Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ̀ bàbá onílé tó ṣekú pa ayálégbé rẹ̀ àti ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ondo.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé Abah Friday; ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Adekunle Ajasin jẹ́ ayálégbé Oladele Femi nígbà tí orúkọ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ sì jẹ́ Okah Eloho; ẹni ọdún mọ́kàndínlógún.
Baba onílé Friday ló lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn kan láti jí Friday gbé kí wọn ó le gba owó gọbọi owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.
Ogúnjọ́, oṣù Okúdù ni wọ́n jí Friday àti Eloho gbé pamọ́, níbi tí ọ̀kan nínú wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Michael Ojo ti ń bá Eloho lò pọ̀ ni Eloho ti fa aṣọ ojú rẹ̀ ṣí, nítorí pé ó ti rí ojú Michael kí ó má ba à le sọ ni wọ́n ṣe pa Eloho àti Friday. Lẹ́yìn náà ni wọ́n mú àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ wọn tí wọ́n sì gbé ọkọ̀ Friday lọ.
Ẹ̀gbọ́n Friday tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Peter ló fi tó àwọn ọlọ́pàá létí pé àbúrò òun Friday di àwátì.
Ìtọpinpin àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi mú Abdul Mohammed Mubarak; ẹni ọdún méjìdínlógójì tí wọ́n bá ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ Friday lọ́wọ́ rẹ̀.
Computer village ní Ikeja, ìpínlẹ̀ Èkó ni wọ́n ti wá mú Mubarak, òun ló ṣe àlàyé pé ọwọ́ Michael Ojo ni òun ti ra ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà.
Àwọn ọlọ́pàá tẹ̀síwájú nínú ìwádìí wọn, wọ́n lọ mú Michael ní Aramoko-Ekiti, wọ́n tún bá ọkọ̀ Friday ní àkàtà rẹ̀.
Michael ló mú àwọn ọlọ́pàá dé ọ̀dọ Oladele Femi tó gbé iṣẹ́ náà fún òun àti àwọn yòókù rẹ̀, lára wọn ni Kola wà àmọ́ ó ti fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ báyìí.
Michael jẹ́wọ́ pé òun ló ṣekú pa Eloho àti Friday nígbà tí òun ń bá Eloho lò pọ̀ tó sì fi ọwọ́ ṣí aṣọ ojú òun. Kí ó má baà le sọ ni òun ṣe pa òun àti Friday.
Michael ló lọ sọ òkú Eloho nù sí Agbado-Ekiti nígbà tí Kola ju òkú Friday nù sódò ní Ode-Ekiti.
Wọ́n ti rí òkú Eloho àmọ́ wọn kò rí òkú Friday, Kola sì ti sá lọ.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo; Adebowale Lawal sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ó wí pé àwọn gba ìfisùn láti ọ̀dọ àwọn agbẹjọ́rò Peter nípa àbúrò rẹ̀ tó sọnù.
Àwọn ọlọ́pàá ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ wọ́n sì tọpinpin ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ Friday dé Computer village ní Èkó. Mubarak tó ra ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà ló júwe Michael Ojo tó wá júwe Oladele tó jẹ́ bàbá onílé Friday.
Oladele Femi tó ṣètò gbogbo ìjínigbé náà ti jẹ́wọ́ fún àwọn ọlọ́pàá pé òun ló lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú Michael àti Kola láti jí Friday tó jẹ́ ayálágbé rẹ̀ gbé. Ó wí pé òun jí Friday gbé kí òun ó le gba owó lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí pé ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ra ọkọ̀ olówó iyebíye ni. Lọ́jọ́ tí wọ́n gbé Friday, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rin náírà ni wọ́n gbà nínú àpò owó rẹ̀.
Ní báyìí, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti sọ pé àwọn yóò parí ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, gbogbo àwọn tó bá mọ̀ nípa rẹ̀ ni yóò fi ojú winá òfin.
Bákan náà la gbọ́ nípa bí àwọn ọmọ ìyá méjì ṣe ń jí àwọn èèyàn gbé nítorí owó ìtúsílẹ̀. Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Ọmọ ìyá méjì kìí réwèlè ni Yorùbá wí àmọ́ àwọn ọmọ ìyá bíi àwùsá kan ló lẹ̀dí àpò pọ̀ tí wọ́n jí ẹ̀gbọ́n wọn gbé ní ìpínlẹ̀ Enugu.
Ìròyìn fi yé wa pé Juliet Chukwu àti Ngozi Nancy Chuku lẹ̀dí àpò pọ̀, wọ́n jí ẹ̀gbọ́n wọn; Friday Chukwu gbé.
Juliet Chukwu jẹ́ ẹ̀ṣọ́ aláàbò ẹ̀ka NSCDC nígbà tí Ngozi jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ ìrìn-àjò immigration, àwọn méjéèjì gbìmọ̀pọ̀ wọ́n sì gbé ẹ̀gbọ́n wọn; Friday ní ojú ọ̀nà márosẹ̀ Enugu sí Port Harcourt.
Ọgbọ̀n mílíọ́nù náírà ni wọ́n gbà lọ́wọ́ ẹ̀gbọ́n wọn kí wọ́n tó dá a sílẹ̀.
Èyí tó bu wọ́n lọ́wọ́ ni alámòójútó ilé iṣẹ́ China Orienta Mining Company; Amojú ẹ̀rọ Dennis Igwe tí wọ́n jí gbé lójú ọ̀nà kan náà.
Mílíọ́nù mẹ́wàá náírà ni wọ́n gbà lọ́wọ́ rẹ̀ owó ìtúsílẹ̀.
Àwọn ọlọ́pàá ló tọpinpin wọn dé inú ilé kan tí wọ́n ń fara pamọ́ sí bí wọ́n bá ti fẹ́ ṣe iṣẹ́ ìjínigbé wọn, wọ́n bá wọn níbi tí wọ́n ti ń pín owó lọ́wọ́ wọ́n sì fi òfin mú wọn.
Ìgbà náà ni wọ́n ríi pé ẹṣọ́ aláàbò ni àwọn méjéèjì tí wọ́n sì túbn jẹ́ ọmọ ìyá. Ìwádìí ló fi hàn pé àwọn náà ló gbé ẹ̀gbọ́n wọn lọ́sẹ̀ tó ṣáájú ọ̀sẹ̀ tí wọ́n gbé Dennis Igwe.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Bí a ti ń kọ èyí lọ́wọ́ ni ìròyìn kan tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti ìpínlẹ̀ Kano nípa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé girama Bichi tí wọ́ ṣekú pa akẹgbẹ́ wọn méjì.
A gbọ́ pé:
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ àwọn afurasí mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé girama ti ìjọba tó wà ní Bichi, ìpínlẹ̀ Kano.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano; Abdullahi Haruna fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ti mú àwọn afurasí akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kànlá náà lórí ikú tó pa akẹgbẹ́ wọn méjì.
Ó wí pé àwọn ti kó wọn sí àhámọ́ láti fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò lórí ipa tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kó nínú ikú àwọn akẹgbẹ́ wọn méjì náà.
Hamza Idris Tofawa àti Umar Idris Dungurawa ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì náà tí wọ́n ṣekú pa. ìròyìn fi yé wa pé lẹ́yìn tí wọ́n jáde ilé ìwé ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹgbẹ́ wọn ṣe ìkọlù sí wọn tí wọ́n sì fi irin ìbílẹ̀ kan tí wọ́n ń pè ní ‘Gwale gwale’ ṣekú pa wọ́n.
Kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀ Kano; Dọ́kítà Ali Haruna Makoda ti pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó ṣe ìwádìí fínní lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Abdullahi Haruna ti wá fi àwọn aráàlú lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn yóò ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà tí àwọn yóò sì mú àwọn tó pa àwọn ọmọ náà.
Adarí ètò ẹ̀kọ́ girama ìpínlẹ̀ Kano; Abbas Abdullahi náà dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ó rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé kí wọn ó má ṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn ó sì rọ àwọn ọlọ́pàá láti ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.



