Níbi ibùdó àwọn ọlọ́pàá tó wà ní Isuofia ní ìjọba ìbílẹ̀ Aguata ni ìkọlù náà ti wáyé. Alẹ́ àná Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹẹ̀dógún ni èyí ṣẹlẹ̀ ó sì ti da àlàáfíà agbègbè náà rú.
Àlàyé tí a rí gbà láti ẹnu adarí ìlú náà ni pé alẹ́ àná ni àwọn agbébọn náà dé lógúnlógún lọ́gbọ̀nlọ́gbọ̀n sí inú igbó kan tó wà ní ìtòsí ibùdó àwọn ọlọ́pàá náà.
Nígbà tí alẹ́ lẹ́ dáadáa, tọ́wọ́ pa tẹ́sẹ̀ pa ni wọ́n dáná ìbọn yá àwọn ọlọ́pàá ibùdó náà, àwọn ọlọ́pàá náà fi ìbọn dá wọn lóhùn. Ìkọlù náà pọ̀ débi pé àti ọlọ́pàá àti àgbébọn ló pàdánù ẹ̀mí wọn, a kò tíì le sọ pàtó iye àwọn tó kú nítorí wọ́n sì ń ṣa òkú kiri ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ìkọlù náà lé ní wákàtí kan kó tó dúró, kódà, àwọn agbébọn yòókù náà padà sá lọ ni nígbà tí ìbọn àwọn ọlọ́pàá ṣe ṣégè fún wọn.
Ìdí tí wọ́n fi ṣe ìkọlù náà kò yé ẹnìkankan lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí.
Lórí ọ̀rọ̀ ààbò yìí kan náà.
Àwọn ológun ilẹ̀ yìí ti ṣekú pa agbésùnmọ̀mí méjì ní ìpínlẹ̀ plateau. Àwọn ológun ilẹ̀ yìí gbógun ti àwọn agbésùnmọ̀mí ní ìpínlẹ̀ Plateau wọ́n sì pa méjì nínú wọn. Ikọ̀ àwọn ọmọ ogun Operation Safe Haven ni wọ́n kojú àwọn agbésùnmọ̀mí náà tí wọ́n sì mú méjì balẹ̀ nínú wọn. Agbègbè Nemaledu tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Wase ni wọ́n ti mú àwọn agbésùnmọ̀mí náà.
Lẹ́yìn tí wọ́n pa àwọn méjì náà, ìbọn mẹ́tàdínláàdọ́ta ni wọ́n rí gbà padà lọ́wọ́ wọn. Ikọ̀ Operation Safe Haven wí pé kò sí ààyè fún àwọn agbésùnmọ̀mí mọ́ báyìí.
Bóyá ká wá ní ìrètí nínú ikọ̀ ológun yìí ni báyìí nítorí ìṣọwọ́ tí àwọn agbésùnmọ̀mí fi ń dáná yá àwọn èèyàn kò dẹrùn rárá, wọ́n pa pa pa, wọ́n tún pa àwọn ọmọ ológun, bí ẹran ni wọ́n ṣe dú wọn kalẹ̀ lọ́sẹ̀ tí a wà yìí.
Èyí tí wọ́n ṣe ní Plateau yìí kan náà kò tíì tán nílẹ̀, àwọn èèyàn kò le gbàgbé ní kíákíá itú tí wọ́n fi wọ́n pa. ìròyìn ìkọlù náà kà báyìí pé òru ní nǹkan bíi aago méjìlá kọjá ni àwọn agbébọn ya wọ abúlé Zikke lógúnlógún lọ́gbọ̀nlọ́gbọ̀n. Wọ́n yìnbọn lákọlákọ, wọ́n dáná sun ọ̀pọ̀ ilé, wọ́n pa àwọn èèyàn bíi àádọ́ta wọ́n sì tún ṣe ogúnlọ́gọ̀ báṣubàṣu.
Ó lé ní wákàtí kan tí wọ́n fi ṣe ọṣẹ́ yìí láìsí ìdíwọ́ kankan.
Olórí ọ̀dọ́ abúlé Zikke, ẹni tó jẹ́ akọ̀wé ẹgbẹ́ Irigwe; Joseph Chudu bá ikọ̀ àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó wí pé wọ́n ti kó àwọn tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Jos, ipò wọn burú wọ́n sì nílò ẹ̀jẹ̀.
Chudu rọ ìjọba láti ṣe àtúnṣe sí ètò ààbò tó mẹ́hẹ yìí. Gbogbo akitiyan láti kàn sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Plateau kò so èso rere nípa pé agbẹnusọ wọn; Alabo Alfred kò gbé ìpè àwọn oníròyìn.
Ìkọlù yìí jẹ́ ọ̀tun lẹ́yìn gbogbo àwọn ìkọlù tó ti wáyé ní ìpínlẹ̀ Plateau lẹ́nu lọ́lọ́ yìí. Ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn ni wọ́n fẹ́rẹ̀ run gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ Bokko ní ìpínlẹ̀ Plateau yìí kan náà. Àádọ́ta èèyàn ni wọ́n pa lọ́sẹ̀ náà nìkan tí ọ̀pọ̀ dúkìá sì tún ṣòfò.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù tó ń wáyé sásá yìí ó sì rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò láti wá àwọn agbésùnmọ̀mí náà jáde.
Kọmíṣọ́nà fún ìfitónilétí; Joyce Renmap wí pé ìkọlù tó gba ìpínlẹ̀ Plateau kan yìí jẹ́ ohun tó bani lọ́kàn jẹ́. Joyce wí pé ogúnlọ́gọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n pa ní ìjọba ìbílẹ̀ Bokko àti Bassa láàrín ọ̀sẹ̀ méjì yìí.
Ọ̀rọ̀ Joyce tẹ̀síwájú pé ìlú tó kún fún ìfẹ́ àti àdùn tẹ́lẹ̀ ti paradà di ibi tó kún fún ìkorò àti ìbànújẹ́ látàrí ìkọlù ojoojúmọ́ yìí. Ó gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé kí àwọn èèyàn ó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba láti borí àdojúkọ yìí.
Wàyí o, àwọn ará abúlé bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ibi tí iná gbà jó wọn. Lancaster Akpa; ẹni ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta wí pé ẹbí òun mẹ́sàn-án ló bá ìkọlù náà lọ. Akpa wí pé Jos ni òun wà nígbà tí àbúrò òun pe òunp pé àwọn agbésùnmọ̀mí ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù, ó ní òun kò le sùn mọ́ lóru ọjọ́ náà, ìgbà tí òun pe aago rẹ̀ tí kò lọ mọ́ ni ara ti ń fu òun kó tó wá di pé òun dé bá òkú rẹ̀, ẹ̀gbọ́n òun àti àwọn ọmọ wọn méje.
Akpa wí pé àwọn tí wọ́n wá ṣe ìkọlù náà wọ aṣọ ológun àmọ́ Fulani ni wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun tí òun gbọ́.
Jerry Muwa náà sọ tirẹ̀, ó ní àwọn ọmọọmọ òun mẹ́fẹ́ẹ̀fà ni wọ́n dáná sun mọ́lé nígbà tí wọn kò rí ìlẹ̀kùn já. Ó ní òun rápálá jáde lóru ọjọ́ náà ni pẹ̀lú ọmọ òun tó jẹ́ bàbá àwọn ọmọ náà. Muwa wí pé àwọn ọmọ náà jóná di éérú débi pé kò sí ẹran tàbí eegun tí àwọn le sin, àwọn kan kó éérú wọn jọ sínú sàárè kan ni.
Ní báyìí tí àwọn ológun ti ṣetán àti kojú àwọn agbésùnmọ̀mí, ẹ jẹ́ ká fi àdúrà ràn wọ́n lọ́wọ́.
Ká sáré dé ilẹ̀ Amẹ́rìkà lọ́hùn-ún.
Gbajúgbajà olórin tàkasúfèé ilẹ̀ Amẹ́ríkà, ẹni tó ti fìgbà kan jẹ́ àfẹ́sọ́nà Rihana; Chris Brown ni ilé ẹjọ́ tó fìkàlẹ̀ sí UK ti pàṣẹ pé kó wà ní àtìmọ́lé di ọjọ́ kẹtàlá, oṣù tó ń bọ̀ tí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ yóò tẹ̀ síwájú.
Ẹ̀sùn tí Chris Brown ń jẹ́jọ́ rẹ̀ náà ni pé ó ṣe ìpalára fún olórin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Abe Diaw ní ọdún 2023. Àlàyé ẹ̀sùn náà ni pé Chris Brown fi ìgò ya Abe lára ní ilé ọtí kan tó wà ní London lálẹ́ ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù Èrèlé, ọdún 2023.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí Chris Brown yóò jẹ́jọ́ irú ìwà báyìí, ní ọdún 2009, ó lu àfẹ́sọ́nà rẹ̀; Rihanna lálùbami tí ìyẹn kò sì le lọ sí ìpéjọ ọlọ́dọọdún tó yẹ kó lọ.
Bákan náà ni pé ní ọdún 2012, Chris Brown ju ìgò mọ́ ojú Tony Parker, ojú náà kò ríran tààrà mọ́ di àsìkò yìí. Ọdun 2016 ni ó lu olólùfẹ́ rẹ̀ kan tó gbìyànjú àti sún mọ́ ọn ní Washington.
Obìrin kan fi ẹ̀sùn kàn án ní ọdún 2016 pé ó yọ ìbọn sí òun, obìnrin kan náà wí pé ó lu òun ní Las Vegas. Paríparí ẹ̀ ni ti obìnrin tó ní ó fipá bá òun lò ní ilé ìtura Luxury Paris.
Gbogbo àwọn ẹ̀sùn yìí ni Chris Brown ti mọ́rí bọ́ nínú rẹ̀ sẹ́yìn, bóyá yóò tún mórí bọ nínú ti ọ̀tẹ̀ yìí, a kò tíì le sọ, ó di ọjọ́ kẹtàlá, oṣù tó ń bọ̀.
Discussion about this post