lú IbomAir yìí kan náà, a rí àwọn òṣìṣẹ́ IbomAir tí wọ́n ń wọ́ ọkúnrin kan bọ́ sílẹ̀ nínú bàlúù wọn.
Gbogbo àwọn fọ́nrán yìí bẹ̀rẹ̀ sí ní jáde nigba tí ọ̀rọ̀ Comfort ṣẹlẹ̀.
Ohun tí àwọn èèyàn ń sọ nísìn yìí ni pé àwọn òṣìṣẹ́ IbomAir gan-an ò kí ń ṣe èèyàn ire láti ọjọ́ tó ti pẹ́, wọ́n ní bí agbèrò ni wọ́n ṣe máa ń ṣe tí wọ́n sì máa ń sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà sí arìrìnàjò.
Ta ló ti lo IbomAir rí tó le dá sí ọ̀rọ̀ yìí?




