Ayé ló ṣe ọlọ́pàá tó yìnbọn pa èèyàn; Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta; Bright Edafe ti fèsì sí fọ́nrán tó ń jà ràìnràìn lórí àwọn ìkànnì ayélujára. Bright wí pé láti ọdún mẹ́fà tí òun ti jẹ́ alukoro, ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí òun kò mọ ohun tí òun le sọ sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Ó wí pé kò sí àlàyé tí òun le ṣe ju pé ayé ló ṣe ọlọ́pàá náà, èèdì ayé ló mú un tí o fi yìnbọn pa ọ̀dọ́mọkùnrin náà – Ayé ló ṣe ọlọ́pàá tó yìnbọn pa èèyàn
Ohun tó ṣẹlẹ̀ ní pàtó ni ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí ọlọ́pàá yìnbọn pa ní ìpínlẹ̀ Delta. Mene Ogidi ni orúkọ rẹ̀, ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n níí ṣe. Ó mú ẹrù kékeré kan lọ sí ibùdókọ̀ kan ní Delta pé ó fẹ́ fi ránṣẹ́. Àwọn adarí ibùdókọ̀ náà ló tú ẹrù náà wò tí wọ́n sì ríi pé ìbọn ló wà nínú rẹ̀. Wọ́n mú un mọ́lẹ̀ wọ́n sì pe àwọn ọlọ́pàá.
Àgọ́ Effurrun ni àwọn ọlọ́pàá náà ti wá, ẹni tó ṣaáju wọn náà ni ASP Nuhu Usman, òun àti ikọ̀ rẹ̀ so ọwọ́ Mene sẹ́yìn wọ́n sì dè é mọ́lẹ̀. Mene bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀mí rẹ̀, ó ní òun kò mọ ohun tó wà nínú ẹrù náà pé òun yóò mú wọn lọ sí ilé ẹni tó fi rán òun.
Nuhu kò ṣe méní ṣe méjì, ó yìnbọn fún un lápá, Mene tún bẹ̀bẹ̀ àmọ́ Nuhu yìnbọn fún un lórí tó sì kú.
Àwọn èèyàn faraya lórí ìtàkùn ayélujára, wọ́n bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà tí ọlọ́pàá yìí wù yìí, wọ́n bèèrè fún ìdájọ́ òdodo lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Ní báyìí, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti fèsì pé ayé ló ṣe ọlọ́pàá náà tó fi pa èèyàn lọ́sàn-án gan-an lójú gbogbo ayé – Ayé ló ṣe ọlọ́pàá tó yìnbọn pa èèyàn

Àwọn ọlọ́pàá ṣe tiwọn, àwọn ológun náà kò gbẹ́yìn:
Àwọn ológun ilẹ̀ wa ya wọ ilé agùnbánirọ̀ kan ní Abuja wọ́n sì yìnbọn pa á. Ìyá AbdulSamad Jamiu ṣe àlàyé pé òun àti ọkọ òun rin ìrìn àjò lọ síbi ìsìnkú mọ̀lẹ́bí wọn kan. Abdulsamad tó ń sìnrú ìlú lọ́wọ́ àti àbúrò rẹ̀ ni wọ́n wà nílé.
Òru mọ́jú ni onílé kejì rẹ̀ pe aago rẹ̀ pé wọ́n gbọ́ ìró ìbọn nínú ilé rẹ̀. Àyà rẹ̀ já ó sì pe aago Abdulsamad àmọ́ kò lọ, ó pe ti àbúrò náà àmọ́ kò gbé e. Ìgbà náà ló fura pé nǹkan ti ṣẹlẹ̀ nílé rẹ̀. ó tún pe aráalé mìíràn, ẹni náà kò sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní pàtó, ó sọ fún un pé àwọn ológun ti gbé Abdulsamad lọ.
Ìyá Abdulsamad tẹ ọkọ̀ létí padà sí Abuja àmọ́ òkú ọmọ rẹ̀ ló bá, wọ́n ti yìnbọn pa ọmọ rẹ̀ mọ́ inú yàrá rẹ̀ tó sùn sí.
Àlàyé tí àwọn ará ilé ṣe fún un ni pé àwọn ológun fo ìgànná wọ inú ilé náà ni òru ní nǹkan bíi aago méjì ààbọ̀, wọn kò gba ẹnu ọ̀nà wọlé, ẹ̀yìn ni wọ́n gbà wọlé, yàrá Abdulsamad sì ni wọ́n lọ tààrà. Ilẹ̀kùn rẹ̀ wà ní títì ọmọ náà sì ti sùn.
Wọ́n yin ìbọn láti ara ilẹ̀kùn náà pa Abdulsamad mọ́ orí ìbùsùn rẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì. Lẹ́yìn náà ni wọ́n pàṣẹ fún àwọn ọdẹ àdúgbò kí wọn ó nu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tó sàn sílẹ̀. Wọ́n wọ inú ilé ìdáná bu omi àti mọ́ọ̀bù tí wọ́n fi nu ẹ̀jẹ̀ náà mọ́ tóní.
Ìyá Abdulsamad ní òun fẹ́ mọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ọmọ náà ṣẹ̀ gan-an ní pàtó tí wọ́n fi pa á.
Wàyí o, ilé iṣẹ́ ológun ti fèsì pé àwọn gba ìpè pàjáwìrì pé àwọn olè ń jà ní àdúgbò náà, wọ́n lọ kojú wọn ni àwọn olè náà bá yìnbọn mọ́ wọn, àwọn ológun náà fi ìbọn kojú wọn padà ni wọ́n fi pa Abdulsamad.
Ọ̀gágun ibùdó àwọn ológun náà ní Abdulsamad jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn afurasí olè náà.
Àwọn ẹbí Abdulsamad ti kọ̀ jálẹ̀, wọ́n ní irọ́ pọ́ńbélé ni èyí, wọ́n ní inú ilé ni wọ́n ti yìnbọn náà kìí ṣe ìta àti pé ihò rẹ̀ wà ní ara ilẹ̀kùn yàrá náà. Bákan náà ni pé orí ibùsùn ni wọ́n pa Abdulsamad sí pé kìí ṣe olè.
Àwọn ológun tún padà fèsì pé lóòótọ́ ni pé Abdulsamad kìí ṣe olè àmọ́ ìbọn bà á nígbà tí àwọn ń lé olè lọ ni.
Àwọn ẹbí Abdulsamad ti kọ ìwé sí ìjọba lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n bèèrè fún ìgbẹ́jọ́ àwọn ológun tó pa ọmọ wọn àti ìdájọ́ òdodo lórí ikú ọmọ náà.

Àwọn ẹ̀ṣọ́ ìbílẹ̀ náà kò gbẹ́yìn:
Àwọn ẹ̀ṣọ́ ilé ìwósàn ti ilé ìwé gíga Abubakar Audu tó wà ní Anyigba, ìpínlẹ̀ Kogi ti ṣekú pa akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé náà kan. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ìpèníjà ààrùn ọpọlọ ó sì ti wà níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú rẹ̀. Lọ́jọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, akẹ́kọ̀ọ́ yìí sá kúrò níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú rẹ̀, ó lọ sí ilé ìwòsàn tó wà nínú ilé ìwé rẹ̀ náà, àwọn ẹ̀ṣọ́ ibẹ̀ kìí mọ́lẹ̀, wọ́n lù ú títí wọ́n sì tún yìnbọn pa á.
Andrew Amehson Aziko ni orúkọ akẹ́kọ̀ọ́ yìí, ìpele kẹrin tó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ló wà. Ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣe àlàyé pé Aziko ni ẹnìkejì tí àwọn ẹ̀ṣọ́ náà yóò pa láàrín oṣù méjì.
Akọ̀wé tẹ́lẹ̀rí fún ìjọba ìbílẹ̀ Olamaboro tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Danjuma Onoja ló kọ ìwé sí ìjọba ìpínlẹ̀ náà. Ohun tó kọ náà ni pé lọ́jọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Igbe, àwọn ẹ̀ṣọ́ ilé ìwòsàn Nana ti ilé ìwé gíga Abubakar Audu ti ṣekú pa akẹ́kọ̀ọ́ kan kí ìjọba ó ṣe ìwádìí kó sì fi ojú wọn winá òfin.
Onoja kọ ọ́ sínú ìwé náà pé fọ́nrán tí ẹ̀rọ akáwòrán ilé ìwòsàn náà ká sílẹ̀ fi hàn bí àwọn ẹ̀ṣọ́ náà ṣe fi póńpó lu Aziko tí wọ́n sì tún yìnbọn fún un ní orí, ìdodo àti ẹ̀yìn.
Nínú fọ́rán náà, Andrew ń bẹ àwọn ẹ̀ṣọ́ náà láti ṣe òun jẹ́jẹ́, ó ní kí wọn ó yẹ ọwọ́ òun wò ó sì tún ń pe orúkọ wọn tó fi hàn pé ó mọ̀ wọ́n rí.
Ọ̀kan nínú wọn bèèrè pé ta ló rán an wá sílé ìwòsàn náà, Andrew fèsì pé bàbá òun, ẹni náà dá a lóhùn pé bàbá rẹ̀ ti kú, èyí fi hàn pé wọ́n mọ Andrew dáadáa.
Ìwádì fi hàn pé bàbá Andrew jẹ́ olùkọ́-fẹ̀yìntì nílé ìwé náà nígbà ayé rẹ̀, ọmọ rẹ̀ Andrew sì wà ní ìpele àgbà.
Gbogbo àwọn tó mọ Andrew ló sọ wí pé ọmọ jẹ́jẹ́ ni kìí fa wàhálà tó fi dé orí ìyá onílé rẹ̀. Ìyá yìí wí pé ààrùn ọpọlọ tó dé síi lára nígbà tó kù díẹ̀ kó parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni wọ́n fi lọ tọ́jú rẹ̀, lọ́jọ́ náà, ó sá kúrò níbẹ̀ ó sì gba ilé ìwé lọ tí wọ́n fi pá yìí. Onoja kọ gbogbo èyí sínú ìwé tó kọ ránṣẹ́ sí ìjọba Kogi pé kí wọn ó gbọ́ ẹjọ́ ikú ọmọ náà.
Monday Ujah; ẹni tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí Andrew ṣe àlàyé pé Anyigba ni Andrew dàgbà sí, àwọn ẹ̀ṣọ́ náà sì mọ̀ ọ́n dáadáa nítorí wọ́n jọ gbé ìlú ni. Ó wí pé ìwà ọ̀dájú gbáà ni wọ́n hù nípa pípa ẹni tó jẹ́ bíi àbúrò sí wọn.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kogi; Nasir Bello Kankarofi ti fèsì sí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ó wí pé Andrew gbìyànjú àti wọ inú ilé ìwé náà lọ́nà tí kò tọ́, àwọn ẹ̀ṣọ́ náà dáa dúró wọ́n sì kojú rẹ̀. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwé rí i nílẹ̀ pẹ̀lú àpá lára wọ́n sì gbé e lọ sí ilé ìwòsàn níbi tó padà kú sí.
Kọmíṣọ́nà wí pé àwọn ẹ̀ṣọ́ yìí ti na pápá bora àmọ́ àwọn yóò wá wọn jáde. Ó pè fún sùúrù àti àlàáfíà ní agbègbè náà.




