Ó lé ní ọgọ́rùn-ún àwọn agbésùnmọ̀mí tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn Bello Turji tó dágbére fáyé nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ Zamfara kóra jọ tí wọ́n sì ṣe ìkọlù sí ibùdó wọn.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé lọ́jọ́ Ajé, ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù yìí ni àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò náà kóra jọ láti ṣe ìkọlù sí ibùdó Bello Turji kí wọn ó le mú un lókú tàbí ààyè. Àmọ́ Bello Turji ti rí ẹni ta á lolóbó nípa èyí, ẹgbẹ̀rún àwọn agbésùnmọ̀mí ló kó wá sí ibùdó náà ní kíá mọ́sá, ìjà náà gbóná janjan láàárín àwọn méjéèjì, ìbọn ń ró lákọlákọ.
Àṣẹ̀yìnwá àṣẹ̀yìnbọ̀, ó lé ní ọgọ́rùn-ún àwọn omọlẹ́yìn Bello Turji tó kú nígbà tí àwọn ẹ̀ṣọ́ tó kú lé ní ogún.
A gbọ́ pé Bushari Meniyo; ẹni tó ti fìgbà kan jẹ́ agbésùnmọ̀mí àmọ́ tó ti ronú pìwàdà ló ṣaájú àwọn ẹ̀ṣọ́ ìbílẹ̀ náà láti lọ kojú Bello Turji. Bushari wà lára àwọn tó bá ogun náà lọ.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ náà wí pé àwọn ológun kò yọjú rárá fún gbogbo wákàtí tí àwọn fi jagun náà, wọ́n ní bí ó bá ṣe pé àwọn ológun wá ran àwọn lọ́wọ́ ni, àwọn kò bá rí Bello Turji pa lọ́jọ́ náà.
Gbogbo akitiyan láti kàn sí agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ológun; Suleimon Omale kò so èso rere látàrí pé kò gbé aago bẹ́ẹ̀ sì ni kò fèsì sí àtẹ̀jíṣẹ́ lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí.
Ọjọ́ kẹta ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni a gbọ́ pé Bello ránṣẹ́ ìdúnkokò sí àwọn ará Sokoto pé:
Bello Turji; ògbóǹtarìgì agbésùnmọ̀mí tó ń da àwọn ìpínlẹ̀ Sokoto, Taraba àti Zamfara láàmú ti ránṣẹ́ sí àwọn ará agbègbè Isa ní ìpínlẹ̀ Sokoto pé kí wọn ó kúrò ní ìlú wọn ní kíákíá kí wọn ó wábi gbà lọ.
Ó fi lée pé òun ń bọ̀ wá pa gbogbo wọn bí wọ́n bá kọ̀ tí wọn ò lọ.
Àwọn ará agbègbè yìí ti wá ké gbàjarè sí ìjọba pé kí ìjọba ó gba àwọn lọ́wọ́ Bello Turji yìí o, wọ́n ní ìdúnkokò yìí kò jọ àwàdà rárá, ohun tí yóò ṣe ló ti sọ yẹn o.
Abubakar Isa; ọ̀kan nínú àwọn ará àdúgbò náà wí pé ó ṣeni láàánú ò sì tún bani lọ́kàn jẹ́ àwọn àrè àtọ̀húnrìnwá ni wọ́n ń pàṣẹ fún àwọn onílùú pé kí àwọn ó kúrò ní ìlú àwọn.
Àwọn ará agbègbè náà ṣe àlàyé pé inú fu àyà fu ni àwọn wà láti ìgbà tí Bello Turji ti ránṣẹ́ náà nítorí pé ìgbàkúùgbà ni ó le dé bí ó ṣe sọ. Wọ́n ní àwọn ó le fi ilé àti ọ̀nà àwọn sílẹ̀ sá lọ fún àwọn àlejò tí wọ́n ń ṣe àwọn báṣubàṣu. Wọ́n wá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba láti gba àwọn kalẹ̀.
Ta ni Bello Turji?
Bello Turji ni olórí àwọn agbésùnmọ̀mí ẹ̀kun Zamfara, Sokoto, Kastina àti àwọn agbègbè. Ó ti sọ ara rẹ̀ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ọrùn àwọn ará ìpínlẹ̀ náà.
Gbogbo ìkọlù tó ń wáyé ní àwọn agbègbè yìí kò ṣẹ̀yìn rẹ̀. Bí ó kọjá ní àdúgbò náà lásán, òkú á sùn.
Ní ọdún ìtunu ààwẹ tó kọjá, Bello Turji àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ kí irun ọdún, nígbà tó ń padà sí ibùdó rẹ̀, gbogbo abúlé tó gbà kọjá ló ti ṣe ìkọlù, ó ní kí wọn ó le mọ̀ pé òun kọjá.
Ṣáájú àkókò yìí ni ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ wa ti jábọ̀ pé àwọn ti ṣekú pa ọlọ́wọ́ ọ̀tún Bello Turji. Àbọ̀ náà kà báyìí pé:
Ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn ti pa ọlọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Shaudo Alku pẹ̀lú àwọn ikọ̀ rẹ̀. Ìbùdó àwọn agbésùnmọ̀mí tó wà ní ìtòsí ilé ìwé ìjọba alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Tunfa tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Sokoto ni wọ́n ti ṣe ìkọlù sí wọn.
Shaudo Alku wá sí Sokoto láti ilẹ̀ Nìjéè wá ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn lọ́gàálọ́gàá agbésùnmọ̀mí pẹ̀lú àṣe Bello Turji. Shaudo ni ó máa ń kó àwọn ohun ìjà olóró wọlé fún Bello láti ilẹ̀ òkèrè.
Ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá àwọn agbésùnmọ̀mí yòókù tó na pápá bora. Wọ́n ní Shaudo tí àwọn pa yìí yóò da ètò àwọn agbésùnmọ̀mí náà rú wọn kò sì ní le rí àwọn ohun ìjà olóró lò mọ́ nítorí pé Shaudo náà ni ó máa ń kó wọn wọlé. Àṣeyọrí ńlá ni ikú Shaudo jẹ́ àmọ́ bí wọn ó bá rí àwọn agbésùnmọ̀mí náà mú délẹ̀, dandan ni kí orílẹ̀-ède Nìjéè àti Chad ó fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Nàìjíríà.
Àwọn ará Isa ní Sokoto fèsì sí èyí, wọ́n ní àwọn yóò tilẹ̀ ní ìsinmi lọ́wọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí pẹ̀lú ikú Shaudo yìí. Ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn kò ní sinmi lórí ọ̀rọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí.
Bíi ewé àgbọn ni ọ̀rọ̀ Bello Turji dà báyìí, ọlọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ tí wọ́n pa kò tu irun kankan lára rẹ̀, ojoojúmọ́ ló fi ń ṣe ìkọlù sí àwọn ará ìlú.
Àwọn ará agbègbè Isa tí wọ́n rò pé àwọn ti bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀ ló tún ti wà nínú hílàhílo báyìí.
Kò sí ìsinmi fún àwọn ará agbègbè tí Bello Turji ń dà láàmú, wọn ò le sùn kí wọn ó di ojú méjéèjì nítorí pé ìgbàkúùgbà ni Bello le wọ ìlú wá tí yóò sì pa wọ́n bé ẹran.
Gbogbo bí ó ṣe ń ṣe yìí ni ilé iṣẹ́ ológun ń fi àwọn rá ìlú lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn yóò mú un, ó ti lé ní ọdún mẹ́rin báyìí, ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ti bọ́.
Ní báyìí tó tilẹ̀ ti wa ránṣẹ́ sí àwọn ará Isa pé kí wọn ó fi ìlú wọn sílẹ̀, mú tó bạ wọn kò ṣe é ròyìn.




