Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno; Babangana Zulum ti sọ gudugbẹ ọ̀rọ̀ lónìí nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tó ṣe pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn News central. Ó fi ẹ̀sùn kan àwọn olóṣèlú pé àwọn ni wọ́n ń fún àwọn agbésùnmọ̀mí lọ́wọ́ tí wọ́n fi ń ṣe gbogbo àwọn ohun tí wọ́n ń ṣe náà.
Gómìnà Zulum wí pé kìí ṣe àwọn olóṣèlú nìkan ló ń fún àwọn agbésùnmọ̀mí lọ́wọ́, àwọn ológun náà ń fún wọn lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn aráàlú. A kò ní fi ààyè gba gbogbo pálapàla yìí mọ́ báyìí, ẹni tí a bá mú yóò jẹ iyán rẹ̀ níṣu. Bí ìjọba bá kò sí ọ̀rọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí, kò le tó oṣù mẹ́fà tí a ó fi rẹ́yìn wọn àmọ́ ìjọba ti ki òṣèlú bọ ọ̀rọ̀ náà – Zulum ló sọ bẹ́ẹ̀.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pe ‘ àwọn agbésùnmọ̀mí tí a ti mú tí wọ́n sì ti ronú pìwàdà ń ṣe dáadáa báyìí, wọn kò lọ́wọ́ nínú àwọn ìkọlù tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò yìí. Ó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn agbésùnmọ̀mí tí wọ́n ti ronú pìwàdà tí wọ́n sì ti di èèyàn ire láwùjọ. Gómìnà Zulum wí pé ‘ mo gbé oríyìn fún àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ wa lórí gbogbo akitiyan wọn láti kojú àwọn agbésùnmọ̀mí yìí àmọ́ ìjọba kò pèsè àwọn ohun ìjà tó kúnjú òṣùwọ̀n fún wọn ni wọn kò ṣe le ṣẹ́gun àwọn agbésùnmọ̀mí yìí.
Ààrẹ̀ Bola Ahmed Tinubu ní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ tí àwọn ń sọ fún un lórí bí ó ṣe le borí àwọn agbésùnmọ̀mí yìí, kò yẹ kí wọn ó ti òṣèlú bọ ọ̀rọ̀ àwọn tí wọ́n ń fi ẹ̀mí ṣòfò yìí. Gbogbo àwọn àlàkalẹ̀ tí a ń gbé síwájú ààrẹ ni ó ń fi ọwọ́ gbá dànù, Zulum wí pé àfi kí ààré Bola Ahmed Tinubu ó gbọ́ ti àwọn bí ó bá fẹ́ ṣẹ́gun àwọn agbésùnmọ̀mí.
Lórí ọ̀rọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí náà ni Gómìnà Zulum fi pàṣẹ kí gbogbo àwọn ará ìpínlẹ̀ Borno ó gba ààwẹ̀ ní ọjọ́ Ajé tó kọjá yìí kí wọn ó sì gba àdúrà ní kíkankíkan.
Ọjọ́ Àìkú ni Gómìnà Zulum kéde fún gbogbo àwọn ará Borno pé kí wọn ó gba ààwẹ̀ ní ọjọ́ Ajé kí wọn ó sì gba àdúrà sí Ọlọ́run kí ó bá wọn ṣẹ́gun àwọn agbésùnmọ̀mí.
Níbi ìkọlù tí wọ́n ṣe sí ìjọba ìbílẹ̀ Marte ni gọ́mìnà Zulum ti sọ ọ̀rọ̀ yìí. Ó wí pé ọ́dúnrún ìlú ni ó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Marte, ẹyọkan ṣoṣo ló kù tí àwọn agbésùnmọ̀mí ò tíì gbà lọ́wọ́ wọn. Gómìnà wí pé kí gbogbo wọn ó yáa bẹ̀rẹ̀ ààwẹ̀ àti àdúrà ní kíkankíkan kí Ọlọ́run ó bá wọn ṣẹ́gun àwọn agbésùnmọ̀mí.
Gbogbo àwọn ará ìlú ibi tí àwọn agbésùnmọ̀mí ti gbà yìí ni wọ́n ń sá lọ sí ìlú mìíràn ní èyí tó mú kí èrò ó pọ̀ jù ní àwọn ìlú tí wọ́n ń sá lọ náà. Gómìnà Zulum rọ̀ wọ́n láti padà sí ìlú wọn pé Ọlọ́run yóò ṣẹ́gun àwọn agbésùnmọ̀mí náà nípasẹ ààwẹ̀ àti àdúrà.
IPA ÀWỌN OLÓGUN LÓRÍ ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ.
Ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ yìí, ẹ̀ka àwọn jagunjagun ojú òfurufú ti kéde pé àwọn ti pa ọlọ́wọ́ ọ̀tún Bello Turji àti àwọn ẹmẹ̀wá rẹ̀ nínú ìkọlù tí àwọn ṣe sí ibùdó wọn.
Bello Turji ni ògbólògbó agbésùnmọ̀mí tó ń da ìpínlẹ̀ Sokoto, Zamfara àti Kastina láàmú, gbogbo àwọn ìkọlù tó nípọn tó ń wáyé ní Sokoto àti àwọn ìlú tó yíi ká kò ṣẹ̀yìn rẹ̀, ó ti pẹ́ tí àwọn ológun ti ń lépa Bello Turji tí wọn kò ríi mú.
Àmọ́ báyìí, ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn ti pa ọlọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Shaudo Alku pẹ̀lú àwọn ikọ̀ rẹ̀. Ìbùdó àwọn agbésùnmọ̀mí tó wà ní ìtòsí ilé ìwé ìjọba alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Tunfa tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Sokoto ni wọ́n ti ṣe ìkọlù sí wọn.
Shaudo Alku wá sí Sokoto láti ilẹ̀ Nìjéè wá ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn lọ́gàálọ́gàá agbésùnmọ̀mí pẹ̀lú àṣe Bello Turji. Shaudo ni ó máa ń kó àwọn ohun ìjà olóró wọlé fún Bello láti ilẹ̀ òkèrè.
Ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá àwọn agbésùnmọ̀mí yòókù tó na pápá bora. Wọ́n ní Shaudo tí àwọn pa yìí yóò da ètò àwọn agbésùnmọ̀mí náà rú wọn kò sì ní le rí àwọn ohun ìjà olóró lò mọ́ nítorí pé Shaudo náà ni ó máa ń kó wọn wọlé. Àṣeyọrí ńlá ni ikú Shaudo jẹ́ àmọ́ bí wọn ó bá rí àwọn agbésùnmọ̀mí náà mú délẹ̀, dandan ni kí orílẹ̀-ède Nìjéè àti Chad ó fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Nàìjíríà.
Àwọn ará Isa ní Sokoto fèsì sí èyí, wọ́n ní àwọn yóò tilẹ̀ ní ìsinmi lọ́wọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí pẹ̀lú ikú Shaudo yìí. Ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn kò ní sinmi lórí ọ̀rọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí.
Ẹ̀yin náà mọ̀ pé ìgbésùnmọ̀mí lápá kan, ìjínigbé lápá kejì ni ọ̀rọ̀ Nàìjíríà báyìí, odidi olórí ìlú kan ní Daura, ìpínlẹ̀ Kastina ni wọ́n ti rọ̀ lóyè báyìí lórí ẹ̀sùn pé ó jí obìnrin kan gbé, ó gba owó ìtúsílẹ̀ ó tún fi ipá bá a lò pọ̀. Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Emir ìlú Daura; Alhaji Faruq Faruq ti rọ baálẹ̀ ìlú Mantau lóyè lórí ẹ̀sùn pé ó fi ipá bá obìnrin kan lò pọ̀.
Àwọn ará ìlú ló fara ya lọ́sẹ̀ tó kọjá tí wọ́n sì ṣe ìwọ́de lórí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan baálẹ̀ wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Iliya Mantau pé ó jí obìnrin kan gbé ó sì fi ipá bá a ní àjọṣepọ̀.
Kìí ṣe pé ó jí Zulaihatu gbé nìkan o, ó gbé e pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ tó ń tọ́ lọ́wọ́ ó sì gba ogún mílíọ́nù náírà owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹbí rẹ̀ lẹ́yìn náà ló tún fi ipá bá a lò.
Ó ti lé lọ́dún kan tí ọ̀rọ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀ àmọ́ tí ìdájọ́ kankan kò wáyé lórí rẹ̀, ilé ẹjọ́ ń sún ìgbẹ́jọ́ síwájú láti ìgbà náà ni. Àwọn ọ̀dọ́ fárí gá lọ́sẹ̀ tó kọjá pé ó tó gẹ́, ìdájọ́ ni àwọn ń fẹ́ báyìí.
Ní èsì sí èyí, Emir ìlú Daura ti yọ baálẹ̀ náà lóyè títí ilé ẹjọ́ ó fi gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀.
Discussion about this post