Ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ yìí, ẹ̀ka àwọn jagunjagun ojú òfurufú ti kéde pé àwọn ti pa ọlọ́wọ́ ọ̀tún Bello Turji àti àwọn ẹmẹ̀wá rẹ̀ nínú ìkọlù tí àwọn ṣe sí ibùdó wọn.
Bello Turji ni ògbólògbó agbésùnmọ̀mí tó ń da ìpínlẹ̀ Sokoto, Zamfara àti Kastina láàmú, gbogbo àwọn ìkọlù tó nípọn tó ń wáyé ní Sokoto àti àwọn ìlú tó yíi ká kò ṣẹ̀yìn rẹ̀, ó ti pẹ́ tí àwọn ológun ti ń lépa Bello Turji tí wọn kò ríi mú.
Àmọ́ báyìí, ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn ti pa ọlọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Shaudo Alku pẹ̀lú àwọn ikọ̀ rẹ̀. Ìbùdó àwọn agbésùnmọ̀mí tó wà ní ìtòsí ilé ìwé ìjọba alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Tunfa tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Sokoto ni wọ́n ti ṣe ìkọlù sí wọn.
Shaudo Alku wá sí Sokoto láti ilẹ̀ Nìjéè wá ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn lọ́gàálọ́gàá agbésùnmọ̀mí pẹ̀lú àṣe Bello Turji. Shaudo ni ó máa ń kó àwọn ohun ìjà olóró wọlé fún Bello láti ilẹ̀ òkèrè.
Ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá àwọn agbésùnmọ̀mí yòókù tó na pápá bora. Wọ́n ní Shaudo tí àwọn pa yìí yóò da ètò àwọn agbésùnmọ̀mí náà rú wọn kò sì ní le rí àwọn ohun ìjà olóró lò mọ́ nítorí pé Shaudo náà ni ó máa ń kó wọn wọlé. Àṣeyọrí ńlá ni ikú Shaudo jẹ́ àmọ́ bí wọn ó bá rí àwọn agbésùnmọ̀mí náà mú délẹ̀, dandan ni kí orílẹ̀-ède Nìjéè àti Chad ó fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Nàìjíríà.
Àwọn ará Isa ní Sokoto fèsì sí èyí, wọ́n ní àwọn yóò tilẹ̀ ní ìsinmi lọ́wọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí pẹ̀lú ikú Shaudo yìí. Ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn kò ní sinmi lórí ọ̀rọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí.
IPA ÀWỌN OLÓGUN LÓRÍ ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ.
Mínísítà fún ètò ààbò ilẹ̀ yìí, Bello Matawalle ti ṣe àlàyé bí ìjọba Tinubu kò ṣe fi ààyè gba àwọn agbésùnmọ̀mí lásìkò tirẹ̀ tó ṣe pé ó dojú ìjà gidi kọ wọ́n ni, Matawalle wí pé igba mẹ́rin ni àwọn agbésùnmọ̀mí tí àwọn ti pa lásìkò ìṣejọba Tinubu yìí.
Ó ṣe àlàyé pé àwọn agbékalẹ̀ titun tí ìṣejọba Tinubu gbé kalẹ̀ ni àwọn fi ń kojú àwọn agbésùnmọ̀mí tí àwọn sì ń mú wọn balẹ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé ìṣọwọ́ gbógun ti àwọn agbésùnmọ̀mí yìí tó ìdí tí a fi gbọdọ̀ dìbò yan ààrẹ Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027 kí ó le bá àwọn agbésùnmọ̀mí náà kanlẹ̀ pátápátá.
Mínísítà fún ètò ààbò wa wí pé àwọn ti ṣe àgbékalẹ̀ ikọ̀ tí ó ń gbógun ti àwọn ajínigbé tí wọ́n ń fi imú wọn danrin ní èyí tó mú kí ìjínigbé ó di ohun ìgbàgbé báyìí. Bákan náà ni ó wí pé àwọn àlàkalẹ̀ ààrẹ Tinubu lórí ètò ààbò yẹ ní ohun tí ó yẹ kó gba oríyìn fún nítorí pé yàtọ̀ sí àwọn agbésùnmọ̀mí ẹgbẹ̀rin tí àwọn ti pa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ìjà olóró ni àwọn ti rí gbà padà lọ́wọ́ wọn.
Matawalle gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé kí ẹ̀yin ọmọ Nàìjíríà ó dìbò yan Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027 kí ó le tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ rere.
A wá le sọ pé ìmúṣẹ ìlérí tí mínísítà fún ètò ààbò ṣe ni èyí tó ń ṣẹlẹ̀ yìí, ká sọ̀rọ̀ ká báa bẹ́ẹ̀ sì ni iyì ọmọ èèyàn. Á jẹ́ pé kí ìrètí wa nínú ìṣejọba ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ó di ọ̀tun ló kù báyìí.
Bí a ṣe ń kọ ìròyìn yìí lọ́wọ́ ni ìròyìn mìíràn tẹ̀ wá lọ́wọ́ nípa ọmọ ogun ilẹ̀ wa tí ó lọ sí òde ijó àmọ́ tí kò padà dé. Ohun tí a gbọ́ ni pé:
Ọmọ ogun ilẹ̀ wa kan tí ó lọ sí òde ijó tí àwọn obìnrin ti máa ń jó ní ìhòhò ni àwọn kan tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ IPOB ti yìnbọn pa lórú ọjọ́ Àbámẹ́ta mọ́jú ọjọ́ Àìkú tó kọjá yìí.
Àlàyé tí ilé iṣẹ́ ológun ṣe ni pé ọmọ ológun náà yọ́ jáde nínú ọgbà láì gba àṣẹ tó fi lọ sí ilé ijó ‘Ladies Jamboree’.
Aṣọ ológun rẹ̀ náà ni ó wọ̀ lọ sí ilé ijó yìí, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ IPOB dáa lọ́nà wọ́n sì yin ìbọn fún un. Nígbà tí àwọn ológun ẹgbẹ́ rẹ̀ kò ríi ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní wá a tí wọ́n sì kan òkú rẹ̀ àti ọmọ ìkókó kan nílẹ̀.
Wọ́n ti gbé òkú rẹ̀ lọ sí ilé ibùdó àwọn ológun báyìí ná.
Ìròyìn mìíràn to ń yọ eruku lala báyìí ni ti wòlíì kan tó gún àwọn ọmọ ìyá mẹ́rin lódó ní ìpínlẹ̀ Enugu. A gbọ́ pé:
Wòlíì ìjọ mímọ́ kan tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Igbo Eze ní ìpínlẹ̀ Enugu ni ọwọ́ ti tẹ̀ báyìí lẹ́yìn tó gún ọmọ ìyá mẹ́rin lódó. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kọ̀ láti fi orúkọ àti àwòrán wòlíì yìí léde fún ìdí tí kò hànde àmọ́ wọ́n fi dá wa lójú pé wòlíì yìí ti wà ní àhámọ́ àwọn báyìí.
Orúkọ àwọn ọmọ ìyá mẹ́rin náà ni Kamsiyochukwu Ezema; ọmọ ọdún méje, Ezinne Ezema; ọmọ ọdún mẹ́fà, Ujunwa Ezenma; ọmọ ọdún márùn-ún àti Chinedu Ezenma; ọmọ ọdún méjì. Ohun tó jọ mọ́ ọṣẹ gígún àmọ́ tí a kò le fìdí ẹ̀ múlẹ̀ dájú ni wòlíì yìí fi àwọn ọmọ náà ṣe àmọ́ ohun tó dájú ni pé ó gún àwọn ọmọ ìyá mẹ́rin náà nínú odó kan.
Nígbà tí wọ́n tú inú àwọn yàrá tó wà nínú ilé ìjọsìn náà, oríṣìí nǹkan ni wọ́n bá níbẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ odó ìbílẹ̀, igbá ọṣẹ lóríṣiríṣi, àwọn ohun ìwòsàn àti ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan tó níi ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí àìrí ló kún ibẹ̀ fọ́fọ́. Àwọn ọlọ́pàá ti gbé ilé ìjọsìn náà tì pa títí di ìgbà tí ìwádìí yóò parí.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Igbo Eze; Ọ̀gbẹ́ni Ferdinand Ukwueze banújẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó lọ sí ilé àwọn òbí ọmọ náà láti bá wọn kẹ́dùn. Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ti sọ pé wòlíì náà ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá, ìdájọ́ òdodo yóò sì wáyé lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Discussion about this post