Àwọn márùn-ún ló ti wà ní agodo àwọn àwọn ọlọ́pàá báyìí lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ta ọmọ ìkókó, ọmọ ọ̀sẹ̀ méjì.
Ìpínlẹ̀ Èkó ni ọwọ́ ti tẹ àwọn èèyàn wọ̀nyìí, ọkùnrin ni ọmọ náà. Àlàyé tí a rí gbà lẹ́nu agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Benjamin Hundeyin ni pé Happiness lóyún ní ẹni ọdún mẹ́rìndínlógun kò sì mọ ẹni tó loyún. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ kò ní owó àti ohun tó le fi tọ́jú rẹ̀ ló bá mú un lọ sí ọ̀dọ obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nonye Osi tó dúró bíi aláàánú.
Ìgbà tí Nonye gbé Happiness kúrò ní ilé tó gbà fún un lọ sí ibòmíràn ni ara ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fu ẹ̀gbọ́n Happiness, láti ìgbà náà ni kò ti rí Happiness mọ́.
Nígbà tí yóò tún padà rí Happiness, kò sí oyún nínú rẹ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ọmọ lọ́wọ́ rẹ̀. Happiness gan-an ò le sọ pàtó ohun tó ṣẹlẹ̀ síi.
Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá wọ́n sì gbé Nonye, òun ló ka àwọn mẹ́rin yòókù tí wọ́n jọ ta ọmọ náà. Orúkọ àwọn yòókù ni Akintan Adedayo, Jimoh Bashiru, Elizabeth Bishop àti Bukola Oladapo.
Wọ́n jẹ́wọ́ pé lẹ́yìn tí Happiness bímọ́ tán ni àwọn ta ọmọ náà ní mílíọ́nù mẹ́ta náírà fún àwọn tó nílò rẹ̀ fún aájò.
Agbègbè Agemuwo ní Badagry ni àwọn ọlọ́pàá ti lọ gbé ọmọ náà. Ìwádìí ṣì ń lọ láti mú àwọn tí wọ́n ta ọmọ náà sí Badagry nítorí pé àtọwọ́dọ́wọ́ ni wọ́n fi títà rẹ̀ ṣe.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí a máa kọ irú ìròyìn báyìí, kìí sìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àwọn agbọ́mọta yóò gbé ọmọ tà. Ṣé ẹ rántí Joy tó ta ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Niger? Ìròyìn náà kà báyìí pé Bí wọ́n bá sọ fún ẹ̀gbọ́n Joy pé omi ni yóò se ẹja jinná, yóò jiyàn rẹ̀. Àbúrò rẹ̀ tó finú tán jí ọmọ rẹ̀ gbé láti tà fún àwọn tí yóò lò ó.
Agbègbè Kwamba, Suleja ní ìpínlẹ̀ Niger ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀. Ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Ọ̀pẹ ọdún tó kọjá ni ìyá ọmọ oṣù mẹ́fà yìí fi ọmọ rẹ̀ ti Joy; ẹni tó jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ pé òun fẹ́ jáde.
Dídé tí yóò dé lálẹ́, kò bá ọmọ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni kò bá Joy tó fi ti ọmọ náà. Kò kọ́kọ́ bìkítà pé bóyá ó sáré jáde ni àmọ́ nígbà tí Joy kò gbé aago tí ilẹ̀ fi ṣú ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé ewu ń bẹ lóko lóńgẹ́.
Obìnrin yìí kàn sí àwọn ọlọ́pàá Suleja wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.
Ohun tó mú kí ìwádìí náà ó rọrùn ni àwọn ara ilé rẹ̀ méjì tí wọn kò sí nílé láti ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà, bí ọ̀kan nínú wọn ṣe dé ni àwọn ọlọ́pàá he é bíi ìgbín, òun ló júwe ibi tí Joy àti àwọn méjì yòókù wà.
Agbègbè Kubwa ní Abuja ni wọ́n gbé ọmọ oṣù mẹ́fà náà lọ láti tàá, Emmanuel Ezekiel jẹ́wọ́ pé àwọn ti ń gbìmọ̀pọ̀ tipẹ́ láti jí ọmọ náà gbé pẹ̀lú Joy, nígbà tí àwọn sì rí anfààní láti gbé e ni àwọn ṣe jọ jí ọmọ náà gbé lọ tà.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ Joy àti Favour, wọ́n mú àwọn ọlọ́pàá lọ sí ilé Patience Obana tí yóò bá wọn ta ọmọ náà, kò tíì rí ọmọ náà tà tí àwọn ọlọ́pàá fi mú un. Àlàáfíà sì ni ọmọ yìí wà.
Wasiu Abiodun; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Niger bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ pé àwọn mú Joy Nuwa; ẹni ogún ọdún tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Nasarawa, Emmanuel Ezekiel; ẹni ọgbọ̀n ọdún tó sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Niger, Favour James; ẹni ọdún márùndínlọ́gbọ̀n tó sì jẹ́ ọmọ ìlú Niger bákan náà àti Patience Obana; ẹni ọdún mẹ́tàlélógún tí òun sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Abuja lórí ẹ̀sùn ìjọ́mọgbé.
Kìí wá ṣe pé ẹ̀sùn ìjọ́mọgbé nìkan o, ọmọ títà ni iṣẹ́ Patience, Kubwa ní Abuja ló tẹ̀dó sí.
Àwọn ọlọ́pàá ti gba ọmọ náà padà lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì ti gbé e fún ìyá rẹ̀.
Ṣebí Joy tilẹ̀ kọ́ ló bí ọmọ náà, ṣé ẹ gbọ́ nípa ìyá tó ta ọmọ tó bí fúnra rẹ̀? Kìí tún wá ṣe òun nìkan o, òun àti ìyá rẹ̀ ni wọ́n jọ gbìmọ̀pọ̀ ta ọmọ náà lọ́jọ́ kejì tó bímọ, àfi bí ìgbà tí wọ́n ti gbèrò rẹ̀ sílẹ̀, bóyá wọ́n dẹ̀ gbèrò rẹ̀ sílẹ̀, àwa ò le sọ. Wọn kò tilẹ̀ tíì gbé ọmọ náà rìn jìnnà tí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá fi tó wọn. Ìròyìn náà kà báyìí pé Grace Walter; ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́ta àti ọmọ rẹ̀; Blessing Walter; ẹni ogún ọdún gbìmọ̀pọ̀ ta ọmọ tí Blessing bí ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rin náírà. Ọjọ́ kejì tí Blessing bí ọmọ náà ni òun àti ìyá rẹ̀ gbé e tà.
Agbègbè Oron ní ìpínlẹ̀ Awka Ibom ni èyí ti ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọwọ́ tẹ àwọn tí wọ́n ta ọmọ́ náà fún.
Àwọn ọlọ́pàá ojú pópó ni wọ́n dá ọkọ̀ àwọn tó ra ọmọ náà dúró ní òpópónà Nsit Atai sí Oron, àwọn mẹ́ta ni wọ́n wà nínú ọkọ̀ náà; ọkùnrin kan tó wa ọkọ̀ náà àti àwọn obìnrin méjì. Àwọn ìdáhùn tí wọ́n fún àwọn ọlọ́pàá lórí bí ọmọ náà ṣe jẹ́ kò gún régé tó ló fàá tí wọ́n fi mú wọn lọ sí àgọ́ wọn fún ìdánilójú.
Àgọ́ ọlọ́pàá ni Naskpo Sonia Labere àti Inemesit Okin Akpan ti jẹ́wọ́ pé wọ́n rán àwọn wá ra ọmọ náà láti Portharcourt ni. Wọ́n ní Wazor Godwin àti Lilian Duru ló rán àwọn wá gba ọmọ náà lọ́wọ́ Grace Inyang ní Oron, Awka Ibom.
Ní báyìí, ọwọ́ ti tẹ Alison Eduno tó ṣọ̀nà rírà àti títa ọmọ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Awka Ibom ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde láti ẹnu alukoro wọn; Timfon John láàárọ̀ yìí pé ọwọ́ tẹ àwọn oníṣòwò ọmọ ní agbègbè Oron ní Awka Ibom. Wọ́n ti mú ìyá àti ìyá ìyá ọmọ náà tó ta ọmọ náà, bákan náà ni wọ́n ti mú Lilian tó mú ẹni tó ra ọmọ mọ ẹni tó ta ọmọ. Wọ́n ti gbé ọmọ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń mójútó ọ̀rọ̀ obìnrin tó wà ní Uyo fún ìtọ́jú.
Òwò ọmọ ti gbilẹ̀ ní àwùjọ wa, ẹ jẹ́ ká máa mójútó àwọn àwọn ọmọ wa ká sì mọ irú ẹni tí a ń fi wọ́n tì, ọmọ wa kò ní sọnù o, Àṣẹ.
Discussion about this post