Abdullai Ganduje; ẹni tó jẹ́ alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC sọ̀rọ̀ níbi ìgbaniwọlé Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta àti àwọn ẹmẹ̀wàá rẹ̀ tó wáyé lọ́jọ́ Ajé pé àwọn Gómìnà yòókù náà ṣì ń bọ̀ wá darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Igbákejì ààrẹ; Kashim Shettima ló gba Gómìnà Sherif Oborovwori àti àwọn ikọ̀ rẹ̀ wọlé sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, ó kí wọn káàbọ̀ ó sì ṣe wọ́n ní pẹ̀lẹ́.
Níbi ètò náà ni Gómìnà Sheriff ti ṣe àlàyé ìdí tí òun àti ikọ̀ rẹ̀ fi darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Ó wí pé ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìfẹ́ hàn sí àwọn ní ìpínlẹ̀ Delta, kò sì sí bí àwọn ṣe le fi ìfẹ́ náà padà bí àwọn bá wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ni àwọn ṣe darapọ̀ mọ́ ọn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ kí ìfẹ́ le máa lọ bó ti yẹ.
Gómìnà Sheriff wí pé òun kò ní ìgbàgbọ́ nínú Festus Keyamo àti àwọn ọmọ Agege yòókù, ó ní òun ni aṣáájú ìpínlẹ̀ Delta, ibi tí òun bá sì lọ ni àwọn yòókù ó lọ pẹ̀lú òun.
Gómìnà Sheriff rọ àwọn Gómìnà yòókù tí wọ́n wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Ọ̀rọ̀ Ganduje.
Bí éégún ẹni bá jóo re ni Ganduje fi ọ̀rọ̀ náà ṣe, ó lu Sheriff lọ́gọ enu fún ìgbésẹ̀ akin náà ó sì gbé oríyìn fún ààrẹ Bola Ahmed Tinubu pé ó jẹ́ aṣáájú rere.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ náà ló ti kí àwọn Gómìnà tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC fún akitiyan wọn nínú ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè yìí.
Ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni Gómìnà Sheriff kéde pé òun yóò darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lọ́sẹ̀ yìí tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ lóòótọ́.
A mú ìròyìn náà wá pé:
Gọ́mìnà ìpínlẹ̀ Delta; Sheriff Oborevwori ti kéde ìṣípòpadà rẹ̀ láti jíjẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sí ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Kìí ṣe Sheriff nìkan ló yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, bí ìgbín bá fà ni ó fi ọ̀rọ̀ náà ṣe, Gómìnà ìpínlẹ̀ Delta tẹ́lẹ̀rí; Ifeanyi Okowa àti gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Delta tó fi dé orí alága ìjọba ìbílẹ̀ ni wọ́n ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC báyìí.
Ìkéde yìí wáyé ní Ọjọ́rú, ọjọ́ kẹtalélógún, oṣù Igbe ní Asaba tíí ṣe olú ìlú Delta. Ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà nnì; James Manager ló fi ìkéde yìí síta lẹ́yìn ìpàdé oníwákàtí mẹ́fà tó wáyé ní ilé ìjọba tó wà ní Asaba.
Aṣòfin James wí pé gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Delta pátá ló ti gbà láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Tó fi dé orí agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ pátá tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, gbogbo wọn ló ti digbá dagbọ̀n wọn báyìí láti ré kété sínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC.
Kọmiṣọ́nà fún ìfitónilétí ní ìpínlẹ̀ Delta; Ọ̀gbẹ́ni Aniagwu Charles náà sọ̀rọ̀ lórí ìṣípòpadà yìí, ó wí pé àwọn kò le wà nínú ọkọ̀ tó ti rì, ó di dandan kí àwọn ó ṣe àtúnṣe sí ètò ìṣejọba àwọn ní èyí tó gba kí àwọn ó ṣe ìpinnu tó nípọn bẹ́ẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Charles wí pé ìpinnu yìí yóò jẹ́ kí iṣẹ́ rere ó le tẹ̀síwájú ní ìpínlẹ̀ Delta. Dídarapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC yóò mú kí ìdàgbàsókè àti ìlọsíwájú ó dé bá ìpínlẹ̀ Delta, ìgbé ayé àwọn ará Delta yóò di ọ̀tun, ìpínlẹ̀ Delta ó wá di ìpínlẹ̀ tí yóò ṣe máa mú yangàn láàrin àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀.
Ọ̀rọ̀ ọ̀gbẹ́ni Charles tẹ̀síwájú pé àwọn aṣáájú ló ṣe ìpinnu náà, ó sì di dandan kí gbogbo àwọn ìsọmọgbè ó tẹ̀lé e nítorí pé ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ Delta ló jẹ gbogbo àwọn lógún.
Ọjọ́ Ajé tó ń bọ̀ yìí ni gbogbo wọn ó di ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC lógidi. Kí a máa retí ìsọdọ̀tun ní ìpínlẹ̀ Delta ló kù báyìí.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn olóṣèlú máa kọ ẹgbẹ́ òṣèlú kan sílẹ̀ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn àmọ èyí kàmọ̀mọ̀, gbogbo ìlú lẹ́ẹ̀kan náà.
Ní báyìí tí gbogbo àwọn olóṣèlú ìpínlẹ̀ Delta ti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC, alága ẹgbẹ́ náà ti sọ pé gbogbo àwọn Gómìnà yòókù náà ń bọ̀ wá darapọ̀.
Ká tún ṣe ìrántí àwọn tí ọkọ̀ tẹ̀ pa ní ọjọ́ ọdún Àjínde ní ìpínlẹ̀ Gombe.
Ohun tí a gbọ́ ni pé bí àwọn èèyan náà ṣe ń sọ̀ kalẹ̀ láti orí òkè náà ni ọkọ̀ yìí já wọ àárín wọn tó sì tẹ àwọn mẹ́rin pa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí àwọn mẹ́jọ mìíràn di èrò ilé ìwòsàn.
Kíá ni àwọn èrò ti sọ iná sí ọkọ̀ àjàgbé yìí, àwọn ọlọ́pàá ló dá wọn lọ́wọ́ kọ́, wọn ò láwọn ò ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Òpópónà Billiri ní ìpínlẹ̀ Gombe ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀ láàárọ̀ òní ọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ ọdún àjíǹde. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Gombe bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn, ọ̀gbẹ́ni Buhari Abdullahi wí pé èèyàn mẹ́rin ló dèrò ọ̀run nínú ìkọlù náà nígbà tí àwọn mẹ́jọ mììràn farapa yánnayànna.
Ọkùnrin méjì àti obìnrin méjì ni àwọn tó kú náà, ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó Gombe tó wà ní Billiri náà ni wọ́n gbé àwọn tó farapa náà lọ.
Ẹ̀yìn ìgbà náà ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Gombe ṣe àbẹ̀wò sí wọn tó sì ṣe ìlérí mílíọ̀nù kan náírà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn tó di olóògbé.
Ohun tí a tún ń gbọ́ báyìí ni pé àwọn kan ti dìde tako Gómìnà lórí ohun tó ṣe yìí, wọ́n ṣe ìwọ́de pé ìdájọ́ òdodo làwọn fẹ́ lórí awakọ̀ ọkọ̀ àjàgbé náà, wọ́n ní àwọn kò fẹ́ kí wọ́n dáa sílẹ̀ bí Gómìnà ṣe sọ.
Discussion about this post