Àwọn ọlọ́pàá ti gba arábìnrin Cynthia Akor kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé tí wọ́n palẹ̀ rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ Ẹtì. Ọmọ ogun ojú òfurufú ilẹ̀ wa ni Cynthia, ilé rẹ̀ tó wà ní Mpape, Abuja ni wọ́n ti lọ gbé e pẹ̀lú àwọn méjì mìíràn.
Josephine Adeh; Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Abuja ṣe àlàyé pé igbákejì kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ; DCP Isyaku Sharu ló ṣaájú ikọ̀ tó lọ gba Cynthia sílẹ̀. Àwọn ọlọ́pàá tí kò gbọ́ nǹkan kan mọ́, àwọn kògbérèégbè àti àwọn ọdẹ ìbílẹ̀ ni wọ́n jọ fọwọ́sowọ́pọ̀ ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí.
Àlàyé náà tẹ̀síwájú pé gbogbo igbó Mpape ni wọ́n tú tú tú, wọ́n tú gbogbo Gidan, Bawa, Anguwan Mu’azu àti òkè Yewa tó wà ní ìloro Abuja mọ́ Nasarawa. Aago méjì òru ni wọ́n rí wọn ní ìletò Fulani kan tó wà láàrin Anguwan àti Yewa, àwọn afurasí mẹ́rin ni wọ́n rí mú tí wọ́n sì gba àwọn èèyàn náà sílẹ̀ láì farapa.
Bákan náà ni wọ́n rị́ owó tó lé ní mílíọ́nù mẹ́ta gbà lọ́wọ́ wọn, owó ìtúsílẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n ti gbé sẹ́yìn ni owó náà.
Àwọn tí wọ́n jọ ń ṣe iṣẹ́ náà ti fẹsẹ fẹ́ẹ àmọ́ àwọn mẹ́rin náà wà ní àtìmọ́lé. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn yóò ṣètò ààbò tó nípọn sí Mpape àti agbègbè rẹ̀.
Bí a ṣe ń kọ èyí lọ́wọ́ ni ìròyìn mìíràn tẹ̀ wà lọ́wọ́ nípa wòlíì Stephen Echexona tí wọ́n jí gbé pé ‘Wòlíì Stephen Echezona tí àwọn ajínigbé gbé ti padà dé o. ilé epo kan tó wà ní Ichda ní ìjọba ìbílẹ̀ Anaocha ni ìpínlẹ̀ Anambra ni wọ́n ti palẹ̀ baba mọ́.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò gbìyànjú àti dá wọn lọ́wọ́ kọ́ lọ́jọ́ náà ni wọn kò fi gbé ọkọ̀ wọn lọ, ọkọ̀ wòlíì ni wọ́n fi gbé e lọ lọ́jọ́ náà.
Àpapọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò ni wọ́n pawọ́pọ̀ gba wòlíì Stephen sílẹ̀ lánàá.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé tí Ikenga Tochukwu; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ṣe, àwọn ọlọ́pàá, àwọn ológun àti àwọn ọdẹ ìbílẹ̀ láti agbègbè Ichida ati Ihiala ló parapọ̀ ṣe iṣẹ́ náà. Wọ́n sa ipá wọn, wọ́n sì rí wòlíì Stephen gbà kalẹ̀ láì fara pa’
*** ** *** ** ** *** *** *** *** *** ** *** *** *** *** *** ** *** *** *** *** *** ** ***
Nígbà tí ìjínigbé ń lọ lápá ọ̀tún, ẹni tí wọn n jí gbé, wọ́n á tún yìn bọn pa á.
Ǹjẹ́ ẹ gbọ́ nípa ọmọ tí bàbá onílé kan yin ìbọn pa nítorí pé ó wọ inú ọgbà rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ bọ́ọ́lù ni ọmọ yìí fẹ́ mú nínú ọgbà bàbá náà. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé ‘Paul, ọmọdékùnrin kan tó fo ìgànná wọ inú ọgbà ilé kan láti mú bọ́ọ̀lù tí wọ́n ń gbá tó wọnú ilé náà ti padà gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra nígbà tí bàbá onílé yìí yìnbọn fún un.
Ìpínlẹ̀ Imo ni èyí ti ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́rú ọ̀sẹ̀ yìí, ilé ìwòsàn Umuguma tó wà ní Owerri lọmọ náà dákẹ́ sí.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé ní ọjọ́rú, ọmọ yìí àti àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ń gbá bọ́ọ̀lù nínú ọgbà, bọ́ọ̀lù yìí ni ọ̀kan nínú wọn gbá wọ inú ọgbà bàbá onílé yìí tí Paul fi fo ìgànná ilé náà láti gbé bọ́ọ̀lù náà. Inú bí bàbá onílé ó sì yin ìbọn fún Paul ní odò ikùn.
Àwọn dọ́kítà sa ipá wọn, nígbà tí ẹ̀rọ ayàwòrán kò rí ibi tí ọta ìbọn náà wà ní pàtó, àwọn dọ́kítà ṣe iṣẹ́ abẹ láti wá ọta náà jáde, ìrètí ni pé yóò jí sáyé lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ yìí àmọ́ Paul sun oorun iṣẹ́ abẹ náà rọ̀run ni.
Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún ni Paul lásìkò ikú rẹ̀, alágbàtọ́ rẹ̀ ṣe àlàyé pé ọdún kẹjọ tó ti ń gbé lọ́dọ̀ òun rèé, ilé ìwé girama Urban tó wà ní Owerri ni ó ń lọ.
Odikanwa wí pé afúnñṣọ́ ni Paul, ikú rẹ̀ wọ òun ní akínyẹmí ara.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo sọ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Henry Okoye pé àwọn ti mú bàbá onílé tó yin ìbọn náà sí àhámọ́’
Ipò tí Odikanwa wà báyìí.
Johnathan Odikanwa bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí ikú àìtọ́jọ́ tó pa ọmọ rẹ. Ó wí pé ọmọ ilé ìwé girama Urban tó wà ní Owerri ni ọmọ náà, ìpele kìíní ni Paul wà.
Ní ọjọ́ náà, àwọn olùkọ́ ilé ìwé rẹ̀ méjì wá bá òun nílé pé Paul ní ìṣòrò kékeré kan, wọ́n ṣe àlàyé pé Paul ń gbá bọ́ọ̀lù pẹ̀lú àwọn akẹgbé rẹ̀ ní nú ọgbà ilé ìwé nígbà tí bọ́ọ́lù náà wọ inú ọgbà ilé kejì, kíá ni Paul ti gun ìgànná ilé yìí pé kó le mú bọ́ọ̀lù náà, ẹ̀ẹ̀kan náà ni gbogbo wọn gúròó ìbọn tí Paul sì jábọ́ sílẹ̀.
Odikanwa tẹ̀lé wọn dé ilé ìwòsàn, lẹ́yìn náà ni ó lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá níbi tó ti bá bàbá onílé yìí.
Bàbá onílé wí pé òun kò yin ìbọn mọ́ ọmọ náà àmọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wí pé lẹ́yìn tó yìnbọ fún Paul tán, ó tún yin bíi mélòó kan sókè.
Bàbá yìí takú pé òun fi ọ̀rá nylon ṣe nǹkan bíi ariwo kó le dẹ́rù ba Paul ló mú kí Paul ó jábọ́ pé igi ló gún un níkùn bó ṣe jábọ́. Ó yarí pe òun kò yìnbọn.
Àyẹ̀wò àwọn dọ́kítà.
Àyẹ̀wò nílé ìwòsàn fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé nǹkan gún ọmọ náà ní inú wọ inú ìfun, gbogbo àyẹ̀wò fi hàn pé ọgbẹ́ náà jinnú ni wọ́n fi ṣe iṣẹ́ abẹ fún un. Gbogbo àwọn èsì àyẹ̀wò náà ni wọ́n ti kó fún àwọn ọlọ́pàá àmọ́ wọ́n kò láti sọ bóyá ọta ìbọn ni wọ́n bá nínú rẹ̀ àbí ọta ìbọn kọ́.
Discussion about this post