Àwọn kan tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni wọ́n ti ṣá arákùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Benjamin pa ní Ikorodu báyìí o. Ohun tí a gbọ́ ni pé Benji ni ìnàgijẹ ọkùnrin náà ó sì jẹ́ gbajúmọ̀ oníṣàwámà tí ilé iṣẹ́ rẹ̀ ń jẹ́ Chibest. Agbègbè Ebutte-Ipakodo ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀.
Nǹkan bíi aago mẹ́jọ ààbọ̀ alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó kọjá ni àwọn ọkùnrin méjì kan dé sí ìsọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó ń dá àwọn oníbàárà lóhùn lọ́wọ́, wọ́n sún mọ́ ọn dáadáa kí wọ́n tó yin ìbọn fún un láìmọye ìgbà. Kò sí ẹni tó le sún mọ́ Benji títí wọ́n fi lọ pátápátá. Nígbà tí wọn yóò fi gbé e dé ilé ìwòsàn, Benji ti dágbére fáyé.
Àwọn ará àdúgbò wí pé ìkọlù àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n ní oró ọ̀kan lára wọn tí wọ́n pa ni wọ́n fi ikú Benji rán.
Gbogbo akitiyan láti kàn sí alukoro ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Benjamin Hundeyin kò so èso rere lásìkò yìí.
Ìkọlù àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn kìí ṣe ìròyìn mọ́ ní ilẹ̀ yìí. Nínú oṣù yìí náà ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣekú pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde ilé ìwé gíga Niger Delta méjì. Ìpakúpa ni wọ́n pa àwọn ọmọ májéèjì yìí. Ohun tí a gbọ́ ni pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́kùnrin méjéèjì yìí ti kẹ́kọ̀ọ́jáde, ìwé ìpè sí ìsìnrú ìlú ni wọ́n ń retí kí wọ́n tó sá wọn pa. Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde méjì ti ilé ìwé gíga Niger Delta tó wà ní Amassoma ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ti ṣá láṣàápa báyìí.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé àwọn méjì yìí wà ní Gbarantoru ní Yenogoa, ìpínlẹ̀ Bayelsa, ìwé ìpè sí àgùnbánirọ̀ ni wọ́n ń retí kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà tó ṣá wọn pa.
Orúkọ èkíní ń jẹ́ Ayaokpe Sinclair nígbà tí a kò tíì mọ orúkọ èkejì. Ìrọ̀lẹ́ àná; Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹjọ, oṣù Èbìbí ni wọ́n ṣá wọn pa.
Aláṣẹ ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Bayelsa; Tolummbofa Johnathan ṣe àlàyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde méjì yìí ń rìn lọ ní òpópónà ni àwọn kan pariwo láti inú ọkọ̀ pé “àwọn nìyẹn” wọ́n bọ́ sílẹ̀ tì àwọn méjì náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní pariwo “Aye, Aye, Aye” kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣá wọn ládàá níṣàákúṣàá.
Ayaokpe kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ àmọ́ èkejì rẹ̀ gbìyànjú àti sálọ, awakọ̀ tó gbé wọn wá ríi pé àbúrò òun ni ó sì gbé e lọ sínú ọkọ̀ kó le gbé é sálọ àmọ́ wọ́n ká wọn mọ́ inú ọkọ̀ náà wọ́n sì ṣá a pa.
Johnathan wí pé àwọn rí awakọ̀ náà mú àwọn sì ti fàá lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́.
Bákan náà ni a gbọ́ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ṣá olórí wọn láṣàápa ní ìpínlẹ̀ Bayelsa. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ kà báyìí pé:
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn Bobos ti ṣekú pa olórí wọn; Olotu Omubo nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ipò náà.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bayelsa pé àwọn ọmọlẹ́yìn Olotu Omubo náà ni wọ́n pa á nítorí pé wọ́n fẹ́ fi èèyàn tiwọn sí ipò náà ní ẹni tí wọ́n lérò pé àsìkò rẹ̀ yóò san àwọn.
Ìdílé Nembe ni Omubo ti jáde wá, òpópónà Goodnews ní Azikoro, Yenagoa ni wọ́n pa á sí lọ́jọ́bọ, ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Igbe tó lọ yìí. Ìṣọ́wọ́paá nípakúpa tí wọ́n pa á kalẹ̀ ló tọ́ka sí pé iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni.
Bákan náà ni àwọn èèyàn rò o pé o ṣeéṣe kó jẹ́ àwọn ikọ̀ mìíràn ló pa á ní ìránró àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn tó ti pa.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé ìjà abẹ́nú wà nínú ẹgbẹ́ Bobos tí Omubo jẹ́ olórí wọn, wọ́n ní àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ̀ ló pa á lọ́nà tí yóò fi dàbí pé àwọn ikọ̀ mìíràn ni ó ṣekú pa á. Wọ́n ní ìdí ni pé wọ́n kò fẹ́ Omubo ní olórí wọn mọ́.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe àfikún pé oríṣìí ẹ̀sùn ni Omubo ní nílẹ̀ ṣáájú ikú rẹ̀.
Bákan náà ni ọwọ́ wa tẹ ìròyìn kan nípa ohun tó jẹ mọ́ ìkọlù àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn yìí kan náà tó wáyé ní Idimu ní ìlú Èkó. Ohun tí a gbọ́ ni pé:
Jìnìjìnì bo àwọn ará Idimu ní Èkó láàárọ̀ ọjọ́ Àìkú nígbà tí wọ́n rí òkú àwọn èèyàn méjì tí ọ̀kan kò sì tún ní orí mọ́.
Ìròyìn fi yé wa pé òru ọjọ́ àbámẹ́ta ni wọ́n pa àwọn èèyàn náà kí àwọn èèyàn tó jí rí wọn láàarọ̀ ọjọ́ Àìkú.
Lanre Ajao, ẹni tó jẹ́ ará àdúgbò náà wí pé Baba ọjà ni àwọn ń pe ọ̀kan nínú àwọn òkú náà, ìyẹn èyí tí orí rẹ̀ ṣì wà lọ́rùn rẹ̀, ó wí pé ó nira láti dá èkejì tí kò ní orí náà mọ̀.
Lanre wí pé òdú ni bàbá ọjà ní agbègbè náà, àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ aládàáni ló máa ń sọ́nà fún nínú súnkẹrẹ-fàkẹrẹ, wọ́n ní ó ṣì sọ́nà fún ọkọ̀ lọ́jọ́ Ẹtì.
Jamiu Raji náà bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, ó wí pé ìṣọwọ́ pa àwọn èèyàn náà tọ́ka sí iṣẹ́ ọwọ́ àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn. O ní kò sí ìjà tàbí fàǹfà kankan ló jẹ́ kí òun ròó bẹ́ẹ̀ àti pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí kò ṣẹlẹ̀ rí ní àdúgbò náà. Bákan náà ló ṣe ìdámọ̀ ẹnìkejì bíi ará àdúgbò náà.
Àwọn akọ̀ròyìn fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ó lé ní wákàtí mẹ́wàá kí àwọn ọlọ́pàá tó dé ibẹ̀, ẹnìkan tí kò fẹ́ kí wọ́n dárúkọ òun wí pé àwọn gba owó lọ́wọ́ àwọn ẹbí àwọn òkú náà kí wọ́n tó jẹ́ kí wọ́n gbé wọn.
Discussion about this post