Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ló ti digbádagbọ̀n wọn kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú NNPP ta kọ́sọ́ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Kabiru Usman ló ń ṣojú ẹ̀kun Rano mọ́ Bunkere nígbà tí Abdullahu Sani ń ṣojú ẹ̀kun Karaye mọ́ Rago, ìpínlẹ̀ Kano ni àwọn méjéèjì wà.
Agbẹnusọ fún ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin; Tajudeen Abass ló kéde ìyapa yìí níbi ìjókòó ilé tó wáyé láàárọ̀ òní.
Bákan náà ni ọmọ ilé tó ń ṣojú ẹ̀kun Oriade/Obokun ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun; Oluwole Oke náà kéde pé òun ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC báyìí.
Ìṣọwọ́ tí àwọn olóṣèlú fi ń darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lẹ́nu lọ́lọ́ yìí ló fà á tí àwọn oníròyìn fi pe Tinubu ní ìjì tó ń da àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú yòókù wó.
Bí ẹ bá ń fi ọkàn bá wa lọ, kòpẹ́kòpẹ́ yìí ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta àti gbogbo àwọn ẹmẹ̀wàá rẹ̀ ta kọ́sọ́ sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Ìròyìn náà kà báyìí pé Gọ́mìnà ìpínlẹ̀ Delta; Sheriff Oborevwori ti kéde ìṣípòpadà rẹ̀ láti jíjẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Kìí ṣe Sheriff nìkan ló yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, bí ìgbín bá fà ni ó fi ọ̀rọ̀ náà ṣe, Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta tẹ́lẹ̀rí; Ifeanyi Okowa àti gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Delta tó fi dé orí alága ìjọba ìbílẹ̀ ni wọ́n ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC báyìí.
Ìkéde yìí wáyé ní Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹtalélógún, oṣù Igbe ní Asaba tíí ṣe olú ìlú Delta. Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà nnì; James Manager ló fi ìkéde yìí síta lẹ́yìn ìpàdé oníwákàtí mẹ́fà tó wáyé ní ilé ìjọba tó wà ní Asaba.
Aṣòfin James wí pé gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Delta pátá ló ti gbà láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Tó fi dé orí agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ pátá tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, gbogbo wọn ló ti digbá dagbọ̀n wọn báyìí láti ré kété sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Kọmiṣọ́nà fún ìfitónilétí ní ìpínlẹ̀ Delta; Ọ̀gbẹ́ni Aniagwu Charles náà sọ̀rọ̀ lórí ìṣípòpadà yìí, ó wí pé àwọn kò le wà nínú ọkọ̀ tó ti rì, ó di dandan kí àwọn ó ṣe àtúnṣe sí ètò ìṣejọba àwọn ní èyí tó gba kí àwọn ó ṣe ìpinnu tó nípọn bẹ́ẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Charles wí pé ìpinnu yìí yóò jẹ́ kí iṣẹ́ rere ó le tẹ̀síwájú ní ìpínlẹ̀ Delta. Dídarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC yóò mú kí ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ó dé bá ìpínlẹ̀ Delta, ìgbé ayé àwọn ará Delta yóò di ọ̀tun, ìpínlẹ̀ Delta ó wá di ìpínlẹ̀ tí yóò ṣe máa mú yangàn láàrin àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ọ̀gbẹ́ni Charles tẹ̀síwájú pé àwọn aṣáájú ló ṣe ìpinnu náà, ó sì di dandan kí gbogbo àwọn ìsọmọgbè ó tẹ̀lé e nítorí pé ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Delta ló jẹ gbogbo àwọn lógún.
Ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò mú ọ̀rọ̀ ìdarapọ̀ yìí ní kékeré rárá, kódà alága ẹgbẹ́ náà ti wí pé gbogbo àwọn olóṣèlú yòókù ni yóò darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC báyìí tó já sí pé kò ní ṣẹ́ku ẹyẹ ló kéré jù nínú àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú yòókù.
Níbi ayẹyẹ ìgbaniwọlé tí wọ́n ṣe fún Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta àti ikọ̀ rẹ̀ ni Ganduje ti sọ ọ̀rọ̀ náà. Ìròyin náà kà báyìí pé:
Abdullai Ganduje; ẹni tó jẹ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC sọ̀rọ̀ níbi ìgbaniwọlé Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta àti àwọn ẹmẹ̀wàá rẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Ajé pé àwọn Gómìnà yòókù náà ṣì ń bọ̀ wá darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Igbákejì ààrẹ; Kashim Shettima ló gba Gómìnà Sherif Oborovwori àti àwọn ikọ̀ rẹ̀ wọlé sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ó kí wọn káàbọ̀ ó sì ṣe wọ́n ní pẹ̀lẹ́.
Níbi ètò náà ni Gómìnà Sheriff ti ṣe àlàyé ìdí tí òun àti ikọ̀ rẹ̀ fi darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Ó wí pé ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfẹ́ hàn sí àwọn ní ìpínlẹ̀ Delta, kò sì sí bí àwọn ṣe le fi ìfẹ́ náà padà bí àwọn bá wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ni àwọn ṣe darapọ̀ mọ́ ọn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ kí ìfẹ́ le máa lọ bó ti yẹ.
Gómìnà Sheriff wí pé òun kò ní ìgbàgbọ́ nínú Festus Keyamo àti àwọn ọmọ Agege yòókù, ó ní òun ni aṣáájú ìpínlẹ̀ Delta, ibi tí òun bá sì lọ ni àwọn yòókù ó lọ pẹ̀lú òun.
Gómìnà Sheriff rọ àwọn Gómìnà yòókù tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Ọ̀rọ̀ Ganduje.
Bí éégún ẹni bá jóo re ni Ganduje fi ọ̀rọ̀ náà ṣe, ó lu Sheriff lọ́gọ enu fún ìgbésẹ̀ akin náà ó sì gbé oríyìn fún ààrẹ Bola Ahmed Tinubu pé ó jẹ́ aṣáájú rere.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ náà ló ti kí àwọn Gómìnà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC fún akitiyan wọn nínú ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè yìí.
Nígbà tí wọ́n wá sọ pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC nìkan ni yóò wà tí wọ́n sì ń gbé ìgbésẹ̀ àti sọ ìdìbò di dandan, kín ni yóò wá ṣẹ́lẹ̀?
Òní yìí ni àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin jókòó lórí àbá tí yóò sọ́ ìbò dídì di dandan fún gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-ède Nàìjíríà, kódà àbá náà ti wà ní ìpele kejì báyìí. A gbọ́ pé Ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ tí yóò sọ ìbò dídì di dandan fún gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n ní kò sí ààyè fún mọ́ fún jíjókòó sílé lọ́jọ́ ìdìbò. Bákan náà ni ìjìyà tó nípọn yóò wà fún ẹni tí kò bá jáde dìbò.
Àbá yìí ti wà ní ìpele kejì báyìí, ó ku kí wọn ó parí ìjíròrò rẹ̀ kí wọ́n sì fi òǹtẹ̀ lù ú. Agbẹnusọ fún ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin; Tajudeen Abass ló ń ṣe pẹ́pẹ́fúrú lórí bí àbá yìí yóò ṣe di àṣẹ.
Discussion about this post